ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 September ojú ìwé 20-25
  • Ṣé O Ò Gbàgbé Ìkìlọ̀ Jésù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé O Ò Gbàgbé Ìkìlọ̀ Jésù?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN ÀGÙNTÀN ÀTI EWÚRẸ́
  • ÀWỌN WÚŃDÍÁ OLÓYE ÀTÀWỌN WÚŃDÍÁ ÒMÙGỌ̀
  • ÀPÈJÚWE TÁLẸ́ŃTÌ
  • TA NI A ‘MÁA MÚ LỌ?’
  • GBỌ́ ÌKÌLỌ̀
  • Ṣé Wàá “Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ Sì Jẹ́ Aláápọn!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • ‘Ẹrú Olóòótọ́’ Náà Yege Nígbà Àbẹ̀wò!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Wúńdíá Mẹ́wàá Kọ́ Wa
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 September ojú ìwé 20-25

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 38

ORIN 25 Àkànṣe Ìní

Ṣé O Ò Gbàgbé Ìkìlọ̀ Jésù?

“A máa mú ọ̀kan lọ, a sì máa pa ìkejì tì.”—MÁT. 24:40.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa sọ̀rọ̀ nípa àpèjúwe mẹ́ta tí Jésù sọ, a sì máa jíròrò báwọn àpèjúwe náà ṣe kan àkókò ìdájọ́ tó máa wáyé nígbà tí ayé burúkú yìí bá ti fẹ́ dópin.

1. Kí ni Jésù máa ṣe láìpẹ́?

ÀKÓKÒ tí àwọn nǹkan tí ò ṣẹlẹ̀ rí máa tó ṣẹlẹ̀ la wà yìí! Láìpẹ́, Jésù máa ṣèdájọ́ gbogbo èèyàn. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ kí ọjọ́ ìdájọ́ yẹn tó dé, ó sọ “àmì” táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ máa rí táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ti wà níhìn-ín àti pé “ìparí ètò àwọn nǹkan” ti sún mọ́lé. (Mát. 24:3) Àwọn àmì yìí wà ní Mátíù orí 24 àti 25, ó sì tún wà ní Máàkù orí 13 àti Lúùkù orí 21.

2. Àwọn àpèjúwe wo la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, kí ni wọ́n sì jẹ́ ká mọ̀?

2 Jésù sọ àpèjúwe mẹ́ta tó máa jẹ́ ká wà lójúfò, wọ́n sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa. Àwọn àpèjúwe náà ni àpèjúwe àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, àpèjúwe àwọn wúńdíá olóye àti wúńdíá òmùgọ̀ àti àpèjúwe tálẹ́ńtì. Àpèjúwe kọ̀ọ̀kan jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ṣe ni Jésù máa fi dá a lẹ́jọ́. Torí náà, bá a ṣe ń gbé àwọn àpèjúwe náà yẹ̀ wò, ẹ kíyè sí àwọn ẹ̀kọ́ tá a máa kọ́ àti bá a ṣe máa fi àwọn ẹ̀kọ́ náà sílò. Àpèjúwe àkọ́kọ́ tá a máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni àpèjúwe àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́.

ÀWỌN ÀGÙNTÀN ÀTI EWÚRẸ́

3. Ìgbà wo ni Jésù máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́?

3 Nínú àpèjúwe àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ tí Jésù sọ, ó ṣàlàyé pé ohun tóun máa fi ṣèdájọ́ àwọn èèyàn ni nǹkan tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere àti bóyá wọ́n ran àwọn arákùnrin òun lọ́wọ́ àbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 25:31-46) Ìgbà “ìpọ́njú ńlá” ni Jésù máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn bóyá àgùntàn ni wọ́n tàbí ewúrẹ́, ìyẹn tó bá kù díẹ̀ kí ogun Amágẹ́dọ́nì bẹ̀rẹ̀. (Mát. 24:21) Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù máa ya àwọn tó ran àwọn ẹni àmì òróró lọ́wọ́ sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tí kò ràn wọ́n lọ́wọ́.

4. Bí Àìsáyà 11:3, 4 ṣe sọ, kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Jésù máa dá ẹjọ́ àwọn èèyàn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ? (Wo àwòrán.)

4 Jèhófà ti yan Jésù pé kó jẹ́ onídàájọ́, torí náà Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa dá ẹjọ́ àwọn èèyàn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. (Ka Àìsáyà 11:3, 4.) Jésù máa wo ìwà táwọn èèyàn ń hù, ohun tí wọ́n ń rò, ohun tí wọ́n ń sọ àtohun tí wọ́n ń ṣe sáwọn ẹni àmì òróró. (Mát. 12:36, 37; 25:40) Jésù tún máa mọ àwọn tó ran àwọn ẹni àmì òróró lọ́wọ́, tí wọ́n sì bá wọn ṣiṣẹ́.a Ohun pàtàkì táwọn tó fìwà jọ àgùntàn lè ṣe láti ran àwọn arákùnrin Kristi lọ́wọ́ ni pé kí wọ́n máa wàásù. Jésù máa pe àwọn tó bá ràn wọ́n lọ́wọ́ ní “olódodo,” wọ́n sì máa ní “ìyè àìnípẹ̀kun” ní ayé. (Mát. 25:46; Ìfi. 7:16, 17) Ẹ ò rí i pé èrè ńlá nìyẹn fáwọn tó jẹ́ olóòótọ́! Torí náà, tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ nígbà ìpọ́njú ńlá àti lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá, orúkọ wọn máa wà nínú “ìwé ìyè.”—Ìfi. 20:15.

Jésù jókòó lórí ìtẹ́ lọ́run, ó ń wo àwùjọ méjì tí ìwà wọn yàtọ̀ síra láyé. Fọ́tò: Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń jọ́sìn Jèhófà. 1. Arábìnrin kan gbé tablet ẹ̀ dání, ó ń wo ojú ọ̀run. 2. Tọkọtaya kan ń ka Bíbélì. 3. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run. 4. Arákùnrin kan wà lẹ́wọ̀n, ó ń gbàdúrà. 5. Arábìnrin àgbàlagbà kan ń dáhùn nípàde. 6. Arábìnrin kan wà lórí bẹ́ẹ̀dì nílé ìwòsàn, ó fún òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn ní ìwé ìléwọ́. 7. Bàbá kan àti ìyàwó ẹ̀ ń kọ́ ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Fọ́tò: Àwọn èèyàn tó ń ṣe ohun tó ta ko ìlànà Bíbélì. 1. Ọkùnrin kan ń gbàdúrà nílé tẹ́tẹ́. 2. Ọkùnrin kan lu obìnrin kan. 3. Àwọn tínú ń bí, tí wọ́n sì ń wọ́de. 4. Ọkùnrin kan mú ìbọn dání, ó sì ń tẹ̀ lé obìnrin kan níbi tí wọ́n ń páàkì ọkọ̀ sí. 5. Àlùfáà kan ń gbàdúrà fáwọn ọmọ ogun. 6. Obìnrin kan ń lo oògùn olóró.

Tó bá kù díẹ̀ kí ogun Amágẹ́dọ́nì bẹ̀rẹ̀, Jésù máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn bóyá wọ́n fìwà jọ àgùntàn tàbí ewúrẹ́ (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. Ẹ̀kọ́ wo la kọ́ nínú àpèjúwe àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, àwọn wo ló sì máa ṣe láǹfààní?

5 Jẹ́ olóòótọ́ àti adúróṣinṣin sí Jèhófà. Àwọn tó máa gbé ayé ni àpèjúwe tí Jésù sọ nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ dá lé. Wọ́n fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ torí pé wọ́n ń ran àwọn arákùnrin Kristi lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì jẹ́ adúróṣinsin sí Jèhófà bí wọ́n ṣe ń ṣe ohun táwọn ẹni àmì òróró sọ, ìyẹn àwùjọ kékeré tí Jésù yàn kó máa darí wa. (Mát. 24:45) Àmọ́, ìkìlọ̀ inú àpèjúwe yìí náà kan àwọn tó ń lọ sọ́run. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù ń wo ohun táwọn náà ń ṣe, ohun tí wọ́n ń rò àtohun tí wọ́n ń sọ. Torí náà, àwọn náà gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Kódà, Jésù dìídì sọ àpèjúwe méjì míì tó fi kìlọ̀ fáwọn ẹni àmì òróró. Àwọn àpèjúwe náà wà ní Mátíù orí 25. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àpèjúwe àwọn wúńdíá olóye àti wúńdíá òmùgọ̀.

ÀWỌN WÚŃDÍÁ OLÓYE ÀTÀWỌN WÚŃDÍÁ ÒMÙGỌ̀

6. Báwo ni márùn-ún lára àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ olóye? (Mátíù 25:6-10)

6 Nínú àpèjúwe àwọn wúńdíá tí Jésù sọ, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá tí wọ́n jáde lọ pàdé ọkọ ìyàwó. (Mát. 25:1-4) Gbogbo wọn ló fẹ́ tẹ̀ lé e lọ síbi àsè ìgbéyàwó. Jésù sọ pé àwọn márùn-ún jẹ́ “olóye,” àwọn márùn-ún sì jẹ́ “òmùgọ̀.” Àwọn wúńdíá olóye ti múra sílẹ̀ ní tiwọn, wọ́n sì wà lójúfò. Wọ́n ti pinnu pé tí ọkọ ìyàwó bá tiẹ̀ pẹ́, àwọn máa dúró dè é, kódà tó bá jẹ́ pé àárín òru ló dé. Torí náà, kálukú wọn gbé fìtílà dání, kí wọ́n lè fi ríran lálẹ́. Wọ́n tiẹ̀ gbé òróró tó pọ̀ tó dání tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkọ ìyàwó pẹ́ dé. Ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé wọn ò fẹ́ kí fìtílà wọn kú rárá. (Ka Mátíù 25:6-10.) Nígbà tí ọkọ ìyàwó dé, àwọn wúńdíá olóye bá a wọlé síbi àsè ìgbéyàwó. Lọ́nà kan náà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n múra sílẹ̀, tí wọ́n wà lójúfò, tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ títí dìgbà tí Kristi bá dé máa láǹfààní láti bá a ṣàkóso lọ́run.b (Ìfi. 7:1-3) Àmọ́, kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn wúńdíá tó jẹ́ òmùgọ̀?

7. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn wúńdíá tó jẹ́ òmùgọ̀, kí sì nìdí?

7 Nígbà tí ọkọ ìyàwó dé, àwọn wúńdíá òmùgọ̀ ò lè wọlé bíi tàwọn wúńdíá olóye torí pé wọn ò múra sílẹ̀. Fìtílà wọn ti fẹ́ kú, òróró wọn sì ti tán. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ọkọ ìyàwó ò ní pẹ́ dé ni wọ́n jáde lọ ra òróró. Wọn ò tíì pa dà dé nígbà tí ọkọ ìyàwó dé. Àsìkò yẹn ni “àwọn wúńdíá tí wọ́n ti ṣe tán bá a wọlé síbi àsè ìgbéyàwó náà, a sì ti ilẹ̀kùn.” (Mát. 25:10) Nígbà táwọn wúńdíá òmùgọ̀ yẹn pa dà dé, tí wọ́n fẹ́ wọlé, ọkọ ìyàwó sọ fún wọn pé: “Mi ò mọ̀ yín rí.” (Mát. 25:11, 12) Àwọn wúńdíá òmùgọ̀ yẹn ò múra sílẹ̀ láti dúró de ọkọ ìyàwó, kódà tó bá tiẹ̀ máa pẹ́ dé. Ẹ̀kọ́ wo làwọn ẹni àmì òróró rí kọ́ nínú àpèjúwe yìí?

8-9. Ẹ̀kọ́ wo làwọn ẹni àmì òróró lè rí kọ́ nínú àpèjúwe àwọn wúńdíá? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Múra sílẹ̀, kó o sì wà lójúfò. Nínú àpèjúwe àwọn wúńdíá tí Jésù sọ, kò sọ pé àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró méjì ló máa wà tàbí pé àwùjọ kan máa múra sílẹ̀ títí di àkókò òpin, tí àwùjọ kejì ò sì ní múra sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn tí wọn ò bá múra sílẹ̀, kí wọ́n fara dà á, kí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin. Tí wọn ò bá múra sílẹ̀, wọn ò ní gba èrè wọn. (Jòh. 14:3, 4) Ẹ ò rí i pé àdánù ńlá nìyẹn máa jẹ́! Bóyá ọ̀run la máa gbé tàbí ayé, gbogbo wa ló yẹ ká fi ìkìlọ̀ inú àpèjúwe àwọn wúńdíá sílò. Torí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló yẹ kó wà lójúfò, ká múra sílẹ̀, ká sì ṣe tán láti fara dà á títí dé òpin.—Mát. 24:13.

9 Lẹ́yìn tí Jésù sọ àpèjúwe àwọn wúńdíá láti jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká múra sílẹ̀, ká sì wà lójúfò, ó wá sọ àpèjúwe tálẹ́ńtì. Àpèjúwe yìí jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká jẹ́ òṣìṣẹ́ kára.

Arákùnrin kan ń gbọ́ ìròyìn lórí tẹlifíṣọ̀n, ó ń fi wé ohun tó kà nínú Bíbélì. Àpèjúwe Jésù nípa wúńdíá mẹ́wàá ló wà nínú àwòrán tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀.

Ohun tá a kọ́ nínú àpèjúwe àwọn wúńdíá jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa má gbàgbé ìkìlọ̀ Jésù, ká múra sílẹ̀, ká wà lójúfò, ká sì ṣe tán láti fara dà á títí dé òpin (Wo ìpínrọ̀ 8-9)


ÀPÈJÚWE TÁLẸ́ŃTÌ

10. Báwo làwọn ẹrú méjì ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́? (Mátíù 25:19-23)

10 Nínú àpèjúwe tálẹ́ńtì, Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹrú mẹ́ta kan, ó ní méjì jẹ́ olóòótọ́ sí ọ̀gá wọn, àmọ́ ọ̀kan ò jẹ́ olóòótọ́. (Mát. 25:14-18) Jésù pe àwọn ẹrú méjì yẹn ní olóòótọ́ torí pé wọ́n ṣiṣẹ́ kára, wọ́n sì jèrè owó tó pọ̀ sí i fún ọ̀gá wọn. Kí ọ̀gá wọn tó rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, ó fún wọn ní owó tálẹ́ńtì, owó ńlá sì ni. Àwọn ẹrú méjì yẹn ṣiṣẹ́ kára gan-an torí pé wọ́n fi owó ọ̀gá wọn ṣòwò. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Nígbà tí ọ̀gá wọn fi máa pa dà dé, wọ́n ti jèrè ìlọ́po méjì owó tó fún wọn. Ọ̀gá wọn wá sọ fáwọn méjèèjì pé, ẹ “bọ́ sínú ayọ̀ ọ̀gá [yín].” (Ka Mátíù 25:19-23.) Àmọ́, kí ni ẹrú kẹta ṣe? Báwo ló ṣe lo owó tí ọ̀gá ẹ̀ fún un?

11. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ẹrú tó “ń lọ́ra,” kí sì nìdí?

11 Tálẹ́ńtì kan ni ọ̀gá náà fún ẹrú kẹta, àmọ́ ńṣe ló “ń lọ́ra.” Ọ̀gá ẹ̀ retí pé kó fowó náà ṣòwò, àmọ́ ńṣe ló rì í mọ́lẹ̀. Nígbà tí ọ̀gá ẹ̀ pa dà dé, ẹrú yìí ò jèrè nǹkan kan. Ohun tí ẹrú yìí ṣe ò dáa rárá. Dípò kó bẹ ọ̀gá ẹ̀ pé kó má bínú pé òun ò jèrè owó púpọ̀ sí i, ńṣe ló ń wá àwíjàre, tó sì sọ pé “ẹni tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn” ni ọ̀gá òun. Ọ̀gá náà ò gbóríyìn fún ẹrú yìí. Ọ̀gá yẹn tún ṣe nǹkan míì, ó gba tálẹ́ńtì náà lọ́wọ́ ẹ̀, ó sì lé e jáde.—Mát. 25:24, 26-30.

12. Ta ni àwọn ẹrú méjì tó jẹ́ olóòótọ́ yẹn ṣàpẹẹrẹ lónìí?

12 Àwọn ẹrú méjì tó jẹ́ olóòótọ́ yẹn ṣàpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Jésù Ọ̀gá wọn sọ fún wọn pé kí wọ́n “bọ́ sínú ayọ̀ ọ̀gá [wọn].” Bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́ jẹ́ kí wọ́n lè gba èrè wọn lọ́run, ìyẹn àjíǹde àkọ́kọ́. (Mát. 25:21, 23; Ìfi. 20:5b) Àmọ́ ní ti ẹrú kẹta tó ń lọ́ra, ìkìlọ̀ lohun tó ṣe jẹ́ fáwọn ẹni àmì òróró. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

13-14. Ẹ̀kọ́ wo làwọn ẹni àmì òróró kọ́ nínú àpèjúwe tálẹ́ńtì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Máa ṣiṣẹ́ kára. Nínú àpèjúwe àwọn wúńdíá, Jésù ò sọ pé àwọn ẹni àmì òróró máa jẹ́ aláìṣòótọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ò sọ pé wọ́n máa lọ́ra nínú àpèjúwe tálẹ́ńtì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ tí wọn ò bá nítara mọ́. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ‘pípè àti yíyàn wọn ò ní dá wọn lójú’ mọ́, Jèhófà ò sì ní jẹ́ kí wọ́n wọ Ìjọba ọ̀run.—2 Pét. 1:10.

14 Àpèjúwe tí Jésù sọ nípa àwọn wúńdíá àti tálẹ́ńtì jẹ́ ká rí i pé àwọn ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀, kí wọ́n wà lójúfò, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ kára. Àmọ́, ṣé Jésù sọ nǹkan míì láti kìlọ̀ fún wọn? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe bẹ́ẹ̀! Ó sọ fáwọn ẹni àmì òróró pé tóun bá fẹ́ ṣèdájọ́, tóun sì rí i pé wọn ò wà lójúfò, wọn ò ní gba èdìdì ìkẹyìn, bí Mátíù 24:40, 41 ṣe sọ.

Arábìnrin kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró ń kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àpèjúwe Jésù nípa tálẹ́ńtì ló wà nínú àwòrán tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀.

Jésù fẹ́ káwọn ẹni àmì òróró ṣiṣẹ́ kára títí dé òpin (Wo ìpínrọ̀ 13-14)d


TA NI A ‘MÁA MÚ LỌ?’

15-16. Báwo ni Mátíù 24:40, 41 ṣe jẹ́ káwọn ẹni àmì òróró rí i pé wọ́n gbọ́dọ̀ wà lójúfò?

15 Kí Jésù tó sọ àwọn àpèjúwe mẹ́ta yẹn, ó ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ ìkẹyìn táwọn ẹni àmì òróró máa gbà táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá Jèhófà tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Ó sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin méjì tó wà nínú pápá àti obìnrin méjì tó ń lọ nǹkan lórí ọlọ. Nínú àpẹẹrẹ méjèèjì yìí, ó jọ pé iṣẹ́ kan náà làwọn ọkùnrin yẹn ń ṣe, ó sì jọ pé iṣẹ́ kan náà làwọn obìnrin yẹn ń ṣe. Àmọ́, Jésù sọ pé “a máa mú ọ̀kan lọ, a sì máa pa ìkejì tì.” (Ka Mátíù 24:40, 41.) Ó wá gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ máa ṣọ́nà, torí pé ẹ ò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.” (Mát. 24:42) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, Jésù sọ ohun tó jọ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn tó sọ àpèjúwe àwọn wúńdíá. (Mát. 25:13) Ṣé ohun kan náà ni Jésù ń sọ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí? Ó jọ bẹ́ẹ̀. Kìkì àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ olóòótọ́ ni Jésù ‘máa mú lọ,’ tó sì máa gbà sínú Ìjọba ọ̀run.—Jòh. 14:3.

16 Ẹ máa ṣọ́nà. Táwọn ẹni àmì òróró ò bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, tí wọn ò sì wà lójúfò, Jésù ò ní kó wọn mọ́ “àwọn àyànfẹ́.” (Mát. 24:31) Síbẹ̀, gbogbo àwa èèyàn Jèhófà ló yẹ ká fi ìkìlọ̀ Jésù yìí sọ́kàn pé ká máa ṣọ́nà, ká sì jẹ́ olóòótọ́, bóyá ọ̀run la máa gbé tàbí ayé.

17. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa da ara wa láàmú nípa ìgbà tí Jèhófà fẹ̀mí mímọ́ yan ẹnì kan?

17 Torí pé a mọ Jèhófà dáadáa, ọkàn wa balẹ̀ pé ohun tó tọ́ ló máa ṣe. Torí náà, a kì í da ara wa láàmú tá a bá rí i pé Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ̀mí yan ẹnì kan.c Ẹ rántí ohun tí Jésù sọ nípa àwọn òṣìṣẹ́ tó ṣiṣẹ́ wákàtí kan nínú àpèjúwe ọgbà àjàrà. (Mát. 20:1-16) Owó kan náà lẹni tó ni ọgbà àjàrà san fún àwọn tó kọ́kọ́ dé àtàwọn tó dé kẹ́yìn. Lọ́nà kan náà, èrè kan làwọn ẹni àmì òróró máa gbà tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́, bóyá Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ̀mí yàn wọ́n àbí ó ti yàn wọ́n tipẹ́.

GBỌ́ ÌKÌLỌ̀

18-19. Àwọn ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ wo la ti jíròrò?

18 Kí la ti jíròrò? Àpèjúwe àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ ti jẹ́ ká rí i pé àwọn tó máa gbé ayé títí láé gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ àti adúróṣinṣin sí Jèhófà nísinsìnyí àti nígbà ìpọ́njú ńlá. Kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀, Jésù máa ṣèdájọ́ pé káwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró lọ “sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Mát. 25:46.

19 A tún ti sọ̀rọ̀ nípa àpèjúwe méjì míì tí Jésù fi kìlọ̀ fáwọn ẹni àmì òróró. Nínú àpèjúwe àwọn wúńdíá olóye àti òmùgọ̀ tí Jésù sọ, márùn-ún lára wọn ló jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Wọ́n ti múra sílẹ̀, wọ́n sì wà lójúfò, kódà wọ́n pinnu pé tí ọkọ ìyàwó bá tiẹ̀ pẹ́, àwọn máa dúró dè é. Àmọ́ àwọn òmùgọ̀ wúńdíá ò múra sílẹ̀ ní tiwọn. Torí náà, ọkọ ìyàwó ò jẹ́ kí wọ́n wọlé síbi àsè ìgbéyàwó ẹ̀. Lọ́nà kan náà, ó yẹ káwa náà máa múra sílẹ̀ títí dìgbà tí Jésù máa pa ayé burúkú yìí run, kódà tó bá dà bíi pé ó ti ń pẹ́ jù. Bákan náà, nínú àpèjúwe tálẹ́ńtì tí Jésù sọ, a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹrú méjì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ àti òṣìṣẹ́ kára. Wọ́n ṣiṣẹ́ kára gan-an nítorí ọ̀gá wọn, ó sì gbóríyìn fún wọn. Àmọ́, Jésù ò gbóríyìn fún ẹrú kẹta tó lọ́ra. Kí la kọ́? Ohun tá a kọ́ ni pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa ṣisẹ́ ìsìn Jèhófà títí òpin fi máa dé. Paríparí ẹ̀, a ti sọ̀rọ̀ nípa báwọn ẹni àmì òróró ṣe gbọ́dọ̀ máa ṣọ́nà, kí Jésù lè ‘mú wọn lọ’ sí ọ̀run láti gba èrè wọn. Torí náà, wọ́n ń retí ìgbà tá a máa ‘kó wọn jọ’ sọ́dọ̀ Jésù ní ọ̀run. Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, wọ́n máa di ìyàwó Jésù nígbà ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.—2 Tẹs. 2:1; Ìfi. 19:9.

20. Kí ni Jèhófà máa ṣe fáwọn tó gbọ́ ìkìlọ̀?

20 Lóòótọ́, Jésù ò ní pẹ́ dé láti ṣèdájọ́, àmọ́ kò yẹ ká bẹ̀rù. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, Baba wa ọ̀run máa fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” ‘ká lè bọ́, ká sì lè dúró níwájú Ọmọ èèyàn.’ (2 Kọ́r. 4:7; Lúùkù 21:36) Bóyá ọ̀run tàbí ayé la máa gbé, inú Baba wa ọ̀run máa dùn sí wa tá a bá fetí sí ìkìlọ̀ inú àpèjúwe mẹ́ta yẹn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa, orúkọ wa sì máa “wà nínú ìwé” ìyè.—Dán. 12:1; Ìfi. 3:5.

KÍ LA KỌ́ NÍNÚ ÀPÈJÚWE . . .

  • àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́?

  • àwọn wúńdíá olóye àti òmùgọ̀?

  • tálẹ́ńtì?

ORIN 26 Ẹ Ti Ṣe É fún Mi

a Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí La Mọ̀ Nípa Bí Jèhófà Ṣe Máa Ṣèdájọ́ Lọ́jọ́ Iwájú?” nínú Ilé Ìṣọ́ May 2024.

b Kó o lè mọ púpọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Wàá ‘Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà’?” nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 2015.

c Wo Ilé Ìṣọ́ January 2020, ojú ìwé 29-30, ìpínrọ̀ 11-14.

d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró ń kọ́ obìnrin kan tó wàásù fún lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́