ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w19 July ojú ìwé 25-29
  • Jèhófà Bù Kún Mi Kọjá Ohun Tí Mo Lérò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Bù Kún Mi Kọjá Ohun Tí Mo Lérò
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÍ MO ṢE BORÍ ÌTÌJÚ TÍ MO SÌ ṢÈPINNU
  • ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ MÁNIGBÀGBÉ TÍ MO KỌ́ NÍ GÍLÍÁDÌ
  • A TÚN KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ Í LẸ́NU IṢẸ́ MÍṢỌ́NNÁRÌ
  • A SÌN NÍ KẸ́ŃYÀ
  • JÈHÓFÀ BÙ KÚN IṢẸ́ WA NÍ ETIÓPÍÀ
  • JÈHÓFÀ MÚ KÍ IṢẸ́ NÁÀ GBÒÒRÒ
  • Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà, Ó sì Ṣe Ohun Tó Yà Mí Lẹ́nu
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Jèhófà Ni Ò Jẹ́ Ká Fà Sẹ́yìn
    Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Mo Kọ́ Ọ̀pọ̀ Nǹkan Látọ̀dọ̀ Olùkọ́ Wa Atóbilọ́lá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Jèhófà Ń hùwà Lọ́nà Ìdúróṣinṣin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
w19 July ojú ìwé 25-29
Manfred àti Gail Tonak lọ́jọ́ tí wọ́n ṣègbéyàwó

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Bù Kún Mi Kọjá Ohun Tí Mo Lérò

Gẹ́gẹ́ bí Manfred Tonak ṣe sọ ọ́

‘MO MỌ̀ pé ó yẹ kí n ṣe aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò ní gbádùn ẹ̀.’ Ìdí sì ni pé mo gbádùn iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí mò ń ṣe gan-an. Mo máa ń fi ẹrù oúnjẹ ránṣẹ́ láti ilẹ̀ Jámánì tí mo wà sáwọn ìlú tó gbayì nílẹ̀ Áfíríkà. Lára àwọn ìlú náà ni Dar es Salaam, Elisabethville àti Asmara. Mi ò mọ̀ pé mo ṣì máa lọ ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún láwọn ìlú yẹn àtàwọn ibòmíì nílẹ̀ Áfíríkà.

Nígbà tí mo pinnu pé màá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìgbésí ayé mi yí pa dà lọ́nà tí mi ò lérò. (Éfé. 3:20) Ṣùgbọ́n, ó lè yà yín lẹ́nu pé báwo ni gbogbo ẹ̀ ṣe yí pa dà bìrí. Ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ara mi fún yín.

Oṣù mélòó kan lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1939 ni wọ́n bí mi nílùú Berlin, lórílẹ̀-èdè Jámánì. Nígbà tó ku díẹ̀ kí ogun yẹn parí lọ́dún 1945, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀jò bọ́ǹbù sórí Berlin. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ju bọ́ǹbù sádùúgbò wa, ni gbogbo wa bá lọ forí pa mọ́ síbì kan. Síbẹ̀, ọkàn wa ò balẹ̀ torí náà a gba ìlú Erfurt lọ níbi tí wọ́n bí màmá mi sí.

Manfred Tonak pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ obìnrin lọ́dún 1950

Èmi àtàwọn òbí mi pẹ̀lú àbúrò mi obìnrin ní Jámánì, ní nǹkan bí ọdún 1950

Taratara ni màmá mi fi ń wá ẹ̀sìn tòótọ́. Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìwé táwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí kọ, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ti ẹ̀sìn kan bọ́ sí òmíì, àmọ́ kò tẹ́ wọn lọ́rùn. Lọ́dún 1948, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wàásù délé wa, màámi sì ní kí wọ́n wọlé. Bí màámi ṣe ń béèrè ìbéèrè kan ni wọ́n ń béèrè òmíì. Kò tó wákàtí kan lẹ́yìn náà ni màámi sọ fún èmi àti àbúrò mi obìnrin pé, “Mo ti rí òtítọ́!” Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni màámi, èmi àti àbúrò mi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé ní Erfurt.

Lọ́dún 1950, a kó pa dà sí Berlin, a sì ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Berlin-Kreuzberg. A tún kó lọ síbòmíì nílùú Berlin kan náà, a sì ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Berlin-Tempelhof. Nígbà tó yá, màámi ṣèrìbọmi, àmọ́ èmi ò ṣe ní tèmi. Ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tó fà á fún yín.

BÍ MO ṢE BORÍ ÌTÌJÚ TÍ MO SÌ ṢÈPINNU

Onítìjú èèyàn ni mí, ìyẹn ni ò jẹ́ kí n tètè tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Jèhófà. Kódà, odindi ọdún méjì ni mo fi lọ sóde ẹ̀rí láì wàásù fún ẹnì kankan. Àmọ́, nǹkan yí pa dà nígbà tí mo sún mọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n lo ìgboyà tí wọ́n sì fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Àwọn kan lára wọn ti fara da ìyà tó le gan-an ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Násì, àwọn kan sì tún lọ sẹ́wọ̀n ní East Germany. Àwọn yòókù fẹ̀mí ara wọn wewu bí wọ́n ṣe ń kó àwọn ìtẹ̀jáde wọ East Germany, torí pé tí ọwọ́ ìjọba bá tẹ̀ wọ́n pẹ́nrẹ́n, wọ́n rugi oyin. Àpẹẹrẹ wọn wú mi lórí gan-an. Torí náà mo ronú pé tí wọ́n bá lè fẹ̀mí ara wọn wewu torí Jèhófà àtàwọn ará, ṣé kò wá yẹ kí n sapá láti borí ìtìjú.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í borí ìtìjú mi nígbà tí mo kópa nínú àkànṣe ìwàásù kan tó wáyé lọ́dún 1955. Nínú lẹ́tà kan tí Arákùnrin Nathan Knorr kọ sínú ìwé Informant,a ó ṣèfilọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe àkànṣe ìwàásù kan tá ò tíì ṣe irú ẹ̀ rí. Ó ní tí gbogbo akéde bá lè kópa nínú ìwàásù náà, “oṣù yẹn ló máa lárinrin jù lọ látìgbà tá a ti ń wàásù láyé yìí.” Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn! Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, nígbà tó sì dọdún 1956, èmi, dádì mi àti àbúrò mi ṣèrìbọmi. Àmọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni mo tún dojú kọ ìpinnu míì.

Ó pẹ́ tí mo ti mọ̀ pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà gan-an ló yẹ kí n ṣe, àmọ́ ṣe ni mò ń fòní dòní fọ̀la dọ́la. Mo kọ́kọ́ pinnu pé màá lọ kọ́ṣẹ́ káràkátà àti bí wọ́n ṣe ń fọjà ránṣẹ́ sórílẹ̀-èdè míì. Lẹ́yìn ìyẹn, mo fẹ́ ṣiṣẹ́ díẹ̀ kí n lè mọwọ́ iṣẹ́ náà dáadáa kí n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Torí náà, lọ́dún 1961, mo gba iṣẹ́ kan nílùú Hamburg, níbi tí wọ́n ti máa ń kó ọjà wọlé jù nílẹ̀ Jámánì. Mo gbádùn iṣẹ́ náà débi pé ṣe ni mò ń sún iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí mo fẹ́ ṣe síwájú. Kí ni màá wá ṣe báyìí?

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó lo àwọn ará láti jẹ́ kí n rí i pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lohun tó dáa jù tí mo lè fayé mi ṣe. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àpẹẹrẹ wọn sì wú mi lórí gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, Arákùnrin Erich Mundt, táwọn náà lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ gbà mí níyànjú pé kí n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Wọ́n sọ fún mi pé nígbà táwọn wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àwọn ará tó gbẹ́kẹ̀ lé ara wọn bọ́hùn. Àmọ́ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá di ìgbàgbọ́ wọn mú, wọ́n sì wà lára àwọn tó ń gbé ìjọ Ọlọ́run ró báyìí.

Manfred Tonak lọ́dún 1963

Ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́dún 1963

Bákan náà, gbogbo ìgbà ni Arákùnrin Martin Poetzinger, tó pa dà di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń gba àwọn ará níyànjú. Ó máa ń sọ pé “Ìgboyà ni ohun tó ṣeyebíye jù tẹ́ ẹ lè ní.” Lẹ́yìn tí mo fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ yìí, mo fiṣẹ́ mi sílẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní June 1963. Ìpinnu tó dáa jù tí mo ṣe ní ìgbésí ayé mi nìyẹn! Lẹ́yìn oṣù méjì péré, àní kí n tó ríṣẹ́ míì rárá, wọ́n sọ mí di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Jèhófà bù kún mi kọjá ohun tí mo lérò, ṣe ni wọ́n pè mí sí kíláàsì kẹrìnlélógójì (44) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ MÁNIGBÀGBÉ TÍ MO KỌ́ NÍ GÍLÍÁDÌ

Ohun tó wọ̀ mí lọ́kàn jù nínú àwọn nǹkan tí mo kọ́ nílé ẹ̀kọ́ náà ni ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Nathan Knorr àti Arákùnrin Lyman Swingle sábà máa ń sọ pé: “Ẹ má jẹ́ kí iṣẹ́ àyànfúnni yín tètè sú yín, ẹ má sì kúrò níbẹ̀.” Wọ́n máa ń gbà wá níyànjú pé a ò gbọ́dọ̀ kúrò níbi tí wọ́n yàn wá sí tí kò bá tiẹ̀ rọrùn. Arákùnrin Knorr sọ pé: “Kí lo máa jẹ́ kó gbà ẹ́ lọ́kàn? Ṣé bí ibẹ̀ ṣe dọ̀tí ni àbí bí ìdun ṣe gba gbogbo ibẹ̀ kan àbí ipò òṣì tó wà nílùú yẹn? Àbí kẹ̀, ṣé àwọn igi tó dùn-ún wò, àwọn òdòdó tó rẹwà àtàwọn èèyàn tó ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sí ẹ lo máa gbájú mọ́? Ṣe ni kẹ́ ẹ gbìyànjú láti nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn náà!” Lọ́jọ́ kan tí Arákùnrin Swingle sọ ìdí táwọn kan fi pa iṣẹ́ wọn tì, ṣe ni omi lé ròrò sójú wọn, kódà wọn ò lè sọ̀rọ̀ mọ́. Wọ́n dá àsọyé náà dúró fúngbà díẹ̀ kí wọ́n tó máa bá ọ̀rọ̀ wọn lọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, mo wá pinnu pé mi ò ní jẹ́ kí ohunkóhun mú kí n já Jésù àtàwọn arákùnrin rẹ̀ kulẹ̀ láé.​—Mát. 25:40.

Manfred Tonak, Claude Lindsay àti Heinrich Dehnbostel nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì nílùú Lubumbashi, Congo, lọ́dún 1967

Èmi, Claude àti Heinrich rèé nígbà tá à ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì nílùú Lubumbashi, Kóńgò lọ́dún 1967

Lẹ́yìn tí wọ́n sọ ibi tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa lọ, àwọn arákùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì béèrè lọ́wọ́ mélòó kan lára wa pé ibo ni wọ́n rán wa lọ. Bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe ń sọ ibi tí wọ́n rán an lọ, bẹ́ẹ̀ làwọn arákùnrin yẹn ń sọ nǹkan tó dáa nípa ibẹ̀. Nígbà tí mo sọ fún wọn pé: “Kóńgò (Kinshasa) ni wọ́n rán mi lọ.” Wọ́n dákẹ́ lọ gbári, wọ́n wá ní: “Há, Kóńgò! Kí Jèhófà wà pẹ̀lú ẹ o!” Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, kò sóhun míì táwọn èèyàn ń gbọ́ nípa Kóńgò ju ọ̀rọ̀ ogun, bọ́ǹbù tí wọ́n ń jù àti bí wọ́n ṣe ń pààyàn nípakúpa. Àmọ́, gbogbo ìyẹn ò kó mi láyà jẹ, ṣe ni mo kàn ń ronú nípa ohun tí mo ti kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Kò pẹ́ lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ náà ní September 1967 ni èmi, Arákùnrin Heinrich Dehnbostel àti Arákùnrin Claude Lindsay lọ sí ìlú Kinshasa tó jẹ́ olú ìlú Kóńgò.

A TÚN KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ Í LẸ́NU IṢẸ́ MÍṢỌ́NNÁRÌ

Oṣù mẹ́ta la fi kọ́ èdè Faransé lẹ́yìn tá a dé Kinshasa. Lẹ́yìn náà, a wọkọ̀ òfúrufú lọ sílùú Lubumbashi tí wọ́n ń pè ní Elisabethville tẹ́lẹ̀. Ó wà nítòsí ibodè orílẹ̀-èdè Sáńbíà, lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Kóńgò, a sì ń gbé nílé àwọn míṣọ́nnárì tó wà nílùú náà.

Inú wa dùn pé àwa la kọ́kọ́ wàásù fún ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbé ní Lubumbashi torí kò tíì sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbẹ̀ nígbà yẹn. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, a ti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀ gan-an débi pé a kì í lè kárí wọn tán. A tún máa ń wàásù fáwọn ọlọ́pàá àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. Ọ̀pọ̀ wọn ló nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń tẹ́tí sí wa dáadáa. Èdè Swahili lọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbébẹ̀ ń sọ, torí náà, èmi àti Claude Lindsay kọ́ èdè náà. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni ètò Ọlọ́run rán wa lọ sí ìjọ tó ń sọ èdè Swahili.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a láwọn ìrírí tó ń gbéni ró níbẹ̀, àwọn ìṣòro kan tún yọjú. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń kojú àwọn sójà tó ti mutí yó tí wọ́n gbé ìbọn dání tàbí àwọn ọlọ́pàá oníjàngbọ̀n tó ń wá ẹ̀sùn sí wa lẹ́sẹ̀. Lọ́jọ́ kan, àwọn ọlọ́pàá tó pọ̀ gan-an já wọ ibi tá a ti ń ṣèpàdé nílé míṣọ́nnárì tá à ń gbé, wọ́n sì kó gbogbo wa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Nígbà tá a débẹ̀, wọ́n ní ká jókòó sílẹ̀ẹ́lẹ̀ títí di aago mẹ́wàá alẹ́, ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n dá wa sílẹ̀.

Lọ́dún 1969, wọ́n sọ mí di alábòójútó arìnrìn àjò. Tí n bá fẹ́ lọ bẹ ìjọ wò, mo máa ń gba inú igbó kìjikìji kọjá láàárín àwọn ewéko tó ga gan-an, ojú ọ̀nà náà sì kún fún ẹrọ̀fọ̀. Ní abúlé kan, abẹ́ bẹ́ẹ̀dì mi ni adìyẹ kan àtàwọn ọmọ rẹ̀ máa ń sùn. Mi ò jẹ́ gbàgbé bó ṣe máa ń jí mi láràárọ̀ tó bá ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde ní ìdájí. Mo máa ń gbádùn ọ̀rọ̀ Bíbélì témi àtàwọn ará jọ máa ń sọ tá a bá jókòó sídìí iná igi lálẹ́.

Ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tó le jù tá a kojú làwọn tí wọ́n ń díbọ́n pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn àmọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Kitawala.b Ṣe ni wọ́n yọ́ wọnú ìjọ, kódà àwọn kan lára wọn di alábòójútó nínú ìjọ. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ dénú ló tú àṣírí àwọn “àpáta tó fara pa mọ́” yẹn. (Júùdù 12) Nígbà tó yá, Jèhófà fọ ìjọ rẹ̀ mọ́, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló sì wá sínú òtítọ́ lẹ́yìn náà.

Lọ́dún 1971, wọ́n gbé mi lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Kinshasa. Oríṣiríṣi iṣẹ́ ni mò ń ṣe níbẹ̀, mo máa ń mojú tó lẹ́tà, ìtẹ̀jáde táwọn ìjọ ń béèrè àti ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn. Kóńgò tóbi gan-an, kò sì sí àwọn nǹkan amáyédẹrùn púpọ̀ níbẹ̀. Síbẹ̀, mo kọ́ bí mo ṣe lè mójú tó iṣẹ́ bàǹtàbanta tá a ní. Nígbà míì, àwọn lẹ́tà àtàwọn nǹkan tá à ń fi ránṣẹ́ sáwọn ìjọ máa ń pẹ́ kó tó dé ọ̀dọ̀ wọn. Lẹ́yìn tí ọkọ̀ òfúrufú bá ti gbé àwọn ìtẹ̀jáde àtàwọn lẹ́tà náà dé pápákọ̀, wọ́n á kó wọn sínú ọkọ̀ ojú omi táá gbé e lọ sáwọn ìjọ. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi náà ò ní lè lọ torí ewé òṣíbàtà tó kún ojú omi. Síbẹ̀, iṣẹ́ náà di ṣíṣe láìka àwọn ìṣòro yìí àtàwọn míì sí.

Ó máa ń yà mí lẹ́nu bí mo ṣe ń rí ohun ribiribi táwọn ará ń ṣe tá a bá fẹ́ ṣe àwọn àpéjọ agbègbè wa. Torí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sówó, wọ́n máa ń fi ilé ikán ṣe pèpéle, wọ́n á kó àwọn koríko tó gùn, wọ́n á sì hun wọ́n pa pọ̀ láti fi ṣe ògiri, wọ́n á tún ká àwọn kan pọ̀ láti fi ṣe ìjókòó fáwọn ará. Wọ́n máa ń fi ọparun kọ́lé, wọ́n á sì fi ẹní esùsú ṣe òrùlé tàbí tábìlì. Dípò kí wọ́n lo ìṣó, wọ́n máa ń ya èèpo igi láti fi so àwọn ọparun náà pọ̀. Gbogbo ìgbà táwọn ará wọ̀nyí bá ń ṣe àwọn nǹkan yẹn ló máa ń yà mí lẹ́nu torí gbogbo ara ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́, ọpọlọ wọn sì pé. Mi ò lè gbàgbé wọn láé. Ó ká mi lára nígbà tí wọ́n rán mi lọ sí orílẹ̀-èdè míì, mo ṣàárò wọn gan-an.

A SÌN NÍ KẸ́ŃYÀ

Lọ́dún 1974, wọ́n gbé mi lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Nairobi, Kẹ́ńyà. Iṣẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ wa gan-an torí pé ẹ̀ka ọ́fíìsì Kẹ́ńyà ló ń bójú tó orílẹ̀-èdè mẹ́wàá míì, àwọn kan lára wọn sì wà lábẹ́ ìfòfindè. Léraléra ni wọ́n ń rán mi lọ sáwọn orílẹ̀-èdè yẹn, pàápàá orílẹ̀-èdè Etiópíà, níbi tí wọ́n ti ń fimú àwọn ará wa dánrin, tí wọ́n sì ń ṣe àtakò tó lágbára sí wọn. Wọ́n fìyà jẹ àwọn kan, wọ́n sọ àwọn míì sẹ́wọ̀n, kódà wọ́n pa àwọn kan lára wọn. Síbẹ̀, wọ́n fara dà á, wọn ò sì bọ́hùn torí pé wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, wọ́n sì ṣe ara wọn lọ́kan.

Ìgbésí ayé mi tún lárinrin lọ́dún 1980 nígbà tí mo fẹ́ Gail Matheson. Ọmọ orílẹ̀-èdè Kánádà ni Gail, a sì jọ wà ní kíláàsì kan náà ní Gílíádì. Lẹ́yìn tá a parí tí oníkálukú sì gba ibi tí wọ́n rán an lọ, a máa ń kọ lẹ́tà síra wa. Bòlífíà ni wọ́n rán Gail lọ, àmọ́ lẹ́yìn ọdún méjìlá (12), a tún pàdé nílùú New York. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, a ṣègbéyàwó ní Kẹ́ńyà. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Gail torí pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ gan-an, ó sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ó ń tì mí lẹ́yìn, kò sì fọ̀rọ̀ mi ṣeré.

Lọ́dún 1986, wọ́n ní ká máa ṣiṣẹ́ arìnrìn àjò láfikún sí pé mo jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Púpọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tá a bẹ̀ wò wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Kẹ́ńyà ń bójú tó.

Manfred Tonak ń sọ àsọyé ní àpéjọ agbègbè ní Asmara (lórílẹ̀-èdè Eritrea), lọ́dún 1992

Mò ń sọ àsọyé ní àpéjọ agbègbè kan ní Asmara, lọ́dún 1992

Mo rántí bá a ṣe ṣètò àpéjọ agbègbè kan lọ́dún 1992 ní Asmara (ìyẹn lórílẹ̀-èdè Eritrea). Wọn ò tíì fòfin de iṣẹ́ wa nígbà yẹn. A wá ibi tá a lè lò títí, a ò rí. Níkẹyìn a rí abà kẹ́jẹ́bú kan, kódà ìta rẹ̀ fani mọ́ra ju inú rẹ̀ lọ. Lọ́jọ́ tá a fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àpéjọ náà, ẹnu yà mí nígbà tí mo rí iṣẹ́ táwọn ará ti ṣe sínú ilé náà, wọ́n sì ti mú kí ibẹ̀ ṣeé lò fún ìjọsìn. Ọ̀pọ̀ wọn ló mú aṣọ aláràbarà wá, wọ́n sì fi dárà débi pé a ò rí gbogbo ìdọ̀tí tó wà níbẹ̀ mọ́. A gbádùn àpéjọ náà gan-an, kódà àwọn 1,279 ló wá síbẹ̀.

Iṣẹ́ arìnrìn àjò ò dẹrùn rárá torí pé oríṣiríṣi ilé la máa ń dé sí. Nígbà míì a lè dé sí ilé kan tó jojú ní gbèsè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun, àmọ́ nígbà míì ilé tí wọ́n fi páànù kọ́ la máa ń dé sí. Nírú àwọn ilé onípáànù bẹ́ẹ̀, ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn máa ń jìnnà sílé gan-an, kódà ó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ẹsẹ̀ bàtà (100 m) lọ. Ibi yòówù ká ti sìn, ohun tá a gbádùn jù ni bá a ṣe máa ń lọ sóde ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn akéde tó nítara. Tí ètò Ọlọ́run bá gbé wa lọ síbòmíì, a máa ń ṣàárò àwọn ọ̀rẹ́ wa yìí gan-an.

JÈHÓFÀ BÙ KÚN IṢẸ́ WA NÍ ETIÓPÍÀ

Láàárín ọdún 1987 sí 1992, wọ́n fàyè gba iṣẹ́ wa lábẹ́ òfin láwọn orílẹ̀-èdè kan tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Kẹ́ńyà ń bójú tó. Ìyẹn wá mú kó ṣeé ṣe fáwọn orílẹ̀-èdè kan láti ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tiwọn. Lọ́dún 1993, wọ́n rán wa lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Addis Ababa, lórílẹ̀-èdè Etiópíà. Kó tó dìgbà yẹn, abẹ́lẹ̀ la ti ń ṣiṣẹ́ wa torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi fòfin de iṣẹ́ wa níbẹ̀.

Manfred àti Gail Tonak ní Etiópíà, lọ́dún 1996

Ìgbà tá a wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn àjò ní Etiópíà lọ́dún 1996

Jèhófà bù kún iṣẹ́ wa gan-an lórílẹ̀-èdè Etiópíà. Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ó kéré tán, ẹnì kan nínú márùn-ún ló ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé lọ́dọọdún láti ọdún 2012. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run ti dá àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì tún kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní ọgọ́fà (120). Lọ́dún 2004, ìdílé Bẹ́tẹ́lì kó lọ sí ọ́fíìsì tuntun, wọ́n sì tún kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ́fíìsì náà, ìbùkún ńlá nìyẹn sì jẹ́ fáwọn ará wa.

Ọjọ́ pẹ́ tá a ti wà pẹ̀lú àwọn ará ní Etiópíà, a sì mọyì wọn gan-an. A nífẹ̀ẹ́ wọn torí pé wọ́n máa ń fìfẹ́ hàn sí wa, wọ́n sì bójú tó wa dáadáa. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ara èmi àtìyàwó mi ò fi bẹ́ẹ̀ le, torí náà ètò Ọlọ́run ní ká pa dà sí ọ́fíìsì tó wà ní Central Europe. Wọ́n ń tọ́jú wa níbí gan-an, àmọ́ a ò lè gbàgbé àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà ní Etiópíà.

JÈHÓFÀ MÚ KÍ IṢẸ́ NÁÀ GBÒÒRÒ

A ti fojú ara wa rí bí Jèhófà ṣe mú kí iṣẹ́ náà gbòòrò sí i láwọn orílẹ̀-èdè yẹn. (1 Kọ́r. 3:​6, 9) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí mo kọ́kọ́ wàásù fáwọn èèyàn Rùwáńdà tó ń wa kùsà ní Kóńgò, kò sí akéde tó ń ròyìn ní Rùwáńdà. Àmọ́ ní báyìí, akéde tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000). Lọ́dún 1967, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) akéde péré ló wà ní Kóńgò. Ní báyìí, wọ́n ti tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgbọ̀n (230,000), yàtọ̀ síyẹn àwọn tó lé ní mílíọ̀nù kan ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2018. Àròpọ̀ àwọn akéde tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tí Kẹ́ńyà ń bójú tó tẹ́lẹ̀ ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún kan (100,000).

Manfred àti Gail Tonak báyìí

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ràn mí lọ́wọ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alákòókò kíkún lóhun tó lé ní àádọ́ta (50) ọdún sẹ́yìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì máa ń tijú díẹ̀díẹ̀, mo ti kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Àwọn nǹkan tí mo kọ́ nílẹ̀ Áfíríkà ti jẹ́ kí n túbọ̀ máa ní sùúrù, kí n sì ní ìtẹ́lọ́rùn. Kò sígbà témi àti Gail rántí àwọn ará yẹn tá ò kí í rántí bí wọ́n ṣe fara da ìṣòro tó le gan-an, bí wọ́n ṣe tọ́jú wa, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Mo dúpẹ́ mo tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà torí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó fi hàn sí wa. Ká sòótọ́, àwọn ìbùkún tí Jèhófà fún wa kọjá ohun tí mo lérò láyé mi.​—Sm. 37:4.

a Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, a sì ti wá fi Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni rọ́pò rẹ̀ báyìí.

b Lédè Swahili, “Kitawala” túmọ̀ sí “jọba lé, darí tàbí ṣàkóso.” Ìdí tí wọ́n fi dá ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ gba òmìnira kúrò lábẹ́ ìjọba Belgium. Àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ yìí máa ń gba ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n máa ń kà á, wọ́n ń pín in kiri, wọ́n sì ń yí ohun tó wà nínú rẹ̀ pa dà kí wọ́n lè fi ti ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n fi ń kọ́ni lẹ́yìn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ń lò ó láti gbé ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ìwà ìṣekúṣe wọn lárugẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́