DAYRELL SHARP | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Jèhófà Ni Ò Jẹ́ Ká Fà Sẹ́yìn
Nígbà tí mo gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́dún 1956, àwọn kan nínú ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé, “Bóyá lá lè ṣe é fóṣù kan.” Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ni mí nígbà yẹn. Ọdún mẹ́rin ṣáájú ìgbà yẹn sì ni mo ṣèrìbọmi torí pé arákùnrin kan tí mo fẹ́ràn ní kí n ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn alàgbà kì í ṣe àtúnyẹ̀wò fún ẹni tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ó kúnjú ìwọ̀n.
Tí ẹ̀yin náà bá mọ irú ẹni tí mo jẹ́ tẹ́lẹ̀, ẹ máa gbà pẹ̀lú àwọn ará yẹn pé mi ò ní lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ìdí ni pé mi ò kì í ṣe ẹni tẹ̀mí, mi ò nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù, kódà mo máa ń gbàdúrà kí òjò rọ̀ láwọn ọjọ́ Sunday kí n má bàa lọ sóde ẹ̀rí. Tí mo bá sì jàjà lọ, ṣe ni mo kàn máa ń fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn, mi ò fi Bíbélì bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ rí. Kódà, màmá mí máa ń ra nǹkan fún mi kí n tó gbà láti ṣiṣẹ́ Bíbélì kíkà nínú ìjọ. Yàtọ̀ síyẹn, kì í wù mí láti kẹ́kọ̀ọ́, mi ò sì ní àfojúsùn tẹ̀mí kankan.
Àpéjọ agbègbè kan tá a ṣe lọ́dún yẹn ní Cardiff, nílùú Wales ló yí ìgbésí ayé mi pa dà. Ọ̀kan lára àwọn tó sàsọyé ní àpéjọ yẹn béèrè àwọn ìbéèrè kan tó ń múni ronú jinlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó béèrè pé: “Ṣé o ti ya ara ẹ sí mímọ́, ṣé o sì ti ṣèrìbọmi?” Mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’ Ó tún ní, “Ṣé o ti ṣèlérí fún Jèhófà pé wàá fi gbogbo ọkàn ẹ, gbogbo èrò ẹ àti gbogbo okun ẹ sìn ín?” Mo tún sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’ Ó tún béèrè pé, “Ṣé o ní àìlera àbí ojúṣe kan nínú ìdílé tí ò ní jẹ́ kó o lè ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà?” Mo dáhùn pé, ‘Rárá.’ Ó tún sọ pé, “Ṣe ohunkóhun wà tó ń dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà?” Mo dáhùn pé, ‘Rárá.’ Ni alásọyé náà bá sọ pé, “Tí ìdáhùn ẹ sí ìbéèrè tó kẹ́yìn bá jẹ́ rárá, kí wá nìdí tó ò tíì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà?”
Ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ṣí aṣọ lójú mi. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé: ‘Irú ìgbésí ayé wo ni mò ń gbé yìí, mi ò mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ mi ṣẹ, mí ò tún fi gbogbo ọkàn mi sin Jèhófà.’ Mo mọ̀ pé tí mo bá fẹ́ kí Jèhófà mú ẹ̀jẹ́ tó ṣe fún mi ṣẹ, èmi náà gbọ́dọ̀ mú ìlérí tí mo ṣe fún un ṣẹ. Torí náà, nígbà tó di October 1956, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
Lọ́dún 1959, ètò Ọlọ́run ní kí n lọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìlú Aberdeen
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìjọ kan tó ní akéde mọ́kàndínlógún (19). Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni mo máa ń sọ àsọyé látìgbà tí mo ti débẹ̀. Àwọn ará mú sùúrù fún mi, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè sunwọ̀n sí í lórí bí mo ṣe ń sọ àsọyé. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1959, ètò Ọlọ́run sọ mí di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì rán mi lọ sí ìlú Aberdeen, ní àríwá orílẹ̀-èdè Scotland. Lẹ́yìn oṣù mélòó kan, wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú London. Mo sì láǹfààní láti ṣiṣẹ́ ní ilé ìtẹ̀wé fún ọdún méje tí mo fi sìn níbẹ̀.
Mo gbádùn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì àmọ́ ó tún wù mí kí n lọ máa wàásù ní pápá. Ọ̀dọ́ ni mí, ìlera mi dáa, ó sì wù mí kí Jèhófà lò mí níbikíbi tó bá wù ú. Torí náà ní April 1965, mo gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì kí wọ́n lè dá mi lẹ́kọ̀ọ́ láti di míṣọ́nnárì.
Lọ́dún yẹn, èmi àti ẹni tá a jọ ń gbé yàrá pinnu láti lọ gbádùn àpéjọ agbègbè kan nílùú Berlin, lórílẹ̀-èdè Jámánì, ká sì tún fi àǹfààní yẹn wo ògiri Berlin tí wọ́n kọ́ lọ́dún mélòó kan ṣáájú.
Lọ́jọ́ kan nígbà àpéjọ yẹn, a lọ sóde ẹ̀rí, wọ́n sì ní kí èmi àti arábìnrin kan tó ń jẹ́ Susanne Bandrock jọ ṣiṣẹ́. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, èmi àti ẹ̀ ṣègbéyàwó lọ́dún 1966. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ètò Ọlọ́run pè wá sí kíláàsì kẹtàdínláàádọ́ta (47) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Inú wa dùn kọjá sísọ. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, oṣù márùn-ún ilé ẹ̀kọ́ náà parí, wọ́n sì rán wa lọ sí orílẹ̀-èdè Zaire, tí wọ́n ń pè ní Democratic Republic of Congo báyìí. A ò fọkàn sí i pé orílẹ̀-èdè yẹn ni wọ́n máa rán wa lọ, a ò sì mọ nǹkan kan nípa orílẹ̀-èdè náà. Torí náà, ó ń ṣe wá bíi ká má lọ, àmọ́ a gba iṣẹ́ náà, a sì fi ara wa lé Jèhófà lọ́wọ́.
Lọ́dún 1969 èmi àti Susanne kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
Lẹ́yìn tá a fi ọ̀pọ̀ wákàtí rìnrìn àjò, tá à ń ti inú ọkọ̀ òfúrufú kan bọ́ sí òmíì, a dé ìlú kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Kolwezi. Ó yà wá lẹ́nu pé kò sẹ́nì kankan tó wá pàdé wa. Ìgbà tó yá la wá mọ̀ pé ọjọ́ méjì lẹ́yìn tá a dé làwọn ará tó rí lẹ́tà tí ètò Ọlọ́run kọ sí wọn pé à ń bọ̀. Ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ ní pápákọ̀ òfúrufú náà sún mọ́ wa, ó sì sọ nǹkan kan ní èdè Faransé, àmọ́ ohun tó sọ ò yé wa torí pé a ò tíì gbọ́ èdè náà. Ni obìnrin kan tó wà ní iwájú wa bá sọ fún wa pé, “Wọ́n fẹ́ fi ọlọ́pàá mú yín ni o.”
Ọlọ́pàá tó mú wa fipá mú ọkùnrin kan pé kó fi mọ́tò ẹ̀ kó wa, mọ́tò náà kéré, èèyàn méjì ló sì lè gbà. Síbẹ̀ èmi, ìyàwó mi, ọlọ́pàá náà àti ẹni tó ni ọkọ̀ fún ara wa mọ́ inú mọ́tò náà. Bá a ṣe ń lọ bẹ́ẹ̀ lọkọ̀ náà ń já sí kòtò tí bọ́nẹ́ẹ̀tì ẹ̀ ń ṣí, tó ń pa dé lẹ́ẹ̀mẹwàá, ṣe ni gbogbo ẹ̀ dà bíi fíìmù lójú mi.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ ibi tí ilé àwọn míṣọ́nnárì wà, ọlọ́pàá yẹn wà wá débẹ̀ torí pé ó mọbẹ̀. Nígbà tá a débẹ̀, ṣe la bá géètì ní títì pa torí gbogbo àwọn míṣọ́nnárì tó wà níbẹ̀ ló ti rìnrìn àjò. Àwọn kan lọ fún àpéjọ àgbáyé, àwọn míì sì gba àkókò ìsinmi. Oòrùn pa fóò sí wa lára níbi tá a dúró sí, a ò sì mọ ohun tá a máa ṣe. Ibẹ̀ la wà tí arákùnrin kan tó ń gbé àdúgbò yẹn fi dé. Bó ṣe rí wa báyìí ló rẹ́rìn-ín músẹ́, ìyẹn sì jẹ́ kára tù wá. Arákùnrin náà mọ ọlọ́pàá tó mú wa, ó sì lọ bá a sọ̀rọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́pàá náà fẹ́ gbowó lọ́wọ́ wa tẹ́lẹ̀, ṣe ló fi wá sílẹ̀ tó sì bá tiẹ̀ lọ. Nígbà tó yá, a ríbi wọlé, ọkàn wa sì balẹ̀.
Èmi àti arákùnrin Nathan H. Knorr dúró síwájú ilé àwọn míṣọ́nnárì nílùú Zaire nígbà tí wọ́n ṣèbẹ̀wò lọ́dún 1971
Àkókò Kọ́ Nìyí Láti Fà Sẹ́yìn
Kò pẹ́ tá a fi rí i pé àárín àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́, tára wọn yá mọ́ọ̀yàn tí wọ́n sì ti fara da ọ̀pọ̀ nǹkan la wà. Ó dunni gan-an pé láti nǹkan bí ọdún mẹ́wàá (10) ṣáájú ìgbà yẹn ni rògbòdìyàn àti ọ̀tẹ̀ ti mú kí nǹkan nira gan-an lórílẹ̀-èdè yẹn. Nígbà tó sì di ọdún 1971, ìjọba fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn wá mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bá a ṣe máa ṣiṣẹ́ wa.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ fúngun mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kí wọ́n sì máa lo báàjì àyà táwọn olóṣèlú ń lò, àwọn ará ò bẹ̀rù kódà ìwọ̀nba díẹ̀ nínú wọn ló juwọ́ sílẹ̀. Ẹni tí ò bá wọ báàjì àyà ò ní jàǹfààní nínú ètò tí ìjọba ṣe, yàtọ̀ síyẹn àwọn sójà àtàwọn ọlọ́pàá máa fojú onítọ̀hún rí màbo. Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn ará wa, wọ́n sì tún lé àwọn ọmọ wọn kúrò ní ilé ìwé. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn ará ni wọ́n jù sẹ́wọ̀n. Nǹkan ò rọrùn rárá fáwọn ará wa lásìkò yìí. Síbẹ̀, àwọn ará ń bá a lọ láti máa fìgboyà wàásù.
A Nílò Ìfaradà
Láwọn ọdún yẹn, èmi àtìyàwó mi ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká àti alábòójútó agbègbè, a sì lo ọ̀pọ̀ àkókò láti bẹ àwọn ìjọ tó wà ní ìgbèríko ìlú náà wò. Ìgbésí ayé láwọn abúlé máa ń ní ìgbà dídùn àti kíkan. Àwọn ilé tá à ń gbé kéré débi pé ó máa ń nira gan-an láti yíra pa dà tá a bá sùn. Mi ò lè ka iye ìgbà tí mo forí gbá igi ẹnu ọ̀nà tí mo bá fẹ́ wọlé tàbí jáde. Omi odò la fi ń wẹ̀, àbẹ́là la fi ń kàwé lálẹ́, èédú la sì fi máa ń dáná. Àmọ́ ìgbésí ayé míṣọ́nnárì tòótọ́ la ka àwọn nǹkan yìí sí. A sì ń gbádùn ẹ̀ torí ohun tá a pinnu láti fayé wa ṣe nìyẹn.
Bá a ṣe ń wà pẹ̀lú àwọn ará wa ní ìgbèríko yìí ti kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan pé, ohun tá a nílò ò ju oúnjẹ, omi, aṣọ àti ibùgbé. (1 Tímótì 6:8) Àfikún làwọn ohun tó kù jẹ́. A ò lè gbàgbé àwọn ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́ yìí láé.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò dojú kọ irú àdánwò tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kojú, àwọn nǹkan tá a kojú lẹ́nu ìrìn àjò wa nígbà míì máa ń jẹ́ ká mọ bí ìgbàgbọ́ wa ṣe lágbára tó. Àwọn ọ̀nà tí ò dáa tó rí gbágungbàgun la máa ń gbà tá a bá ń lọ láti ibì kan sí òmíì, ṣe ni mọ́tò wa máa ń gbọ̀n tá a bá ń lọ torí pé òkúta pọ̀ lójú ọ̀nà yẹn. Lásìkò òjò, ńṣe ni ọkọ̀ wa máa ń rì sínú ẹrọ̀fọ̀. Tó bá sì jẹ́ àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn, ṣe ni àwọn iyẹ̀pẹ̀ tó wà lójú ọ̀nà kì í jẹ́ kí mọ́tò wa lè rìn dáadáa. Ó tiẹ̀ ní ọjọ́ kan tó jẹ́ pé ìgbà méjìlá ni ọkọ̀ wa rì, ìrìn tá a sì rìn ní gbogbo ọjọ́ yẹn ò ju àádọ́rin (70) kìlómítà péré.
Lára àwọn ìṣòro tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa ni ọ̀nà tí ò dáa
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìgbà tá a dojú kọ ipò tó le ní ìgbèríko yẹn la sún mọ́ Jèhófà jù lọ nígbèésí ayé wa. A ti wá rí i pé bá ò tiẹ̀ lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro wa, Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ipò yòówù tá a bá wà ká sì láyọ̀. Ohun kan nípa ìyàwó mi ni pé, kì í ṣe ẹni tó lẹ́mìí wàhálà, ó sì fẹ́ràn kó máa wà nílé. Síbẹ̀, ní gbogbo àkókò tá a fi kojú àwọn ìṣòro yẹn, kì í ráhùn tàbí kó máa ṣàríwísí. A kì í kábàámọ̀ tá a bá ń ronú nípa àwọn àkókò yẹn, dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni inú wa máa ń dùn, tá a sì máa ń rántí àwọn ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́.
Láwọn ọdún tá a fi wà lórílẹ̀-èdè Zaire, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn aláṣẹ mú mi. Ìgbà kan wà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé èmi náà wà lára àwọn fàyàwọ́ tó ń ra dáyámọ́ǹdì tó sì ń tà á lọ́nà tí ò bófin mu. Ẹ̀rù bà wá lóòótọ́, àmọ́ a rán ara wa létí pé tí Jèhófà bá fẹ́ ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó máa ràn wá lọ́wọ́. Ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn.
À Ń Tẹ̀ Síwájú Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
Lọ́dún 1981, ètò Ọlọ́run ní ká wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Kinshasa. Ọdún kan ṣáájú ìgbà yẹn la forúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Àwọn ará ra ilẹ̀ kan kí wọ́n lè fi kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì míì tó tóbi. Àmọ́ ní March 1986, ohun kan ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Ṣe ni ààrẹ orílẹ̀-èdè náà fọwọ́ sí àṣẹ kan pé kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyẹn mú ká dá iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró, kò sì pẹ́ sígbà yẹn ni ọ̀pọ̀ àwọn míṣọ́nnárì fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀.
A sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Zaire fún ọdún mélòó kan
Ó ṣeé ṣe fún wa láti dúró fúngbà díẹ̀. A sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa wàásù nìṣó bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ń ṣọ́ wa lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo bá a ṣe ṣọ́ra tó, wọ́n mú mi níbi tí mo ti ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n wá fi mí sínú yàrá kan tó dà bí àjà ilẹ̀ níbi tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pọ̀ sí. Torí pé ara ihò kékeré kan tó wà lára ògiri ni atẹ́gùn ń gbà wọlé, ibẹ̀ gbóná, ó ń rùn, ó ṣókùnkùn, ó sì ṣòro fún wa láti mí. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan mú mi lọ sọ́dọ̀ ẹlẹ́wọ̀n míì tó jẹ́ ọ̀gá wọn, ó jágbe mọ́ mi pé, “Kọrin orílẹ̀-èdè wa!” Mo sọ fún un pé, “Mi ò mọ̀ ọ́n.” Wọ́n sọ pé, “Kọrin orílẹ̀-èdè ẹ nígbà yẹn!” Mo tún sọ fún wọn pé, “Mi ò mọ̀ ọ́n.” Ó wá pàṣẹ fún mi pé kí n fẹ̀yìn ti ògiri fún nǹkan bí ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta (45). Nígbà tó yá, àwọn arákùnrin kan ṣètò bí wọ́n ṣe dá mi sílẹ̀.
Àwa rèé lẹ́yìn tá a dé ẹ̀ka ọ́fíìsì Sáńbíà lọ́dún 1987
Kò jọ bíi pé nǹkan máa yàtọ̀ lórílẹ̀-èdè yẹn, torí náà ètò Ọlọ́run rán wa lọ sórílẹ̀-èdè Sáńbíà. Nígbà tá a kúrò lórílẹ̀-èdè Zaire, ara tù wá àmọ́ inú wa ò dùn. A bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa odindi ọdún méjìdínlógún (18) tá a fi gbádùn iṣẹ́ wa pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan nira láwọn ìgbà míì, a rí i pé Jèhófà bù kún iṣẹ́ wa níbẹ̀. Gbogbo ìgbà la máa ń rí ọwọ́ Jèhófà láyé wa. A kọ́ èdè Swahili àti Faransé, ìyàwó mi sì gbọ́ èdè Lingala díẹ̀. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa méso jáde gan-an, ìdí ni pé àádóje (130) èèyàn la ràn lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi. Ọkàn wa balẹ̀ gan-an pé iṣẹ́ tá a ṣe máa ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́jọ́ iwájú. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ọ̀pọ̀ èèyàn wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Lọ́dún 1993, ilé ẹjọ́ gíga jù lọ fagi lé ìfòfindè ọdún 1986. Ní báyìí, ó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé ogójì (240,000) akéde ìjọba Ọlọ́run tó wà lórílẹ̀-èdè Congo.
Ní gbogbo àkókò tá a lò ní Sáńbíà, a rí i bí wọ́n ṣe kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun àti bí wọ́n ṣe mú kó gbòòrò sí i. Ní báyìí àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Sáńbíà ti ju ìlọ́po mẹ́ta iye àwọn tó wà níbẹ̀ nígbà tá a dé lọ́dún 1987.
Àwòrán ẹ̀ka ọ́fíìsì Sáńbíà látòkè
Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n sọ pé kò lè lo oṣù kan lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún? Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà àti ìtìlẹ́yìn ìyàwó mi ọ̀wọ́n, mo ti lo ọdún márùndínláàádọ́rin (65) lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, mo sì ti rí i pé ẹni rere ni Jèhófà!—Sáàmù 34:8.
Ohun kan ni pé a kì í ṣẹni tó ṣàrà ọ̀tọ̀; síbẹ̀ a ti sapá láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ. Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa “fà sẹ́yìn,” kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń jẹ́ ká ní ìgbàgbọ́ “kí a lè dá ẹ̀mí wa sí.”—Hébérù 10:39.
Èmi àti Susanne ń bá iṣẹ́ ìsìn wa lọ lórílẹ̀-èdè Sáńbíà
Wo fídíò Dayrell àti Susanne Sharp: A Ṣèlérí Pé Tọkàntọkàn La Fi Máa Sin Jèhófà.