ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Mo Kọ́ Ọ̀pọ̀ Nǹkan Látọ̀dọ̀ Olùkọ́ Wa Atóbilọ́lá
Ọ̀PỌ̀ nǹkan ló ṣẹlẹ̀ sí èmi àtìyàwó mi nígbà tá à ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àti míṣọ́nnárì. Àwọn sójà máa ń dá ọkọ̀ wa dúró, àwọn èèyàn máa ń dáná sójú ọ̀nà, ìjì líle máa ń jà, ogun abẹ́lé máa ń ṣẹlẹ̀, kódà ọ̀pọ̀ ìgbà la ní láti sá kúrò nílé wa. Láìka àwọn ìṣòro yìí sí, a ò kábàámọ̀ ìpinnu tá a ṣe. Torí pé Jèhófà ò fi wá sílẹ̀, ó ń tì wá lẹ́yìn, a sì ń rí ọwọ́ ẹ̀ láyé wa. Ká sòótọ́, Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá ti kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye.—Jóòbù 36:22; Àìsá. 30:20.
MO KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN ÒBÍ MI
Lọ́dún 1957, àwọn òbí mi kó kúrò ní orílẹ̀-èdè Ítálì lọ sílùú Kindersley, ní agbègbè Saskatchewan, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àtìgbà yẹn la sì ti ń fi gbogbo ayé wa sin Jèhófà. Mo rántí pé nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń pẹ́ gan-an lóde ìwàásù pẹ̀lú àwọn ará ilé mi. Ìyẹn ló mú kí n máa dápàárá nígbà míì pé ọmọ ọdún mẹ́jọ péré ni mí tí mo ti ń ṣe “aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.”
Ìdílé wa rèé ní nǹkan bí ọdún 1966
Àwọn òbí mi ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, àmọ́ wọ́n fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká yááfì nǹkan torí ìjọsìn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 1963, wọ́n ta ọ̀pọ̀ lára nǹkan ìní wọn kí wọ́n lè rówó lọ sí àpéjọ àgbáyé tá a ṣe nílùú Pasadena, ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lọ́dún 1972, a kó lọ sílùú Trail, ní ìpínlẹ̀ British Columbia lórílẹ̀-èdè Kánádà ká lè wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Italian lágbègbè yẹn, ibẹ̀ tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún (1,000) kìlómítà síbi tá à ń gbé tẹ́lẹ̀. Ilé ìtajà kan ni bàbá mi ti ń ṣiṣẹ́, àwọn ló sì máa ń tún ibẹ̀ ṣe kó lè mọ́ tónítóní. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n fẹ́ gbé wọn sípò tó ga lẹ́nu iṣẹ́, àmọ́ wọn ò gbà torí kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn Ọlọ́run.
Inú mi dùn pé àwọn òbí mi fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún èmi, ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn àbúrò mi. Ọ̀dọ̀ wọn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí mò ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, mi ò sì ní gbàgbé àwọn ẹ̀kọ́ náà jálẹ̀ ayé mi. Ọ̀kan lára ẹ̀ ni pé tí mo bá ń wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà máa bójú tó mi.—Mát. 6:33.
A BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN
Lọ́dún 1980, mo fẹ́ arábìnrin kan tó rẹwà. Debbie lorúkọ ẹ̀, iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ló sì fẹ́ fi gbogbo ayé ẹ̀ ṣe. Nígbà tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún làwa méjèèjì fẹ́ ṣe, Debbie bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tá a ṣègbéyàwó. Ọdún kan lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, a kó lọ síjọ kékeré kan ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́, èmi náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.
Ìgbà tá a ṣègbéyàwó ní 1980
Nígbà tó yá, ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, a sì pinnu pé a máa kúrò níbẹ̀. Àmọ́, ká tó ṣe bẹ́ẹ̀, a bá alábòójútó àyíká wa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ó fìfẹ́ bá wa sòótọ́ ọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ̀yin gan-an lẹ̀ ń dá kún ìṣòro ara yín. Ìṣòro tẹ́ ẹ ní lẹ gbájú mọ́ dípò àwọn nǹkan tó dáa tó ń ṣẹlẹ̀. Tó bá jẹ́ àwọn nǹkan rere lẹ̀ ń wá, ẹ máa rí i.” Ìmọ̀ràn tá a nílò lásìkò yẹn gan-an ló fún wa. (Sm. 141:5) Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, a sì wá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan rere ló ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wa tó lè fún wa láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ló fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà, títí kan àwọn ọmọdé àtàwọn tí ọkọ tàbí aya wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A ò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Ohun tá a kọ́ ni pé àwọn nǹkan dáadáa tó ń ṣẹlẹ̀ ló yẹ ká máa gbájú mọ́, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé bí nǹkan ò bá tiẹ̀ rí bá a ṣe fẹ́, Jèhófà máa bójú tó o lásìkò tó tọ́. (Míkà 7:7) Bó ṣe di pé a tún pa dà láyọ̀ nìyẹn, a sì ń bá iṣẹ́ ìsìn wa lọ.
Àwọn olùkọ́ tó kọ́ wa nílé ẹ̀kọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà tá a kọ́kọ́ lọ ti sìn nílẹ̀ òkèèrè rí. Wọ́n máa ń fi àwọn fọ́tò tí wọ́n yà nígbà yẹn hàn wá, wọ́n tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n ní àti bí Jèhófà ṣe bù kún wọn, ìyẹn sì jẹ́ kó wu àwa náà láti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Torí náà, a pinnu pé iṣẹ́ míṣọ́nnárì la máa ṣe.
A wà ní Ilé Ìpàdé kan ní ìpínlẹ̀ British Columbia lọ́dún 1983
Kí ọwọ́ wa lè tẹ ohun tá a fojú sùn yẹn, a kó lọ sílùú Quebec lọ́dún 1984 níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé, ibẹ̀ sì tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) kìlómítà sí British Columbia tá a wà tẹ́lẹ̀. Ìyẹn gba pé ká kọ́ èdè àti àṣà tuntun. Ìṣòro míì tá a ní ni pé a kì í sábà lówó lọ́wọ́. Kódà, àwọn ìgbà kan wà tó jẹ́ pé ọ̀dùnkún tó ṣẹ́ kù lóko ẹnì kan ni wọ́n máa ń ní ká wá ṣà. A jẹ ọ̀dùnkún débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ hù lórí wa torí oríṣiríṣi àrà ni Debbie máa ń fi dá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn rárá, à ń láyọ̀ bá a ṣe ń fara dà á. Bákan náà, a rí i pé Jèhófà ń tọ́jú wa.—Sm. 64:10.
Lọ́jọ́ kan, a gba ìpè kan tá ò retí. Wọ́n ní ká wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, a ti gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú wa dùn, iṣẹ́ míṣọ́nnárì ló ṣì ń wù wá. Síbẹ̀, a gbà láti lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tá a débẹ̀, a bi Arákùnrin Kenneth Little tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka pé “Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá lọ pè wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì?” Ó ní, “Ẹ jẹ́ kó dìgbà yẹn ná.”
Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, wọ́n pè wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Torí náà, àfi ká pinnu ohun tá a máa ṣe. Arákùnrin Little sọ fún wa pé: “Èyí ó wù kẹ́ ẹ mú nínú méjèèjì, àwọn ìgbà míì máa wà táá máa ṣe yín bíi pé ẹ̀ bá ti mú ìkejì. Ọ̀kan ò sàn ju ìkejì lọ, kò sí èyí tẹ́ ẹ mú tẹ́ ò ní rọ́wọ́ Jèhófà.” Torí náà, a pinnu láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ọ̀pọ̀ ọdún la sì ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Little sọ fún wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwa náà ti fi ọ̀rọ̀ yìí gba àwọn míì níyànjú tí wọ́n bá fẹ́ pinnu iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n máa ṣe.
A DI MÍṢỌ́NNÁRÌ
(Apá Òsì) Ulysses Glass
(Apá Ọ̀tún) Jack Redford
Inú wa dùn pé a wà lára àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mẹ́rìnlélógún (24) tó wá sí kíláàsì kẹtàlélọ́gọ́rin (83) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ìlú Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York la ti ṣe kíláàsì náà ní April 1987. Arákùnrin Ulysses Glass àti Arákùnrin Jack Redford gangan làwọn olùkọ́ wa. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, oṣù márùn-ún ti pé, a sì kẹ́kọ̀ọ́ yege ní September 6, 1987. Orílẹ̀-èdè Haiti ni wọ́n rán wa lọ, àwa pẹ̀lú John àti Marie Goode.
A wà ní Haiti lọ́dún 1988
Látọdún 1962 tí wọ́n ti lé àwọn míṣọ́nnárì kúrò lórílẹ̀-èdè Haiti, wọn ò tíì rán àwọn míì lọ síbẹ̀. Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege, a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Haiti, a sì ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ kékeré kan tó ní akéde márùndínlógójì (35), ibẹ̀ jìnnà gan-an, òkè sì pọ̀ níbẹ̀. Ọ̀dọ́ ṣì ni wá, a ò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí, àwa nìkan la sì ń gbé ilé míṣọ́nnárì tó wà níbẹ̀. Tálákà làwọn èèyàn ibẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn ò sì mọ̀wé kà. Lásìkò tá a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì, àwọn ará ìlú máa ń jà fún ẹ̀tọ́ wọn, àwọn èèyàn máa ń gbìyànjú láti fipá gbàjọba, wọ́n máa ń dáná sójú ọ̀nà, ìjì líle sì tún máa ń jà níbẹ̀.
Ọ̀pọ̀ nǹkan la kọ́ lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà ní Haiti, wọ́n nífaradà, wọ́n sì ń fayọ̀ sin Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún ọ̀pọ̀ lára wọn, wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì ń fìtara wàásù. Arábìnrin àgbàlagbà kan wà níbẹ̀ tí ò lè kàwé, àmọ́ ó mọ nǹkan bí àádọ́jọ (150) ẹsẹ Bíbélì lórí. Bá a ṣe ń rí ìṣòro táwọn èèyàn náà ń bá yí jẹ́ ká túbọ̀ fìtara wàásù pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló máa yanjú ìṣòro àwa èèyàn. Inú wa dùn gan-an bá a ṣe rí lára àwọn tá a kọ́kọ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti alàgbà.
Nígbà tí mo wà ní Haiti, mo pàdé ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Trevor, èsìn Mormon ló ń ṣe, míṣọ́nnárì sì ni. A jọ sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì láwọn ìgbà mélòó kan. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo gba lẹ́tà kan tí mi ò retí látọ̀dọ̀ ẹ̀. Ó sọ pé: “Mo máa ṣèrìbọmi ní àpéjọ àyíká tó ń bọ̀ yìí! Ó wù mí kí n pa dà sí Haiti, kí n sì ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lágbègbè tí mo ti ṣe míṣọ́nnárì nígbà tí mò ń ṣe ẹ̀sìn Mormon.” Ohun tí òun àti ìyàwó ẹ̀ sì ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún nìyẹn.
WỌ́N RÁN WA LỌ SÍ YÚRÓÒPÙ, LẸ́YÌN NÁÀ A LỌ SÍ ÁFÍRÍKÀ
Ìgbà tí mo wà ní Slovenia lọ́dún 1994
Ètò Ọlọ́run rán wa lọ sí apá ibì kan nílẹ̀ Yúróòpù nígbà tó túbọ̀ rọrùn láti wàásù níbẹ̀. Lọ́dún 1992, a dé ìlú Ljubljana lórílẹ̀-èdè Slovenia nítòsí ibi táwọn òbí mi dàgbà sí kí wọ́n tó kó lọ sórílẹ̀-èdè Ítálì. Nígbà yẹn, wọ́n ṣì ń jagun láwọn agbègbè tí wọ́n ń pè ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀. Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Austria, Croatia àti Serbia ló ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbègbè yìí tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, gbogbo ìlú tó bá ti gbòmìnira lágbègbè yẹn ló máa ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tiẹ̀.
Torí náà, ìyẹn máa gba pé ká kọ́ èdè àti àṣà tuntun. Àwọn ará ìlú yẹn máa ń sọ pé “Jezik je težek” tó túmọ̀ sí “Èdè wa le gan-an o.” Èdè wọn sì le lóòótọ́. Inú wa dùn pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin fara mọ́ àwọn àyípadà tí ètò Ọlọ́run ṣe, a sì rí bí Jèhófà ṣe bù kún wọn. Ìyẹn tún jẹ́ ká rí i pé tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà, ó máa ṣàtúnṣe àwọn nǹkan tí kò tọ́. Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti kọ́ ká tó wá sí Slovenia, àmọ́ àwọn ọdún tá a lò níbẹ̀ jẹ́ ká rántí àwọn ẹ̀kọ́ yẹn, a sì tún kọ́ àwọn nǹkan tuntun.
Àmọ́ àwọn àtúnṣe míì ṣì wà tá a máa ṣe. Lọ́dún 2000, wọ́n rán wa lọ sórílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire, ní West Africa. Nígbà tó sì di November 2002, wọ́n ní ká máa lọ sórílẹ̀-èdè Sierra Leone torí ogun abẹ́lé. Ogun abẹ́lé tí wọ́n jà ní Sierra Leone fún odindi ọdún mọ́kànlá (11) ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ni, torí náà kò rọrùn láti tètè kúrò ní Côte d’Ivoire. Àmọ́ ní gbogbo àsìkò yẹn, àwọn ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́ ń jẹ́ ká máa láyọ̀.
Nígbà tá a débẹ̀, àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àtàwọn ará tó ti fara da ogun abẹ́lé fún ọ̀pọ̀ ọdún la gbájú mọ́. Wọn ò lówó, àmọ́ inú wọn máa ń dùn láti fáwọn èèyàn ní nǹkan. Arábìnrin kan kó àwọn aṣọ kan fún Debbie. Nígbà tí Debbie ò fẹ́ gba àwọn aṣọ náà, ó sọ fún un pé: “Nígbà ogun abẹ́lé, àwọn ará láti orílẹ̀-èdè míì fi ọ̀pọ̀ nǹkan ránṣẹ́ sí wa. Ní báyìí, àwa ló kàn láti ràn yín lọ́wọ́.” Ohun tí arábìnrin yìí sọ jẹ́ ká pinnu pé àwa náà á máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.
Nígbà tó yá, a pa dà sí Côte d’Ivoire, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jà. Torí náà, ní November 2004, wọ́n fi hẹlikópítà gbé wa kúrò níbẹ̀, àmọ́ báàgì kékeré kan péré ni wọ́n sọ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè gbé. Ibùdó àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Faransé ni wọ́n gbé wa lọ, ilẹ̀ẹ́lẹ̀ la sùn sí, nígbà tó sì dọjọ́ kejì, wọ́n gbé wa lọ sí Switzerland. Òru la dé ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Switzerland, àmọ́ àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àtàwọn olùkọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ìyàwó wọn gbá wa mọ́ra, wọ́n fún wa lóúnjẹ gbígbóná àti ọ̀pọ̀ ṣokoléètì. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn múnú wa dùn gan-an ni.
Mò ń bá àwọn tí ogun lé kúrò nílùú sọ̀rọ̀ ní Côte d’Ivoire lọ́dún 2005
Wọ́n rán wa lọ sórílẹ̀-èdè Gánà fúngbà díẹ̀, nígbà tó sì yá, wọ́n ní ká pa dà sí Côte d’Ivoire lẹ́yìn tí ogun náà rọlẹ̀. Inúure táwọn ará fi hàn sí wa ló jẹ́ ká fara dà á láwọn àsìkò tá à ń ṣí kiri torí ogun àti láwọn ìgbà tí wọ́n ní ká lọ ṣiṣẹ́ níbòmíì fúngbà díẹ̀. Òótọ́ ni pé àwa èèyàn Jèhófà máa ń fìfẹ́ hàn síra wa, àmọ́ èmi àti Debbie mọyì ìfẹ́ yìí gan-an, a sì pinnu pé àwa náà á máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbà tó yá la wá rí i pé ṣe ni Jèhófà ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ní gbogbo àsìkò tí nǹkan nira yẹn.
WỌ́N RÁN WA LỌ SÍ MIDDLE EAST
Ìgbà tá a wà ní Middle East lọ́dún 2007
Ní 2006, a gba lẹ́tà kan láti oríléeṣẹ́, wọ́n sì sọ fún wa pé Middle East là ń lọ báyìí. Ìyẹn tún máa gba pé ká kọ́ èdè àti àṣà tuntun, ká sì jẹ́ kára wa mọlé níbẹ̀. Àwọn olóṣèlú àtàwọn ẹlẹ́sìn máa ń fa wàhálà gan-an níbẹ̀, torí náà a kọ́ bá a ṣe lè máa fọgbọ́n ṣe nǹkan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà nínú àwọn ìjọ, inú wa ń dùn pé àwọn ará wà níṣọ̀kan torí pé wọ́n ń ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ. A mọyì àwọn ará gan-an torí pé ọ̀pọ̀ lára wọn ló nígboyà, tí wọ́n sì ń fara dà á bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará ilé wọn, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn aládùúgbò àtàwọn ọmọ ilé ìwé wọn ń ta kò wọ́n.
Ní 2012, a lọ sí àkànṣe àpéjọ tá a ṣe nílùú Tel Aviv, lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé táwa èèyàn Jèhófà máa ṣe àpéjọ lágbègbè yẹn táwọn èèyàn sì pọ̀ gan-an níbẹ̀ látọdún Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S. K. A ò lè gbàgbé ẹ̀ láé!
Láwọn ọdún yẹn, wọ́n rán wa lọ sórílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti ń dí iṣẹ́ wa lọ́wọ́. Nígbà tá à ń lọ, a kó díẹ̀ lára àwọn ìwé wa dání, a sì tún máa ń lọ sóde ìwàásù. Bákan náà, a máa ń ṣe àwọn àpéjọ àyíká kéékèèké. Àwọn sójà tó kó ìbọn dání máa ń wà lójú ọ̀nà, àmọ́ ẹ̀rù kì í bà wá torí pé àwa díẹ̀ la jọ máa ń rìn tá a bá ń wàásù kí wọ́n má bàa fura sí wa.
ÈTÒ ỌLỌ́RUN NÍ KÁ PA DÀ SÍ ÁFÍRÍKÀ
Mò ń múra àsọyé kan lórílẹ̀-èdè Kóńgò, lọ́dún 2014
Ní 2013, ètò Ọlọ́run rán wa lọ síbòmíì tó gba ọ̀pọ̀ àyípadà. Wọ́n ní ká lọ máa ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nílùú Kinshasa, lórílẹ̀-èdè Kóńgò. Orílẹ̀-èdè yẹn tóbi, ó sì rẹwà, àmọ́ ìyà máa ń jẹ wọ́n gan-an torí pé tálákà ló pọ̀ jù níbẹ̀, wọ́n sì tún máa ń jagun. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ sọ fún wa, a sọ pé “A mọ Áfíríkà, ó yá, a ti ṣe tán.” Àmọ́ nígbà tá a débẹ̀, a rí i pé nǹkan ò rọrùn torí pé ọ̀nà ò dáa, kò sì sí àwọn nǹkan amáyédẹrùn míì níbẹ̀. Síbẹ̀, àwọn nǹkan tó dáa tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ la gbájú mọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará máa ń láyọ̀, wọ́n sì máa ń fara dà á bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lówó. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì máa ń wá sípàdé àtàwọn àpéjọ. A rí bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń tẹ̀ síwájú torí pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ nǹkan la kọ́ láwọn ọdún tá a lò ní Kóńgò, a sì ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ tó dà bí ọmọ ìyá.
À ń wàásù ní South Africa lọ́dún 2023
Níparí ọdún 2017, ètò Ọlọ́run tún fún wa níṣẹ́ míì, wọ́n ní ká máa lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní South Africa. Ẹ̀ka ọ́fíìsì yìí ló tóbi jù nínú gbogbo ẹ̀ka ọ́fíìsì tá a ti sìn, iṣẹ́ tuntun ni wọ́n sì gbé fún wa níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ò mọ́ wa lára níbi tá a wà báyìí, àmọ́ àwọn nǹkan tá a ti kọ́ níbi tá a ti sìn tẹ́lẹ̀ ló ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló ti ń fi ọ̀pọ̀ ọdún sin Jèhófà, wọ́n nífaradà, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Inú wa tún máa ń dùn bá a ṣe ń rí ìdílé Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n wà níṣọ̀kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà wọn àti àṣà wọn yàtọ̀ síra. Jèhófà jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwa èèyàn ẹ̀ torí pé à ń gbé ìwà tuntun wọ̀, a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì.
Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, èmi àti Debbie ti ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ tó jẹ́ ká láyọ̀, a sìn láwọn agbègbè tí àṣà àwọn èèyàn ti yàtọ̀ síra, a sì kọ́ oríṣiríṣi èdè. Ká sòótọ́ kò rọrùn, àmọ́ gbogbo ìgbà la máa ń rí i pé Jèhófà lo ètò ẹ̀ àtàwọn ará láti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa. (Sm. 144:2) Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àwọn nǹkan yẹn sì ti jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kí ìwà wa sì dáa sí i.
Mo mọyì bí àwọn òbí mi ṣe tọ́ mi dàgbà àti bí ìyàwó mi ṣe dúró tì mí gbágbáágbá, mo sì tún mọyì bí àwọn ará kárí ayé ṣe wà níṣọ̀kan. Bá a ṣe ń ronú nípa ọjọ́ iwájú wa, a ti pinnu pé àá máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó lọ́dọ̀ Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá.