ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 March ojú ìwé 2-7
  • Má Jẹ́ Kí Ohunkóhun Dí Ẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣèrìbọmi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Jẹ́ Kí Ohunkóhun Dí Ẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣèrìbọmi
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN ARÁ SAMÁRÍÀ ṢÈRÌBỌMI
  • SỌ́Ọ̀LÙ ARÁ TÁSÙ ṢÈRÌBỌMI
  • KỌ̀NÍLÍÙ ṢÈRÌBỌMI
  • ÀWỌN ARÁ KỌ́RÍŃTÌ ṢÈRÌBỌMI
  • ÌGBÀGBỌ́ RẸ LÈ ṢÍ ÒKÈ KÚRÒ NÍBI TÓ WÀ
  • “Máa Tẹ̀ Lé” Jésù, Lẹ́yìn Tó O Bá Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ṣé O Ti Ṣe Tán Láti Ya Ara Ẹ Sí Mímọ́ fún Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 March ojú ìwé 2-7

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 9

ORIN 51 A Ti Ya Ara Wa sí Mímọ́ fún Ọlọ́run!

Má Jẹ́ Kí Ohunkóhun Dí Ẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣèrìbọmi

“Kí lò ń dúró dè? Dìde, kí o ṣèrìbọmi.”—ÌṢE 22:16.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpẹẹrẹ àwọn ará Samáríà, Sọ́ọ̀lù ará Tásù, Kọ̀nílíù atàwọn ará Kọ́ríńtì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú kó o lè ṣèrìbọmi.

1. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣèrìbọmi?

ṢÉ O nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tó ń fún ẹ ní gbogbo ohun tó o fẹ́, tó sì jẹ́ kó o wà láàyè? Ṣé wàá fẹ́ ṣe nǹkan tó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀? Nǹkan tó dáa jù tó o lè ṣe ni pé kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó o sì ṣèrìbọmi. Àwọn nǹkan yìí máa jẹ́ kó o di ara ìdílé Jèhófà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà Bàbá ẹ ọ̀run àti Ọ̀rẹ́ ẹ máa tọ́ ẹ sọ́nà, á sì máa bójú tó ẹ torí pé o ti di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀. (Sm. 73:24; Àìsá. 43:1, 2) Yàtọ̀ síyẹn, ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi máa jẹ́ kó o wà láàyè títí láé.—1 Pét. 3:21.

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Ṣé ohun kan wà tí ò jẹ́ kó o tíì ṣèrìbọmi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, bó ṣe rí fáwọn míì náà nìyẹn. Àìmọye àwọn ará ló yí ìwà wọn àti bí wọ́n ṣe ń ronú pa dà kí wọ́n lè ṣèrìbọmi. Ní báyìí, wọ́n ń láyọ̀, wọ́n sì ń fìtara sin Jèhófà. Kí lo lè kọ́ lára àwọn kan tó ṣèrìbọmi nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n ní àtohun tá a lè kọ́ lára wọn.

ÀWỌN ARÁ SAMÁRÍÀ ṢÈRÌBỌMI

3. Ìṣòro wo làwọn ará Samáríà kan gbọ́dọ̀ borí kí wọ́n tó lè ṣèrìbọmi?

3 Nígbà ayé Jésù, ẹ̀sìn àwọn ará Samáríà yàtọ̀ sí ẹ̀sìn àwọn Júù, itòsí Ṣékémù àti Samáríà àtijọ́ tó wà ní àríwá Jùdíà ni wọ́n sì ń gbé. Kí àwọn ará Samáríà tó lè ṣèrìbọmi, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, ìyẹn ìwé Jẹ́nẹ́sísì títí dé Diutarónómì nìkan ni wọ́n gbà gbọ́, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n tún gba ìwé Jóṣúà gbọ́. Àmọ́, àwọn ará Samáríà ń retí Mèsáyà torí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe ní Diutarónómì 18:18, 19. (Jòh. 4:25) Kí wọ́n tó lè ṣèrìbọmi, wọ́n gbọ́dọ̀ gbà pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. “Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà” ló sì gba èyí gbọ́. (Jòh. 4:39) Àmọ́ àwọn ará Samáríà kan gbọ́dọ̀ borí ìkórìíra tó wà láàárín wọn àtàwọn Júù.—Lúùkù 9:52-54.

4. Kí ni Ìṣe 8:5, 6, 14 sọ pé àwọn ará Samáríà kan ṣe nígbà tí Fílípì wàásù fún wọn?

4 Kí ló mú káwọn ará Samáríà ṣèrìbọmi? Nígbà tí Fílípì ajíhìnrere “wàásù nípa Kristi” fáwọn ará Samáríà, àwọn kan lára wọn “gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Ka Ìṣe 8:5, 6, 14.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Júù ni Fílípì, wọ́n gbọ́ ìwàásù ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan nínú ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ inú Bíbélì tó sọ pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. (Diu. 10:17-19) Èyí ó wù ó jẹ́, wọ́n “pọkàn pọ̀ sórí ohun tí Fílípì ń sọ” nípa Kristi, wọ́n sì rí ẹ̀rí tó dájú pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú Fílípì. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ló ṣe, lára ẹ̀ ni pé ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó sì lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù jáde.—Ìṣe 8:7.

5. Kí lo kọ́ lára àwọn ará Samáríà?

5 Àwọn ará Samáríà yẹn lè sọ pé àwọn ò ní ṣèrìbọmi torí pé àwọn àtàwọn Júù kì í ṣe nǹkan pa pọ̀ tàbí torí pé àwọn ò mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà táwọn ará Samáríà rí i pé òtítọ́ ni Fílípì kọ́ wọn, kíákíá ni wọ́n ṣèrìbọmi. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí wọ́n gba Fílípì gbọ́, ẹni tó ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti orúkọ Jésù Kristi, tọkùnrin tobìnrin wọn sì ń ṣèrìbọmi.” (Ìṣe 8:12) Ṣé o gbà pé òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í kórìíra àwọn èèyàn? Ṣé o tún gbà pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa, ìyẹn sì lohun tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀? (Jòh. 13:35) Torí náà, má bẹ̀rù, tó o bá ṣèrìbọmi, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ẹ.

6. Kí lo kọ́ lára Ruben?

6 Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí Ruben, orílẹ̀-èdè Jámánì ló sì dàgbà sí. Àmọ́ nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, kò dá a lójú pé Jèhófà wà. Báwo ló ṣe borí iyèméjì tó ní? Nígbà tó mọ̀ pé ẹ̀kọ́ yẹn ò yé òun dáadáa, ó ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. Ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í dá kẹ́kọ̀ọ́ kí n lè mọ òótọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ka àwọn ìwé tó jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn nǹkan ò ṣàdédé wà, Ọlọ́run ló dá wọn.” Ó ka ìwé Is There a Creator Who Cares About You? Ìwé yẹn ran Ruben lọ́wọ́ gan-an. Ló bá sọ pé: ‘Ẹ̀n-ẹ́n! Àṣé Jèhófà wà lóòọ́tọ́.’ Nígbà tí Ruben lọ sí orílé iṣẹ́ wa, ó túbọ̀ mọyì ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé. Nígbà tó pa dà sí Jámánì, ó ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17). Torí náà, tí ohun tó o gbà gbọ́ ò bá dá ẹ lójú, rí i pé o ṣèwádìí nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. “Ìmọ̀ pípéye” ò ní jẹ́ kó o máa ṣiyèméjì. (Éfé. 4:13, 14) Tó o bá ń gbọ́ báwọn ará ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n wà níṣọ̀kan kárí ayé, tó o sì tún fojú ara ẹ rí i nínú ìjọ tó o wà, wàá túbọ̀ mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kárí ayé.

SỌ́Ọ̀LÙ ARÁ TÁSÙ ṢÈRÌBỌMI

7. Èrò tí ò tọ́ wo ló yẹ kí Sọ́ọ̀lù ṣàtúnṣe ẹ̀?

7 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Sọ́ọ̀lù ará Tásù. Ó mọ òfin àwọn Júù dáadáa, ó ń fìtara ṣe ẹ̀sìn Júù, ó sì gbajúmọ̀ láàárín wọn. (Gál. 1:13, 14; Fílí. 3:5) Nígbà yẹn, ojú apẹ̀yìndà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù fi ń wo àwọn Kristẹni. Torí náà, Sọ́ọ̀lù ta kò wọ́n, ó sì fojú wọn rí màbo. Ó rò pé inú Ọlọ́run dùn sóhun tóun ń ṣe. (Ìṣe 8:3; 9:1, 2; 26:9-11) Tí Sọ́ọ̀lù bá gba Jésù gbọ́, tó sì ṣèrìbọmi kó lè di Kristẹni, ó gbọ́dọ̀ ṣe tán láti fara da àtakò.

8. (a) Kí ló mú kí Sọ́ọ̀lù ṣèrìbọmi? (b) Kí ni Ìṣe 22:12-16 sọ pé Ananáyà ṣe kó lè ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Kí ló mú kí Sọ́ọ̀lù ṣèrìbọmi? Nígbà tí Jésù Olúwa tá a ti ṣe lógo fara han Sọ́ọ̀lù, ojú ẹ̀ fọ́. (Ìṣe 9:3-9) Ọjọ́ mẹ́ta gbáko ló fi gbààwẹ̀, ó sì dájú pé ó máa ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Ó wá dá Sọ́ọ̀lù lójú pé Jésù ni Mèsáyà àti pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ló ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́. Ó ṣeé ṣe kí ọkàn Sọ́ọ̀lù dá a lẹ́bi torí ó wà lára àwọn tó pa Sítéfánù! (Ìṣe 22:20) Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta tó ti ń gbààwẹ̀, ọmọ ẹ̀yìn Jésù kan tó ń jẹ́ Ananáyà wá sọ́dọ̀ ẹ̀, ó la ojú ẹ̀, ó sì gbà á níyànjú pé kó ṣèrìbọmi láìjáfara. (Ka Ìṣe 22:12-16.) Torí pé Sọ́ọ̀lù nírẹ̀lẹ̀, ó gbà kí Ananáyà ran òun lọ́wọ́, ó sì ṣèrìbọmi.—Ìṣe 9:17, 18.

Sọ́ọ̀lù ń wọnú odò kó lè ṣèrìbọmi. Inú àwọn tó wà níbẹ̀ ń dùn bí wọ́n ṣe ń wò ó.

Ṣé wàá jẹ́ kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣèrìbọmi bíi ti Sọ́ọ̀lù? (Wo ìpínrọ̀ 8)


9. Kí lo kọ́ lára Sọ́ọ̀lù?

9 Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ lára Sọ́ọ̀lù. Tí Sọ́ọ̀lù bá jẹ́ agbéraga tàbí tó jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn mú òun, ó lè má ṣèrìbọmi. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Torí pé ó nírẹ̀lẹ̀, ó yí pa dà, ó sì gbà láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (Ìṣe 26:14, 19) Sọ́ọ̀lù ṣe tán láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù bó tiẹ̀ mọ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sóun. (Ìṣe 9:15, 16; 20:22, 23) Lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó gbára lé Jèhófà pé á ran òun lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro tóun bá ní. (2 Kọ́r. 4:7-10) Torí náà, tó o bá ṣèrìbọmi tó o sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣeé ṣe káwọn ìṣòro tó máa dán ìgbàgbọ́ ẹ wò yọjú, àmọ́ Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó dájú pé Ọlọ́run àti Kristi ò ní fi ẹ́ sílẹ̀.—Fílí. 4:13.

10. Kí lo kọ́ lára Anna?

10 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Anna tó wá látinú ẹ̀yà Kurd ní ìlà oòrùn Yúróòpù. Lẹ́yìn tí ìyá ẹ̀ ṣèrìbọmi, bàbá ẹ̀ fọwọ́ sí i pé kó máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án. Àmọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí Anna tó ń gbé pẹ̀lú wọn ò fara mọ́ ọn pé kó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n sọ pé ìtìjú ńlá ni pé kéèyàn fi ẹ̀sìn àwọn baba ńlá ẹ̀ sílẹ̀. Nígbà tí Anna pé ọmọ ọdún méjìlá (12), ó bẹ bàbá ẹ̀ pé kó jẹ́ kóun ṣèrìbọmi. Àmọ́ bàbá ẹ̀ fẹ́ mọ̀ bóyá òun fúnra ẹ̀ ló pinnu pé òun fẹ́ ṣèrìbọmi àbí ẹnì kan ló fẹ́ fipá mú un. Ó wá sọ fún bàbá ẹ̀ pé, “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.” Bí bàbá ẹ̀ ṣe gbà kó ṣèrìbọmi nìyẹn. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n máa ń fi Anna ṣe yẹ̀yẹ́ gan-an, wọ́n sì fojú ẹ̀ rí màbo. Ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ sọ pé, “Ó sàn kó o máa ṣèṣekúṣe, kó o sì máa mu sìgá ju kó o di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ.” Kí ló ran Anna lọ́wọ́? Ó sọ pé, “Jèhófà fún mi lókun kí n lè fara dà á, ìyá mi àti bàbá mi sì dúró tì mí gbágbáágbá.” Anna kọ àwọn ìgbà tó ti rọ́wọ́ Jèhófà láyé ẹ̀ sínú ìwé kan, ó sì tọ́jú ẹ̀. Ó máa ń yẹ̀ ẹ́ wò látìgbàdégbà kó má bàa gbàgbé bí Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́. Torí náà, tó o bá ń bẹ̀rù pé wọ́n á ṣe inúnibíni sí ẹ tó o bá ṣèrìbọmi, rántí pé Jèhófà máa ran ìwọ náà lọ́wọ́.—Héb. 13:6.

KỌ̀NÍLÍÙ ṢÈRÌBỌMI

11. Kí ló lè mú kí Kọ̀nílíù má fẹ́ ṣèrìbọmi?

11 Ẹlòmíì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni Kọ̀nílíù. “Balógun ọ̀rún” ni, ìyẹn ni pé ó máa ń darí àwọn ọmọ ogun Róòmù tí wọ́n tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún (100). (Ìṣe 10:1, àlàyé ìsàlẹ̀) Èyí sì ti lè mú kó di gbajúmọ̀ láwùjọ àti lẹ́nu iṣẹ́ ológun. Ó tún máa ń “fún àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ ọrẹ àánú.” (Ìṣe 10:2) Torí náà, Jèhófà rán àpọ́sítélì Pétérù pé kó lọ wàásù ìhìn rere fún un. Ṣé Kọ̀nílíù jẹ́ kí ipò tó wà dí i lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi?

12. Kí ló mú kí Kọ̀nílíù ṣèrìbọmi?

12 Kí ló mú kí Kọ̀nílíù ṣèrìbọmi? Bíbélì sọ pé ‘òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run.’ Kọ̀nílíù tún máa ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run nígbà gbogbo. (Ìṣe 10:2) Nígbà tí Pétérù wàásù ìhìn rere fún Kọ̀nílíù, òun àti agbo ilé ẹ̀ gba Kristi gbọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi láìjáfara. (Ìṣe 10:47, 48) Ó hàn gbangba pé Kọ̀nílíù ṣe tán láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kóun àti ìdílé ẹ̀ lè jọ máa sin Jèhófà.—Jóṣ. 24:15; Ìṣe 10:24, 33.

13. Kí lo kọ́ lára Kọ̀nílíù?

13 Bíi ti Sọ́ọ̀lù, Kọ̀nílíù náà ò jẹ́ kí ipò tó wà láwùjọ dí òun lọ́wọ́ láti di Kristẹni. Ṣé ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ò ń kọ́ gba pé kó o ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó máa bù kún ìpinnu tó o ṣe pé wàá máa sìn ín, wàá sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀.

14. Kí lo kọ́ lára Tsuyoshi?

14 Tsuyoshi tó ń gbé orílẹ̀-èdè Japan ṣe àwọn àyípadà kan níbi iṣẹ́ ẹ̀ kó lè ṣèrìbọmi. Òun ni igbá kejì ọ̀gá àgbà ilé ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Ikenobo, níbi tí wọ́n ti ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń to òdòdó pa pọ̀. Tí ọ̀gá ẹ̀ ò bá lè gbé òdòdó lọ síbi táwọn ẹlẹ́sìn Búdà ti ń ṣe ètò ìsìnkú, ó máa ń sọ fún Tsuyoshi pé kó lọ ṣojú òun, wọ́n sì máa ń ṣètùtù níbẹ̀. Àmọ́, nígbà tí Tsuyoshi kẹ́kọ̀ọ́ nípa ipò táwọn òkú wà, ó mọ̀ pé ohun tí wọ́n máa ń ṣe níbi ìsìnkú yẹn ò ní jẹ́ kóun lè ṣèrìbọmi. Torí náà, ó pinnu pé òun ò ní bá wọn ṣe ètùtù náà mọ́. (2 Kọ́r. 6:15, 16) Ni Tsuyoshi bá sọ fún ọ̀gá ẹ̀ pé òun ò ní lè lọ máa ṣojú ẹ̀ mọ́ níbi ìsìnkú. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Ọ̀gá Tsuyoshi fara mọ́ ohun tó sọ, ó sì ní kó máa bá iṣẹ́ ẹ̀ lọ. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ó ṣèrìbọmi lẹ́yìn ọdún kan tó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.a Tó bá gba pé kó o ṣe àyípadà níbi iṣẹ́ kó o lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, mọ̀ dájú pé ó máa pèsè fún ìwọ àti ìdílé ẹ.—Sm. 127:2; Mát. 6:33.

ÀWỌN ARÁ KỌ́RÍŃTÌ ṢÈRÌBỌMI

15. Kí ló lè mú kó nira fáwọn ará Kọ́ríńtì láti ṣèrìbọmi?

15 Ní Kọ́ríńtì àtijọ́, àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ nǹkan tara gan-an, wọ́n sì tún máa ń ṣèṣekúṣe. Ìwà tí Ọlọ́run kórìíra ni èyí tó pọ̀ jù nínú wọn máa ń hù. Ká sòótọ́, ìwà táwọn èèyàn ń hù yìí máa jẹ́ kó nira fún ẹni tó bá fẹ́ gba ìhìn rere gbọ́. Àmọ́, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá sí ìlú náà tó sì wàásù ìhìn rere nípa Kristi fún wọn, “ọ̀pọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì tí wọ́n gbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà gbọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi.” (Ìṣe 18:7-11) Lẹ́yìn náà, Jésù Kristi Olúwa fara han Pọ́ọ̀lù nínú ìran, ó sì sọ fún un pé: “Mo ní ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìlú yìí.” Torí náà Pọ́ọ̀lù dúró síbẹ̀ fún ọdún kan àti ààbọ̀, ó sì ń wàásù.

16. Kí ló mú káwọn ará Kọ́ríńtì ṣèrìbọmi? (2 Kọ́ríńtì 10:4, 5)

16 Kí ló mú káwọn ará Kọ́ríńtì ṣèrìbọmi? (Ka 2 Kọ́ríńtì 10:4, 5.) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kíákíá nígbèésí ayé wọn. (Héb. 4:12) Àwọn ará Kọ́ríńtì tí wọ́n gba ìhìn rere nípa Kristi gbọ́ fi àwọn ìwà tí ò dáa sílẹ̀, irú bí ìmutípara, olè àti ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀.—1 Kọ́r. 6:9-11.b

17. Kí lo kọ́ lára àwọn ará Kọ́ríńtì?

17 Ẹ kíyè sí i pé àwọn ará Kọ́ríńtì kan láwọn ìwà tó yẹ kí wọ́n fi sílẹ̀, àmọ́ wọn ò sọ pé àwọn ò ní lè ṣe àyípadà tó yẹ kí wọ́n lè di Kristẹni. Torí náà, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè máa rìn lójú ọ̀nà híhá tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Mát. 7:13, 14) Ṣé ìwà burúkú kan wà tó ò ń sapá láti fi sílẹ̀ kó o lè ṣèrìbọmi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, má jẹ́ kó sú ẹ! Tó bá ń wù ẹ́ láti ṣe ohun tí kò dáa, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ kó o lè máa ṣe ohun tó tọ́.

18. Kí lo kọ́ lára Monika?

18 Monika tó ń gbé orílẹ̀-èdè Jọ́jíà sapá gan-an láti jáwọ́ nínú ìsọkúsọ àti eré ìnàjú tí ò dáa kó lè ṣèrìbọmi. Ó sọ pé: “Nígbà tí mi ò tíì pé ọmọ ogún (20) ọdún, àdúrà ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Jèhófà mọ̀ pé ó máa ń wù mí láti ṣe ohun tó tọ́, torí náà gbogbo ìgbà ló máa ń ràn mí lọ́wọ́, tó sì ń tọ́ mi sọ́nà.” Nígbà tí Monika pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), ó ṣèrìbọmi. Ṣé àwọn ìwà kan wà tó yẹ kó o fi sílẹ̀ kó o lè sin Jèhófà bó ṣe fẹ́? Máa bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ kó o lè ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Ó sì dájú pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.—Jòh. 3:34.

ÌGBÀGBỌ́ RẸ LÈ ṢÍ ÒKÈ KÚRÒ NÍBI TÓ WÀ

19. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro tó dà bí òkè? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

19 Mọ̀ dájú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì fẹ́ kó o di ara ìdílé òun. Ohun tí Jèhófà fẹ́ fún ẹ nìyẹn, bó o tiẹ̀ láwọn ìṣòro tí ò jẹ́ kó o lè ṣèrìbọmi. Jésù sọ fún àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ nígbà tó wà láyé pé: “Tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbí lọ sí ọ̀hún,’ ó sì máa lọ, kò sì sí ohun tí ẹ ò ní lè ṣe.” (Mát. 17:20) Kò tíì ju ọdún mélòó kan lọ táwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ di ọmọlẹ́yìn ẹ̀, torí náà ìgbàgbọ́ wọn ò tíì lágbára. Àmọ́ Jésù jẹ́ kó dá wọn lójú pé tí wọ́n bá nígbàgbọ́ tó lágbára, Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ìṣòro tó dà bí òkè. Ó sì dájú pé Jèhófà máa ran ìwọ náà lọ́wọ́!

Inú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan ń dùn, wọ́n sì ń pàtẹ́wọ́ fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi ní àpéjọ agbègbè.

Mọ̀ dájú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì fẹ́ kó o di ara ìdílé òun (Wo ìpínrọ̀ 19)c


20. Báwo ni àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ àtàwọn Kristẹni òde òní tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́?

20 Tó o bá ti mọ ohun tí ò jẹ́ kó o ṣèrìbọmi, tètè gbégbèésẹ̀ láti ṣe àyípadà láìjáfara. Jẹ́ kí àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ àtàwọn Kristẹni òde òní máa tù ẹ́ nínú, kó sì máa fún ẹ lókun. Kọ́ ìgboyà lára wọn, kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó o sì ṣèrìbọmi. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tó dáa jù lo ṣe yẹn!

KÍ LO KỌ́ LÁRA ÀWỌN KRISTẸNI ÀKỌ́BẸ̀RẸ̀ YÌÍ NÍPA BÓ O ṢE LÈ BORÍ ÌṢÒRO TÍ Ò JẸ́ KÓ O ṢÈRÌBỌMI?

  • Àwọn ará Samáríà

  • Sọ́ọ̀lù ará Tásù àti Kọ̀nílíù

  • Àwọn ará Kọ́ríńtì

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

a Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Tsuyoshi Fujii wà nínú Jí! August 8, 2005, ojú ìwé 20-23 lédè Gẹ̀ẹ́sì.

b Wo fídíò náà ‘Kí Ló Ń Dá Ẹ Dúró Láti Ṣe Ìrìbọmi?’ lórí jw.org.

c ÀWÒRÁN: Inú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan ń dùn bí wọ́n ṣe ń kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́