ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 5/1 ojú ìwé 20-24
  • Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ Sì Jẹ́ Aláápọn!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ Sì Jẹ́ Aláápọn!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wà Lójúfò, Gẹ́gẹ́ Bí Tàwọn Wúńdíá Márùn-ún Nì!
  • Jẹ́ Aláápọn Bí Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé
  • Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ Sì Jẹ́ Aláápọn Nígbà Wíwàníhìn-ín Rẹ̀
  • Ṣé Wàá “Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ṣé O Ò Gbàgbé Ìkìlọ̀ Jésù?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Wúńdíá Mẹ́wàá Kọ́ Wa
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Ìlanilóye fun “Ipari Eto-Igbekalẹ Awọn Nǹkan”
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 5/1 ojú ìwé 20-24

Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ Sì Jẹ́ Aláápọn!

“Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.”—MÁTÍÙ 25:13.

1. Kí ni àpọ́sítélì Jòhánù ń wọ̀nà fún?

NÍNÚ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó wáyé kẹ́yìn nínú Bíbélì, Jésù ṣèlérí pé: “Mo ń bọ̀ kíákíá.” Jòhánù àpọ́sítélì rẹ̀ fèsì pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.” Àpọ́sítélì náà kò ṣiyè méjì nípa bíbọ̀ Jésù. Jòhánù wà lára àwọn àpọ́sítélì tó béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ [lédè Gíríìkì, pa·rou·siʹa] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” Bẹ́ẹ̀ ni, Jòhánù ń fojú sọ́nà fún wíwàníhìn-ín Jésù ní ọjọ́ ọ̀la pẹ̀lú ìgbọ́kànlé.—Ìṣípayá 22:20; Mátíù 24:3.

2. Ní ti wíwàníhìn-ín Jésù, ọwọ́ wo làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi mú un?

2 Irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n lóde òní. Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ní àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni nípa “wíwá” Jésù, ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn mẹ́ńbà wọn ló ń retí wíwá náà. Wọ́n sì ń lo ìgbésí ayé wọn bí ẹni pé Jésù kò ní wá. Ìwé náà, The Parousia in the New Testament, sọ pé: “Ipa díẹ̀ ni ìrètí Ìpadàbọ̀ Kristi ní nínú ìgbésí ayé, ìrònú àti iṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì. . . . Ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú tó yẹ kí ṣọ́ọ̀ṣì ní sí ìpolongo ìrònúpìwàdà àti iṣẹ́ ìkéde ìhìn rere náà ti ń kú lọ, tàbí ká kúkú sọ pé ó tilẹ̀ ti kú pátápátá.” Àmọ́ ṣá o, kò rí bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn!

3. (a) Kí ni ìmọ̀lára àwọn Kristẹni tòótọ́ nípa pa·rou·siʹa? (b) Ní pàtàki, kí la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?

3 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ ń fi ìháragàgà dúró de òpin ètò àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí. Bí a ti ń fi ìdúróṣinṣin ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti ní ojú ìwòye tòótọ́ nípa gbogbo àwọn ohun tó wé mọ́ wíwà níhìn-ín Jésù, kí a sì hùwà lọ́nà tó bá a mu. Ìyẹn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ‘fara dà á dé òpin kí a bàa lè rí ìgbàlà.’ (Mátíù 24:13) Nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ táa rí nínú Mátíù orí kẹrìnlélógún àti ìkẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, Jésù pèsè ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí a lè fi sílò, fún àǹfààní wa ayérayé. Orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní àwọn àkàwé tó ṣeé ṣe kóo ti mọ̀, títí kan ọ̀kan tó sọ nípa wúńdíá mẹ́wàá (olóye àti òmùgọ̀ wúńdíá) àti àkàwé tálẹ́ńtì. (Mátíù 25:1-30) Báwo la ṣe lè jàǹfààní láti inú àwọn àkàwé wọ̀nyẹn?

Wà Lójúfò, Gẹ́gẹ́ Bí Tàwọn Wúńdíá Márùn-ún Nì!

4. Kí ló ṣẹlẹ̀ nínú àkàwé àwọn wúńdíá?

4 O lè fẹ́ láti tún àkàwé àwọn wúńdíá náà kà, èyí tó wà nínú Mátíù 25:1-13. Ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó híhẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ kan tó jẹ́ ti àwọn Júù ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, níbi tọ́kọ ìyàwó ti lọ sílé àna ẹ̀, kó lè sin ìyàwó ẹ̀ wálé ara rẹ̀ (tàbí kó lè mú un wá sílé baba tirẹ̀). Àwọn akọrin àti àwọn olóhùn arò lè wà nínú irú ìtọ́wọ̀ọ́rìn bẹ́ẹ̀, kò sì sẹ́ni tó lè mọ àkókò náà gan-an tí wọn yóò mú ìyàwó dé. Nínú àkàwé náà, wúńdíá mẹ́wàá ló dúró pé kí ọkọ ìyàwó dé. Nítorí pé àwọn márùn-ún kan gọ̀, wọn ò mú òróró fìtílà tó tó lọ́wọ́, ó wá pọndandan pé kí wọ́n lọ rà sí i. Àwọn márùn-ún yòókù jẹ́ olóye, wọ́n rọ òróró pa mọ́ sínú kólòbó wọn torí a-kì í-mọ̀ bí tinú fìtílà wọn bá tán níbi tí wọ́n ti ń dúró de ọkọ ìyàwó, wọ́n á lè rí nǹkan rọ sí i. Àwọn márùn-ún wọ̀nyí nìkan ló wà nítòsí, tí wọ́n sì ti gbára dì nígbà tí ọkọ ìyàwó dé. Nítorí náà, àwọn nìkan la yọ̀ǹda fún láti wọlé síbi àsè náà. Ìgbà táwọn òmùgọ̀ wúńdíá márùn-ún fi máa padà dé, wọn kò ráyè wọlé mọ́, wọ́n ti pẹ́ jù.

5. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìtumọ̀ ìṣàpẹẹrẹ tí àkàwé àwọn wúńdíá ní?

5 Ọ̀pọ̀ ohun tó wà nínú àkàwé yìí la lè lóye pé ó jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ. Fún àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ sọ nípa Jésù gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó. (Jòhánù 3:28-30) Jésù fi ara rẹ̀ wé ọmọ ọba tí a ti se àsè ìgbéyàwó sílẹ̀ fún. (Mátíù 22:1-14) Bíbélì sì fi Kristi wé ọkọ. (Éfésù 5:23) Ó yẹ fún àfiyèsí pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a sọ̀rọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró níbòmíràn gẹ́gẹ́ bí “ìyàwó” Kristi, àkàwé eléyìí kò mẹ́nu kan ìyàwó. (Jòhánù 3:29; Ìṣípayá 19:7; 21:2, 9) Ṣùgbọ́n, ó sọ nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá, níbòmíràn ni a sì ti wá fi àwọn ẹni àmì òróró wé wúńdíá tí a ti fẹ́ sọ́nà fún Kristi.—2 Kọ́ríńtì 11:2.a

6. Ọ̀rọ̀ ìṣítí wo ni Jésù fúnni nígbà tó ń parí àkàwé rẹ̀ nípa àwọn wúńdíá?

6 Yàtọ̀ sí irú kúlẹ̀kúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ àti ọ̀nà èyíkéyìí tí àsọtẹ́lẹ̀ náà gbà ní ìmúṣẹ, ó dájú pé, àwọn ìlànà àtàtà wà tí a lè kọ́ nínú àkàwé yìí. Fún àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí pé Jésù parí àkàwé náà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.” Nítorí náà, àkàwé náà jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti wà lójúfò bí òpin ètò yìí ti ń sún mọ́lé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè sọ ọjọ́ kan pàtó, kò sí àní-àní pé òpin yìí ń bọ̀. Ní ti èyí, ṣàkíyèsí ìwà tí ẹgbẹ́ méjèèjì ti àwọn wúńdíá náà hù.

7. Ọ̀nà wo làwọn márùn-ún lára àwọn wúńdíá inú àkàwé náà gbà fi hàn pé wọ́n jẹ́ òmùgọ̀?

7 Jésù wí pé: “Márùn-ún nínú wọn jẹ́ òmùgọ̀.” Ìyẹn ha jẹ́ nítorí pé wọn kò gbà gbọ́ pé ọkọ ìyàwó ń bọ̀ ni bí? Ṣé fàájì ni wọ́n ń bá kiri ni? Àbí a tàn wọ́n jẹ ni? Bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè wọ̀nyí. Jésù sọ pé àwọn márùn-ún wọ̀nyí “jáde lọ láti pàdé ọkọ ìyàwó.” Wọ́n mọ̀ pé ó ń bọ̀, wọn ò sì fẹ́ kó ṣẹ̀yìn wọn, wọ́n tilẹ̀ fẹ́ kópa nínú “àsè ìgbéyàwó náà.” Síbẹ̀, ǹjẹ́ wọ́n múra sílẹ̀ tó? Wọ́n dúró dè é fúngbà díẹ̀, títí di “àárín òru,” ṣùgbọ́n wọn kò múra sílẹ̀ láti kí i káàbọ̀ nígbàkigbà tó bá dé—yálà ó tètè dé tàbí ó pẹ́ ju bí wọn ti rò.

8. Báwo làwọn márùn-ún nínú àwọn wúńdíá inú àkàwé náà ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ olóye?

8 Àwọn márùn-ún yòókù—àwọn tí Jésù pè ní olóye—gbé fìtílà wọn tí wọ́n ti tàn dáni, wọ́n ń retí kí ọkọ ìyàwó dé. Àwọn pẹ̀lú ní láti dúró, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ “olóye.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà táa tú sí “olóye” lè túmọ̀ sí jíjẹ́ “onílàákàyè, olórípípé, ẹni tó gbọ́n dáadáa.” Àwọn márààrún yìí fi hàn pé àwọn jẹ́ olóye nípa mímú kólòbó tó ní òróró nínú dání, kí wọn lè rí nǹkan rọ sí fìtílà wọn, bó bá di kàráǹgídá. Lóòótọ́, mímúra sílẹ̀ de ọkọ ìyàwó náà gbà wọ́n lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò fi fòróró wọn tọrẹ. Irú wíwà lójúfò bẹ́ẹ̀ kò lòdì, gẹ́gẹ́ bí wíwà tí wọ́n wà níbẹ̀ àti ìgbáradì wọn nígbà tí ọkọ ìyàwó dé ti fi hàn. Àwọn “tí wọ́n sì . . . gbára dì wọlé pẹ̀lú rẹ̀ síbi àsè ìgbéyàwó náà; a sì ti ilẹ̀kùn.”

9, 10. Kí ni kókó inú àkàwé àwọn wúńdíá, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?

9 Kì í ṣe ẹ̀kọ́ lórí ìwà tó yẹ ká hù níbi ìgbéyàwó ni Jésù ń kọ́ni, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe pé ó ń fúnni nímọ̀ràn nípa báa ṣe lè ṣàjọpín nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ohun tó ń kọ́ni ni pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.” Wá béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni mo wà lójúfò nípa wíwàníhìn-ín Jésù?’ A gbà gbọ́ pé nísinsìnyí Jésù ń ṣàkóso lókè ọ̀run, ṣùgbọ́n báwo la ṣe pọkàn pọ̀ tó sórí òtítọ́ náà pé ‘Ọmọ ènìyàn yóò fara hàn ní àwọsánmà ọ̀run láìpẹ́ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá?’ (Mátíù 24:30) Nígbà tó di “àárín òru,” ó dájú pé dídé ọkọ ìyàwó náà ti wá sún mọ́lé ju ìgbà tí àwọn wúńdíá náà kọ́kọ́ jáde láti lọ pàdé rẹ̀. Bákan náà, dídé Ọmọ ènìyàn láti pa ètò nǹkan ìsinsìnyí run sún mọ́lé ju ìgbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí fojú sọ́nà fún bíbọ̀ rẹ̀. (Róòmù 13:11-14) Ǹjẹ́ a ṣì wà lójúfò, ṣé a ṣì túbọ̀ wà lójúfò bí àkókò náà ti ń sún mọ́lé?

10 Láti ṣègbọràn sí àṣẹ náà “ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà” ń béèrè pé kí a máa wà lójúfò nígbà gbogbo. Àwọn wúńdíá márùn-ún jẹ́ kí òróró wọn tán, kí wọ́n tó wá lọ rà sí i. Bákan náà lónìí, a lè pín ọkàn Kristẹni kan níyà pẹ̀lú kó má bàa lè múra sílẹ̀ dáradára fún dídé Jésù tó sún mọ́lé. Ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni kan lọ́rùn-úndún kìíní. Ó lè ṣẹlẹ̀ sáwọn kan lónìí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká béèrè lọ́wọ́ ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ ó ń ṣẹlẹ̀ sí mi?’—1 Tẹsalóníkà 5:6-8; Hébérù 2:1; 3:12; 12:3; Ìṣípayá 16:15.

Jẹ́ Aláápọn Bí Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé

11. Àkàwé wo ni Jésù fúnni tẹ̀ lé e, kí ló sì fara jọ?

11 Nínú àkàwé tó tẹ̀ lé e tí Jésù ṣe, kò fi ọ̀ràn náà mọ sí rírọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti wà lójúfò. Lẹ́yìn tó ti sọ nípa àwọn wúńdíá olóye àti òmùgọ̀, ó ṣàkàwé tálẹ́ńtì. (Ka Mátíù 25:14-30.) Lọ́pọ̀ ọ̀nà, èyí fara jọ àkàwé rẹ̀ ìṣáájú nípa mínà, èyí tí Jésù sọ nítorí pé ọ̀pọ̀ “lérò pé ìjọba Ọlọ́run yóò fara rẹ̀ hàn sóde ni ìṣẹ́jú akàn.”—Lúùkù 19:11-27.

12. Kí ló ṣẹlẹ̀ nínú àkàwé tálẹ́ńtì?

12 Nínú àkàwé tálẹ́ńtì, Jésù sọ nípa ọkùnrin kan, tó jẹ́ pé kó tó lọ sájò, ó pe àwọn ẹrú rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ó fún ọ̀kan ní tálẹ́ńtì márùn-ún, ó fẹ́nìkan ní méjì, ó sì fún ẹnì kan tó kù ní ẹyọ kan ṣoṣo—“olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú agbára ìlèṣe-nǹkan tirẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ tálẹ́ńtì fàdákà kan, owó tó tó iye tí lébìrà kan ń gbà lọ́dún mẹ́rìnlá—owó ńlá mà nìyẹn o! Nígbà tọ́kùnrin náà tàjò dé, ó ní káwọn ẹrú òun wá ròyìn ohun tí wọ́n ṣe ní “àkókò gígùn” tí òun kò fi sí nílé. Ẹrú méjì àkọ́kọ́ ti sọ ohun táa fi síkàáwọ́ wọn di ìlọ́po méjì. Ọ̀gá náà wí pé “o káre láé,” ó ṣèlérí pé òun yóò fi kún ẹrù iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, paríparí rẹ̀ ó wí pé: “Bọ́ sínú ìdùnnú ọ̀gá rẹ.” Nítorí tí ẹrú tọ́gàá rẹ̀ fún ní tálẹ́ńtì kan gbà pé afipámúni lọ̀gá òun, kò fi tálẹ́ńtì náà ṣòwò rárá. Ṣe ló lọ fi owó náà pa mọ́, kò tilẹ̀ tún lọ fi pa mọ́ sí báńkì kí èlé lè gorí rẹ̀. Ọ̀gá náà pè é ní ẹni “burúkú àti onílọ̀ọ́ra” nítorí pé ó dínà èrè ọ̀gá rẹ̀. Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, wọ́n gba tálẹ́ǹtì náà lọ́wọ́ ẹ̀, wọ́n sì tì í síta níbi tí “ẹkún rẹ̀ àti ìpayínkeke rẹ̀” yóò wà.

13. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun dà bí ọ̀gá inú àkàwé náà?

13 Lẹ́ẹ̀kan sí i, a lè lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ àkàwé yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Fún àpẹẹrẹ, Jésù, tí ọkùnrin tó rìnrìn àjò lọ sílẹ̀ òkèèrè náà ṣàpẹẹrẹ, yóò fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀, yóò lọ sọ́run, yóò sì dúró fún àkókò pípẹ́ títí dìgbà tó bá gba agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.b (Sáàmù 110:1-4; Ìṣe 2:34-36; Róòmù 8:34; Hébérù 10:12, 13) Ṣùgbọ́n, a tún lè lóye ẹ̀kọ́ ńlá kan tàbí ìlànà kan tí gbogbo wa lè fi sílò nínú ìgbésí ayé wa. Èwo nìyẹn?

14. Ohun pàtàkì wo ni àkàwé tálẹ́ńtì tẹnu mọ́?

14 Yálà ìrètí wa jẹ́ níní ìyè àìleèkú ní ọ̀run tàbí ti ìyè àìnípẹ̀kun lórí párádísè ilẹ̀ ayé, ó ṣe kedere láti inú àkàwé Jésù pé ó yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe nínú ìgbòkègbodò Kristẹni. Lóòótọ́, a lè fi ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ṣàkópọ̀ àkàwé yìí: aápọn. Àwọn àpọ́sítélì fi àwòṣe lélẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa. A kà pé: “[Pétérù] sì fi ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ mìíràn jẹ́rìí kúnnákúnná, ó sì ń gbà wọ́n níyànjú ṣáá, pé: ‘Ẹ gba ara yín là kúrò lọ́wọ́ ìran oníwà wíwọ́ yìí.’” (Ìṣe 2:40-42) Èrè tó gbà fún ìsapá rẹ̀ mà pọ̀ gan-an o! Bí àwọn mìíràn ti ń dara pọ̀ mọ́ àwọn àpọ́sítélì nínú iṣẹ́ ìwàásù Kristẹni wọn, àwọn náà jẹ́ aláápọn nínú ìhìn rere náà “tí ó . . . ń bí sí i ní gbogbo ayé.”—Kólósè 1:3-6, 23; 1 Kọ́ríńtì 3:5-9.

15. Ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ wo ló yẹ ká fi àwọn kókó inú àkàwé tálẹ́ńtì sílò?

15 Rántí àyíká ọ̀rọ̀ inú àkàwé yìí—àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwàníhìn-ín Jésù. A ní ẹ̀rí tó pọ̀, tó fi hàn pé pa·rou·siʹa Jésù ṣì ń bá a nìṣó àti pé kò ní pẹ́ tó fi máa dé òtéńté rẹ̀. Rántí bí Jésù ṣe fi ìbátan tó wà láàárín “òpin” àti iṣẹ́ tí àwọn Kristẹni ní láti ṣe hàn, ó wí pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Pẹ̀lú èyí lọ́kàn wa, ẹrú wo làwá fẹ́ fìwà jọ? Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ: ‘Ìdí kankan ha wà fún mi láti parí èrò sí pé mo fìwà jọ ẹrú tó lọ fi ohun táa fi síkàáwọ́ rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n tó lè jẹ́ pé ó ń bójú tó àwọn nǹkan tirẹ̀? Àbí ó ṣe kedere pé mo fìwà jọ àwọn ẹrú rere, tó ṣeé fọkàn tán? Mo ha ti pinnu pátápátá láti máa mú ki èrè Ọ̀gá náà máa pọ̀ sí i ní gbogbo ìgbà bí?’

Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ Sì Jẹ́ Aláápọn Nígbà Wíwàníhìn-ín Rẹ̀

16. Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú àkàwé méjèèjì táa ti jíròrò yìí?

16 Bẹ́ẹ̀ ni, yàtọ̀ sí ìtumọ̀ ìṣàpẹẹrẹ àti ti alásọtẹ́lẹ̀ tí àwọn àkàwé méjèèjì wọ̀nyí ní, wọ́n tún fún wa ní ìṣírí tó ṣe kedere tó ti ẹnu Jésù alára jáde. Ohun tó sọ ni pé: Ẹ wà lójúfò; ẹ jẹ́ aláápọn, pàápàá nígbà tí ẹ ti rí àmì pa·rou·siʹa Kristi. Ìyẹn ni àkókò táa wà yìí. Nítorí náà, ǹjẹ́ a wà lójúfò, tí a sì jẹ́ aláápọn lóòótọ́ bí?

17, 18. Kí ni ọmọlẹ́yìn náà Jákọ́bù gbani nímọ̀ràn nípa wíwàníhìn-ín Jésù?

17 Jákọ́bù tó jẹ́ iyèkan Jésù kò sí lórí Òkè Ólífì láti gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù; ṣùgbọ́n lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ó gbọ́ nípa rẹ̀, ó si lóye rẹ̀ dáadáa. Ó kọ̀wé pé: “Nítorí náà, ẹ mú sùúrù, ẹ̀yin ará, títí di ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa. Wò ó! Àgbẹ̀ a máa dúró de èso ṣíṣeyebíye ilẹ̀ ayé, ní mímú sùúrù lórí rẹ̀ títí yóò fi rí òjò àkọ́rọ̀ àti òjò àrọ̀kúrò. Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fìdí ọkàn-àyà yín múlẹ̀ gbọn-in, nítorí wíwàníhìn-ín Olúwa ti sún mọ́lé.”—Jákọ́bù 5:7, 8.

18 Lẹ́yìn tó ti mú un dá àwọn Kristẹni lójú pé Ọlọ́run yóò ṣèdájọ́ fún àwọn tó bá ṣi ọrọ̀ wọn lò, Jákọ́bù rọ̀ wọ́n láti ní sùúrù bí wọ́n ti ń dúró dé ìgbésẹ̀ tí Jèhófà yóò gbé. Kristẹni tó bá jẹ́ oníwàǹwára lè di ẹni tó fẹ́ fúnra rẹ̀ gbẹ̀san, bí ẹni pé òun fúnra rẹ̀ lè ṣàtúnṣe ìwà àìtọ́ tí ẹnì kan ti hù. Ṣùgbọ́n, kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó dájú pé àkókò ìdájọ́ yóò dé. Àpẹẹrẹ àgbẹ̀ kan ṣàkàwé ìyẹn, gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ti ṣàlàyé.

19. Sùúrù wo ni kí àgbẹ̀ kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ní?

19 Bí àgbẹ̀ kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì bá gbin nǹkan, ó ní láti ní sùúrù, kí irúgbìn náà kọ́kọ́ yọ èéhù, lẹ́yìn náà kó dàgbà, nígbẹ̀yìngbẹ́yín kó wá kórè rẹ̀. (Lúùkù 8:5-8; Jòhánù 4:35) Jálẹ̀ àwọn oṣù wọ̀nyẹn, àkókò yóò wà tí ìdààmú yóò dé bá a, ó sì lè ní ohun kan tó fà á. Ṣé òjò àkọ́rọ̀ yóò wà, ṣé yóò sì tó? Òjò àrọ̀kúrò ńkọ́? Ṣé kòkòrò kò ní pa irúgbìn náà báyìí, àbí kí ìjì rún un mọ́lẹ̀? (Fi wé Jóẹ́lì 1:4; 2:23-25.) Síbẹ̀síbẹ̀, ní gbogbo gbòò àgbẹ̀ kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti àwọn ìyípoyípo àkókò tí ó ti ṣètò. (Diutarónómì 11:14; Jeremáyà 5:24) Sùúrù àgbẹ̀ náà tilẹ̀ lè jẹ́ ìrètí tó dáni lójú. Nítorí ìgbàgbọ́ tó ní, ó mọ̀ pé ohun tóun ń dúró dè yóò dé. Ó sì dájú pé yóò dé!

20. Báwo la ṣe lè fi sùúrù hàn ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Jákọ́bù?

20 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àgbẹ̀ kan lè mọ ìgbà tí àkókò ìkórè yóò jẹ́, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kò lè ṣírò ìgbà tí wíwàníhìn-ín Jésù yóò jẹ́. Àmọ́ ṣá o, ó dájú pé yóò dé. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Wíwàníhìn-ín [lédè Gíríìkì, pa·rou·siʹa] Olúwa ti sún mọ́lé.” Nígbà tí Jákọ́bù ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àmì wíwàníhìn-ín Kristi lọ́nà gbígbòòrò tàbí lọ́nà tó kárí ayé kò tí ì fara hàn. Ṣùgbọ́n ó ti fara hàn báyìí o! Nítorí náà, kí ló yẹ kó jẹ́ ìmọ̀lára wa lákòókò yìí? Àmì náà ti fara hàn ní ti gidi. A ti rí i kòrókòró. A lè fi ìdánilójú sọ pé: ‘Mo ti rí ìmúṣẹ àmì náà.’ Àní a lè sọ ọ́ gbangba gbàǹgbà pé, ‘Olúwa ti wà níhìn-ín, òtéńté wíwàníhìn-ín rẹ̀ sì kù sí dẹ̀dẹ̀.”

21. Kí la ti pinnu pátápátá láti ṣe?

21 Nígbà tó jẹ́ pé bọ́ràn ti rí nìyí, a ní ìdí tó ṣe pàtàkì gan-an láti fi àkàwé Jésù méjèèjì táa ti jíròrò sọ́kàn, kí a sì lo àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ń bẹ nínú wọn. Ó wí pé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.” (Mátíù 25:13) Kò sí iyè méjì pé àkókò yìí ló yẹ ká jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ ìsìn Kristẹni wa. Ẹ jẹ́ ká máa fi hàn nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ pé a lóye ọ̀rọ̀ Jésù. Ẹ jẹ́ ká wà lójúfò! Ẹ jẹ́ ká jẹ́ aláápọn!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tó wà nínú àkàwé náà, wo ìwé náà, God’s Kingdom of a Thousand Years Has Approached, ojú ìwé 169 sí 211, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. tẹ̀ jáde.

b Wo ìwé náà, God’s Kingdom of a Thousand Years Has Approached, ojú ìwé 212 sí 256.

Ǹjẹ́ O Rántí?

◻ Kókó pàtàkì wo lo rí fà yọ nínú àkàwé olóye àti òmùgọ̀ wúńdíá?

◻ Nípasẹ̀ àkàwé tálẹ́ńtì, ìmọ̀ràn pàtàkì wo ni Jésù fún ẹ?

◻ Ọ̀nà wo ni sùúrù rẹ fi ní ìbátan pẹ̀lú pa·rou·siʹa gẹ́gẹ́ bí ti sùúrù àgbẹ̀ kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì?

◻ Èé ṣe tí àkókò tí a ń gbé yìí fi jẹ́ èyí tó múni láyọ̀, tó sì tún peni níjà ní pàtàkì?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú àkàwé àwọn wúńdíá àti ti tálẹ́ńtì?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́