OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́
Máa Fi Bíbélì Yẹ Ara Ẹ Wò Bíi Dígí
Ọmọ ẹ̀yìn náà Jémíìsì fi Bíbélì wé dígí tó ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́. (Jém. 1:22-25) Báwo la ṣe lè fi Bíbélì yẹ ara wa wò bíi dígí?
Máa fara balẹ̀ kà á. Tá a bá kàn wo ara wa gààràgà nínú dígí, ó ṣeé ṣe ká má rí àwọn àléébù tó wà lára wa. Lọ́nà kan náà, ká tó lè mọ irú ẹni tá a jẹ́ àtàwọn ibi tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, ìyẹn sì máa gba pé ká máa fara balẹ̀ kà á.
Máa wo ibi tó yẹ kó o ti ṣàtúnṣe, má wo tàwọn ẹlòmíì. Tá a bá tẹ dígí wa sí apá kan, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àléébù àwọn ẹlòmíì la máa rí. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ka Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibi tó yẹ káwọn ẹlòmíì ti ṣàtúnṣe làá máa rí. Tó bá sì rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn ò ní jẹ́ káwa fúnra wa ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ ká ṣe.
Má ṣàṣejù. Tó bá jẹ́ pé àwọn àléébù wa tá a rí nínú dígí nìkan la gbájú mọ́, inú wa ò ní dùn. Torí náà, má ṣàṣejù tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ni pé kó o má ṣe kọjá ohun tí Jèhófà mọ̀ pé agbára ẹ gbé.—Jém. 3:17.