Ori 5
Ìlanilóye fun “Ipari Eto-Igbekalẹ Awọn Nǹkan”
1. Fun “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” yii, igbeyawo ti ó gba afiyesi wo ni “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa sọtẹlẹ, ninu owe wo si ni?
NIPA “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan,” “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa wi ninu Matteu 24:38 pe yoo maa ṣẹlẹ pe ‘wọn o maa gbeyawo, ti a o si maa fa iyawo funni.’ Ṣugbọn laaarin akoko kan naa yii, igbeyawo ti ó tobi julọ patapata bẹrẹ ní ọ̀run. Igbeyawo naa ni a tọkasi ninu apejuwe Jesu ti awọn onifitila mẹwaa, awọn wundia mẹwaa.—Matteu 24:3, NW; 25:1-12.
2. (a) Ni akoko wo ni igbeyawo inu owe yii ṣẹlẹ? (b) Ki ni o tẹ̀lé igbeyawo naa, bawo ni a si ṣe pese imọlẹ?
2 Ibi ti igbeyawo yii ti ṣẹlẹ ni Aarin Gbungbun Ila-Oorun Ayé. O ṣẹlẹ ní òru, o sì wọnu ààjìn òru. Ìsopọ̀ iyawo ati ọkọ-iyawo ni a kọ́kọ́ ṣe tí ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ alayẹyẹ lọ sí ile ayẹyẹ àpèjẹ sì tẹ̀lé e. Kò si awọn àtùpà òpópónà lati tanmọlẹ si oju ọna naa. Awọn ti wọn ń lọwọ ninu ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ ayẹyẹ naa ní o pese imọlẹ, ti awọn ero ti ó duro sì le maa wo awọn ti wọn ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ naa bi wọn ti ń lọ, ni sísúre ayọ̀ fun awọn tọkọtaya titun naa.
3, 4. (a) Awọn wo ni wọn fi ìfẹ́-ọkàn hàn si ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ alayẹyẹ ti ó tẹ̀lé e, pẹlu imurasilẹ wo sì ni? (b) Imuṣẹ owe yii fi ẹri kun otitọ wo? (c) A lè layọ bi a ba ṣe ki ni?
3 Ní hihuwa gẹgẹ bi itẹsi ọkan wọn bi obinrin, awọn wundia nifẹẹ si igbeyawo naa. Nitori naa, awọn wundia mẹwaa kan duro ní òpópó ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ alayẹyẹ naa titi ti ẹgbẹ́ awọn alayẹyẹ igbeyawo naa yoo fi de ibi ti wọn duro si. Ìfẹ́-ọkàn wọn ni lati tanmọlẹ si ayẹyẹ naa, ati nitori ìdí yii gbogbo wọn gbé fitila ti a ti tanna sí wá, ṣugbọn kìkì marun-un pere ninu wọn ni o mu ipese ororo itanna fun pàjáwìrì dani. Awọn marun-un wọnyi jẹ wundia ọlọgbọn-inu. Imuṣẹ owe yii yẹ ki ó gba afiyesi wa lonii, nitori gẹgẹ bi Jesu Kristi ti wí, o tun fidi rẹ̀ mulẹ siwaju sii pe a wà ní ipari eto ogbologboo isinsinyi.—Matteu 25:13.
4 Awa lè jẹ́ alayọ bi a bá jẹ́ ọlọgbọn-inu ti a si foyemọ ijoootọ gidi igbeyawo ti ó ju gbogbo igbeyawo lọ yii pẹlu awọn iṣẹlẹ ti wọn so mọ́ ọn! Awọn wo lonii ni a fi ojurere hàn si nipa gbigba wọn wọle sinu ayẹyẹ àpèjẹ naa? O ha kan ẹnikẹni ninu wa bi? Jẹ ki a wò ó ná!
5. Ki ni o fi iyatọ hàn laaarin awọn wọnni ti wọn parapọ jẹ́ wundia mẹwaa naa, ki ni o sì ṣẹlẹ laaarin akoko ti ọkọ-iyawo naa pẹ́ dé?
5 Apejuwe ti Jesu fifunni nipa awọn wundia mẹwaa naa niiṣe pẹlu “ijọba ọ̀run,” iṣakoso agbaye kan fun ibukun gbogbo iran eniyan. Nitori naa Jesu Kristi ń baa lọ lati wi pe: “A o fi ijọba ọ̀run wé awọn wundia mẹwaa, ti ó mu fitila wọn, ti wọn si jade lọ lati pade ọkọ-iyawo. Marun-un ninu wọn ṣe ọlọgbọn [“ọlọgbọn-inu,” NW], marun-un si ṣe alaigbọn [“omugọ,” NW]. Awọn ti ó ṣe alaigbọn mu fitila wọn, wọn kò sì mu ororo lọwọ: Ṣugbọn awọn ọlọgbọn mu ororo ninu kòlòbó pẹlu fitila wọn. Nigba ti ọkọ-iyawo pẹ́, gbogbo wọn tòògbé, wọn sì sùn.”—Matteu 25:1-5.
6. (a) Ta ni awọn wundia mẹwaa naa ṣapẹẹrẹ rẹ̀? (b) Eeṣe ti a kò fi darukọ iyawo kankan ninu owe naa?
6 Nisinsinyi ta ni awọn wundia mẹwaa wọnyẹn duro fun? Wọn duro fun awọn mẹmba iyawo ọjọ iwaju ti Ọkọ-Iyawo tẹmi naa, Jesu Kristi. Laisi àníàní fun idi yii a kò darukọ iyawo kankan ninu apejuwe Jesu; kìkì ọkọ-iyawo ni o fi ara hàn. Nitori naa, kò sí idarudapọ kankan niti alaye naa, bi ẹni pe awọn wundia naa duro fun ẹgbẹ miiran kan.
7. Laaarin akoko igba wo ni ó dabi ẹni pe Ọkọ-Iyawo naa pẹ́ dé lati mu iyawo naa, eesitiṣe?
7 Isopọ ninu igbeyawo ti awọn mẹmba lọ́la ti ẹgbẹ iyawo naa pẹlu Ọkọ wọn ọ̀run kò ṣẹlẹ, bi a ti reti rẹ̀, ní ipari “akoko awọn keferi” ní 1914. (Luku 21:24) Lọna ti ó bọgbọnmu, sí wọn o dabi ẹni pe Ọkọ-Iyawo naa pẹ́ dé, bi o tilẹ jẹ pe ifarahan rẹ̀ ninu Ijọba rẹ̀ ọ̀run ṣẹlẹ ní 1914. Awọn ọdun ti ó kun fun ọ̀fọ̀ wọnni ti Ogun Agbaye I farahan bi òru dudu biribiri ninu ìrírí ẹgbẹ wundia naa.
8. (a) Bawo ni ó ṣe ṣẹlẹ pe, ni sisọ ọ lọna apejuwe, awọn wundia naa tòògbé ti wọn sì lọ sùn? (b) Fun ète wo ni Ọkọ-Iyawo naa ṣe wá sinu tẹmpili, eeṣe ti eyi si ṣe kan ẹgbẹ iyawo naa?
8 Ní sisọrọ lọna apejuwe, awọn wundia naa tòògbé wọn si lọ sùn. Iwaasu ní gbangba nipa ihinrere ti iṣakoso ẹlẹgbẹrun ọdun ti Kristi ti ń bọ wa fun ibukun gbogbo iran eniyan dawọduro niti gidi. Lati ọdun ti Ogun Agbaye I pari, akoko manigbagbe kan ti idajọ bẹrẹ fun awọn wundia iṣapẹẹrẹ naa. Eyi jẹ nitori pe Ọba ti ń ṣakoso naa Jesu Kristi ti dé sinu tẹmpili tẹmi naa. Bi o ti ṣe dé sibẹ, oun bẹrẹ itolẹsẹẹsẹ idajọ ki ó baa lè ṣe iwẹnumọ awọn ti a yansipo lati ṣe iṣẹ-isin ninu tẹmpili fun Jehofa Ọlọrun. (Malaki 3:1-3) Eyi ni akoko fun ifihan ní kedere rẹ̀ ti oun, gẹgẹ bi Ọkọ-Iyawo ti ọ̀run, yoo gba awọn mẹmba ẹgbẹ iyawo naa ti a tẹwọgba ti wọn sì ti kú nigba naa si ọdọ araarẹ̀ ní ọ̀run.
9. Nigba wo ni ó tó akoko lati jí ẹgbẹ awọn wundia naa kalẹ ninu ipo alaisi igbokegbodo, eesitiṣe?
9 Ní 1919, tẹ̀lé itusilẹ awọn mẹmba mẹjọ ti wọn gbajumọ ti Watch Tower Bible and Tract Society lati inu isọsẹwọn laitọ, akoko wá tó wayii lati jí ẹgbẹ awọn wundia naa kuro ninu oorun ti aisi igbokegbodo wọn. Iṣẹ ìlanilóye kárí-ayé wà ní iwaju. Akoko tó fun wọn, pẹlu awọn fitila ti a ti tan ina si, lati pade Ọkọ-Iyawo naa, ti ó ti dé sinu tẹmpili tẹmi. Eyi ri bẹẹ ki awọn eniyan lati inu orilẹ-ede gbogbo lè wọ́ tìrítìrí wá sinu “ile Jehofa” ti a ti gbega rekọja awọn oke nla, ki a sọ ọ lọna bẹẹ.—Isaiah 2:1-4, NW.
Titun Awọn Fitila Wọn Ṣe Bọsipo
10. Ki ni ororo ti a dà lati inu kòlòbó awọn wundia ọlọgbọn-inu naa ṣapẹẹrẹ rẹ̀?
10 Awọn ọlọgbọn-inu ninu ẹgbẹ wundia naa ti mu ipese ororo itanna fun pàjáwìrì dani ninu kòlòbó wọn. Wọn kò lọra rara lati fi ororo sinu fitila wọn. Ororo fun itanmọlẹ naa ṣapẹẹrẹ Ọ̀rọ̀ Jehofa ti ń laniloye ati ẹmi mímọ́ rẹ̀. Nitori naa, ki ni ororo ti a dà lati inu kòlòbó awọn wundia ọlọgbọn-inu naa ṣapẹẹrẹ rẹ̀? Iwọn ẹmi Jehofa ti ó wà nipamọ fun lilo ti ń tanmọlẹ sori Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti a kọsilẹ, eyi ti àṣẹ́kù awọn ẹni-ami-ororo ti awọn ọmọ-ẹhin Ọkọ-Iyawo naa ti a fi ẹmi bi ní ninu araawọn nigba ti a pinnu pe iṣẹ ìlanilóye kárí-ayé nipa “ijọba ọ̀run” naa yoo bẹrẹ ní ọdun ẹhin ogun.
11. Ki ni awọn kòlòbó iṣapẹẹrẹ ti ororo naa wà ninu rẹ̀?
11 Awọn kòlòbó naa ṣapẹẹrẹ awọn wundia ọlọgbọn-inu iṣapẹẹrẹ naa funraawọn bi ẹni ti ó ní ororo ìlanilóye iṣapẹẹrẹ naa ninu. Eyi kò tumọsi pe a ti kọkọ fi ẹmi Jehofa yan ẹgbẹ wundia naa nigba naa. Bẹẹkọ, awọn wundia naa ko fi ẹmi rẹ̀ yan araawọn. Oun ni ó ṣe e!—Isaiah 61:1, 2; Luku 4:16-21.
12. (a) Asọtẹlẹ Joeli wo ni o tó asiko lati ní imuṣẹ lori awọn wundia ọlọgbọn-inu naa? (b) Nigba wo ni akoko tó fun wọn lati jẹ́ ki ìlàlóye tan jade nipasẹ fitila wọn?
12 Ní itilẹhin yiyan wọn fun iṣẹ gbigbooro ti lila araye loye nipa “ijọba ọ̀run,” awọn wundia ọlọgbọn-inu naa ni a ṣojurere si pẹlu imuṣẹ Joeli 2:28, 29 lori wọn. Ọna ti aposteli Peteru gba tọkasi awọn ẹsẹ wọnyi niyi: “Ọlọrun wi pe, Yoo si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi yoo tu ninu Ẹmi mi jade sara eniyan gbogbo: ati awọn ọmọ yin ọkunrin ati awọn ọmọ yin obinrin yoo maa sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin yin yoo sì maa ri iran, awọn arugbo yin yoo sì maa lá àlá.” (Iṣe 2:17) Nitori naa lati 1919 siwaju awọn ọlọgbọn-inu ninu ẹgbẹ awọn wundia iṣapẹẹrẹ naa nilati gbé ohun-eelo itanmọlẹ wọn, fitila iṣapẹẹrẹ wọn—funraawọn. Eyi ni wọn ṣe ki wọn baa lè fun gbogbo awọn ti wọn ṣì wà ninu okunkun nipa tẹmi ní ìlàlóye. Nitori iru igbesi-aye ti wọn ń gbe labẹ agbara idari Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati ẹmi rẹ̀, wọn di “imọlẹ ní ayé.” (Filippi 2:15) Nipa bayii wọn gbé igbesẹ titọpasẹ Ọkọ-Iyawo naa bi oun ti ń mura lati gba gbogbo awọn mẹmba ẹgbẹ iyawo naa sọdọ araarẹ̀ ninu Ijọba ọ̀run lẹhin iku wọn lori ilẹ̀-ayé.—Matteu 5:14-16.
Awọn Abajade Iwa Omugọ Nipa Tẹmi
13. Bawo ni awọn wundia ọlọgbọn-inu naa ṣe dahunpada si ibeere awọn wundia omugọ naa?
13 Ki ni, nisinsinyi, nipa ti awọn omugọ wọnni ninu ẹgbẹ awọn wundia naa? Jesu ń baa lọ lati sọ pe: “Awọn alaigbọn wi fun awọn ọlọgbọn pe, Fun wa ninu ororo yin; nitori fitila wa ń ku lọ. Ṣugbọn awọn ọlọgbọn da wọn lohun, wi pe, Bẹẹkọ; ki o ma baa ṣe alaito fun awa ati ẹyin: ẹ kuku tọ awọn ti ń tà lọ, ki ẹ sì rà fun ara yin.”—Matteu 25:8, 9.
14. Eeṣe ti awọn wundia ti wọn kọ̀ lati ṣajọpin ororo wọn fi jẹ́ ọlọgbọn-inu dipo jijẹ anikanjọpọn?
14 Awọn wọnni ti wọn kọ̀ lati ṣajọpin pẹlu awọn omugọ naa kii ṣe anikanjọpọn, wọn wulẹ jẹ́ ọlọgbọn-inu ni. Wọn ń dìrọ̀ mọ́ mimu ète afẹnifẹre wọn ibẹrẹpẹpẹ ṣẹ ni, ti titanmọlẹ si ayika olokunkun naa ní ṣiṣoju fun Ọkọ-Iyawo naa. Wọn kò si labẹ aigbọdọmaṣe lọnakọna lati juwọsilẹ, lati din iwọn ẹmi mímọ́ Jehofa ti wọn ní kù lati baa lè gba awọn ti wọn jẹ́ omugọ nipa tẹmi mọra. Iru awọn omugọ bẹẹ kò mura araawọn silẹ lati fi aijafara kowọnu anfaani iṣẹ-isin ti ó ṣisilẹ fun wọn ní 1919.
15. (a) Nigba ti akoko alaafia ṣisilẹ, awọn wo ninu ẹgbẹ awọn wundia naa ni o bẹrẹsii fi iwa omugọ nipa tẹmi hàn? (b) Eeṣe ti kò fi ṣeeṣe fun awọn wundia ọlọgbọn-inu naa lati ṣeranwọ fun awọn wundia omugọ nipa tẹmi naa?
15 Bi akoko alaafia ti ṣisilẹ, diẹ lara awọn alabaakẹgbẹpọ wọnyẹn ti wọn sọ pe awọn ti ṣe iyasimimọ, ati baptisi bẹrẹsii fi iwa omugọ nipa tẹmi hàn. Lẹhin iku aarẹ Watch Tower Society akọkọ, Charles Taze Russell, wọn kò fohunṣọkan lẹkun-unrẹrẹ pẹlu bi awọn nǹkan ṣe ń lọ pẹlu ohun-eelo ti a lè fojuri ti Jehofa Ọlọrun ń lò labẹ aarẹ titun rẹ̀, J. F. Rutherford. Ọkan-aya wọn ko ṣọkan niti gidi pẹlu ọna ti a ń gba ṣe awọn nǹkan. Wọn fi aini imọriri hàn fun ọna ti Jehofa gbà bá awọn eniyan rẹ̀ lò. Nipa bayii, kò ṣeeṣe fun awọn ti wọn dabi awọn wundia ọlọgbọn-inu naa lati gbin ẹmi ifọwọsowọpọ atọkanwa gidi sinu awọn omugọ wọnyi ti wọn ń tẹsiwaju ati siwaju sii lati ya araawọn sọtọ.
16. Bawo ni a ṣe mu ki iwa omugọ nipa tẹmi jẹyọ niha ọ̀dọ̀ awọn wundia omugọ naa?
16 Iwa omugọ nipa tẹmi ni a tipa bayii mu ki ó jẹyọ. Bawo? Nipasẹ ikuna lati ní ororo iṣapẹẹrẹ naa ní akoko ti ó ṣe pataki gidi gan-an tí aini kanjukanju wà fun ìlàlóye nipa tẹmi bi idagbasoke titun ti ń tẹsiwaju, ní fifihan pe Ọkọ-Iyawo naa ti dé. Nitori naa akoko niyẹn lati jade lọ pade rẹ̀ pẹlu fitila wọn ti ń tan yanranyanran, ki a sọ ọ lọna apejuwe. Ṣugbọn kaka bẹẹ, awọn wọnni ti ń ṣapẹẹrẹ awọn wundia omugọ naa, ti ina wọn ń ku lọ, pinya pẹlu awọn ti ó jẹ́ ọlọgbọn-inu.
17. Àdánù ti kò ní atunṣe wo ni awọn ti awọn wundia omugọ naa ṣapẹẹrẹ rẹ̀ jiya rẹ̀, bi a ti fihan ninu Matteu 25:10?
17 Ẹ wo iru àdánù ti kò ní atunṣe ti eyi jẹ́ nigba ti ẹnikan ti ó sọ pe a yan oun si ara ẹgbẹ awọn wundia naa bá padanu àyè ati anfaani alailatunṣe naa ti kíkí Ọkọ-Iyawo tẹmi naa, Jesu Kristi kaabọ! Iru àdánù bẹẹ ni awọn omugọ laaarin awọn wundia ti ode-oni jiya rẹ̀, bi awọn ọ̀rọ̀ apejuwe Jesu siwaju sii ṣe fihan! “Nigba ti wọn sì ń lọ rà á, ọkọ-iyawo de; awọn ti ó si muratan ba a wọle lọ si ibi iyawo: a sì ti ilẹkun.”—Matteu 25:10.
18. (a) Anfaani wo ni awọn wundia omugọ ti ọrundun yii kuna lati nipin-in ninu rẹ̀? (b) Eeṣe ti awọn omugọ wọnyi fi pẹ lẹhin jù fun ninipa ninu ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ alayẹyẹ igbeyawo ati wiwọle sinu àpèjẹ naa?
18 Ẹ wo iru iriri abanininujẹ ti awọn wundia omugọ ode-oni jiya rẹ̀! Ní akoko ti ó ṣu dùdù julọ ninu gbogbo itan iran eniyan yii, wọn kuna lati nipin-in ninu iṣẹ líla awọn wọnni ti wọn jokoo sinu okunkun tẹmi ati sinu ojiji iku ninu “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” loye! (Ìfihàn 16:14) Pẹlu aisi ororo ninu fitila iṣapẹẹrẹ wọn lati tanmọlẹ sipa ọna wọn, wọn fi ibẹ silẹ lati maa táràrà ninu okunkun ọganjọ oru. Fun idi yii wọn kò dé lásìkò lati tọ ipasẹ Ọkọ-Iyawo naa ninu ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ onidunnu nla gba ẹnu ọna kọja bọ sinu iyara àpèjẹ igbeyawo ti a ti tan ina yanranyanran sí. Wọn ti padanu ami idanimọ wọn bi ọmọlẹhin rẹ̀ ti wọn wà ní ìlà fun didi ẹni ti ó gbé ni iyawo ní Ijọba ọ̀run. A kò bá wọn ní ‘imuratan’ nigba ti akoko to. Ẹ wo iru apẹẹrẹ onikilọ ti wọn pese funni!
19. Iriri wo ni ń duro dè wá ti a ba tọpinpin ọran yii de opin rẹ̀?
19 Otitọ rironilara yii ni a gbeyọ ní kedere ní apa ikẹhin apejuwe Jesu Kristi, Ọkọ-Iyawo naa, paapaa julọ fun awa ti a ń gbe ní “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.” Nitori naa ẹ jẹ́ ki a tubọ tọpinpin ọran naa siwaju sii! Ilaniloye ti ń funni layọ ń duro dè wá fun ṣiṣe bẹẹ, bi awa yoo ṣe rii ninu akori ti ó tẹ̀lé e yii.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 45]
Awọn wọnni ti wọn dabi awọn wundia omugọ naa kì yoo wọle sinu àpèjẹ igbeyawo naa