ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ws orí 6 ojú ìwé 47-55
  • Ṣíṣọ́nà Ni Akoko “Ipari Eto-Igbekalẹ Awọn Nǹkan”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣọ́nà Ni Akoko “Ipari Eto-Igbekalẹ Awọn Nǹkan”
  • Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Abayọri Ina Fitila Ní Ọganjọ Oru
  • Awọn Alabaakẹgbẹpọ Wiwulo ti Awọn Olutan Imọlẹ Naa
  • “A Sì Ti Ilẹkun”
  • Ìlanilóye fun “Ipari Eto-Igbekalẹ Awọn Nǹkan”
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Wúńdíá Mẹ́wàá Kọ́ Wa
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Ṣé Wàá “Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ṣé O Ò Gbàgbé Ìkìlọ̀ Jésù?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
ws orí 6 ojú ìwé 47-55

Ori 6

Ṣíṣọ́nà Ni Akoko “Ipari Eto-Igbekalẹ Awọn Nǹkan”

1. Eeṣe ti ó fi yẹ ki a maa ṣọna?

ATI rìn jinna sinu “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan,” ṣugbọn a “kò . . . mọ ọjọ tabi wakati” ti akoko ilaniloye ti ń gbẹmila naa yoo pari. Idi niyẹn ti Jesu fi sọ pe: “Nitori naa, ẹ maa ṣọna, bi ẹyin kò ti mọ ọjọ, tabi wakati.”​—⁠Matteu 24:⁠3, NW; 25:⁠13.

2. Iriri onijakulẹ wo ni a gbọdọ yẹra fun?

2 Yoo jẹ́ ijakulẹ gidi fun ẹnikan ti ó ba pẹ́ dé sibi àpèjẹ igbeyawo kan ti ó wá rí ilẹkun ní títì. Sibẹ ohun ti a ti pinnu tẹlẹ pe yoo ṣẹlẹ si ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ti o pọ̀ julọ awọn alafẹnujẹ Kristian niyẹn laipẹ. “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ṣakawe eyi pẹlu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi: “Ni ikẹhin ni awọn wundia yooku si de, wọn ń wi pe, Oluwa, Oluwa, ṣilẹkun fun wa. Ṣugbọn o dahun, wi pe, Loootọ ni mo wi fun yin, emi kò mọ̀ yin.”​—⁠Matteu 25:​11, 12.

3. (a) Ọdun naa 1919 ti jẹ́ akoko fun ki ni? (b) Njẹ o ha ti ṣeeṣe fun awọn onisin Kristẹndọm lati pese ororo tẹmi ti a ń fẹ bi?

3 Lati 1919 ni ilaloye nipa tẹmi lati ọwọ́ awọn ọlọgbọn-inu pẹlu iranlọwọ “ororo” Ọ̀rọ̀ ati ẹmi mímọ́ Jehofa ti wà larọọwọto, ṣugbọn awọn omugọ gbiyanju lati ra ororo tẹmi lati ọwọ́ awọn wọnni ninu Kristẹndọm ti wọn sọ pe awọn ń tà á. (Matteu 25:⁠9) Bi o ti wu ki o ri, awọn onisin Kristẹndọm kò ní iru ororo ti ó yẹ. Ko ṣeeṣe fun wọn lati pese imọlẹ oye nipa wiwanihin-⁠in Jesu Kristi bi Ọkọ-Iyawo ti ọ̀run. Wọn ń reti pe nigba ti wọn bá kú wọn yoo lọ si ọ̀run lẹsẹkẹsẹ lati pade rẹ̀, laijẹ pe wọn ṣajọpin ninu iṣẹ ilaloye naa lakooko “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.”

4. Titi di isinsinyi, ki ni awọn wọnni ti awọn wundia omugọ naa ṣapẹẹrẹ rẹ̀ ti kuna lati ṣe, eesitiṣe?

4 Lodikeji ẹ̀wẹ̀, awọn kan wà, gẹgẹ bi awọn wundia nipa tẹmi, ti wọn ti fi ẹri hàn pe wọn ní “ororo” ti ẹmi mímọ́ ati Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ipamọ fun iṣẹ́ ilaniloye kárí-ayé nipa “ijọba naa” ní ọdun ẹhin ogun. (Matteu 24:14) Awọn tí owe Jesu ṣapẹẹrẹ rẹ̀ bi awọn wundia omugọ kò nipin-in ninu rẹ̀ nipa jijẹ ki imọlẹ tàn sori ihinrere yii ti ó ní ijẹpataki kárí-ayé kan. Wọn kò ní “ororo” Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti ń laniloye ati ẹmi mímọ́ rẹ̀, Ọkọ-Iyawo Onidaajọ ti ó wà ninu tẹmpili tẹmi naa si ṣakiyesi ikuna wọn yii. Kò si ọkàn wọn ninu iṣẹ ọdun ẹhin ogun naa ti a bẹrẹ rẹ̀ laijafara ní 1919 lati ọwọ́ awọn wundia Kristian ti wọn jẹ́ ọlọgbọn-inu ni fifoye mọ akoko ati iṣẹ naa.

5. Ninu ki ni awọn wundia omugọ naa kuna lati nipin-in, ti ó si ṣe pataki fun isopọ wọn pẹlu Ọba Ọkọ-Iyawo naa?

5 Ní yiya araawọn sọtọ kuro lọdọ awọn wọnni ti ó kọwọ ti ètò-àjọ Jehofa ti a lè fojuri lẹhin, awọn omugọ naa ń kuna lati ṣajọpin ninu iṣẹ ijẹrii Ijọba naa kárí-ayé. Ní igbẹhin-gbẹhin wọn ri “ororo” ilaniloye ti isin gbà, ṣugbọn kii ṣe iru ororo ti ó yẹ. Ki yoo pese imọlẹ oye fun iṣẹlẹ títọ́ kan ní akoko ti ó tọ́. Nitori naa wọn kò waasu ihin-iṣẹ Ijọba naa ati “ọjọ ẹsan Ọlọrun wa.” (Isaiah 61:​1-⁠3) Wọn kò kókìkí Ọba Ọkọ-Iyawo naa bi àṣẹ́kù awọn ẹni-ami-ororo ti ẹgbẹ wundia naa ti ń ṣe.

Abayọri Ina Fitila Ní Ọganjọ Oru

6, 7. (a) Ki ni ṣẹlẹ laaarin awọn ọdun 1930 ti ó damọran pe awọn wundia ti wọn wà ti tó lati mu iye mẹmba ẹgbẹ iyawo naa pe rẹgi? (b) Si ẹgbẹ ti ó yẹ ki a kojọpọ wo ni a pe afiyesi si?

6 Laaarin awọn ọdun 1930, ohun ṣiṣe pataki kan ṣẹlẹ. Ohun ti ó ṣẹlẹ naa damọran pe iye mẹmba iyawo Kristi tẹmi ti pé, pe iye awọn ọmọ-ẹhin Ọkọ-Iyawo naa ti a fi ẹmi bi ti wọn wà lori ilẹ̀-ayé ti pọ̀ tó lati kunju iye awọn mẹmba ẹgbẹ iyawo rẹ̀ ti ọ̀run.

7 Nigba yẹn, ní 1935, a bẹrẹsii pe afiyesi sí ẹgbẹ miiran ti awọn ẹni bi agutan ọmọ-ẹhin Jesu. Ẹgbẹ yii ni a ti kọ́kọ́ pè wá si afiyesi gbogbogboo ní igba ogun agbaye kìn-ín-ní. Ní February 24, 1918, ni a sọ asọye kan lori ọrọ-ẹkọ naa “Araadọta Ọkẹ Ti Wọn N Bẹ Laaye Nisinsinyi Lè Ma Ku Mọ́ Lae” fun awujọ olufi iharagaga fẹ́ lati mọ̀ kan, ti ó ṣeeṣe ki wọn kun fun iyemeji. Ní apejọpọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti 1935 ní Washington, D.C., ohun ti ó ṣe deedee kan ni a nasẹ rẹ̀ sode nipa ṣiṣe ikojọpọ awọn araadọta ọkẹ “awọn agutan miiran” ti Kristi yii sinu “agbo” ti a mu ṣọkan labẹ Jesu Kristi gẹgẹ bi “oluṣọ agutan kan” naa. (Johannu 10:16) Ami ìdánimọ̀ ti ẹgbẹ “awọn agutan miiran” yii bi a ti sọ ọ tẹ́lẹ̀ ninu Ìfihàn 7:​9-⁠17 ni a tọka jade.

8. Abẹ́ iṣẹ aigbọdọmaṣe wo, ti wọn kò fojusọna fun tẹ́lẹ̀, ni awọn wundia ọlọgbọn-inu naa bọ́ sí ní 1935?

8 Àṣẹ́kù “agbo kekere” naa wá bọ sabẹ iṣẹ aigbọdọmaṣe ti bibẹrẹ ikojọpọ “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran.” (Luku 12:32) Eyi jẹ́ nitori pe iye awọn wundia ọlọgbọn-inu ti a ń fẹ fun iyawo Jesu lati pé rẹgi ni ó ti kún nisinsinyi. Ṣugbọn iru awọn wundia bẹẹ ni a kò mu lọ si ọ̀run lẹsẹkẹsẹ. A ṣì maa pe wọn wọle sinu yara àpèjẹ naa nigba ti wọn ba pari iṣẹ wọn ori ilẹ̀-ayé bi awọn ẹlẹ́rìí olupa iwatitọ mọ́ fun Ọlọrun wọn, Jehofa. Nitori iṣẹ iṣotitọ wọn ti ilaniloye titi de 1935, a dari wọn si anfaani pataki kan ti wọn kò fojusọna fun tẹ̀lẹ́ ṣaaju ìlàjì awọn ọdun 1930.

9. Iye àṣẹ́kù awọn wundia ọlọgbọn-inu naa ti wá yipada di mélòó nisinsinyi?

9 Eyi ti ó ju aadọta ọdun ni ó ti kọja lati 1935, ati ní awọn ọdun wọnyi iye awọn ọlọgbọn-inu ti ẹgbẹ awọn wundia naa ti ń dinku sii. Ní odikeji ẹ̀wẹ̀, iṣẹ ijẹrii naa ti gbooro sii kárí-ayé ní idiwọn, bẹẹni, ti ó fi ní eyi ti ó ju 200 ilẹ ọtọọtọ ninu. Nisinsinyi, ẹgbẹ awọn wundia naa ti lọsilẹ si eyi ti o dinku si 9,000 ní iye.

Awọn Alabaakẹgbẹpọ Wiwulo ti Awọn Olutan Imọlẹ Naa

10. Loju iwoye iṣẹ ribiribi yii, o ha ṣeeṣe fun àṣẹ́kù awọn wundia ọlọgbọn-inu naa lati kaju iwọn aini naa fun awọn oṣiṣẹ bi?

10 Àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo ti awọn wundia iṣapẹẹrẹ naa ni awọn olupolongo Ijọba ti wọn ju igba ọ̀kẹ́ lọ ti wọn wà ninu eyi ti ó ju 69,000 ijọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kárí-ayé ti fẹrẹẹ bò mọlẹ patapata kuro ninu iran naa. Bawo ni yoo ti ṣeeṣe fun iye kereje àṣẹ́kù awọn ẹni-ami-ororo lati bojuto iṣẹ ijẹrii naa ní eyi ti ó ju 200 ilẹ nibi ti awọn ẹgbẹẹgbẹrun ijọ wọnyẹn wà? Kò ṣeeṣe fun wọn.

11. (a) Dida “ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” naa mọ mu ki ki ni ṣẹlẹ laaarin awọn wọnni ti wọn sọ pe wundia ni awọn? (b) Ki ni kò ṣeeṣe fun ẹgbẹ “ẹru buburu naa” lati foyemọ nitori aini imọlẹ oye tẹmi ti ó tó?

11 Bi o ti wu ki o ri, wọn ṣiṣẹsin ní ibamu pẹlu Iwe Mímọ́ ní ipo ti a sọtẹlẹ naa ti “ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” tí Ọkọ-Iyawo Ọga naa bá ní oluṣotitọ nigba ti ó wá sinu tẹmpili fun idajọ. Igba yẹn gan-⁠an ni ipinya bẹrẹsii ṣẹlẹ laaarin awọn wundia ọlọgbọn-inu ati awọn wundia omugọ ti ẹgbẹ awọn wundia iṣapẹẹrẹ naa. Awọn tí a kà sí ẹgbẹ “ẹru buburu naa” kò ní ororo ilaniloye ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati ẹmi mímọ́ rẹ̀ ninu kòlòbó wọn lati fi tan fitila wọn. Nipa bayii wọn kò ní imọlẹ oye tẹmi ti ó tó lati foyemọ “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ti a ti ń kojọpọ nisinsinyi lati ọdun 1935 gẹgẹ bi apakan “agbo kan” yẹn.​—⁠Matteu 24:​45-⁠51, NW.

12. Awọn wo ni ó ti wa di alabaakẹgbẹpọ alaiṣeeja pẹlu àṣẹ́kù ẹgbẹ iyawo naa?

12 Lati igba Ogun Agbaye II, imuṣẹ asọtẹlẹ Jesu fun “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” ni eyi ti ó pọ julọ jẹ́ nitori ipa ti “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ń sà. Imọlẹ oye lati inu awọn fitila àṣẹ́kù ti a tàn ti mu ki oju ọkan wọn mọlẹ sii, a sì ti ran wọn lọwọ lati ta àtagbà imọlẹ yẹn si awọn ẹlomiran ti wọn ṣì wà ninu okunkun ayé yii. (Fiwe Efesu 1:18.) Wọn ti ran araadọta ọkẹ awọn olugbe ilẹ̀-ayé yii lọwọ lati fi oye mọ wiwanihin-⁠in Ọba Ọkọ-Iyawo naa bi ọjọ igbeyawo rẹ̀ pẹlu ẹkunrẹrẹ ẹgbẹ iyawo naa ti ń sunmọle. Wọn ti wa di alabaakẹgbẹpọ alaiṣeeja pẹlu àṣẹ́kù ẹgbẹ iyawo naa.

13, 14. (a) Ipo amunilọkanyọ wo niti awọn alabaakẹgbẹpọ àṣẹ́kù naa ni a fi apejuwe tolẹsẹẹsẹ ninu Ìfihàn 7:​9, 10? (b) Ki ni idahunpada oju ẹsẹ si alaye asọtẹlẹ yẹn?

13 Lati 1935 ipin awọn alabaakẹgbẹpọ àṣẹ́kù ẹgbẹ iyawo naa wọnyi ti jẹ́ ti onidunnu nla kan. Wọn ń yọ̀ kii ṣe kiki lori awọn anfaani atobilọla eyi ti àṣẹ́kù naa ti kowọnu rẹ̀ nikan ni ṣugbọn bakan naa lori awọn anfaani onibukun ninu eyi ti a ti ṣamọna awọn funraawọn si nipasẹ àṣẹ́kù ẹgbẹ iyawo naa.

14 Ẹsẹ iwe mímọ́ agbayanu kan ni a ṣipaya si oye awọn eniyan Jehofa ninu apejọpọ ti 1935, ní Washington, D.C., o sọtẹlẹ nipa ipo amunilọkanyọ kan fun “ogunlọgọ nla” naa, alabaakẹgbẹpọ ẹni-ami-ororo. Wò wọn nibẹ, “wọn duro niwaju itẹ [Jehofa Ọlọrun], ati niwaju Ọdọ-Agutan naa, a wọ̀ wọn ní aṣọ funfun, imọ̀-ọ̀pẹ si ń bẹ ní ọwọ wọn”! Fetisilẹ si ohun ti wọn ń kigbe jade ní ohùn rara fun gbogbogboo lati gbọ́: “Igbala ni ti Ọlọrun wa ti ó jokoo lori itẹ, ati ti Ọdọ-Agutan”! (Ìfihàn 7:​9, 10) Wọn ti fi igbagbọ hàn ninu “Ọdọ-Agutan Ọlọrun, ẹni ti ó ko ẹṣẹ ayé lọ,” ati nipasẹ rẹ̀ wọn ti ya araawọn si mímọ́ fun Jehofa Ọlọrun wọn si ti ṣe iribọmi ní apẹẹrẹ iyasimimọ yẹn. (Johannu 1:29) Eeṣe, 840 ninu wọn ni wọn ṣe iribọmi ní ọjọ ti o tẹle gbigbọ alaye Ìfihàn 7:​9-⁠17 ní Friday, May 31, 1935.

15. Lati ìgbà naa, awọn meloo ni a ti ṣe iribọmi fun, bawo ni a sì ti ṣapẹẹrẹ wọn ninu Ìfihàn 7:​14-⁠17?

15 Eyi ti ó ju igba ọ̀kẹ́ lọ ti ṣe bakan naa lati ìgbà apejọpọ Washington yẹn ni 1935. Nipa bayii a ṣapẹẹrẹ wọn bi ẹni ti a wọ̀ ní aṣọ funfun nitori ti a ti fọ̀ wọn ninu ẹjẹ iwẹnumọ Ọdọ-Agutan naa. Wọn si ní ireti jijade wá lati inu ipọnju nla naa ti ó wà ní iwaju fun gbogbo ayé araye, nitori wọn ní aabo atọrunwa taarata la ipọnju naa já. (Matteu 24:​21, 22) Nitori naa, a ṣaṣefihan wọn bi ẹni wà ninu tẹmpili tẹmi ti Jehofa ti wọn sì ń sin in nibẹ pẹlu àṣẹ́kù ẹgbẹ awọn wundia naa.​—⁠Ìfihàn 7:​14-⁠17.

16. Nigba naa, si awọn ta ni a dari ọpẹ gidigidi si niti ipa ti wọn sà ní isopọ pẹlu mimu Matteu 24:14 ṣẹ?

16 Ọpẹ gidigidi ni, nigba naa, fun “ogunlọgọ nla” elédè ahọn pupọ naa jakejado awọn orilẹ-ede fun ipa ribiribi ti wọn ti sà ní mimu asọtẹlẹ Ọkọ-Iyawo naa ninu Matteu 24:14 ṣẹ!

“A Sì Ti Ilẹkun”

17. (a) Nigba wo ni a ó ti ilẹkun àpèjẹ igbeyawo naa? (b) Ki ni ohun ti ó yẹ fun àṣẹ́kù ẹgbẹ awọn wundia naa ati “ogunlọgọ nla” alabaakẹgbẹpọ wọn lati ṣe nisinsinyi?

17 Akoko gan-⁠an ti àṣẹ́kù ẹgbẹ awọn wundia naa yoo ti wọnu ayẹyẹ àsè igbeyawo naa, ti a o sì wá ti ilẹkun, ni a kò mọ̀. Ṣugbọn laiṣe aniani o sunmọle ju ti igbakigba ri lọ, akoko sì ń tan lọ! Lọna ti o baamu gẹẹ, nigba naa, Jesu pari owe awọn wundia naa pẹlu awọn ọ̀rọ̀ ikilọ naa pe: “Nitori naa ẹ maa ṣọna, bi ẹyin kò ti mọ ọjọ tabi wakati.”​—⁠Matteu 25:⁠13.

18. (a) Awọn wo ni awọn wundia omugọ naa darapọ mọ́ nisinsinyi? (b) Apa wo ninu owe Jesu ni wọn yoo ní iriri rẹ̀ laipẹ?

18 Nitori idi eyi awọn wundia omugọ naa ni a o bá lábo laisi lojufo. Nipa pipinya pẹlu awọn wundia ọlọgbọn-inu naa, wọn ti di apakan ayé ti a ti dalẹbi yii, wọn sì ka araawọn kun ẹgbẹ gbogbo awọn onisin miiran ti wọn wà ní ita ninu okunkun kárí-ayé ti ó tubọ ń ṣú dùdù sii. Nipa bayii a ti ṣedajọ wọn lati ní iriri ohun ti Ọkọ-Iyawo naa Jesu Kristi fihan ninu awọn ọ̀rọ̀ owe rẹ̀ wọnyi: “Ní ikẹhin ni awọn wundia yooku si de, wọn ń wi pe, Oluwa, Oluwa, ṣilẹkun fun wa. Ṣugbọn o dahun, wi pe, Loootọ ni mo wi fun yin, emi kò mọ̀ yin.”​—⁠Matteu 25:​10-⁠12.

19. Awọn wo ni awọn wundia omugọ naa jẹ apejuwe rẹ̀ nigba naa, eesitiṣe ti a o fi kà wọn mọ́ Babiloni Nla?

19 Nitori naa ilẹkun sinu àpèjẹ naa ni a kò ní ṣí fun awọn wundia omugọ wọnni. Wọn jẹ́ apejuwe daradara ti awọn wọnni ti wọn kuna laaarin “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” lati dé “ijọba ọ̀run.” (Matteu 24:⁠3; 25:⁠1) Nitori ti wọn tẹpẹlẹ mọ́ iru ijọsin ti wọn yàn, bi lilọ ti wọn lọ si ọjà lati ra ororo miiran ti fihàn, a kà wọn mọ́ Babiloni Nla.

20. (a) Nigba ti awọn wundia omugọ naa ba rii ti “iwo mẹwaa” “ẹranko ẹhanna” naa ba bẹrẹsii yijupada lodisi Babiloni Nla, ta ni wọn yoo ké gbajare lọ bá ati lori sisọ pe wọn jẹ ki ni? (b) Sibẹsibẹ, eeṣe ti iparun yoo fi jẹ ti wọn?

20 Nitori naa, nigba ti “ẹranko ẹhanna” iṣapẹẹrẹ naa, eyi ti obinrin agbere onisin naa ń gun, bá yijupada lodisi i pẹlu “iwo mẹwaa” rẹ̀, wọn yoo pin ninu atubọtan rẹ̀. (Ìfihàn 17:16) Nigba ti iru awọn onisin bẹẹ, ti awọn wundia omugọ marun-un naa ṣapẹẹrẹ rẹ̀, ba ri ibẹrẹ kikọ isin Babiloni silẹ lati ọwọ́ ẹgbẹ ogun alagbara ti awọn alaṣẹ iṣelu, wọn yoo yíjú si Ọba Ọkọ-Iyawo naa, ní sisọ pe awọn jẹ́ ara ẹgbẹ ti “ijọba ọ̀run” naa ti wọn si lẹ́tọ̀ọ́ si ìgbàwọlé sinu ayẹyẹ igbeyawo tẹmi naa pẹlu awọn wundia ọlọgbọn-inu naa. Lọna bibanilẹru, ẹni naa ti wọn pè ní “Oluwa,” Ọkọ-Iyawo naa Jesu Kristi, yoo kọ̀ lati tẹwọgba wọn bi ẹni ti ó lẹ́tọ̀ọ́ si gbígbàwọlé sinu Ijọba ọ̀run. Wọn kò si tii fi igba kan ri ṣajọpin ireti iye ayeraye eyikeyii lori ilẹ̀-ayé pẹlu “ogunlọgọ nla” naa. Nitori naa kò si ohun ti ó kù silẹ fun awọn omugọ onisin wọnyi ayafi iparun pẹlu ilẹ ọba-isin eke agbaye, Babiloni Nla!

21. (a) Loju iwoye ifojusọna ti ń kó jìnnìjìnnì báni yẹn, ipa ọna wo ni awọn wundia ọlọgbọn-inu naa ati awọn alabaakẹgbẹpọ wọn ń lepa rẹ̀? (b) Awọn anfaani iṣẹ-isin wo ni awọn mẹmba “ogunlọgọ nla” naa ń reti lati gbadun rẹ̀?

21 Ẹ wo iru ifojusọna ti ń kó jìnnìjìnnì báni ti wọn ń reti! Ní mimọ eyi, àṣẹ́kù naa ati ọgọọrọ awọn alabaakẹgbẹpọ wọn yoo maa kọbiara si imọran Jesu nigbagbogbo lati maa “ṣọna.” Gbogbo igba ni wọn yoo maa kun fun ẹmi mímọ́ Ọlọrun ti wọn yoo si maa jẹ́ ki imọlẹ naa tàn laibẹru si ogo Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi. Gẹgẹ bi ẹsan, idunnu nla ni ipin tiwọn didaju! Awọn ipo ọmọ-alade ninu “ayé titun” naa ń duro de awọn mẹmba “ogunlọgọ nla” naa, gẹgẹ bi a ti yàn án lati ọwọ́ Ọba Ọkọ-Iyawo ti ó ti ṣe igbeyawo naa.​—⁠Isaiah 32:⁠1; fiwe Orin Dafidi 45:⁠16.

22. (a) Imuṣẹ owe awọn wundia naa ṣiṣẹ gẹgẹ bi ẹri idaniloju fun otitọ wo? (b) Ta ni yoo yọ̀ lori igbeyawo Ọba Ọkọ-Iyawo naa pẹlu wundia iyawo rẹ̀?

22 Nitori naa imuṣẹ gbigbooro ti owe awọn wundia mẹwaa naa ṣiṣẹ gẹgẹ bi ẹri idaniloju otitọ naa pe awa ń gbe ní “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.” Ẹ wo bi ó ti yẹ ki a mọriri rẹ̀ tó pe a ti là wa loye lati ri ẹri sisunmọle igbeyawo Jesu Kristi pẹlu ẹkunrẹrẹ ẹgbẹ iyawo rẹ̀! Lori igbeyawo ọ̀run yii, ọ̀run ati “ayé titun” lapapọ yoo yọ̀ pẹlu ayọ̀ ti kò ṣee fẹnusọ.​—⁠Ìfihàn 19:​6-⁠9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́