ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 10
ORIN 31 Bá Ọlọ́run Rìn!
Máa Ronú Bí Jèhófà àti Jésù Ṣe Ń Ronú
“Níwọ̀n bí Kristi ti jìyà nínú ẹran ara, kí ẹ̀yin náà fi irú èrò kan náà gbára dì.”—1 PÉT. 4:1.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa rí ohun tí àpọ́sítélì Pétérù kọ́ lára Jésù nípa bó ṣe yẹ kó máa ronú, àá sì rí báwa náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.
1-2. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwọn nǹkan wo ló máa gba pé ká ṣe, báwo sì ni Jésù ṣe ṣe é?
“KÍ O fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo okun rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Lúùkù 10:27) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé òfin yìí ló ṣe pàtàkì jù nínú Òfin Mósè. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo ọkàn wa la gbọ́dọ̀ fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìyẹn sì kan ohun tọ́kàn wa máa ń fà sí àti bọ́rọ̀ ṣe ń rí lára wa. Ó tún gba pé ká máa sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, ká sì máa lo gbogbo okun wa fún un. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún sọ pé ká fi gbogbo èrò wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìyẹn sì kan bá a ṣe ń ronú. Àmọ́ o, kò sí bá a ṣe lè mọ bí Jèhófà ṣe ń ronú délẹ̀délẹ̀. Síbẹ̀, a lè mọ bí Ọlọ́run ṣe ń ronú tá a bá mọ “èrò inú Kristi” torí pé Jésù fìwà jọ bàbá ẹ̀ láìkù síbì kan.—1 Kọ́r. 2:16 àti àlàyé ọ̀rọ̀ “we do have the mind of Christ” nínú nwtsty-E.
2 Gbogbo ọkàn ni Jésù fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ó mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kóun ṣe, ó sì pinnu láti ṣe é bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn máa gba pé kó jìyà. Ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe ló gbájú mọ́, kò sì jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́.
3. Kí ni àpọ́sítélì Pétérù kọ́ lára Jésù, kí ló sì rọ àwa Kristẹni pé ká ṣe? (1 Pétérù 4:1)
3 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù máa ń wà pẹ̀lú Jésù, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe ń ronú. Nígbà tí Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, ó gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n fi irú èrò tí Kristi ní gbára dì. (Ka 1 Pétérù 4:1.) Pétérù lo ọ̀rọ̀ táwọn ọmọ ogun máa ń lò nígbà tó sọ pé: “Gbára dì.” Torí náà, tí Kristẹni kan bá ń ronú bíi Jésù, á lè gbára dì láti gbógun ti àwọn nǹkan tó lè mú kó dẹ́ṣẹ̀ nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí.—2 Kọ́r. 10:3-5; Éfé. 6:12.
4. Báwo ni àpilẹ̀kọ yìí ṣe máa jẹ́ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pétérù fún wa?
4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe ń ronú àti báwa náà ṣe lè máa ronú bíi tiẹ̀. A máa mọ bá a ṣe lè (1) máa ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú, ìyẹn á sì jẹ́ ká wà níṣọ̀kan, (2) bá a ṣe lè nírẹ̀lẹ̀ àti (3) bá a ṣe lè máa ronú jinlẹ̀, ká sì máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà.
MÁA RONÚ BÍ JÈHÓFÀ ṢE Ń RONÚ
5. Kí ni Pétérù ṣe nígbà kan tó fi hàn pé kò ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú?
5 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan tó fi hàn pé Pétérù ò ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú. Jésù ti sọ fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n á fa òun lé àwọn olórí ẹ̀sìn lọ́wọ́, wọ́n á fìyà jẹ òun, wọ́n á sì pa òun. (Mát. 16:21) Ó ṣeé ṣe kó nira fún Pétérù láti gbà pé Jèhófà máa fàyè gbà á kí wọ́n pa Jésù tó jẹ́ Mèsáyà tá a ṣèlérí, tó sì máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀. (Mát. 16:16) Torí náà, Pétérù pe Jésù sẹ́gbẹ̀ẹ́, ó sì sọ fún un pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; èyí ò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ rárá.” (Mát. 16:22) Àmọ́ Jésù ò gba ohun tí Pétérù sọ torí pé Pétérù ò ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú.
6. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó máa ń ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú?
6 Bí Jèhófà ṣe máa ń ronú ni Jésù ṣe ń ronú. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fún Pétérù pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ lo jẹ́ fún mi, torí èrò èèyàn lò ń rò, kì í ṣe ti Ọlọ́run.” (Mát. 16:23) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó dáa ni Pétérù ní lọ́kàn, àmọ́ Jésù ò gba ìmọ̀ràn ẹ̀. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Jésù mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kóun jìyà, kóun sì kú, ohun tí Jésù náà sì ṣe nìyẹn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí Pétérù kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ni pé kó máa ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú.
7. Kí ni Pétérù ṣe nígbà tó yá tó fi hàn pé ó ti ń ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú? (Wo àwòrán.)
7 Nígbà tó yá, Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú. Nígbà tí àkókò tó lójú Jèhófà pé káwọn Kèfèrí tí kò dádọ̀dọ́ wá jọ́sìn òun, Pétérù ni Jèhófà yàn pé kó lọ wàásù fún Kèfèrí kan tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù, òun sì ni Kèfèrí àkọ́kọ́ tó di Kristẹni. Àwọn Júù kì í da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kèfèrí, torí náà ó dájú pé kò ní rọrùn fún Pétérù láti ṣe iṣẹ́ yìí. Àmọ́ nígbà tí Pétérù mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe, ó yí èrò ẹ̀ pa dà. Torí náà, ó lọ “láìjanpata” nígbà tí Kọ̀nílíù ránṣẹ́ pè é. (Ìṣe 10:28, 29) Ó wàásù fún Kọ̀nílíù àti ìdílé ẹ̀, wọ́n sì ṣèrìbọmi.—Ìṣe 10:21-23, 34, 35, 44-48.
Pétérù ń wọnú ilé Kọ̀nílíù (Wo ìpínrọ̀ 7)
8. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú? (1 Pétérù 3:8)
8 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí èrò wọn “ṣọ̀kan.” (Ka 1 Pétérù 3:8.) Táwa èèyàn Jèhófà bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè máa ronú bíi Jèhófà, bó ṣe wà nínú Bíbélì ọ̀rọ̀ ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wọn. (Mát. 6:33) Torí náà, tí ẹnì kan níjọ ẹ bá sọ pé iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lòun fẹ́ ṣe, kàkà kó o sọ fún un pé kó tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́, kó má fìyà jẹ ara ẹ̀, ńṣe ló yẹ kó o sọ ohun tó máa jẹ́ kíṣẹ́ náà wù ú, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́.
NÍRẸ̀LẸ̀
9-10. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ gan-an?
9 Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, Jésù kọ́ Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ẹ̀kọ́ náà ni pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n nírẹ̀lẹ̀. Kó tó dìgbà yẹn, Jésù rán Pétérù àti Jòhánù pé kí wọ́n lọ ṣètò ibi tóun ti máa jẹ oúnjẹ tó kẹ́yìn pẹ̀lú wọn kóun tó kú àtàwọn nǹkan tí wọ́n máa lò níbẹ̀. Lára àwọn nǹkan tí wọ́n máa ṣètò ni bàsíà àti aṣọ ìnura tí wọ́n máa fi fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó máa wá síbẹ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun. Àmọ́ ta ló máa ṣiṣẹ́ tó rẹlẹ̀ yìí tí àkókò bá tó?
10 Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Jésù ṣe ohun tó fi hàn pé ó nírẹ̀lẹ̀ gan-an. Ẹnu ya àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ nígbà tí wọ́n rí i pé Jésù ń ṣiṣẹ́ táwọn ìránṣẹ́ máa ń ṣe. Jésù bọ́ aṣọ àwọ̀lékè ẹ̀ sílẹ̀, ó so aṣọ ìnura mọ́ ìbàdí, ó bu omi sínú bàsíà kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fọ ẹsẹ̀ wọn. (Jòh. 13:4, 5) Ó máa gba àkókò kí Jésù tó lè fọ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ méjìlá (12) títí kan Júdásì tó máa dalẹ̀ ẹ̀. Síbẹ̀, Jésù fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀, ó sì fọ ẹsẹ̀ gbogbo wọn. Jésù wá fara balẹ̀ ṣàlàyé fún wọn pé: “Ṣé ohun tí mo ṣe fún yín yé yín? Ẹ̀ ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ òótọ́ lẹ sì sọ, torí ohun tí mo jẹ́ nìyẹn. Torí náà, tí èmi, tí mo jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ̀yin náà máa fọ ẹsẹ̀ ara yín.”—Jòh. 13:12-14.
Ìrẹ̀lẹ̀ ju ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lọ, . . . ó gba pé kéèyàn máa fojú tó tọ́ wo ara ẹ̀ àtàwọn ẹlòmíì
11. Báwo ni Pétérù ṣe fi hàn pé òun ti kọ́ ìrẹ̀lẹ̀ lára Jésù? (1 Pétérù 5:5) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Pétérù kọ́ ìrẹ̀lẹ̀ lára Jésù. Lẹ́yìn tí Jésù pa dà sọ́run, Pétérù wo ọkùnrin kan tó ti yarọ látìgbà tí wọ́n ti bí i sàn. (Ìṣe 1:8, 9; 3:2, 6-8) Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí máa jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn kóra jọ síbẹ̀. (Ìṣe 3:11) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé níbi tí Pétérù ti wá, wọ́n máa ń ka àwọn tó bá wà nípò pàtàkì sẹ́ni ńlá. Ṣé Pétérù máa wá jẹ́ kí wọ́n yin òun lógo? Rárá o. Ìrẹ̀lẹ̀ mú kí Pétérù gbà pé Jèhófà àti Jésù ló yẹ kí wọ́n yìn lógo. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Nípasẹ̀ orúkọ [Jésù] àti nípa ìgbàgbọ́ tí a ní nínú orúkọ rẹ̀, ni ara ọkùnrin tí ẹ rí, tí ẹ sì mọ̀ yìí fi yá.” (Ìṣe 3:12-16) Bákan náà, àwọn ọ̀rọ̀ tí Pétérù lò nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni nípa ìrẹ̀lẹ̀ rán wa létí ìgbà tí Jésù so aṣọ mọ́ ìbàdí, tó sì wẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì ẹ̀.—Ka 1 Pétérù 5:5.
Lẹ́yìn tí Pétérù ṣiṣẹ́ ìyanu, Jèhófà àti Jésù ló yìn lógo. Táwa náà bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, tá ò sì retí pé kí wọ́n máa yìn wá, á fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 11-12)
12. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ bíi Pétérù?
12 Àwa náà lè nírẹ̀lẹ̀ bíi Pétérù. Ká rántí pé ìrẹ̀lẹ̀ ju ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lọ, ó gba kéèyàn fi ṣèwàhù. Ọ̀rọ̀ tí Pétérù lò fún “ìrẹ̀lẹ̀” nínú ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí i pé ìrẹ̀lẹ̀ gba pé kéèyàn máa fojú tó tọ́ wo ara ẹ̀ àtàwọn ẹlòmíì. Ìdí tá a fi ń ṣe nǹkan fáwọn èèyàn ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn, kì í ṣe torí pé a fẹ́ kí wọ́n máa yìn wá. Torí náà, tá a bá ń fayọ̀ sin Jèhófà, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn ará lọ́wọ́, bóyá àwọn èèyàn rí ohun tá a ṣe tàbí wọn ò rí i, ìyẹn á fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀.—Mát. 6:1-4.
MÁA “RONÚ JINLẸ̀”
13. Kí lẹni tó ń “ronú jinlẹ̀” máa ń ṣe?
13 Kí lẹni tó ń “ronú jinlẹ̀” máa ń ṣe? (1 Pét. 4:7) Tí Kristẹni kan tó máa ń ronú jinlẹ̀ bá fẹ́ ṣèpinnu, ó máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú. Irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé kò sóhun tó ṣe pàtàkì tó àjọṣe òun àti Jèhófà. Kì í ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ torí ó mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan lòun mọ̀. Ó sì máa ń gbàdúrà déédéé kó lè fi hàn pé Jèhófà lòun gbára lé.a
14. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà kan tó fi hàn pé Pétérù ò gbára lé Jèhófà?
14 Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Gbogbo yín lẹ máa kọsẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi lóru òní.” Àmọ́, Pétérù fi ìdánilójú sọ pé: “Tí gbogbo àwọn yòókù bá tiẹ̀ kọsẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó dájú pé èmi ò ní kọsẹ̀ láé!” Jésù ti kọ́kọ́ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ kan lálẹ́ ọjọ́ yẹn pé: “Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo.” (Mát. 26:31, 33, 41) Ká sọ pé Pétérù ṣe ohun tí Jésù sọ ni, á nígboyà láti sọ pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lòun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Pétérù sọ pé òun ò mọ Ọ̀gá òun rí, ó sì kábàámọ̀ ohun tó ṣe yẹn.—Mát. 26:69-75.
15. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó ronú jinlẹ̀ lálẹ́ tó ṣáájú ikú ẹ̀?
15 Jésù gbára lé Jèhófà pátápátá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, léraléra ló gbàdúrà lálẹ́ tó ṣáájú ikú ẹ̀. Ìyẹn ló jẹ́ kó nígboyà láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Mát. 26:39, 42, 44; Jòh. 18:4, 5) Ó dájú pé Pétérù ò ní gbàgbé ohun tó kọ́ bó ṣe rí bí Jésù ṣe ń gbàdúrà léraléra lálẹ́ ọjọ́ yẹn.
16. Báwo ni Pétérù ṣe fi hàn pé òun ti ń ronú jinlẹ̀? (1 Pétérù 4:7)
16 Nígbà tó yá, Pétérù gbára lé Jèhófà, ó sì túbọ̀ ń gbàdúrà. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fi dá Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù lójú pé wọ́n máa rí ẹ̀mí mímọ́ gbà kí wọ́n lè wàásù dé ibi tó yẹ. Àmọ́, Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n dúró sí Jerúsálẹ́mù títí wọ́n fi máa rí ẹ̀mí mímọ́ gbà. (Lúùkù 24:49; Ìṣe 1:4, 5) Kí ni Pétérù wá ń ṣe ní gbogbo àsìkò tí wọ́n fi ń dúró yẹn? Pétérù àtàwọn ará tó kù “tẹra mọ́ àdúrà.” (Ìṣe 1:13, 14) Nígbà tí Pétérù ń kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, ó gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa ronú jinlẹ̀, kí wọ́n sì máa gbàdúrà kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn gbára lé Jèhófà. (Ka 1 Pétérù 4:7.) Nígbà tó yá, Pétérù kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kóun máa gbára lé Jèhófà, ìyẹn sì mú kó lè ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lọ́wọ́ nínú ìjọ.—Gál. 2:9.
17. Tá a bá tiẹ̀ mọ ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe, kí ló ṣì yẹ ká máa ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
17 Tá a bá fẹ́ jẹ́ ẹni tó ń ronú jinlẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé. Tá a bá tiẹ̀ mọ ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe, tá a sì ní oríṣiríṣi ẹ̀bùn, ó ṣì yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà léraléra. Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, àsìkò yẹn gan-an ló yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà, ká sì fọkàn tán an pé ó mọ ohun tó dáa jù fún wa.
Pétérù máa ń gbàdúrà, ìyẹn sì jẹ́ kó kọ́ béèyàn ṣe ń gbára lé Jèhófà. Táwa náà bá ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà, àá lè máa ronú jinlẹ̀ pàápàá ká tó ṣèpinnu pàtàkì (Wo ìpínrọ̀ 17)b
18. Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ máa ronú bíi Jèhófà?
18 A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè máa ronú bíi tiẹ̀. (Jẹ́n. 1:26) Lóòótọ́, a ò lè fara wé Jèhófà lọ́nà tó pé. (Àìsá. 55:9) Àmọ́ bíi Pétérù, ẹ jẹ́ káwa náà máa ronú bíi Jèhófà, ká nírẹ̀lẹ̀, ká sì máa ronú jinlẹ̀.
ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi
a Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè máa ronú jinlẹ̀, kó o sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, wo àlàyé tá a ṣe lórí “2 Tímótì 1:7—‘Ọlọ́run Kò Fún Wa Ní Ẹ̀mí Ìbẹ̀rù,’” ní abala “Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì” lórí jw.org tàbí JW Library®. Tó o bá débẹ̀, wo “Àròjinlẹ̀” ní ìpínrọ̀ karùn-ún.
b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN : Arábìnrin kan ń gbàdúrà kí wọ́n tó fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò níbi tó wáṣẹ́ lọ.