ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 April ojú ìwé 26-31
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́kùnrin, Ẹ Fara Wé Máàkù àti Tímótì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́kùnrin, Ẹ Fara Wé Máàkù àti Tímótì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • MÚRA TÁN LÁTI RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́ BÍI MÁÀKÙ
  • MÁA ṢE OHUN TÓ FI HÀN PÉ O NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ARÁ BÍI TÍMÓTÌ
  • MÁA FI ÌMỌ̀RÀN PỌ́Ọ̀LÙ SÍLÒ
  • WÀÁ JÀǸFÀÀNÍ TÓ O BÁ Ń RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́
  • Pọ́ọ̀lù “Ń Fún Àwọn Ìjọ Lókun”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Ẹ̀yin Arákùnrin, Ṣé Ẹ̀ Ń Ṣiṣẹ́ Kára Kẹ́ Ẹ Lè Di Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Máa Rántí Pé Jèhófà Ni “Ọlọ́run Alààyè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 April ojú ìwé 26-31

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 18

ORIN 65 Ẹ Tẹ̀ Síwájú!

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́kùnrin, Ẹ Fara Wé Máàkù àti Tímótì

“Mú Máàkù dání tí o bá ń bọ̀, torí ó ń ràn mí lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.”—2 TÍM. 4:11.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa rí bí àwọn ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè fara wé Máàkù àti Tímótì kí wọ́n lè ní àwọn ànímọ́ táá jẹ́ kí wọ́n ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà àtàwọn ará.

1-2. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó ṣòro fún Máàkù àti Tímótì láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

Ẹ̀YIN ọ̀dọ́kùnrin, ṣé ó wù yín láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kẹ́ ẹ sì túbọ̀ máa ran àwọn ará ìjọ lọ́wọ́? Ó dájú pé ó ń wù yín láti ṣe bẹ́ẹ̀. Inú wa ń dùn bá a ṣe ń rí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n ṣe tán láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lọ́wọ́! (Sm. 110:3) Àmọ́ àwọn nǹkan kan lè mú kó ṣòro fún ẹ láti ṣe púpọ̀ sí i. Ṣé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà torí pé o ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ? Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o má gba iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ gbé fún ẹ nínú ìjọ torí ò ń wò ó pé o ò ní lè ṣe é dáadáa? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé ìwọ nìkan kọ́ nirú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí.

2 Irú nǹkan báyìí ti ṣẹlẹ̀ sí Máàkù àti Tímótì rí. Àmọ́ wọn ò jẹ́ kí ìbẹ̀rù ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tàbí torí pé àwọn ò nírìírí tó pọ̀ dí wọn lọ́wọ́ láti ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ilé tó dáa ni Máàkù àti ìyá ẹ̀ jọ ń gbé nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ní kó rìnrìn àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ pẹ̀lú àwọn. (Ìṣe 12:12, 13, 25) Àmọ́, Máàkù fi àdúgbò tó ti mọ̀ dáadáa yẹn sílẹ̀ kó lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Ó kọ́kọ́ lọ sí Áńtíókù, lẹ́yìn náà, ó tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lọ sáwọn agbègbè míì tó jìnnà. (Ìṣe 13:1-5) Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí Tímótì máa gbé pẹ̀lú àwọn òbí ẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé káwọn jọ máa wàásù. Torí pé ọ̀dọ́ ni, kò sì tíì nírìírí tó pọ̀, ó lè máa bẹ̀rù láti tẹ̀ lé e. (Fi wé 1 Kọ́ríńtì 16:10, 11 àti 1 Tímótì 4:12.) Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, ó gbà láti tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù, Jèhófà sì bù kún iṣẹ́ tó ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀.—Ìṣe 16:3-5.

3. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù mọyì Máàkù àti Tímótì? (2 Tímótì 4:6, 9, 11) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Àtìgbà tí Máàkù àti Tímótì ti wà lọ́dọ̀ọ́ ni wọ́n ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè bójú tó ojúṣe tó pọ̀ nínú ìjọ, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n ní ìrírí tó pọ̀. Pọ́ọ̀lù mọyì àwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí gan-an débi pé ó fẹ́ kí wọ́n wá sọ́dọ̀ òun nígbà tó mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ kú. (Ka 2 Tímótì 4:6, 9, 11.) Àwọn ànímọ́ tó dáa wo ni Máàkù àti Tímótì ní tó mú kí Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ wọn? Báwo lẹ̀yin arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ ṣe lè fìwà jọ wọ́n? Báwo lẹ sì ṣe lè jàǹfààní nínú ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wọn?

Fọ́tò: 1. Máàkù ṣètò oúnjẹ àtohun tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà máa mu. 2. Tímótì ń ka lẹ́tà fáwọn alàgbà, wọ́n sì ń fetí sóhun tó ń kà.

Máàkù àti Tímótì nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù gan-an, wọ́n sì bá a bójú tó ọ̀pọ̀ ojúṣe nínú ìjọ (Wo ìpínrọ̀ 3)b


MÚRA TÁN LÁTI RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́ BÍI MÁÀKÙ

4-5. Kí ni Máàkù ṣe tó fi hàn pé ó múra tán láti ran àwọn ará lọ́wọ́?

4 Ìwé kan sọ pé kéèyàn ṣèrànwọ́ tàbí ṣèránṣẹ́ fáwọn míì ni pé “kẹ́ni náà ṣiṣẹ́ kára kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, kó má sì jẹ́ kó sú òun.” Ohun tí Máàkù sì ṣe gan-an nìyẹn. Ó ṣeé ṣe kó dun Máàkù bí Pọ́ọ̀lù ò ṣe mú un dání nígbà tó fẹ́ rìnrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì, ìyẹn sì lè mú kó rẹ̀wẹ̀sì. (Ìṣe 15:37, 38) Àmọ́, Máàkù ò jẹ́ kí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kóun má ṣèrànwọ́ fáwọn ará mọ́.

5 Torí náà, Máàkù tẹ̀ lé Bánábà ìbátan ẹ̀ lọ sí ibòmíì, kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ Ọlọ́run nìṣó. Nǹkan bí ọdún mọ́kànlá (11) lẹ́yìn náà, Máàkù wà lára àwọn tó ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ fi sẹ́wọ̀n nílùú Róòmù. (Fílém. 23, 24) Kódà, Pọ́ọ̀lù mọyì bí Máàkù ṣe ran òun lọ́wọ́ gan-an débi tó fi sọ pé “orísun ìtùnú” ló jẹ́ fóun.—Kól. 4:10, 11.

6. Àǹfààní wo ni Máàkù rí torí pé ó máa ń wà pẹ̀lú àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

6 Máàkù jàǹfààní gan-an torí pé gbogbo ìgbà ló máa ń wà pẹ̀lú àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Ó wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù fúngbà díẹ̀ nílùú Róòmù, lẹ́yìn náà ó lọ sọ́dọ̀ àpọ́sítélì Pétérù nílùú Bábílónì. Àwọn méjèèjì mọwọ́ ara wọn débi pé Pétérù pè é ní “Máàkù ọmọ mi.” (1 Pét. 5:13) Bí àwọn méjèèjì ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, ó ṣeé ṣe kí Pétérù sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn nǹkan tí Jésù ṣe nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ fún Máàkù ọ̀rẹ́ ẹ̀, àwọn nǹkan yìí sì ni Máàkù kọ sínú Ìwé Ìhìn Rere rẹ̀ nígbà tó yá.a

7. Báwo ni Arákùnrin Seung-Woo ṣe fara wé Máàkù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Máàkù ò fìgbà kankan dẹwọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà, ó sì sún mọ́ àwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Báwo lo ṣe lè fara wé Máàkù? Tó bá ń wù ẹ́ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn kan àmọ́ tọ́wọ́ ẹ ò tíì tẹ̀ ẹ́, ní sùúrù, kó o sì wo àwọn nǹkan míì tó o lè máa ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà àti nínú ìjọ. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Seung-Woo tó ti di alàgbà báyìí. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó máa ń fi ara ẹ̀ wé àwọn ọ̀dọ́kùnrin míì tí wọ́n ti fún láwọn ojúṣe kan nínú ìjọ. Torí náà, ó rò pé wọ́n ti pa òun tì, àmọ́ ó sọ̀rọ̀ náà fáwọn alàgbà. Ọ̀kan lára àwọn alàgbà náà gbà á nímọ̀ràn pé kó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti máa ran àwọn ará lọ́wọ́, kódà tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan ò rí àwọn nǹkan rere tó ń ṣe. Seung-Woo ṣe ohun tí alàgbà yẹn sọ, ó máa ń ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ àtàwọn ará tí ipò wọn gba pé ká fi mọ́tò gbé wọn wá sípàdé. Nígbà tó rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ohun tí alàgbà yẹn sọ jẹ́ kí n mọ àwọn nǹkan míì tí mo lè ṣe kí n lè túbọ̀ máa ran àwọn ará lọ́wọ́. Mo wá rí i pé ayọ̀ mi ń pọ̀ sí i bí mo ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́.”

Arákùnrin ọ̀dọ́ kan fi mọ́tò gbé arákùnrin àgbàlagbà kan lọ sípàdé.

Àǹfààní wo lẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin máa rí tẹ́ ẹ bá ń bá àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣiṣẹ́? (Wo ìpínrọ̀ 7)


MÁA ṢE OHUN TÓ FI HÀN PÉ O NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ARÁ BÍI TÍMÓTÌ

8. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi yan Tímótì pé kó tẹ̀ lé òun? (Fílípì 2:19-22)

8 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ pa dà sáwọn ìlú tí wọ́n ti ṣenúnibíni sí i, ó gba pé káwọn arákùnrin tó nígboyà tẹ̀ lé e. Sílà tó ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún ló ní kó kọ́kọ́ tẹ̀ lé òun. (Ìṣe 15:22, 40) Nígbà tó yá, ó ní kí Tímótì máa báwọn rìnrìn àjò. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi fẹ́ kí Tímótì tẹ̀ lé òun? Ọ̀kan lára ìdí náà ni pé àwọn ará sọ̀rọ̀ Tímótì dáadáa. (Ìṣe 16:1, 2) Bákan náà, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará dénú.—Ka Fílípì 2:19-22.

9. Àwọn nǹkan wo ni Tímótì ṣe tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ará jẹ ẹ́ lógún?

9 Àtìgbà tí Tímótì ti ń rìnrìn àjò pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù ló ti ń ṣe ohun tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ará jẹ ẹ́ lógún, kò sì mọ tara ẹ̀ nìkan. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi fọkàn tán an, tó sì ní kó dúró sí Bèróà kó lè fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni níṣìírí. (Ìṣe 17:13, 14) Lásìkò yẹn, ó dájú pé Tímótì máa kẹ́kọ̀ọ́ lára Sílà tóun náà wà ní Bèróà. Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé kó máa lọ sílùú Tẹsalóníkà, kó lè fáwọn ará tó wà níbẹ̀ lókun. (1 Tẹs. 3:2, àlàyé ìsàlẹ̀) Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, Tímótì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. Ó nífẹ̀ẹ́ wọn débi pé nígbà míì ó máa ń “sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún,” àánú àwọn tó ń jìyà sì máa ń ṣe é. (Róòmù 12:15; 2 Tím. 1:4) Báwo lẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè fara wé Tímótì?

10. Báwo ni arákùnrin kan tó ń jẹ́ Woo Jae ṣe kọ́ bó ṣe lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará?

10 Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Woo Jae kọ́ bó ṣe lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó máa ń ṣòro fún un láti bá àwọn ará tó jù ú lọ sọ̀rọ̀. Ṣe ló kàn máa kí wọn nípàdé, táá sì máa bá tiẹ̀ lọ. Ni alàgbà kan bá gbà á nímọ̀ràn pé kó máa bá àwọn ará sọ̀rọ̀, kó sì máa sọ ohun tó dáa tí wọ́n ń ṣe fún wọn. Alàgbà náà tún sọ fún un pé kó ronú nípa àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. Woo Jae ṣe ohun tí alàgbà náà sọ. Ní báyìí, Woo Jae ti di alàgbà. Ó sọ pé: “Ó ti wá rọ̀ mí lọ́rùn gan-an láti máa báwọn ará sọ̀rọ̀ bóyá ọmọdé ni wọ́n tàbí àgbàlagbà. Inú mi ń dùn báyìí pé kì í ṣe tara mi nìkan ni mo mọ̀, mo ti wá mọ ohun táwọn ará ń bá yí, ìyẹn sì ń jẹ́ kí n máa ràn wọ́n lọ́wọ́.”

11. Báwo lẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará nínú ìjọ? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin náà lè kọ́ bẹ́ ẹ ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará. Tó o bá wà nípàdé, máa bá gbogbo èèyàn sọ̀rọ̀, ì báà jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà. Béèrè bí nǹkan ṣe ń lọ, kó o sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, ìyẹn á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè rí i pé tọkọtaya kan tó ti dàgbà ò mọ bí wọ́n ṣe ń lo JW Library®, ó sì lè jẹ́ pé ó ń wù wọ́n láti lọ wàásù, àmọ́ wọn ò tíì rí ẹni tí wọ́n á jọ lọ. Ṣé o lè kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè lo JW Library lórí fóònù wọn tàbí kẹ́ ẹ jọ lọ wàásù? Tó o bá ń ran àwọn ará lọ́wọ́ lọ́nà yìí, àpẹẹrẹ tó dáa lò ń fi lélẹ̀ yẹn.

Arákùnrin ọ̀dọ́ kan àti arákùnrin àgbàlagbà kan jọ ń wàásù láti ilé dé ilé. Arákùnrin àgbàlagbà náà ń bá ọkùnrin kan sọ̀rọ̀, arákùnrin ọ̀dọ́ náà sì ń fi fídíò han ẹni náà.

Ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin lè ṣe nínú ìjọ láti ran àwọn ará lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 11)


MÁA FI ÌMỌ̀RÀN PỌ́Ọ̀LÙ SÍLÒ

12. Báwo lẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì sílò?

12 Pọ́ọ̀lù fún Tímótì nímọ̀ràn táá jẹ́ kó gbé ìgbé ayé tó dáa, kó sì ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀. (1 Tím. 1:18; 2 Tím. 4:5) Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin náà lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìmọ̀ràn tó dáa tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì. Báwo lẹ ṣe lè ṣe é? Á dáa kó o ka lẹ́tà méjèèjì tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, kó o sì wò ó bíi pé ìwọ gan-an ló kọ ọ́ sí, ìyẹn á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè fi í sílò nígbèésí ayé ẹ. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan.

13. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà?

13 “Kọ́ ara rẹ láti fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe àfojúsùn rẹ.” (1 Tím. 4:7b) Kí ni ìfọkànsin Ọlọ́run? Ìfọkànsin Ọlọ́run ni kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí, kó sì máa wu onítọ̀hún láti ṣe ohun tínú Jèhófà dùn sí. Kò sẹ́ni tí wọ́n bí ànímọ́ yìí mọ́, torí náà ó yẹ ká kọ́ ọ. Báwo la ṣe lè ṣe é? Wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “kọ́ ara rẹ” fáwọn eléré ìdárayá tí wọ́n ń fi gbogbo okun wọn múra sílẹ̀ bí ìdíje ṣe ń sún mọ́. Kí wọ́n tó lè ṣàṣeyọrí, wọ́n gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ohun tí wọ́n ń ṣe. Torí náà, tá a bá fẹ́ sún mọ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ tẹra mọ́ àwọn ohun táá jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀.

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ka Bíbélì? Sọ àpẹẹrẹ kan.

14 Jẹ́ kó túbọ̀ mọ́ ẹ lára láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó o sì máa rántí pé ìdí tó o fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ nínú ìtàn ọ̀dọ́kùnrin alákòóso kan tó wá bá Jésù. (Máàkù 10:17-22) Ọ̀dọ́kùnrin náà mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà, àmọ́ kò nígbàgbọ́ tó lágbára táá jẹ́ kó di ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Síbẹ̀, Jésù “nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Ṣé ara tù ẹ́ nígbà tó o kà nípa bí Jésù ṣe fìfẹ́ bá ọ̀dọ́kùnrin yẹn sọ̀rọ̀? Ó dájú pé Jésù fẹ́ kí ọkùnrin yẹn ṣe àyípadà tó yẹ kó lè máa sin Jèhófà. Ohun tí Jésù ṣe yẹn tún jẹ́ ká rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ọkùnrin náà gan-an. (Jòh. 14:9) Bó o ṣe ń ronú nípa ọkùnrin yìí, bi ara ẹ pé, ‘Kí ló yẹ kí n ṣe kí n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kí n sì máa ran àwọn ará lọ́wọ́?’

15. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọ̀dọ́kùnrin máa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan. (1 Tímótì 4:12, 13)

15 “Jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn olóòótọ́.” (Ka 1 Tímótì 4:12, 13.) Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé kó tẹra mọ́ kíkàwé, kó sì máa kọ́ni, àmọ́ ó tún sọ fún un pé ó ṣe pàtàkì kó láwọn ànímọ́ tó dáa, bí ìfẹ́, ìgbàgbọ́ àti ìwà mímọ́. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ìwà wa máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ju ọ̀rọ̀ ẹnu wa lọ. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé wọ́n ní kó o sọ àsọyé kan nípa ìdí tó fi yẹ ká máa fìtara wàásù, ó dájú pé ọ̀rọ̀ máa dùn lẹ́nu ẹ tó o bá ń wàásù déédéé. Àwọn ará sì máa múra tán láti ṣe ohun tó o sọ torí wọ́n rí i pé ìwọ náà ń wàásù déédéé.—1 Tím. 3:13.

16. (a) Nǹkan márùn-ún wo làwọn ọ̀dọ́kùnrin lè ṣe kí wọ́n lè fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀? (b) Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe lè jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa “nínú ọ̀rọ̀” sísọ?

16 Ní 1 Tímótì 4:12, Pọ́ọ̀lù sọ nǹkan márùn-ún táwọn ọ̀dọ́kùnrin lè ṣe kí wọ́n lè fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. O ò ṣe wáyè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan márùn-ún náà? Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o fẹ́ túbọ̀ sunwọ̀n sí i “nínú ọ̀rọ̀” sísọ, á dáa kó o ronú nípa bó o ṣe lè máa fi ọ̀rọ̀ ẹ gbé àwọn míì ró. Tó o bá ṣì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí ẹ, ṣé o lè túbọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o mọrírì àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe fún ẹ? Lẹ́yìn ìpàdé, ṣé o lè sọ ohun tó o gbádùn nínú iṣẹ́ tẹ́nì kan ṣe fún un? Bákan náà, gbìyànjú láti máa dáhùn lọ́rọ̀ ara ẹ nípàdé. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ará máa rí i pé ò ń tẹ̀ síwájú.—1 Tím. 4:15.

17. Kí ló máa jẹ́ kọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin kan tẹ àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run? (2 Tímótì 2:22)

17 “Sá fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìgbà ọ̀dọ́, àmọ́ máa wá òdodo.” (Ka 2 Tímótì 2:22.) Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé kó yẹra fáwọn nǹkan tí ò ní jẹ́ kọ́wọ́ ẹ̀ tẹ àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, tó sì máa ba àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. O lè rí i pé àwọn nǹkan kan wà tó o máa ń ṣe tí kì í jẹ́ kó o ráyè ṣe àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan náà ò burú. Bí àpẹẹrẹ, wo iye àkókò tó o máa ń lò nídìí eré ìnàjú, lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí iye àkókò tó o fi ń gbá géèmù. Ṣé o lè lo díẹ̀ lára àkókò yẹn láti ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn Jèhófà? Ṣé o lè yọ̀ǹda ara ẹ láti tún Ilé Ìpàdé yín ṣe tàbí kó o lọ wàásù níbi ìpàtẹ ìwé? Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, wàá ní àwọn ọ̀rẹ́ táá jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run.

WÀÁ JÀǸFÀÀNÍ TÓ O BÁ Ń RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́

18. Kí ló mú ká gbà pé Máàkù àti Tímótì láyọ̀, wọ́n sì gbádùn ayé wọn?

18 Máàkù àti Tímótì yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ìyẹn mú kí wọ́n láyọ̀, kí wọ́n sì gbádùn ayé wọn. (Ìṣe 20:35) Torí pé Máàkù fẹ́ ran àwọn ará lọ́wọ́, ó rìnrìn àjò lọ síbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láyé. Ó tún kọ ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ lọ́nà tó wọni lọ́kàn. Tímótì náà ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti dá àwọn ìjọ sílẹ̀, ó sì fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin níṣìírí. Ó dájú pé Jèhófà mọyì bí Máàkù àti Tímótì ṣe yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn ará lọ́wọ́.

19. Kí nìdí tó fi yẹ kẹ́yin ọ̀dọ́kùnrin fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì sílò, àǹfààní wo lẹ sì máa rí tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀?

19 Àwọn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì ọ̀rẹ́ ẹ̀ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an, ẹ ò sì ní gbàgbé pé ọ̀dọ́ ni Tímótì lásìkò tá à ń sọ yìí. Bí Jèhófà ṣe fi ẹ̀mí ẹ̀ darí Pọ́ọ̀lù láti kọ àwọn lẹ́tà yìí fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin gan-an. Ó fẹ́ kẹ́ ẹ ṣàṣeyọrí. Torí náà, ṣe gbogbo nǹkan tó o lè ṣe láti fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò, kó o sì jẹ́ kó túbọ̀ máa wù ẹ́ láti ran àwọn ará lọ́wọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá gbádùn ayé ẹ báyìí, wàá sì “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tím. 6:18, 19.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí lo kọ́ lára Máàkù?

  • Bíi Tímótì, kí lo lè ṣe táá fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn ará?

  • Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin táá jẹ́ kẹ́ ẹ ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn Ọlọ́run?

ORIN 80 ‘Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà’

a Torí pé Pétérù kì í fi bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ pa mọ́, ìyẹn jẹ́ kó lè ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ fún Máàkù nípa bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jésù àtàwọn nǹkan tó ṣe láwọn ìgbà tó yàtọ̀ síra. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nínú Ìwé Ìhìn Rere tí Máàkù kọ, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sọ̀rọ̀ nípa bọ́rọ̀ ṣe rí lára Jésù àtàwọn nǹkan tó ṣe.—Máàkù 3:5; 7:34; 8:12.

b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Máàkù ran Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò míṣọ́nnárì. Tímótì bẹ ìjọ kan wò, ó sì fún wọn níṣìírí kí wọ́n lè lókun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́