ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 6/1 ojú ìwé 19-23
  • Jèhófà Ń hùwà Lọ́nà Ìdúróṣinṣin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Ń hùwà Lọ́nà Ìdúróṣinṣin
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbésí Ayé Tí Kò Ní Ète Nínú
  • Lílo Ìdúróṣinṣin Tuntun
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún ní England
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí A Mú Gbòòrò Sí I ní Áfíríkà
  • A Pa Dà sí Áfíríkà
  • Àyíká Ipò Tuntun ní England
  • Ibi Tá A Ti Ń Ṣiṣẹ́ Míṣọ́nnárì Di Ilé Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kárí Ayé fún Mi Lókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Jèhófà Bù Kún Mi Kọjá Ohun Tí Mo Lérò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ìpinnu Tó Tọ́ Yọrí Sí Ìbùkún Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 6/1 ojú ìwé 19-23

Jèhófà Ń hùwà Lọ́nà Ìdúróṣinṣin

GẸ́GẸ́ BÍ PETER PALLISER ṢE SỌ Ọ́

December 1985 ni. A ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bí a ṣe fẹ́ balẹ̀ sí pápákọ̀ òfuurufú ní Nairobi, Kenya. Bí a ṣe wọnú ìlú náà, àwọn ohun tí a ti rí tẹ́lẹ̀ àti ìró tí a ti gbọ́ rí mú kí a bẹ̀rẹ̀ sí rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá.

A WÁ sí Kenya láti gbádùn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùpàwàtítọ́mọ́” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní ọdún 12 sẹ́yìn, a fipá mú èmi àti aya mi láti fi Kenya sílẹ̀, nítorí fífòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. A ti gbé Bẹ́tẹ́lì ibẹ̀ rí, orúkọ tí a ń pe ẹ̀ka tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò. Ẹ wo ohun àgbàyanu tí ó gbádùn mọ́ni tí ó ń dúró dè wá nígbà tí a pa dà síbẹ̀ láti ṣèbẹ̀wò!

Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan, tí a ti mọ̀ nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún méjì, ni ó ń ṣèrànwọ́ láti gbọ́únjẹ ọ̀sán ní Bẹ́tẹ́lì. Ó kéré tán, mẹ́fà lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì jẹ́ àwọn tí a ti mọ̀ nígbà tí wọ́n ṣì jẹ́ ọmọdé. Ẹ wo bí ó ṣe jẹ́ ohun ìdùnnú tó láti rí i pé wọ́n ti di géńdé nísinsìnyí, pa pọ̀ pẹ̀lú ìdílé wọn, tí gbogbo wọ́n ṣì jẹ́ ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́! Ọlọ́run wa, Jèhófà, ti bójú tó wọn ní mímú ìlérí Bíbélì náà ṣẹ pé: “Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.” (Sámúẹ́lì Kejì 22:26, NW) Ẹ wo irú ìyàtọ̀ tí mo rí nínú ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé mi àti ìgbésí ayé tí ó lérè nínú tí àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ń gbé!

Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbésí Ayé Tí Kò Ní Ète Nínú

A bí mi ní Scarborough, England, ní August 14, 1918. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, màmá mi àti iyèkan mi obìnrin lọ sí Kánádà, nítorí náà mo gbé pẹ̀lú bàbá mi, màmá rẹ̀, àti ẹ̀gbọ́n bàbá mi obìnrin fún ọdún mẹ́ta tí ó tẹ̀ lé e. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún márùn-ún, Màmá jí mi gbé lọ sí Montreal, Kánádà. Ní ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà, ó rán mi pa dà lọ sí England láti gbé pẹ̀lú Bàbá àti láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́.

Oṣù mẹ́fà mẹ́fà ni màmá mi àti iyèkan mi tí ó jẹ́ obìnrin máa ń kọ lẹ́tà sí mi. Ní òpin lẹ́tà wọn, wọn yóò sọ èrò wọn jáde pé inú àwọn yóò dùn bí mo bá lè jẹ́ ọlọ̀tọ̀ rere, adúróṣinṣin sí Ọba àti orílẹ̀-èdè. Èsì mi dà bí èyí tí ó já wọn kulẹ̀, nítorí mo kọ̀wé pé, mo gbà gbọ́ pé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ogun lòdì. Síbẹ̀, nítorí tí n kò mọ ibi tí ọlọ́kọ̀ mi ń wà mí lọ, mo wulẹ̀ gbé ìgbésí ayé tí kò ní ète nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́langba.

Lẹ́yìn náà, ní July 1939, ọ̀sẹ̀ mẹ́fà kí Ogun Àgbáyé Kejì tó bẹ̀rẹ̀, a fipá mú mi wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Mo jẹ́ ọmọ 20 ọdún péré nígbà náà. Kò pẹ́ kò jìnnà, a rán ọ̀wọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí mo wà lọ sí àríwá ilẹ̀ Faransé. Nígbà tí ọkọ̀ òfuurufú ilẹ̀ Germany dojú ìjà kọ wá, àwa ọ̀dọ́mọkùnrin gbé ìbọn wa, a sì yìn ín lù wọ́n. Ìgbésí ayé kan tí ń kó jìnnìjìnnì báni ni a gbé nígbà yẹn. A kógun pa dà nígbà tí a rí àwọn ọmọ ogun Germany, mo sì wà lára àwọn tí a kó kúrò ní Dunkirk ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ June 1940. Mo ṣì rántí àwọn òkú ọ̀wọ́ ọmọ ogun kan látòkè délẹ̀ tí wọ́n sùn lọ rẹrẹ ní etíkun, ìrántí yẹn sì máa ń kó jìnnìjìnnì bá mi. Mo la ìṣẹ̀lẹ̀ búburú yẹn já, mo sì wọ ọkọ̀ òkun kékeré kan dé Harwich ìhà ìlà oòrùn England.

Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, ní March 1941, a rán mi lọ sí Íńdíà. Ibẹ̀ ni mo ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtún ohun èlò ìwakọ̀ òfuurufú ṣe. Lẹ́yìn lílo sáà díẹ̀ ní ilé ìwòsàn nítorí àrùn kan, a gbé mi lọ sí ẹ̀ka ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Delhi, olú ìlú Íńdíà. Níwọ̀n bí mo ti jìnnà sílé, tí ara mi kò sì dá, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ọjọ́ ọ̀la. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì ní pàtàkì nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tí a bá kú.

Lílo Ìdúróṣinṣin Tuntun

Bert Gale, tí òun pẹ̀lú jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bíi tèmi, ni alábàágbé mi ní Delhi. Lọ́jọ́ kan, ó wí pé, “Èṣù ni ó ni ìsìn,” ọ̀rọ̀ kan tí ó ru ọkàn ìfẹ́ mi sókè. Aya rẹ̀ ti di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì máa ń fi àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì ránṣẹ́ sí i látìgbàdégbà. Ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí, ìwé kékeré náà, Hope, gba àfiyèsí mi. Ìjíròrò rẹ̀ nípa ìrètí àjíǹde fún mi ni ojúlówó ìbàlẹ̀ ọkàn.

Nígbà kan ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1943, Bert bá Teddy Grubert sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ apá kan Gẹ̀ẹ́sì apá kan Íńdíà, ẹni tí kì í ṣe sójà, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wa ní ibùdó ológun. Sí ìyàlẹ́nu wa, a gbọ́ pé Ẹlẹ́rìí ni Teddy. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti fòfin de ìtẹ̀jáde Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní 1941, ó mú wa lọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Delhi. Nínú ìjọ kékeré yẹn, mo rí ojúlówó ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ọlọ́yàyà fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi. Basil Tsatos, Kristẹni arákùnrin àgbàlagbà kan láti Gíríìsì, fẹ́ràn mi jọjọ, ó sì dáhùn àwọn ìbéèrè mi. Ó pèsè ìdáhùn Bíbélì ṣíṣe kedere sí àwọn ìbéèrè nípa ìdí tí a fi ń darúgbó, tí a sì ń kú, nípa àjíǹde, àti ayé tuntun òdodo tí Ọlọ́run ṣèlérí.—Ìṣe 24:15; Róòmù 5:12; Pétérù Kejì 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.

Ìwé kékeré náà, Peace—Can It Last?, tí a tẹ̀ jáde ní 1942, gba àfiyèsí mi ní pàtàkì. Ó fi Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè hàn gẹ́gẹ́ bí “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀ dòdò.” (Ìṣípayá 17:3) Ní ṣíṣàyọlò orí 17, ẹsẹ 11, Ìṣípayá, ìwé kékeré náà wí pé: “A lè sọ nísinsìnyí pé, Ìmùlẹ̀ náà ‘ti wà tẹ́lẹ̀, kò sì sí i mọ́.’” Ní bíbá a nìṣó, ó wí pé: “Ẹgbẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé yóò dìde lẹ́ẹ̀kan sí i.” Ní 1945, ohun tí ó ju ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn nígbà tí a dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀!

Nígbà tí a fòfin de ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí, ó ṣeé ṣe fún mi láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ní. Nígbà tí páálí ìwé kékeré náà, Peace—Can It Last? dé, ìjọ ní kí n tọ́jú rẹ̀ pa mọ́. Ta ni yóò ronú pé ibùdó àwọn ológun ni ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fòfin dè yóò wà? Gbogbo ìgbà tí mo bá lọ sí ìpàdé ni mo máa ń mú ìwé kékeré díẹ̀ lọ́wọ́ láti fún àwọn ará. Mo tilẹ̀ máa ń bá wọn fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn pa mọ́, nígbà tí wọ́n bá ń fòyà pé wọ́n lè wá yẹ ilé wọn wò. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ní December 11, 1944, a gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí iṣẹ́ wọn.

A dán ìdúróṣinṣin mi sí àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni wò nígbà ayẹyẹ Kérésìmesì tí a ṣètò fún ọ̀wọ́ ọmọ ogun wa ní 1943. Mo kọ̀ láti kópa, níwọ̀n bí mo tí kẹ́kọ̀ọ́ pé kì í ṣe ìgbà òtútù December ni a bí Jésù àti pé àwọn Kristẹni ìjímìjí kò ṣe Kérésìmesì.—Fi wé Lúùkù 2:8-12.

Nígbà tí a ṣe Àpéjọ “Àwọn Akéde Tí Ó Wà Níṣọ̀kan” ní Jubbulpore (Jabalpur) December 27 sí 31, 1944, mo wà lára nǹkan bí 150 tí ó pésẹ̀. Ọkọ̀ ojú irin ni ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ náà wọ̀ wá láti Delhi, ìrìn àjò tí ó lé ní 600 kìlómítà. N kò lè gbàgbé ipò àgbàyanu tí ó wà ní gbàgede náà, níbi tí mo ti rí ètò àjọ Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́.

A fi àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ náà wọ̀ sí ilé gbígbé ní àwọn ilé ẹ̀kọ́, níbi tí a ti kọ orin Ìjọba, tí a sì gbádùn ìkẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni. Nígbà àpéjọpọ̀ yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ síí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ní gbangba, iṣẹ́ kan tí ó jẹ mí lógún títí di ìsinsìnyí.

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún ní England

Mo pa dà sí England ní 1946, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ Ìjọ Wolverton. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé akéde Ìjọba mẹ́wàá péré ni a ní, èyí mú kí ọkàn mi balẹ̀, mo sì ní irú ìtẹ́lọ́rùn kan náà tí mo ní láàárín àwọn arákùnrin mi ní Íńdíà. Vera Clifton jẹ́ ẹni tí gbogbo ènìyàn mọ̀ nínú ìjọ, nítorí ó jẹ́ ojúlówó ọlọ́yàyà ẹ̀dá. Nígbà tí mo mọ̀ pé ó ní irú ìfẹ́ ọkàn kan náà bíi tèmi láti di aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, a ṣègbéyàwó, ní May 24, 1947. Mo tún ọkọ̀ onílé lẹ́yìn, tàbí onílé àgbérìn kan ṣe, ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, a rí iṣẹ́ àyànfúnni wa àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà gbà láti ṣiṣẹ́ ní ìgbèríko Huntingdon.

Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, a óò ta lé kẹ̀kẹ́ ológeere wa ní òwúrọ̀ kùtù láti lọ sí ìgbèríko. Odindi ọjọ́ ni a fi ń wàásù, àfi àkókò díẹ̀ tí a ń lò láti fi sáré jẹ oúnjẹ ọ̀sán. Láìka bí ẹ̀fúùfù ti lè le tó tàbí bí òjò ti lè pọ̀ tó nígbà tí a bá ń gun kẹ̀kẹ́ wa pa dà sílé sí, inú wa máa ń dùn, a sì máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ Olúwa.

Bí àkókò ti ń lọ, a yán hànhàn láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i àti láti ṣàjọpín “ìhìn rere” náà pẹ̀lú àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè míràn. (Mátíù 24:14) Nítorí náà, a kọ̀wé béèrè fún lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gilead ti àwọn míṣọ́nnárì ní Gúúsù Lansing, New York, U.S.A. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, a gbà wá sí kíláàsì kẹrìndínlọ́gbọ̀n ti ilé ẹ̀kọ́ Gilead ní February 1956.

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí A Mú Gbòòrò Sí I ní Áfíríkà

Àríwá Rhodesia (tí a mọ̀ sí Zambia nísinsìnyí) ní Áfíríkà ni ibi iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí a yàn fún wa. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí a dé, a pè wá láti wá ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè náà. Gẹ́gẹ́ bí ara iṣẹ́ mi ní Bẹ́tẹ́lì, mo bójú tó gbígba lẹ́tà àti kíkọ lẹ́tà sí Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Ní 1956, Ẹlẹ́rìí mẹ́rin péré ni ó wà ní Kenya—ọ̀kan nínú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí ó wà ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà—nígbà tí Ẹlẹ́rìí tí ó lé ní 24,000 sì ń bẹ ní Àríwá Rhodesia. Èmi àti Vera bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa bí yóò ti dára tó láti ṣiṣẹ́ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ sí i.

Lẹ́yìn náà, láìròtẹ́lẹ̀, mo rí ìkésíni mìíràn gbà láti wá sí ilé ẹ̀kọ́ Gilead, lọ́tẹ̀ yí fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù mẹ́wàá fún àwọn alábòójútó. Ní fífi Vera sílẹ̀ ní Àríwá Rhodesia, mo rìnrìn àjò lọ sí New York City, níbi tí Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead wà nígbà yẹn. Lẹ́yìn tí mo parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà ní November 1962, a yàn mí sí Kenya láti dá ọ́fíìsì ẹ̀ka kan sílẹ̀ níbẹ̀. Ní àkókò yí, Kenya ti ní Ẹlẹ́rìí tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún.

Nígbà tí mo bá ń pa dà sí Àríwá Rhodesia láti lọ bá Vera, a retí pé kí n fẹsẹ̀ kan yà ní Nairobi, Kenya. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo débẹ̀, Bill Nisbet, akẹ́kọ̀ọ́yege kan ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead ti kíláàsì kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, pàdé mi pẹ̀lú ìròyìn náà pé àǹfààní wà láti rí ìwé àṣẹ gbà láti wọ Kenya lójú ẹsẹ̀. A tọ àwọn aláṣẹ àtiwọ̀lú lọ, láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, mo rí ìwé àṣẹ ọlọ́dún márùn-ún gbà. Nítorí náà, n kò wulẹ̀ pa dà sí Àríwá Rhodesia mọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, Vera ni ó wá bá mi ní Nairobi.

Lẹ́yìn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí a ṣètò fún wa láti kọ́ èdè Swahili, a dara pọ̀ mọ́ ìjọ kékeré ti Nairobi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Nígbà míràn, lẹ́yìn tí a bá ti ka ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa tán ní èdè Swahili, onílé yóò pariwo pé, “N kò gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì!” Láìka èyí sí, a forí tì í, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ a sì borí ìṣòro èdè.

Ìpínlẹ̀ wa ní àwọn ilé ńláǹlà tí wọ́n ní orúkọ inú Bíbélì bíi Jerúsálẹ́mù àti Jẹ́ríkò. Kíákíá ni wọ́n ń mú ọkàn ìfẹ́ dàgbà, ọ̀pọ̀ akéde Ìjọba tuntun sì ti wá láti àgbègbè wọ̀nyẹn. Ẹ wo irú ipa tí ó pẹtẹrí tí òtítọ́ Bíbélì ní lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí! Ìmọ̀lára ẹ̀yà tèmi lọ̀gá pòórá bí ìdúróṣinṣin sí Ìjọba náà ti ń mú ìṣọ̀kan wá sáàárín àwọn ènìyàn Jèhófà. Àní ìgbéyàwó láàárín ẹ̀yà kan sí ìkejì pàápàá wáyé, ohun kan tí ó ṣàjèjì láàárín àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.

Àwọn olùpòkìkí Ìjọba tuntun fi ìtara tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Fún àpẹẹrẹ, Samson hára gàgà pé kí òtítọ́ Bíbélì wọ abúlé rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ ṣáá pé kí a rán àwọn aṣáájú ọ̀nà síbẹ̀. Ní tòótọ́, ó kọ́ iyàrá díẹ̀ mọ́ ilé rẹ̀ ní ẹkùn Ukambani láti pèsè ilé gbígbé fún wọn. Kò pẹ́ kò jìnnà, a dá ìjọ tuntun ti àwọn olùpòkìkí Ìjọba sílẹ̀ níbẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń bẹ àwọn ará wa ní orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn Áfíríkà náà, Etiópíà, wò. Ní ìpíndọ́gba, wọ́n ń lo ohun tí ó lé ní 20 wákàtí lóṣooṣù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, láìka ìfisẹ́wọ̀n, ìluni, àti ìṣọ́ni lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ ìgbà gbogbo sí. Nígbà kan, àwọn arákùnrin àti arábìnrin ará Etiópíà tí wọ́n kún inú bọ́ọ̀sì méjì rìnrìn àjò fún ọ̀sẹ̀ kan, ní líla àwọn òkè eléwu kọjá, láti pésẹ̀ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè kan ní Kenya. Ìtìlẹ́yìn wọn ní ṣíṣètò fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìjọba láti wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní ilẹ̀ wọn pẹtẹrí. Àwa tí a wà ní Kenya láyọ̀ láti máa fi ìwé ránṣẹ́ sí wọn.

A fòfin de iṣẹ́ wa ní Kenya ní 1973, a sì fipá mú àwọn míṣọ́nnárì láti fìlú sílẹ̀. Nígbà yẹn, a ti ní Ẹlẹ́rìí tí ó lé ní 1,200 ní Kenya, ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí sì wà ní pápákọ̀ òfuurufú láti kí wa pé ó dìgbóṣe lọ́nà kan tí a kò ní lè gbàgbé láé. Wíwà tí wọ́n wà níbẹ̀ sún ẹnì kan tí a jọ ń rìnrìn àjò láti béèrè bóyá gbajúgbajà kan ni wá. Èmi àti Vera pa dà sí England, a sì yanṣẹ́ fún wa níbẹ̀, ṣùgbọ́n a yán hànhàn láti pa dà sí Áfíríkà.

A Pa Dà sí Áfíríkà

Nípa bẹ́ẹ̀, ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, a rí iṣẹ́ àyànfúnni wa tuntun gbà, láti lọ sí Bẹ́tẹ́lì tí ó wà ní Accra, olú ìlú orílẹ̀-èdè ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà náà, Gánà. Níhìn-ín, ọ̀kan nínú iṣẹ́ tí a yàn fún mi mú kí n fojú ara mi rí ìnira tí àwọn ará wa dojú kọ. Bí mo ṣe ń bójú tó ríra oúnjẹ àti àwọn ohun èlò fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì, ó máa ń yà mí lẹ́nu láti rí bí oúnjẹ ti wọ́n tó. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹnì kan kò ní lè ra àwọn ohun tí ó nílò. Àìtó epo mọ́tò àti ọ̀wọ́n gógó ẹ̀yà ara ọkọ̀ tún ń dá kún ìṣòro náà.

Mo wá kọ́ ìjẹ́pàtàkì níní sùúrù, ohun kan tí àwọn ará wa ní Gánà ti mú dàgbà. Ó fúnni níṣìírí gan-an láti rí pé wọn kò sọ ẹ̀mí ọ̀yàyà wọn nù bí wọ́n ṣe kọ àdánwò láti fi ọ̀nà gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kó ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé jọ. Nítorí èyí, àwọn ènìyàn Jèhófà ní Gánà di ẹni tí a mọ̀ bí ẹní mowó fún ìwà àìlábòsí wọn, wọ́n sì wá gbádùn orúkọ rere lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ọba.

Ṣùgbọ́n, láìka àìní ohun ìní ti ara sí, aásìkí nípa tẹ̀mí ń pọ̀ sí i. Jákèjádò ilẹ̀ náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ilé ni a ti lè rí àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì wa. A sì rí i tí iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba gbèrú ní Gánà láti orí 17,156 ní 1973 nígbà tí a dé, sí iye tí ó lé ní 23,000 ní 1981. Ní ọdún yẹn, àrùn jẹjẹrẹ awọ ara tí ó dé bá mi, tí kò sí àní-àní pé oòrùn Íńdíà àti Áfíríkà tí ó ti pa mí púpọ̀ dá kún un, mú kí ó di dandan fún wa láti fi Gánà sílẹ̀, kí a sì pa dà lọ sí England fún ìtọ́jú déédéé.

Àyíká Ipò Tuntun ní England

Fún mi, pípadà tí a pa dà jẹ́ ṣíṣe àtúnṣebọ̀sípò ńláǹlà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi. Ó ti mọ́ mi lára láti máa bá àwọn tí wọ́n ní ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run àti Bíbélì sọ̀rọ̀ ní fàlàlà. Ṣùgbọ́n ní London, ó ṣọ̀wọ́n láti bá irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ pàdé. Ìforítì àwọn ará ní Britain yà mí lẹ́nu. Èyí ti mú kí n túbọ̀ rí ìjẹ́pàtàkì mímú ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò dàgbà fún àwọn tí ‘a bó láwọ tí a sì fọ́n ká’ nípa tẹ̀mí.—Mátíù 9:36.

Lẹ́yìn tí a ti Áfíríkà dé, èmi àti Vera jùmọ̀ ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti London títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní September 1991, ni ẹni ọdún 73. Kò rọrùn rárá láti pàdánù irú olùṣòtítọ́ alábàákẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀, tí ó ti ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú mi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ikú rẹ̀ gbò mí gidigidi. Ṣùgbọ́n mo láyọ̀ fún ìtìlẹ́yìn àtàtà tí mo ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ ìdílé Bẹ́tẹ́lì wa ti ó ní nǹkan bí 250 mẹ́ńbà.

Mo kà á sí àǹfààní ńláǹlà láti nírìírí ìtẹ̀síwájú ètò àjọ Jèhófà àti láti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń sọ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún di ọ̀nà ìgbésí ayé wọn. Mo lè fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ pé kò sí ọ̀nà ìgbésí ayé mìíràn tí ó dára ju èyí lọ, nítorí “Jèhófà . . . kì yóò . . . fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.”—Orin Dáfídì 37:28, NW.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

A ṣe aṣáájú ọ̀nà ní England láti 1947 sí 1955

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìgbà àkọ́kọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbà àpéjọpọ̀ kan ní Íńdíà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Nígbà tí a jẹ́ míṣọ́nnárì ní Àríwá Rhodesia

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ní 1985, àwa pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa tí a kò fojú kan fún ọdún 12

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́