ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 April ojú ìwé 20-25
  • Jèhófà Ò Ní Fi Wá Sílẹ̀ Láé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Ò Ní Fi Wá Sílẹ̀ Láé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • JÈHÓFÀ Ń TỌ́ WA SỌ́NÀ
  • JÈHÓFÀ Ń PÈSÈ FÚN WA
  • JÈHÓFÀ Ń DÁÀBÒ BÒ WÁ
  • JÈHÓFÀ Ń TÙ WÁ NÍNÚ
  • JÈHÓFÀ KÌ Í FI WÁ SÍLẸ̀
  • Máa Rántí Pé Jèhófà Ni “Ọlọ́run Alààyè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Jèhófà “Ń Mú Àwọn Tó Ní Ọgbẹ́ Ọkàn Lára Dá”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Wàá Túbọ̀ Láyọ̀ Tó O Bá Ń Fún Àwọn Èèyàn Ní Nǹkan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 April ojú ìwé 20-25

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 17

ORIN 99 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwa Ará

Jèhófà Ò Ní Fi Wá Sílẹ̀ Láé

“Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.”—ÀÌSÁ. 41:10.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa rí ọ̀nà mẹ́rin tí Jèhófà ń gbà bójú tó wa.

1-2. (a) Kí ló mú ká gbà pé Jèhófà kì í dá wa dá ìṣòro wa? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

TÁ A bá níṣòro tó le, ó lè dà bíi pé a dá wà nínú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan tí ìjì ń gbé kiri lójú agbami òkun. Àmọ́ Jèhófà kì í dá wa dá ìṣòro wa. Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ń rí àwọn nǹkan tá à ń bá yí, ó sì ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́. Kó lè dá wa lójú, Jèhófà sọ fáwa ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́ pé: “Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.”—Àìsá. 41:10.

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí nǹkan mẹ́rin tí Jèhófà ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́. (1) Ó ń tọ́ wa sọ́nà, (2) ó ń pèsè fún wa, (3) ó ń dáàbò bò wá (4) ó sì ń tù wá nínú. Jèhófà jẹ́ kó dá wa lójú pé ìṣòro yòówù ká ní, òun ò ní dá wa dá a, òun ò sì ní pa wá tì. Torí náà, a ò dá wà.

JÈHÓFÀ Ń TỌ́ WA SỌ́NÀ

3-4. Báwo ni Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà? (Sáàmù 48:14)

3 Ka Sáàmù 48:14. Jèhófà ò retí pé ká máa darí ara wa. Àmọ́ báwo ló ṣe ń tọ́ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́ sọ́nà lónìí? Ọ̀kan lára nǹkan tó ń lò ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀. (Sm. 119:105) Jèhófà máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣe ìpinnu àtàwọn nǹkan táá jẹ́ ká túbọ̀ láyọ̀ báyìí, ká sì ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú.a Bí àpẹẹrẹ, ó kọ́ wa pé ká má di àwọn èèyàn sínú, ká jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo nǹkan tá a bá ń ṣe, ká sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú. (Sm. 37:8; Héb. 13:18; 1 Pét. 1:22) Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, a máa jẹ́ òbí rere, ọkọ gidi àti aya àtàtà, àá sì jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi sáwọn èèyàn.

4 Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ ìtàn àwọn tó nírú ìṣòro tá a ní àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn sínú Bíbélì. (1 Kọ́r. 10:13; Jém. 5:17) Tá a bá ń ka àwọn ìtàn yìí, tá a sì ń fi ohun tá a kọ́ sílò, ó kéré tán àǹfààní méjì la máa rí. Àkọ́kọ́, a máa rí i pé àwa nìkan kọ́ la nírú ìṣòro yẹn, àwọn míì ti nírú ìṣòro yìí rí, tí wọ́n sì fara dà á. (1 Pét. 5:9) Ìkejì, àá rí bá a ṣe lè fara da àwọn ìṣòro tiwa náà.—Róòmù 15:4.

5. Àwọn wo ni Jèhófà ń lò láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa rìn lójú ọ̀nà ìyè?

5 Jèhófà tún máa ń lo àwọn ará láti tọ́ wa sọ́nà.b Bí àpẹẹrẹ, àtìgbàdégbà làwọn alábòójútó àyíká máa ń bẹ ìjọ wò kí wọ́n lè fún wa níṣìírí. Àwọn àsọyé tí wọ́n ń sọ máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i, ó sì máa ń jẹ́ ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan. (Ìṣe 15:40–16:5) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alàgbà máa ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń bójú tó wa. (1 Pét. 5:2, 3) Bákan náà, àwọn òbí máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n máa ronú bó ṣe tọ́, kí wọ́n sì níwà tó dáa. (Òwe 22:6) Àwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn máa ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn arábìnrin míì nínú ìjọ, wọ́n máa ń gbà wọ́n nímọ̀ràn, wọ́n sì máa ń fún wọn níṣìírí.—Títù 2:3-5.

6. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ wa sọ́nà?

6 Jèhófà ti fún wa láwọn nǹkan tó máa tọ́ wa sọ́nà. Àmọ́ báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì nǹkan tí Jèhófà ṣe fún wa? Òwe 3:5, 6 sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.” Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ‘á mú kí àwọn ọ̀nà wa tọ́,’ ìyẹn ni pé á ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fáwọn nǹkan tó lè kó wa sí wàhálà, ká lè máa láyọ̀. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ń fún wa nímọ̀ràn tó máa ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láǹfààní!—Sm. 32:8.

JÈHÓFÀ Ń PÈSÈ FÚN WA

7. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà tún máa ń pèsè fún wa? (Fílípì 4:19)

7 Ka Fílípì 4:19. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà máa ń pèsè àwọn nǹkan tó máa jẹ́ ká lájọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀, ó tún máa ń bù kún ìsapá wa ká lè rí oúnjẹ, aṣọ àti ilé tá a máa gbé. (Mát. 6:33; 2 Tẹs. 3:12) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò burú láti ronú nípa àwọn nǹkan tá a nílò, Jèhófà rọ̀ wá pé ká má ṣàníyàn jù nípa wọn. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mátíù 6:25 nínú nwtsty-E.) Kí nìdí? Torí Baba wa ọ̀run ò ní pa àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́ tì nígbà ìṣòro. (Mát. 6:8; Héb. 13:5) Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ láti pèsè fún wa.

8. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́?

8 Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́. Ní gbogbo ọdún tí Dáfídì fi ń sá káàkiri, Jèhófà pèsè oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì tí òun àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀ nílò. Nígbà tí Dáfídì ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń bójú tó o látọdún yìí wá, ó sọ pé: “Mo ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, àmọ́ ní báyìí mo ti darúgbó, síbẹ̀, mi ò tíì rí i kí a pa olódodo tì, tàbí kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” (Sm. 37:25) Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí i pé Jèhófà máa ń pèsè fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́, kì í sì í fi wọ́n sílẹ̀.

9. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń pèsè fáwọn èèyàn ẹ̀ lónìí tí àjálù bá ṣẹlẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 Jèhófà tún máa ń pèsè fáwọn èèyàn ẹ̀ tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìyàn kan mú ní Jerúsálẹ́mù nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn Kristẹni tó wà láwọn ìlú míì fi oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì ránṣẹ́ sáwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀. (Ìṣe 11:27-30; Róòmù 15:25, 26) Ohun táwa èèyàn Ọlọ́run náà máa ń ṣe lónìí nìyẹn. Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, Jèhófà máa ń mú káwọn èèyàn ẹ̀ pèsè oúnjẹ, omi, aṣọ, oògùn àtàwọn nǹkan míì fáwọn tí àjálù náà bá. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó ń kọ́lé ètò Ọlọ́run máa ń tún àwọn Ilé Ìpàdé àti ilé àwọn èèyàn tó bà jẹ́ ṣe. Bákan náà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń tètè tu àwọn tí àjálù náà bá nínú, wọ́n sì máa ń ṣètò tó máa jẹ́ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lágbára.c

Fọ́tò: Nígbà tí àjálù ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Màláwì, ètò Ọlọ́run pèsè oúnjẹ fáwọn ará, wọ́n sì fi Bíbélì tù wọ́n nínú. 1. Omi ya bo agbègbè kan. 2. Arákùnrin Gage Fleegle ń tu àwọn ará nínú. 3. Àwọn arákùnrin ń já oúnjẹ sílẹ̀ látinú mọ́tò.

Báwo ni Jèhófà ṣe ń tù wá nínú nígbà àjálù? (Wo ìpínrọ̀ 9)e


10-11. Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Borys?

10 Jèhófà tún máa ń pèsè fáwọn tí ò jọ́sìn ẹ̀. Bákan náà, a máa ń wá bá a ṣe máa fi inúure hàn sáwọn tí ò jọ́sìn Jèhófà. (Gál. 6:10) Lọ́pọ̀ ìgbà, ìyẹn máa ń jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìwàásù. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Borys tó jẹ́ ọ̀gá àgbà ilé ìwé kan ní Ukraine. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Borys kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó máa ń hùwà tó dáa sáwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí tó wà nílé ìwé ẹ̀, kì í sì í ta ko ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Nígbà tí Borys pinnu pé òun fẹ́ sá kúrò níbi tí wọ́n ti ń jagun lọ sí apá ibòmíì lórílẹ̀-èdè wọn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ràn án lọ́wọ́. Nígbà tó yá, Borys lọ sí Ìrántí Ikú Kristi. Nígbà tí Borys ń rántí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi inúure hàn sí mi, wọ́n sì tọ́jú mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn gan-an.”

11 Àwa náà lè fara wé Baba wa ọ̀run aláàánú tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ bóyá Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (Lúùkù 6:31, 36) A nírètí pé bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn máa mú kí wọ́n di ọmọlẹ́yìn Kristi. (1 Pét. 2:12) Bóyá wọ́n wá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀, a mọ̀ pé a máa láyọ̀ gan-an tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan.—Ìṣe 20:35.

JÈHÓFÀ Ń DÁÀBÒ BÒ WÁ

12. Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fáwa èèyàn ẹ̀ lápapọ̀? (Sáàmù 91:1, 2, 14)

12 Ka Sáàmù 91:1, 2, 14. Lónìí, Jèhófà ṣèlérí pé òun ò ní jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe òun àtàwa èèyàn ẹ̀ jẹ́. Kò ní jẹ́ kí Sátánì ba ìjọsìn tòótọ́ jẹ́ láé. (Jòh. 17:15) Nígbà tí “ìpọ́njú ńlá” bá bẹ̀rẹ̀, ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní jẹ́ kí àjọṣe òun àtàwa èèyàn ẹ̀ bà jẹ́, ó sì tún máa dáàbò bò wá bó ṣe ṣèlérí.—Ìfi. 7:9, 14.

13. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

13 Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? Jèhófà máa ń fi Bíbélì kọ́ wa láti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Héb. 5:14) Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò, àjọṣe àwa àti Ọlọ́run ò ní bà jẹ́, a ò sì ní kó ara wa sínú wàhálà. (Sm. 91:4) Bákan náà, Jèhófà máa ń lo àwọn ará láti dáàbò bò wá nínú ìjọ. (Àìsá. 32:1, 2) Tá a bá ń wà pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀, a máa rí ìṣírí gbà, a ò sì ní ṣe ohun tó lè kó bá wa.—Òwe 13:20.

14. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìṣòro wa ni Jèhófà máa ń mú kúrò? (b) Kí ni Sáàmù 9:10 fi dá wa lójú? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

14 Láyé àtijọ́, àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà dáàbò bo àwọn èèyàn ẹ̀, tí ò sì jẹ́ kí ohunkóhun ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà ló ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé “ìgbà àti èèṣì” máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà míì. (Oníw. 9:11) Bákan náà, tipẹ́tipẹ́ ni Jèhófà ti máa ń fàyè gbà á kí wọ́n ṣe inúnibíni sáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, kí wọ́n sì pa wọ́n torí pé ó fẹ́ fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. (Jóòbù 2:4-6; Mát. 23:34) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì kì í ṣe gbogbo ìṣòro wa ni Jèhófà máa ń mú kúrò, ó dá wa lójú pé kò ní fi àwa tá a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ sílẹ̀ láé.d—Sm. 9:10.

JÈHÓFÀ Ń TÙ WÁ NÍNÚ

15. Báwo ni Jèhófà ṣe ń tù wá nínú tá a bá ń gbàdúrà, tá à ń ka Bíbélì, tá a sì ń wà pẹ̀lú àwọn ará? (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4)

15 Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4. Nígbà míì, a máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn, a sì máa ń ṣàníyàn. Ó sì ṣeé ṣe kó o láwọn ìṣòro kan báyìí tó ń mú kó o máa rò pé o dá wà. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tiẹ̀ mọ ohun tó ò ń bá yí? Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà mọ̀ ọ́n. Yàtọ̀ sí pé ó mọ ẹ̀dùn ọkàn wa, ó tún máa “ń tù wá nínú nínú gbogbo àdánwò wa.” Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣe é? Tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, ó máa fún wa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye.” (Fílí. 4:6, 7) Jèhófà tún máa ń tù wá nínú tá a bá ń ka Bíbélì. Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Bákan náà, Jèhófà máa ń lo àwọn ará láti tù wá nínú tá a bá wà nípàdé àtìgbà tá a bá gbọ́rọ̀ ìṣírí látinú Bíbélì.

16. Kí lo kọ́ lára Nathan àti Priscilla?

16 Ká lè mọ bí Jèhófà ṣe ń fi Bíbélì tù wá nínú, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Nathan àti ìyàwó ẹ̀ Priscilla tí wọ́n ń gbé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, wọ́n pinnu láti lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù. Arákùnrin Nathan sọ pé: “Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún wa tá a bá lọ ṣèrànwọ́.” Àmọ́, ibi tí wọ́n fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀ torí pé nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn, wọn ò sì lówó lọ́wọ́. Nígbà tó yá, wọ́n pa dà sílé, síbẹ̀ nǹkan ò rọrùn fún wọn. Nathan sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé Ọlọ́run ò ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe rò. Ńṣe ló kàn ń ṣe mí bíi pé mo ti ṣẹ Jèhófà.” Àmọ́, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Nathan àti Priscilla rí i pé Ọlọ́run ò fìgbà kankan pa wọ́n tì lásìkò táwọn níṣòro. Nathan tún sọ pé, “Lásìkò tí nǹkan ò rọrùn yẹn, ńṣe ni Bíbélì dà bí ọ̀rẹ́ àtàtà kan tó ń tù wá nínú, tó sì ń tọ́ wa sọ́nà. Bá a ṣe ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa, dípò ká gbé e sọ́kàn. Ìyẹn sì múra wa sílẹ̀ de àwọn ìṣòro míì tó lè wáyé lọ́jọ́ iwájú.”

17. Báwo ni Jèhófà ṣe tu Arábìnrin Helga nínú? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa náà lè tù wá nínú. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Helga tó ń gbé orílẹ̀-èdè Hungary. Ọ̀pọ̀ ọdún ni ìṣòro fi ń yí lu ìṣòro fún arábìnrin yìí, ìyẹn jẹ́ kó máa ṣàníyàn, kó sì máa rò pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, nígbà tó rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, ó rí i pé Jèhófà lo àwọn ará ìjọ láti tu òun nínú. Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni Jèhófà ń ràn mí lọ́wọ́ lásìkò tí mi ò lókun torí àwọn ìṣòro tí mò ń bá yí, irú bíi wàhálà ibi iṣẹ́, bí màá ṣe bójú tó ọmọkùnrin mi tó ń ṣàìsàn àtàwọn ìṣòro míì. Ọgbọ̀n ọdún (30) ti kọjá báyìí, síbẹ̀ kò sí ọjọ́ kan tí Jèhófà kì í tù mí nínú. Ó sábà máa ń lo àwọn ará láti sọ̀rọ̀ tó máa fi mí lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé wọ́n mọyì gbogbo ohun tí mò ń ṣe. Gbogbo ìgbà làwọn ará máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù mi, wọ́n máa ń fi káàdì ránṣẹ́, wọ́n sì máa ń gbóríyìn fún mi nígbà tí mo bá nílò ẹ̀ gan-an.”

Fọ́tò: Àwọn ará tu arákùnrin àgbàlagbà kan nínú. 1. Ó ń wo àwòrán táwọn ọmọ kékeré yà fún un. 2. Arákùnrin kan fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù ẹ̀. 3. Tọkọtaya kan gbé oúnjẹ, èso àti ewébẹ̀ wá fún un. 4. Arákùnrin kan ń pè é lórí fóònù. 5. Ọmọdébìnrin kan ya àwòrán kìnnìún tó wà ní Párádísè kó lè fi ránṣẹ́ sí arákùnrin náà.

Báwo ni Jèhófà ṣe lè lò ẹ́ láti tu àwọn míì nínú? (Wo ìpínrọ̀ 17)


18. Báwo la ṣe lè tu àwọn èèyàn nínú?

18 Tá a bá ń tu àwọn èèyàn nínú, Jèhófà là ń fara wé, àǹfààní ńlá sì nìyẹn. Báwo la ṣe lè ṣe é? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, tá a bá sọ̀rọ̀ tó tù wọ́n nínú, tá a sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. (Òwe 3:27) Ó yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tu àwọn ará wa nínú nígbà ìṣòro, títí kan àwọn tí ò sin Jèhófà. Tí àwọn aládùúgbò wa bá ní ẹ̀dùn ọkàn, tí wọ́n ń ṣàìsàn tàbí tí wọ́n ń ṣàníyàn, ó yẹ ká lọ sọ́dọ̀ wọn, ká fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, ká sì sọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Bíbélì fún wọn. Tá a bá ń fara wé Jèhófà “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” kì í ṣe pé à ń ran àwọn ará lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wọn nìkan ni, á tún jẹ́ káwọn tí ò sin Jèhófà báyìí wá jọ́sìn ẹ̀ tó bá yá.—Mát. 5:16.

JÈHÓFÀ KÌ Í FI WÁ SÍLẸ̀

19. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ń ṣe fún wa, báwo la sì ṣe lè fara wé e?

19 Ọ̀rọ̀ gbogbo àwa tá a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà jẹ ẹ́ lógún gan-an. Jèhófà kì í fi wá sílẹ̀ nígbà ìṣòro. Bí òbí kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀ ṣe máa ń bójú tó o, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa ń bójú tó àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀. Ó máa ń tọ́ wa sọ́nà, ó ń pèsè fún wa, ó ń dáàbò bò wá, ó sì máa ń tù wá nínú. Tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, tá a sì ń fún wọn níṣìírí nígbà ìṣòro, ńṣe là ń fara wé Jèhófà Bàbá wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa. Òótọ́ ni pé a lè níṣòro tàbí kí ohun kan ṣẹlẹ̀ sí wa tó jẹ́ ká ní ẹ̀dùn ọkàn, àmọ́ ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀. Ó ṣe tán, ó ṣèlérí fún wa pé ká ‘má bẹ̀rù, torí òun wà pẹ̀lú wa.’ (Àìsá. 41:10) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Ká sòótọ́, Jèhófà ò fìgbà kankan fi wá sílẹ̀.

BÁWO NI JÈHÓFÀ ṢE Ń . . .

  • tọ́ wa sọ́nà?

  • pèsè fún wa?

  • dáàbò bò wá, tó sì ń tù wá nínú?

ORIN 100 Máa Fi Ìfẹ́ Gbà Wọ́n Lálejò

a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ẹ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga” nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2011.

b Wo ìpínrọ̀ 11-14 nínú àpilẹ̀kọ náà “Máa Ṣe Ohun Tí Jèhófà Bá Sọ” nínú Ilé Ìṣọ́ February 2024.

c Tó o bá lọ sórí jw.org, wàá rí àwọn àjálù tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa láìpẹ́ yìí. Tẹ “ìrànlọ́wọ́ nígbà àjálù” sínú àpótí tá a fi ń wá ọ̀rọ̀.

d Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ February 2017.

e ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Nígbà tí àjálù ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Màláwì, ètò Ọlọ́run pèsè oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì fáwọn ará, wọ́n sì fi Bíbélì tù wọ́n nínú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́