Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
Kárí ayé, àìmọye èèyàn ló ní àárẹ̀ ọpọlọ. Ìṣòro yìí ò mọ ọmọdé bẹ́ẹ̀ ni kò mọ àgbà, kò mọ olówó bẹ́ẹ̀ ni kò mọ tálákà. Bákan náà, kò sí ẹ̀yà tàbí àwọn ẹlẹ́sìn kan tí wọn ò lè níṣòro yìí. Kí ni àárẹ́ ọpọlọ? Báwo la ṣe lè mọ̀ tẹ́nì kan bá ní àárẹ̀ ọpọlọ? Ìwé yìí sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn tó níṣòro yìí gba ìtọ́jú tó yẹ, ó sì tún sọ àwọn ọ̀nà pàtàkì tí Bíbélì lè gbà ran àwọn tó ní àárẹ̀ ọpọlọ lọ́wọ́.