ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/08 ojú ìwé 7
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kí Ayọ̀ àti Iyì Ọjọ́ Ìgbéyàwó Rẹ Pọ̀ Sí I
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Ìgbéyàwó Aláyọ̀ Tí Ń bọlá Fún Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ayẹyẹ Ìgbéyàwó Tí Ń Bọlá fún Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìgbéyàwó Tó Ní Ọlá Lójú Ọlọ́run Àti Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 11/08 ojú ìwé 7

Àpótí Ìbéèrè

◼ Bí tọkọtaya kan bá fẹ́ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ìgbéyàwó wọn, àwọn nǹkan wo ni wọ́n ní láti jíròrò pẹ̀lú àwọn alàgbà?

Bá a bá ṣètò ìgbéyàwó lọ́nà tó bá àwọn ìlànà Bíbélì mu, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún Jèhófà. Èyí tún wá ṣe pàtàkì gan-an tá a bá fẹ́ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ìgbéyàwó náà, torí pé ńṣe làwọn ará àdúgbò máa ń wo àwọn nǹkan tá à ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń ṣàgbéyọ ètò Ọlọ́run. Nítorí náà, “kí ohun gbogbo [lè] máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò,” ó dára káwọn alàgbà bá àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ìgbéyàwó sọ̀rọ̀.—1 Kọ́r. 14:40.

Káwọn tó bá fẹ́ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ìgbéyàwó kọ̀wé béèrè fún àyè, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Kí wọ́n tètè fi lẹ́tà yìí ránṣẹ́, kí wọ́n kọ ọjọ́ àti àkókò tí wọ́n fẹ́ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba náà síbẹ̀. Kí wọ́n fi sọ́kàn pé àwọn alàgbà ò ní yí àkókò ìpàdé kankan pa dà nítorí ayẹyẹ ìgbéyàwó. Síwájú sí i, ọkọ àti ìyàwó gbọ́dọ̀ ní ìdúró rere nínú ìjọ, wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwàhù kí wọ́n sì máa gbé níbàámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Jèhófà.

Láti rí i dájú pé ayẹyẹ ìgbéyàwó náà ṣàgbéyọ iyì Ọlọ́run, àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ jíròrò àwọn ètò tí wọ́n fẹ́ ṣe fún ìgbéyàwó náà pẹ̀lú ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn ìjọ kó tó di pé wọ́n parí àwọn ìmúrasílẹ̀ tí wọ́n ń ṣe. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà ò ní sọ fáwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó pé kí wọ́n fara mọ́ èrò àwọn tipátipá, tó bá lọ jẹ́ pé àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó ń ṣètò ohunkóhun tí kò bójú mu, wọ́n ní láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àtúnṣe táwọn alàgbà bá ṣe. Àwọn orin tó wà nínú ìwé orin wa nìkan la lè lò. Kí wọ́n gba àṣẹ lọ́dọ̀ àwọn alàgbà tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n fẹ́ ṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba náà lọ́ṣọ̀ọ́, tàbí pé wọ́n fẹ́ tún àwọn àga tó wà níbẹ̀ tò. Bí wọ́n bá fẹ́ ya fọ́tò tàbí pé wọ́n fẹ́ fídíò ayẹyẹ ìgbéyàwó náà, èyí kò gbọ́dọ̀ bu iyì ayẹyẹ náà kù. Bó bá jẹ́ pé ayàwòrán náà kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ojúṣe ọkọ ìyàwó ni láti sọ fún un pé kó múra dáadáa, lọ́nà tó máa fọ̀wọ̀ àti iyì fún ayẹyẹ náà. Àwọn alàgbà lè gbà wọ́n láyé láti lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún àwọn ìmúrasílẹ̀ tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìlò Gbọ̀ngàn Ìjọba, tí kò bá ṣáá ti dí àwọn ètò ìjọ lọ́wọ́. Ẹ má ṣe lẹ ìwé ìkésíni mọ́ ará pátákó ìsọfúnni o. Àmọ́, àwọn alàgbà lè ṣe ìfilọ̀ ṣókí ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn láti sọ fún ìjọ nípa ìgbéyàwó tó máa wáyé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe dandan kí gbogbo àwọn tó máa kópa nínú ayẹyẹ ìgbéyàwó náà jẹ́ àwọn tó ti ṣèrìbọmi, kò ní dáa pé kí wọ́n fi àwọn tí ìgbé ayé wọn kò bá àwọn ìlànà Bíbélì mu tàbí tí ìwà wọn lè gbé ìbéèrè dìde lọ́kàn àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà sínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn. Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, alàgbà ni kó bójú tó ayẹyẹ ìgbéyàwó náà. Àwọn alàgbà tóótun dáadáa nínú kíkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, torí náà, àwọn ló tóótun jù lọ láti sọ àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó yẹ kéèyàn lò níbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí.—1 Tím. 3:2.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tó bá ṣẹlẹ̀ níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà á kan alàgbà tó darí ètò ìgbéyàwó náà, ó ṣe pàtàkì pé káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó sọ àwọn ètò tí wọ́n ti ṣe fún alàgbà náà ṣáájú àkókò. Alàgbà náà á wá béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó náà bóyá wọ́n ti hùwà àìmọ́ èyíkéyìí nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra wọn sọ́nà; wọn ò gbọ́dọ̀ fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, wọ́n sì gbọ́dọ̀ sòótọ́ fún alàgbà náà. Bó bá jẹ́ pé ọkọ tàbí aya ti ṣègbéyàwó rí, wọ́n gbọ́dọ̀ pèsè ẹ̀rí pé àwọn lómìnira láti fẹ́ ẹlòmíì lọ́nà tó bá òfin ìjọba àti ìlànà Ìwé Mímọ́ mu. (Mát. 19:9) Èyí á gba pé kí wọ́n fi ìwé àṣẹ ìkọ̀sílẹ̀ han alàgbà náà.

Bí tọkọtaya náà ò bá fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ tí wọ́n sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà, ayẹyẹ ìgbéyàwó náà á lárinrin.—Òwe 15:22; Héb. 13:17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́