ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 January ojú ìwé 19
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fílípì Batisí Ìjòyè Òṣìṣẹ́ Ará Etiópíà kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Fílípì Kéde “Ìhìn Rere Nípa Jésù”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Fílípì—Ajíhìnrere Tó Nítara
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • A Nílò Ìrànlọ́wọ́ Láti Lóye Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 January ojú ìwé 19
Fílípì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ará Etiópíà, ó ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún ọkùnrin náà. Àwọn méjèèjì wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tí ẹnì kan ń fi ẹṣin darí.

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Irú ohun ìrìnnà wo ni ìjòyè Etiópíà wà nínú ẹ̀ nígbà tí Fílípì lọ bá a?

OHUN ìrìnnà tí wọ́n pè ní “kẹ̀kẹ́ ẹṣin” nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun ìrìnnà ìgbà yẹn. (Ìṣe 8:28, 29, 38) Àmọ́, ó jọ pé ohun ìrìnnà tí ìjòyè Etiópíà wà nínú ẹ̀ tóbi ju kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí àwọn ológun ń lò tàbí èyí tí àwọn sárésáré ń lò. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.

Ìjòyè onípò gíga ni ará Etiópíà náà, ó sì ti rìnrìn àjò tó jìnnà gan-an. Òun ni “ọkùnrin tó wà nípò àṣẹ lábẹ́ Káńdésì ọbabìnrin àwọn ará Etiópíà, òun ló ń bójú tó gbogbo ìṣúra rẹ̀.” (Ìṣe 8:27) Orílẹ̀-èdè Sudan àti apá gúúsù orílẹ̀-èdè Íjíbítì òde òní wà lára Etiópíà àtijọ́. Ó lè má jẹ́ inú kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan náà ni ìjòyè yẹn jókòó sí jálẹ̀ ìrìn àjò yìí, ó hàn gbangba pé gbogbo àwọn ẹrù tó máa lò nígbà ìrìn àjò yìí ló wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà. Kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tó nílé lórí wà lára àwọn ohun ìrìnnà tí wọ́n fi ń kó èrò nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Ìwé Acts—An Exegetical Commentary sọ pé: “Irú kẹ̀kẹ́ yìí máa ń gba ẹrù tó pọ̀, ó ń jẹ́ kéèyàn gbádùn ìrìn àjò ẹ̀, ó sì ń jẹ́ kéèyàn lè rin ọ̀nà tó jìn.”

Ará Etiópíà náà ń kàwé nígbà tí Fílípì lọ bá a. Bíbélì sọ pé “Fílípì sáré lọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ó sì gbọ́ tí [ìjòyè náà] ń ka ìwé wòlíì Àìsáyà sókè.” (Ìṣe 8:30) Wọn ò ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí wọ́n fi ń rìnrìn àjò kó lè máa sáré. Torí náà, bí kẹ̀kẹ́ ẹṣin yìí ṣe rọra ń lọ máa jẹ́ kí ìjòyè náà lè máa kàwé nínú ẹ̀, á sì tún jẹ́ kí Fílípì lè fẹsẹ̀ lé kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà bá.

Ará Etiópíà náà “rọ Fílípì pé kó gòkè, kó sì jókòó pẹ̀lú òun.” (Ìṣe 8:31) Nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin táwọn sárésáré máa ń lò, ńṣe lẹni tó gùn ún máa ń dúró. Àmọ́, nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí wọ́n fi ń rìnrìn àjò, àyè máa ń wà níbẹ̀, ìjòyè náà àti Fílípì sì lè jókòó síbẹ̀.

Torí náà, ohun tí Bíbélì sọ nínú Ìṣe orí kẹjọ àti ohun tí ìtàn sọ ló jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwòrán ìjòyè Etiópíà láìpẹ́ yìí sínú àwọn ìwé wa lọ́nà tó fi hàn pé ó wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó tóbi ju èyí táwọn ológun tàbí àwọn sárésáré ń lò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́