Báwo Ni Mo Ṣe Rí Lójú Jèhófà?
1. Báwo ni Bíbélì ṣe dà bí dígí?
1 Ìgbà mélòó lo máa ń wo ara rẹ nínú dígí lóòjọ́? Ojúmọ́ kan kì í lọ kí èyí tó pọ̀ jù nínú wa má wo dígí torí ó máa ń jẹ́ ká rí àwọn ibi tó ń fẹ́ àtúnṣe lára wa. A lè fi Bíbélì wé dígí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an, ìyẹn sì ni Jèhófà ń wò. (1 Sám. 16:7; Ják. 1:22-24.) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Héb. 4:12) Báwo ni kíka Bíbélì lójoojúmọ́ àti ṣíṣàṣàrò lórí ohun tá a kà ṣe lè jẹ́ ká rí àwọn ibi tó yẹ ká ti sunwọ̀n sí i ká lè túbọ̀ kẹ́sẹ járí lẹ́nu iṣẹ́ ajíhìnrere?—Sm. 1:1-3.
2. Báwo la ṣe lè fi Bíbélì ṣàyẹ̀wò ara wa?
2 Máa Lo Bíbélì Bí I Dígí: Ìtàn àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà nínú Bíbélì kọ́ wa láwọn ànímọ́ tó wu Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì ní ìtara fún orúkọ Ọlọ́run. (1 Sám. 17:45, 46) Aísáyà fìgboyà yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti lọ wàásù ní ìpínlẹ̀ tí iṣẹ́ ìwàásù ti ṣòro gan-an. (Aísá. 6:8, 9) Ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jésù ní sí Baba rẹ̀ ọ̀run mú kó ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sí orísun ìtura àti ìtẹ́lọ́rùn dípò kó kà á sí ẹrù ìnira. (Jòh. 4:34) Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi ìtara wàásù, wọ́n gbára lé Jèhófà, wọ́n sì pinnu pé àwọn kò ní juwọ́ sílẹ̀. (Ìṣe 5:41, 42; 2 Kọ́r. 4:1; 2 Tím. 4:17) Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn àpẹẹrẹ bí èyí, yóò jẹ́ ká lè ṣàyẹ̀wò ara wa lọ́nà tí a ó fi lè mú kì iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa sunwọ̀n sí i.
3. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fi àtúnṣe tó yẹ ká ṣe falẹ̀?
3 Gbé Ìgbésẹ̀ Láti Ṣàtúnṣe Tó Bá Yẹ: Kò sí àǹfààní kankan nínú ká wo ara wa nínú dígí ká sì má ṣe àtúnṣe tó yẹ síbi tó kù díẹ̀ káàtó. A lè bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣàyẹ̀wò ara wa lọ́nà tó tọ́, kó sì ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe tó bá yẹ. (Sm. 139:23, 24; Lúùkù 11:13) Torí pé àkókò tó ṣẹ́ kù kò tó nǹkan mọ́, ẹ̀mí àwọn èèyàn sì wà nínú ewu, kò yẹ ká máa fi àtúnṣe tó yẹ ká ṣe falẹ̀ rárá.—1 Kọ́r. 7:29; 1 Tím. 4:16.
4. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá ń wo inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sì ń ṣiṣẹ́ lórí ohun tó rí?
4 Ohun tí Jèhófà ń wò, ìyẹn ẹni tí a jẹ́ gan-an ṣe pàtàkì ju bí ìrísí wa ṣe rí lọ. (1 Pét. 3:3, 4) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá ń wo inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sì ń ṣiṣẹ́ lórí ohun tó rí? “Ẹni yìí, nítorí tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe iṣẹ́ náà, yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.” (Ják. 1:25) Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, a máa ní ayọ̀, a ó sì di òjíṣẹ́ tó jáfáfá torí à ń ṣe “àgbéyọ ògo Jèhófà bí i dígí.”—2 Kọ́r. 3:18.