OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́
Bó O Ṣe Lè Rántí Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
Ṣé ẹsẹ Bíbélì kan wà tó o fẹ́ràn, àmọ́ tó ò rántí ẹ̀ nígbà tó o fẹ́ lò ó? Ó lè jẹ́ ẹsẹ Bíbélì tó tù ẹ́ nínú, ó lè jẹ́ èyí tó jẹ́ kó o borí èrò tí ò tọ́ tàbí èyí tó o fẹ́ fi ran ẹnì kan lọ́wọ́. (Sm. 119:11, 111) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àbá táá jẹ́ kó o rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà.
Lo àwọn àmì tó wà lórí JW Library®. Tó o bá ti wà nínú Bíbélì ẹ lórí JW Library®, wàá rí àmì àròpọ̀ kan lókè lápá ọ̀tún, tẹ àmì náà. Ó máa gbé táàgì kan jáde, kó o pe táàgì náà ní “Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tí Mo Fẹ́ràn.” Ibẹ̀ ni kó o máa gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì náà sí, kó o lè rántí wọn.
Lẹ àwọn ẹsẹ Bíbélì náà mọ́ ibi tó o ti lè rí i. Kọ ẹsẹ Bíbélì kan sínú bébà, kó o sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ibi tí wàá ti máa rí i. Àwọn kan máa ń lẹ̀ ẹ́ mọ́ dígí wọn, àwọn míì sì máa ń lẹ̀ ẹ́ mọ́ ilẹ̀kùn fìríìjì wọn. Ohun táwọn míì máa ń ṣe ni pé wọ́n á ya fọ́tò ẹsẹ Bíbélì náà, wọ́n á sì gbé e sójú kọ̀ǹpútà wọn tàbí ojú fóònù wọn.
Máa lo káàdì. Kọ orí àti ẹsẹ Bíbélì tó o fẹ́ rántí síwájú káàdì kan, kó o sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì náà sí ẹ̀yìn ẹ̀. Lẹ́yìn náà, gbìyànjú kó o sọ ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì náà lórí tàbí kó o sọ ibi tó wà nínú Bíbélì.