OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́
Bá A Ṣe Lè Túbọ̀ Jàǹfààní Látinú Àwọn Àwòrán inú Ìwé Wa
Àwọn àwòrán tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì pọ̀ nínú àwọn ìwé wa. Kí la lè ṣe ká lè jàǹfààní àwọn ẹ̀kọ́ náà?
Wo àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀ kó o tó ka àpilẹ̀kọ náà. Àwọn àwòrán yẹn lè mú kó wù ẹ́ láti ka àpilẹ̀kọ náà. Ńṣe ló máa dà bí ìgbà tá à ń fún ojú lóúnjẹ. Torí náà, bi ara ẹ pé, ‘Kí ni mo rí?’—Émọ́sì 7:7, 8.
Bó o ṣe ń ka àpilẹ̀kọ náà, ronú nípa ìdí tí wọ́n fi lo àwòrán yẹn. Tí wọ́n bá ṣe àlàyé àwòrán náà, rí i pé o kà á. Ronú nípa bí àwòrán tó o rí ṣe kan ohun tí wọ́n ń jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yẹn àti bó ṣe kàn ẹ́.
Lẹ́yìn tó o bá ka àpilẹ̀kọ yẹn tán, fi àwọn àwòrán náà ṣe àtúnyẹ̀wò ohun tó o kọ́ níbẹ̀. Wò ó bóyá wàá lè rántí àwọn àwòrán yẹn àti ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ ẹ láìwo ìwé.
O ò ṣe tún wo àwọn àwòrán tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí, kó o sì wò ó bóyá wàá rántí ohun táwọn àwòrán náà kọ́ ẹ?