ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 June ojú ìwé 32
  • Ṣé O Nígbàgbọ́ Tó Lágbára?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé O Nígbàgbọ́ Tó Lágbára?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìgbàgbọ́—Ànímọ́ Tó Ń Sọni Di Alágbára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Lo Igbagbọ Ti A Gbekari Otitọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 June ojú ìwé 32

GBÓLÓHÙN KAN LÁTINÚ BÍBÉLÌ

Ṣé O Nígbàgbọ́ Tó Lágbára?

A gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ ká tó lè múnú Jèhófà dùn. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé “ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo èèyàn.” (2 Tẹs. 3:2) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń ta kò ó, ó pè wọ́n ní “àwọn ẹni ibi àti èèyàn burúkú,” ó sì ní kí Jèhófà gba òun sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìgbàgbọ́ kan àwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ò gbà pé Ọlọ́run wà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí wà tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́. (Róòmù 1:20) Àwọn kan lè sọ pé ẹlòmíì tàbí nǹkan míì làwọn ń sìn. Ká sòótọ́, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò nígbàgbọ́.

Ó yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run wà àti pé “òun ló ń san èrè” fáwọn tó nígbàgbọ́ tó lágbára nínú ẹ̀. (Héb. 11:6) Ìgbàgbọ́ wà lára nǹkan tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní. Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà, ó máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. (Lúùkù 11:9, 10, 13) Àmọ́, ọ̀kan lára ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà ni pé ká máa ka Bíbélì déédéé. Lẹ́yìn náà, ó ṣe pàtàkì ká ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi í sílò. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé à ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó fi hàn pé a nígbàgbọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́