ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 10/15 ojú ìwé 28-31
  • Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kí Ayọ̀ àti Iyì Ọjọ́ Ìgbéyàwó Rẹ Pọ̀ Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kí Ayọ̀ àti Iyì Ọjọ́ Ìgbéyàwó Rẹ Pọ̀ Sí I
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ló Yẹ Kó Pinnu Ohun Tó Máa Wáyé Níbi Ìgbéyàwó?
  • Bí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Bá Wà, Ayọ̀ Ayẹyẹ Náà Á Pọ̀ Sí I
  • Ó Yẹ Kí Aṣọ àti Ìmúra Wa Buyì Kúnni
  • Gbọ̀ngàn Ìjọba Jẹ́ Ibi Ọ̀wọ̀
  • Ayọ̀ Tí Kò Mọ sí Ọjọ́ Ìgbéyàwó
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • “Ọjọ́ Tó Dùn Jù Lọ Nínú Ìgbésí Ayé Wa”
    Jí!—2002
  • Ayẹyẹ Ìgbéyàwó Tí Ń Bọlá fún Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àwọn Ìgbéyàwó Aláyọ̀ Tí Ń bọlá Fún Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 10/15 ojú ìwé 28-31

Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kí Ayọ̀ àti Iyì Ọjọ́ Ìgbéyàwó Rẹ Pọ̀ Sí I

ARÁKÙNRIN Gordon tó ṣègbéyàwó ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn sọ pé: “Ọjọ́ ìgbéyàwó mi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọjọ́ tó ṣe pàtàkì fún mi tínú mi sì dùn jù lọ láyé mi.” Kí nìdí tí ọjọ́ ìgbéyàwó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ fáwọn Kristẹni tòótọ́? Ìdí ni pé ọjọ́ náà ni wọ́n jẹ́ ẹ̀jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fẹ́ràn tọkàntọkàn, ìyẹn ọkọ tàbí aya wọn àti Jèhófà Ọlọ́run. (Mátíù 22:37; Éfésù 5:22-29) Kò sí àní-àní pé àwọn tó bá ń múra ìgbéyàwó yóò fẹ́ kí ọjọ́ náà dùn gan-an, àmọ́ ó yẹ kí wọ́n tún bọlá fún Ẹni tó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24; Mátíù 19:5, 6.

Báwo ni ọkọ ìyàwó ṣe lè mú kí ayẹyẹ aláyọ̀ yìí túbọ̀ níyì sí i? Kí ni ìyàwó lè ṣe láti fi hàn pé òun bọlá fún ọkọ òun àti fún Jèhófà? Báwo làwọn tó wá síbi ìgbéyàwó náà ṣe lè mú kí ayọ̀ ọjọ́ náà pọ̀ sí i? Tá a bá gbé àwọn ìlànà Bíbélì kan yẹ̀ wò, a ó mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Tá a bá sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà, kò ní fi bẹ́ẹ̀ sáwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó dín iyì ayẹyẹ pàtàkì náà kù.

Ta Ló Yẹ Kó Pinnu Ohun Tó Máa Wáyé Níbi Ìgbéyàwó?

Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìjọba yọ̀ǹda kí òjíṣẹ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà so ọkùnrin àti obìnrin pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya. Àní láwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ pé aṣojú ìjọba ló máa ń so àwọn méjì tó fẹ́ra wọn pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya pàápàá, àwọn tó ṣègbéyàwó náà ṣì lè fẹ́ gbọ́ àsọyé tó dá lórí Bíbélì. Ẹni tó ń sọ àsọyé náà sábà máa ń sọ fún ọkọ ìyàwó náà pé kó ronú jinlẹ̀ lórí ojúṣe tí Ọlọ́run yàn fún un gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Nítorí náà, ọkọ ìyàwó ló yẹ kó pinnu ohun tó máa wáyé níbi ìgbéyàwó. Kò sí àní-àní pé àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó ti máa ń múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó wọn tipẹ́tipẹ́ ṣáájú, títí kan àpèjẹ tó máa wáyé. Kí nìdí tí kì í fi í rọrùn fún ọkọ ìyàwó láti ṣe àwọn ètò yìí?

Ọ̀kan lára ìdí náà ni pé àwọn mọ̀lẹ́bí lọ́tùn-ún lósì tàbí ìyàwó gan-an lè fẹ́ gba gbogbo ètò ìgbéyàwó náà kanrí. Arákùnrin Rodolfo tó ti so ọ̀pọ̀ tọkọtaya pọ̀, sọ pé: “Nígbà míì, ńṣe làwọn ẹbí máa ń fẹ́ darí ọkọ ìyàwó, pàápàá tó bá jẹ́ pé àwọn ló máa gbé ẹrú ìnáwó àpèjẹ ìgbéyàwó. Wọ́n lè fẹ́ máa pàṣẹ ohun táwọn fẹ́ kó wáyé níbi ìgbéyàwó àti níbi àpèjẹ. Èyí lè máà jẹ́ kí ọkọ ìyàwó náà lè ṣe ojúṣe tí Ìwé Mímọ́ yàn fún un bó ṣe yẹ, ìyẹn ni pé kó pinnu ohun tó máa wáyé níbi ayẹyẹ náà.”

Arákùnrin Max tó ti ń so àwọn èèyàn pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya láti ohun tó lé ní ọdún márùndínlógójì sẹ́yìn, sọ pé: “Mo ṣàkíyèsí pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí ni pé ìyàwó ló máa ń sábà sọ bí ayẹyẹ ìgbéyàwó àti àpèjẹ náà ṣe máa lọ, tí ọkọ ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ lẹ́nu ọ̀rọ̀.” Arákùnrin David tóun náà ti so ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya sọ pé: “Ó lè máa tíì mọ́ àwọn ọkọ ìyàwó lára láti máa ṣe kòkárí ètò, wọn kì í sì í sábà kópa nínú ètò ìmúrasílẹ̀ ìgbéyàwó tó bó ṣe yẹ.” Báwo ni ọkọ ìyàwó ṣe lè ṣe ojúṣe rẹ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ?

Bí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Bá Wà, Ayọ̀ Ayẹyẹ Náà Á Pọ̀ Sí I

Kí ọkọ tó lè ṣe ojúṣe rẹ̀ dáadáa bí wọ́n ṣe ń múra ìgbéyàwó náà, ó ní láti rí i pé òun bá àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn jíròrò bí ètò náà yóò ṣe lọ sí. Bíbélì ti sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà nígbà to sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” (Òwe 15:22) Àmọ́, kò ní fi bẹ́ẹ̀ sí ìjákulẹ̀ bí ọkọ ìyàwó bá kọ́kọ́ bá ìyàwó rẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ẹlòmíràn tó lè fún wọn nímọ̀ràn tó yè kooro látinú Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìmúrasílẹ̀ ìgbéyàwó náà.

Dájúdájú, ó ṣe pàtàkì kí àwọn àfẹ́sọ́nà náà kọ́kọ́ jọ jíròrò nípa bí ètò náà á ṣe lọ sí àtàwọn ohun tó ṣeé ṣe kó wáyé níbẹ̀. Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Ivan àti Delwyn yẹ̀ wò. Tọkọtaya yìí ti ń fi tayọ̀tayọ̀ gbé pọ̀ láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra. Nígbà tí Ivan tó jẹ́ ọkọ ń sọ̀rọ̀ nípa ètò tí wọ́n ṣe ṣáájú ìgbéyàwó wọn, ó ní: “Mo ti fọkàn yàwòrán irú ayẹyẹ ìgbéyàwó tí mò ń fẹ́. Mo wò ó pé àá ṣe àpèjẹ fún gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi, àá ṣe kéèkì, ìyàwó mi á sì wọ aṣọ funfun. Àmọ́ ọ̀tọ̀ lohun tó wà lọ́kàn ìyàwó mi ní tiẹ̀. Kò fẹ́ ká pariwo rárá, bẹ́ẹ̀ ni kò fẹ́ ká ṣe kéèkì. Àní, ó tiẹ̀ ń rò ó pé bóyá lòun máa wọ aṣọ funfun pàápàá.”

Kí ni tọkọtaya yìí ṣe nípa èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ní yìí? Ńṣe ni wọ́n jọ sọ ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí-ìnùbí. (Òwe 12:18) Ivan sọ pé: “A gbé àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó yẹ̀ wò, irú bí èyí tó wà nínú Ile-Iṣọ Naa ti October 15, 1984.a Ohun tá a kà níbẹ̀ jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi wo ayẹyẹ yìí. Níwọ̀n bí àṣà ìbílẹ̀ wa ti yàtọ̀ síra, ńṣe làwa méjèèjì jọ fẹnu kò lórí èyí tá a máa ṣe nínú gbogbo ohun tó wu kálukú wa pé ká ṣe.”

Irú ohun tí Aret àti Penny náà ṣe nìyẹn. Nígbà tí Aret ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìgbéyàwó wọn, ó ní: “Èmi àti Penny ìyàwó mi jíròrò nípa bí kálukú ṣe fẹ́ kí ìgbéyàwó náà rí, a sì jọ fẹnu kò lórí èyí tá a máa ṣe. A gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí gbogbo ètò ọjọ́ náà yọrí sí rere. Mo tún fọ̀rọ̀ lọ àwọn òbí wa àtàwọn tọkọtaya míì tí wọ́n dàgbà dénú nínú ìjọ wa. Ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa wúlò gan-an ni. Gbogbo èyí jẹ́ kí ìgbéyàwó wa dùn, kó sì lárinrin.”

Ó Yẹ Kí Aṣọ àti Ìmúra Wa Buyì Kúnni

A mọ̀ pé àtọkọ àtìyàwó ló máa fẹ́ múra lọ́nà tó gbayì gan-an lọ́jọ́ nǹkan ẹ̀yẹ wọn. (Sáàmù 45:8-15) Wọ́n lè náwó nára, kí wọ́n sì ṣe wàhálà púpọ̀ láti wá irú aṣọ tó yẹ kí wọ́n lò lọ́jọ́ náà. Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè jẹ́ kí wọ́n mọ irú aṣọ tó buyì kúnni tó sì fani mọ́ra?

Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ohun tí ìyàwó máa wọ̀ lọ́jọ́ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ lọ̀rọ̀ aṣọ, ohun tí wọ́n ń ṣe lórílẹ̀-èdè kan sì yàtọ̀ sí ti orílẹ̀-èdè mìíràn, ibi gbogbo ni ìmọ̀ràn Bíbélì ti wúlò. Àwọn obìnrin ní láti “máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.” Gbogbo ìgbà ló yẹ káwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni máa fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn, àní títí kan ọjọ́ ìgbéyàwó wọn pàápàá. Kókó ibẹ̀ ni pé kò pọn dandan kéèyàn lo ‘aṣọ olówó ńlá’ kí ìgbéyàwó rẹ̀ tó lè dùn. (1 Tímótì 2:9; 1 Pétérù 3:3, 4) Á mà dára gan-an o bí ìyàwó bá lè fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn!

Arákùnrin David tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó máa ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, ó sì yẹ ká gbóríyìn fún wọn. Àmọ́ o, a ti rí ibi tí ìyàwó àti ọ̀rẹ́ ìyàwó ti wọṣọ tí kò bójú mu, irú bí aṣọ tí kò bo àyà dáadáa tàbí aṣọ tó ń fi ara hàn.” Nígbà tí alàgbà kan tó dàgbà dénú ń bá àwọn kan tó fẹ́ ṣègbéyàwó sọ̀rọ̀ ṣáájú ọjọ́ ìgbéyàwó wọn, ó sọ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n ronú nípa irú aṣọ tó yẹ kí Kristẹni wọ̀. Báwo ló ṣe ṣe é? Ńṣe ló béèrè lọ́wọ́ wọn bóyá aṣọ tí wọ́n fẹ́ wọ̀ lọ́jọ́ náà bójú mu tó èyí tí wọ́n lè wọ̀ lọ sípàdé ìjọ. Òótọ́ ni pé aṣọ téèyàn máa wọ̀ lọ́jọ́ náà lè yàtọ̀ sí irú èyí téèyàn máa ń wọ̀ lọ sí ìpàdé ìjọ, ó sì lè bá bí wọ́n ṣe ń wọṣọ ládùúgbò ẹni mu, síbẹ̀ ó yẹ kí aṣọ náà bójú mu, kó jẹ́ irú èyí tó yẹ Kristẹni. Bí àwọn èèyàn ayé kan bá tiẹ̀ ń sọ pé ìlànà Bíbélì nípa irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù ti le jù, kò yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́ kí ayé sọ wọ́n dà bó ṣe dà.—Róòmù 12:2; 1 Pétérù 4:4.

Arábìnrin Penny sọ pé: “Kì í ṣe aṣọ tá a máa wọ̀ àti àpèjẹ ìgbéyàwó wa ni èmi àti Aret ọkọ mi ká sí pàtàkì jù. Ṣùgbọ́n, bí ìgbéyàwó náà ṣe rí lójú Ọlọ́run ló jẹ wá lọ́kàn jù. Ìyẹn ló ṣe pàtàkì jù lọ́jọ́ náà. Kì í ṣe aṣọ tí mo wọ̀ tàbí oúnjẹ tí mo jẹ lohun pàtàkì tí mo rántí, bí kò ṣe ìfararora tí mo ní pẹ̀lú àwọn tó wá síbẹ̀ lọ́jọ́ náà àti ìdùnnú tí mo ní pé ẹni tí ọkàn mi yàn ni mo fẹ́.” Ó yẹ káwọn Kristẹni tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó fi àwọn kókó pàtàkì wọ̀nyí sọ́kàn bí wọ́n ṣe ń múra ìgbéyàwó wọn.

Gbọ̀ngàn Ìjọba Jẹ́ Ibi Ọ̀wọ̀

Gbọ̀ngàn Ìjọba ni ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ti máa ń fẹ́ ṣègbéyàwó wọn, bó bá ṣeé ṣe. Kí ló mú kó wù wọ́n? Àwọn kan sọ ohun tó mú kó wu àwọn láti lo Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n ní: “A mọ̀ pé ìgbéyàwó jẹ́ ètò pàtàkì tí Jèhófà dá sílẹ̀. Ṣíṣe ìgbéyàwó wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó jẹ́ ibi ìjọsìn Ọlọ́run jẹ́ ká túbọ̀ fi í sọ́kàn látìbẹ̀rẹ̀ pé Jèhófà ní láti wà nínú ìgbéyàwó wa. Àǹfààní mìíràn tó wà nínú ṣíṣègbéyàwó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba dípò ibòmíràn ni pé, yóò jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wá síbi ìgbéyàwó náà mọ̀ pé a ò fọ̀rọ̀ ìjọsìn Ọlọ́run ṣeré.”

Bí àwọn alàgbà ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba náà bá fún àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó láyè láti ṣe é níbẹ̀, àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó ní láti sọ irú ìmúrasílẹ̀ tí wọ́n ń ṣe tó jẹ mọ ìlò gbọ̀ngàn náà fáwọn alàgbà náà ṣáájú. Ọ̀nà kan tí ọkọ àti ìyàwó lè gbà fi hàn pé àwọn ka àwọn tí wọ́n pè wá síbi ìgbéyàwó wọn kún ni pé kí wọ́n rí i dájú pé àwọn dé lákòókò. Ó sì yẹ kí wọ́n rí i dájú pé wọ́n ṣe gbogbo nǹkan lọ́nà tó buyì kúnni.b (1 Kọ́ríńtì 14:40) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tí kò bójú mu tí wọ́n máa ń ṣe níbi ìgbéyàwó àwọn èèyàn ayé kò ní wáyé níbi ìgbéyàwó wọn.—1 Jòhánù 2:15, 16.

Àwọn tó bá wá síbi ìgbéyàwó náà pẹ̀lú lè jẹ́ kó hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ìgbéyàwó làwọn náà fi ń wò ó. Bí àpẹẹrẹ, wọn ò ní máa retí pé kí ìgbéyàwó náà ta yọ àwọn ìgbéyàwó mìíràn táwọn Kristẹni kan ṣe, bí ẹni pé ńṣe làwọn tó ń ṣègbéyàwó ń bára wọn díje láti mọ ẹni tí ìgbéyàwó tiẹ̀ fakíki jù. Àwọn Kristẹni tí wọ́n dàgbà dénú tún mọ̀ pé kéèyàn lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba láti lọ gbọ́ àsọyé ìgbéyàwó tó dá lórí Bíbélì ló ṣe pàtàkì jù, òun ló sì máa ṣeni láǹfààní ju lílọ síbi àpèjẹ ìgbéyàwó tàbí àpèjẹ míì tó bá wáyé lẹ́yìn ìyẹn. Bó bá jẹ́ pé ọ̀kan lèèyàn máa lè lọ nínú méjèèjì, kò sí àní-àní pé Gbọ̀ngàn Ìjọba ló máa dáa jù kéèyàn lọ. Alàgbà kan tó ń jẹ́ William sọ pé: “Bí àwọn tí wọ́n pè ò bá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba láìsí ìdí kan tó ṣe gúnmọ́, tí wọ́n wá lọ síbi àpèjẹ lẹ́yìn ìyẹn, èyí á fi hàn pé wọn ò mọyì jíjẹ́ tí ìgbéyàwó jẹ́ ohun mímọ́ nìyẹn. Àní bí wọn ò bá tiẹ̀ pè wá síbi àpèjẹ pàápàá,c tó bá jẹ́ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba la lọ, yóò fi hàn pé a yẹ́ ọkọ àti ìyàwó sí, èyí á sì jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí rí i pé a ò fọ̀rọ̀ ìjọsìn wa ṣeré.”

Ayọ̀ Tí Kò Mọ sí Ọjọ́ Ìgbéyàwó

Àwọn oníṣòwò ti sọ ayẹyẹ ìgbéyàwó di ìjẹ, èyí tí wọ́n á fi máa pa òbítíbitì owó. Ìròyìn kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé, nílẹ̀ Amẹ́ríkà, “ẹgbẹ̀rún méjìlélógún dọ́là [nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta náírà] tàbí ìdajì iye owó tó ń wọlé fún ìdílé kọ̀ọ̀kan [lọ́dọọdún] ní Amẹ́ríkà làwọn tó ń ṣègbéyàwó ń ná.” Ìpolówó ọjà táwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn ń rí ló máa ń jẹ́ kí wọ́n tọrùn bọ gbèsè tí wọ́n á máa san fún ọ̀pọ̀ ọdún nítorí ayẹyẹ ọjọ́ kan ṣoṣo. Ǹjẹ́ ó mọ́gbọ́n dání kéèyàn fi gbèsè bẹ̀rẹ̀ ìgbéyàwó rẹ̀? Àwọn tí kò bá mọ ìlànà Bíbélì tàbí tí ìlànà náà kò bá jọ lójú lè fẹ́ ṣe irú ṣekárími bẹ́ẹ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá o láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́!

Ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tí wọ́n ṣègbéyàwó wọn ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí wọ́n ṣe ohun tí agbára wọn gbé, tí wọ́n sì tún rí i pé nǹkan tẹ̀mí ló jẹ wọ́n lógún nígbà ìgbéyàwó náà ti láǹfààní láti lo àkókò àti ohun ìní wọn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wọn sí Ọlọ́run. (Mátíù 6:33) Wo àpẹẹrẹ Lloyd àti Alexandra tí wọ́n ti lo ọdún mẹ́tàdínlógún nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún látìgbà tí wọ́n ti ṣègbéyàwó. Lloyd sọ pé: “Àwọn kan lè sọ pé ayẹyẹ ìgbéyàwó wa ti ṣe ráńpẹ́ jù, ṣùgbọ́n inú èmi àti Alexandra dùn gan-an. A wò ó pé kò yẹ ká jẹ́ kí ìnáwó ìgbéyàwó wa pa wá lára, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló yẹ kí ìgbéyàwó wa jẹ́ ayẹyẹ ètò tí Jèhófà ṣe, èyí tó máa fún àwọn méjì tí wọ́n fẹ́ra wọn ní ayọ̀ ńlá.”

Alexandra fi kún un pé: “Mo ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ká tó ṣègbéyàwó, mi ò fẹ́ tìtorí kí ìgbéyàwó lè fakíki pàdánù àǹfààní ńlá yìí. Ọjọ́ pàtàkì lọjọ́ ìgbéyàwó wa. Àmọ́, ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tí àwa méjèèjì yóò jọ máa gbé títí ayé ló wulẹ̀ jẹ́. A tẹ̀ lé ìmọ̀ràn pàtàkì tí ètò Ọlọ́run fún wa pé kò yẹ ká jẹ́ kí ohun tá a máa ṣe ní ọjọ́ ìgbéyàwó náà gbà wá lọ́kàn jù, a sì wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà tó máa ṣe wá láǹfààní lẹ́yìn ọjọ́ ìgbéyàwó wa. Èyí ti mú kí Jèhófà bù kún wa.”d

Dájúdájú, ọjọ́ pàtàkì ni ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ. Ìwà àti ìṣe rẹ lọ́jọ́ náà lè jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí yóò máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tẹ́ ẹ bá ti di tọkọtaya. Nítorí náà, ẹ gbára lé Jèhófà kó lè tọ́ yín sọ́nà. (Òwe 3:5, 6) Ojú tí Jèhófà fi wo ìgbéyàwó náà ló yẹ kẹ́ ẹ fi sọ́kàn jù. Ẹ dúró ti ara yín kẹ́ ẹ lè ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run yàn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ ó lè fi ìpìlẹ̀ tó lágbára lélẹ̀ fún ìgbéyàwó yín. Yàtọ̀ síyẹn, pẹ̀lú ìbùkún Jèhófà, ẹ ó lè ní ayọ̀ tí kò ní mọ sí ọjọ́ ìgbéyàwó yín nìkan.—Òwe 18:22.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, wo ìwé ìròyìn Jí! ti February 8, 2002. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́.

b Bí àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó bá fẹ́ káwọn onífọ́tò àtàwọn tó ń lo kámẹ́rà fídíò ya àwọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n ní láti rí i dájú ṣáájú àkókò pé wọn ò ní ṣe ohunkóhun tó máa bu iyì ayẹyẹ náà kù.

c Ní àwọn ilẹ̀ kan, wọ́n lè pe àwọn kan sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, àmọ́ kí wọ́n má pè wọ́n sí ibi àpèjẹ. Tá a bá lọ gbọ́ àsọyé ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, yóò fi hàn pé a yẹ́ ọkọ àti ìyàwó sí, á sì tún fi hàn pé a mọrírì àsọyé tó dá lórí Ìwé Mímọ́ tí wọ́n máa sọ níbẹ̀.

d Wo ojú ìwé 26 nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Nígbà táwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó bá ń múra sílẹ̀, ó yẹ kí wọ́n jọ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, kí wọn sì ṣe èyí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ojú tí Jèhófà fi wo ìgbéyàwó náà ló yẹ kẹ́ ẹ fi sọ́kàn jù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́