ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 August ojú ìwé 2-7
  • Bí Jèhófà Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìṣòro Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Jèhófà Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìṣòro Wa
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • MÁA GBÀDÚRÀ SÍ JÈHÓFÀ
  • MÁA KA BÍBÉLÌ
  • TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ ÀWỌN ARÁ
  • ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ ṢÈLÉRÍ
  • Máa Rántí Pé Jèhófà Ni “Ọlọ́run Alààyè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Lẹ́tà Tó Máa Mú Ká Jẹ́ Olóòótọ́, Ká sì Fara Dà Á Dópin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Jèhófà “Ń Mú Àwọn Tó Ní Ọgbẹ́ Ọkàn Lára Dá”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 August ojú ìwé 2-7

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 32

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

Bí Jèhófà Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìṣòro Wa

“Ọlọ́run onínúure àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo . . . máa fún yín lókun, ó máa sọ yín di alágbára, ó sì máa fẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gbọn-in.”—1 PÉT. 5:10.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa rí àwọn nǹkan tí Jèhófà fi ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro wa, àá sì rí nǹkan tó yẹ ká ṣe ká lè jàǹfààní wọn.

1. Kí nìdí tá a fi nílò ìfaradà, ta ló sì máa ràn wá lọ́wọ́? (1 Pétérù 5:10)

LÁWỌN ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan nira yìí, àwa èèyàn Jèhófà nílò ìfaradà ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Bí àpẹẹrẹ, ó pẹ́ táwọn kan ti ń ṣàìsàn tó le. Inú àwọn míì ò sì dùn torí èèyàn wọn tó kú. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọba tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn ará wa kan máa ń ta kò wọ́n. (Mát. 10:18, 36, 37) Torí náà, mọ̀ dájú pé ìṣòro yòówù kó o ní, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á.—Ka 1 Pétérù 5:10.

2. Ta ló ń jẹ́ ká lè máa fara da ìṣòro wa?

2 Ìfaradà ni kéèyàn máa forí tì í tó bá níṣòro, tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí i tàbí tí nǹkan kan dẹ ẹ́ wò, kó sì gbà pé nǹkan ṣì máa dáa. Jèhófà ló ń fún wa lókun láti fara da ìṣòro wa, kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe wa, torí òun ló ń fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́rin tí Jèhófà fi ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da ìṣòro wa, àá sì rí nǹkan tó yẹ ká ṣe ká lè jàǹfààní wọn.

MÁA GBÀDÚRÀ SÍ JÈHÓFÀ

3. Kí nìdí tí àdúrà fi jẹ́ ohun àrà ọ̀tọ̀?

3 Jèhófà ti ṣe ohun àrà ọ̀tọ̀ kan fún wa ká lè máa fara dà á. Ó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá òun sọ̀rọ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá. (Héb. 4:16) Rò ó wò ná. Kò sígbà tá ò lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀, kò sì sóhun tá ò lè bá a sọ. Kò sí èdè tá a fi bá Jèhófà sọ̀rọ̀ tí ò gbọ́, kò sì síbi tá a wà tí ò lè gbọ́ wa, ì báà jẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí tá a bá dá wà. (Jónà 2:1, 2; Ìṣe 16:25, 26) Tí àníyàn bá bò wá mọ́lẹ̀ débi pé a ò mọ ohun tá a máa sọ fún Jèhófà, ó ṣì mọ ohun tá a fẹ́ sọ. (Róòmù 8:26, 27) Ká sòótọ́, àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ló jẹ́ pé à ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀!

4. Kí nìdí tí inú Jèhófà fi máa ń dùn tá a bá ní kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da ìṣòro wa?

4 Nínú Bíbélì, Jèhófà jẹ́ kó dá wa lójú pé “tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.” (1 Jòh. 5:14) Àmọ́, ṣé a lè gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa? Bẹ́ẹ̀ ni! Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú ẹ̀ máa dùn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé tá a bá fara da ìṣòro wa, Jèhófà máa lè fún Sátánì Èṣù tó ń pẹ̀gàn ẹ̀ lésì. (Òwe 27:11) Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì sọ pé ó máa ń wu Jèhófà “láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.” (2 Kíró. 16:9) Torí náà, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ń lo agbára ẹ̀ nítorí wa, ó sì máa ń wù ú láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á.—Àìsá. 30:18; 41:10; Lúùkù 11:13.

5. Báwo ni àdúrà ṣe máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀? (Àìsáyà 26:3)

5 Bíbélì sọ pé tá a bá gbàdúrà àtọkànwá sí Ọlọ́run nípa ìṣòro wa, ‘àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye á máa ṣọ́ ọkàn wa àti agbára ìrònú wa.’ (Fílí. 4:7) A mà mọyì ohun tí Jèhófà ń ṣe fún wa yìí o! Àwọn tí ò sin Jèhófà náà máa ń níṣòro, wọ́n sì máa ń ṣe oríṣiríṣi nǹkan kí wọ́n lè gbé ìṣòro wọn kúrò lọ́kàn. Àmọ́ àlàáfíà tí Jèhófà máa ń fún wa tá a bá gbàdúrà máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ìyẹn sì dáa ju táwọn tó ń ṣe oríṣiríṣi nǹkan kí wọ́n lè gbé ìṣòro wọn kúrò lọ́kàn. Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà, á fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, ó sì máa fún wa ní “àlàáfíà tí kò lópin.” (Ka Àìsáyà 26:3.) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fún wa ní àlàáfíà ẹ̀ ni pé ó máa ń jẹ́ ká rántí àwọn nǹkan tá a kọ́ nínú Bíbélì. Àwọn nǹkan tá a kọ́ yẹn máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká ṣàṣeyọrí.—Sm. 62:1, 2.

6. Àwọn nǹkan wo lo lè bá Jèhófà sọ tó o bá ń gbàdúrà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 Ohun tó o lè ṣe. Tó o bá níṣòro, “ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà,” kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀. (Sm. 55:22) Ó tún yẹ kó o bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n kó o lè mọ bí wàá ṣe yanjú ìṣòro ẹ. (Òwe 2:10, 11) Máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè fara dà á, àmọ́ má gbàgbé láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ nítorí àwọn nǹkan tó ń ṣe fún ẹ. (Fílí. 4:6) Ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, kó o sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Má jẹ́ káwọn ìṣòro tó ò ń bá yí gbà ẹ́ lọ́kàn débi pé o ò ní mọyì àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ.—Sm. 16:5, 6.

Arákùnrin àgbàlagbà kan jókòó sínú ilé ẹ̀ nígbà òtútù, ó sì ń gbàdúrà. Bíbélì tó ṣí wà lórí itan ẹ̀, ike oògùn kan sì wà lórí tábìlì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀.

Tó o bá ń gbàdúrà, ò ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nìyẹn. Àmọ́ tó o bá ń ka Bíbélì, Jèhófà ló ń bá ẹ sọ̀rọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 6)b


MÁA KA BÍBÉLÌ

7. Báwo ni Bíbélì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fara da ìṣòro wa?

7 Ohun míì tí Jèhófà fún wa táá jẹ́ ká lè máa fara da ìṣòro wa ni Bíbélì. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Mátíù 6:8 sọ pé: “Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ nílò, kódà kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” Jésù ló sọ̀rọ̀ yìí, ó sì mọ Jèhófà ju ẹnikẹ́ni lọ. Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Nínú Bíbélì, Jèhófà ṣèlérí ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa tó ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, àwọn nǹkan yìí sì ń jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa.—Sm. 94:19.

8. (a) Ìmọ̀ràn Bíbélì wo ló lè jẹ́ ká fara da ìṣòro wa? (b) Kí ló máa jẹ́ ká rántí àwọn ìlànà Bíbélì nígbà ìṣòro tàbí tá a bá fẹ́ ṣèpinnu?

8 Tá a bá ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, a máa lè fara da ìṣòro wa. Ìdí ni pé àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì máa ń jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́. (Òwe 2:6, 7) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká má da àníyàn tọ̀la pọ̀ mọ́ tòní, àmọ́ ṣe ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa pèsè àwọn nǹkan tá a nílò. (Mát. 6:34) Tó bá mọ́ wa lára láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, tá a sì ń ronú nípa nǹkan tá a kà, á rọrùn fún wa láti rántí àwọn ìlànà Bíbélì táá jẹ́ ká fara da ìṣòro wa tàbí ṣe ìpinnu tó tọ́.

9. Báwo ni ìtàn àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà inú Bíbélì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?

9 Nínú Bíbélì, a máa ń ka ìtàn àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti bó ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́. (Héb. 11:32-34; Jém. 5:17) Tá a bá ronú nípa àpẹẹrẹ wọn, á dá wa lójú pé Jèhófà ni “ibi ààbò wa àti okun wa, ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.” (Sm. 46:1) Torí náà, tá a bá ń fara wé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára, àá sì lè fara dà á.—Jém. 5:10, 11.

10. Kí ló yẹ kó o ṣe kó o lè jàǹfààní nínú Bíbélì?

10 Ohun tó o lè ṣe. Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó o sì kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro ẹ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ti rí i pé táwọn bá ka ẹsẹ ojúmọ́ láàárọ̀, ó máa ń jẹ́ káwọn ronú lórí ohun tó máa fún wọn níṣìírí jálẹ̀ ọjọ́ yẹn. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Mariea rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí nígbà tí dókítà sọ pé bàbá àti ìyá ẹ̀ ní àìsàn jẹjẹrẹ. Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á láwọn oṣù tó fi tọ́jú wọn kí wọ́n tó kú? Ó sọ pé: “Láràárọ̀, mo máa ń ka ẹsẹ ojúmọ́ nínú ìwé Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́, mo sì máa ń ṣàṣàrò nípa ohun tí mo bá kà. Ohun tí mò ń ṣe yìí máa ń jẹ́ kí n ronú nípa Jèhófà àtàwọn nǹkan rere tí mo kà nínú Bíbélì dípò kí n máa ronú nípa ìṣòro mi.”—Sm. 61:2.

TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ ÀWỌN ARÁ

11. Báwo ló ṣe rí lára wa bá a ṣe mọ̀ pé gbogbo àwọn ará ló níṣòro tí wọ́n ń fara dà?

11 Jèhófà fún wa láwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà kárí ayé, wọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wa. Bá a ṣe mọ̀ pé “irú ìyà kan náà ló ń jẹ gbogbo àwọn ará [wa]” kárí ayé ń jẹ́ ká lè máa fara dà á nìṣó. (1 Pét. 5:9) Ohun tó dá wa lójú ni pé ìṣòro yòówù ká ní, àwọn ará wa kan ti nírú ẹ̀, wọ́n sì ti fara dà á. Àwa náà lè fara dà á!—Ìṣe 14:22.

12. Báwo làwọn ará ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́, báwo làwa náà ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4)

12 Àwọn ará máa ń fún wa níṣìírí bá a ṣe ń fara da ìṣòro wa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù níṣòro, àwọn ará ràn án lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó ràn án lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n sé e mọ́lé, kódà ó dárúkọ wọn nínú àwọn lẹ́tà tó kọ. Wọ́n tu Pọ́ọ̀lù nínú, wọ́n fún un níṣìírí, wọ́n sì pèsè ohun tó nílò. (Fílí. 2:25, 29, 30; Kól. 4:10, 11) Lónìí, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà. Tá a bá níṣòro, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin máa ń ràn wá lọ́wọ́, táwọn náà bá sì níṣòro, a máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́.—Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

13. Kí ló jẹ́ kí Arábìnrin Maya fara da ìṣòro ẹ̀?

13 Àwọn ará fún arábìnrin kan tó ń jẹ́ Maya lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà níṣìírí nígbà tó níṣòro. Lọ́dún 2020, àwọn ọlọ́pàá wá tú ilé ẹ̀, wọ́n sì fi í sí àtìmọ́lé torí pé ó ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Maya sọ pé: “Lásìkò tí nǹkan ò rọrùn fún mi yẹn, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin máa ń pè mí lórí fóònù, àwọn míì máa ń kọ lẹ́tà sí mi, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ mi. Mo mọ̀ pé àwa èèyàn Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ara wa, àmọ́ lọ́dún 2020, ohun tí wọ́n ṣe jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi gan-an.”

14. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ káwọn ará ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Ohun tó o lè ṣe. Tó o bá níṣòro tó o sì ń fara dà á, túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará. Má bo ìṣòro ẹ mọ́ra, sọ pé káwọn alàgbà ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ “ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù, ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.” (Àìsá. 32:2, àlàyé ìsàlẹ̀) Má gbàgbé pé àwọn ará tó kù náà níṣòro tí wọ́n ń fara dà. Tó o bá ń ṣoore fáwọn tó nílò ìrànwọ́, wàá láyọ̀, wàá sì lè fara da ìṣòro ẹ.—Ìṣe 20:35.

Arákùnrin àgbàlagbà yẹn jókòó sínú ilé ẹ̀ nígbà tó kù díẹ̀ kí ẹ̀rùn dé, ó sì ń bá tọkọtaya kan àtàwọn ọmọbìnrin wọn méjì sọ̀rọ̀. Ọ̀pá tó fi ń tilẹ̀ wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ àtàwọn ike oògùn díẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin yẹn ń fi àwòrán Párádísè tó yà hàn án.

Túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará (Wo ìpínrọ̀ 14)c


ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ ṢÈLÉRÍ

15. Kí ni ìrètí tí Jésù ní mú kó ṣe, kí ló sì mú káwa náà ṣe? (Hébérù 12:2)

15 Jèhófà ti jẹ́ kó dá wa lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, ìyẹn sì ń jẹ́ ká máa fara dà á nìṣó. (Róòmù 15:13) Ìrètí yìí ló ran Jésù lọ́wọ́ láti fara da ọjọ́ tó le jù lọ láyé ẹ̀. (Ka Hébérù 12:2.) Jésù mọ̀ pé tóun bá jẹ́ olóòótọ́, òun máa dá orúkọ Jèhófà láre. Ó mọ̀ pé òun máa pa dà sọ́dọ̀ Bàbá òun lọ́run, òun máa di ọba tí àsìkò bá tó, òun sì máa ṣàkóso pẹ̀lú àwọn arákùnrin òun tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. Lọ́nà kan náà, ìrètí tá a ní pé a máa gbé ayé tuntun títí láé ń jẹ́ ká máa fara da ìṣòro èyíkéyìí nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí.

16. Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run tá à ń retí ṣe jẹ́ kí arábìnrin kan fara da ìṣòro ẹ̀, kí la sì kọ́ nínú ohun tó sọ?

16 Ẹ jẹ́ ká wo bí Ìjọba Ọlọ́run tá à ń retí ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ Arábìnrin Alla lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lágbára nígbà tí wọ́n fi ọkọ ẹ̀ sátìmọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀. Alla sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lásìkò yẹn, ó ní: “Mo gbàdúrà, mo sì ṣàṣàrò nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn ni ò jẹ́ kí n sọ̀rètí nù. Mo mọ̀ pé adùn ló ń gbẹ̀yìn ewúro, ó dá mi lójú pé Jèhófà máa borí, ó sì máa gba àwa náà sílẹ̀.”

17. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì Ìjọba Ọlọ́run tá à ń retí? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Ohun tó o lè ṣe. Máa ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú. Fojú inú wò ó pé o wà nínú ayé tuntun, kó o sì máa ronú nípa àwọn nǹkan rere tó o máa gbádùn níbẹ̀. Ìṣòro yòówù ká ní báyìí, “fún ìgbà díẹ̀ [ni], kò sì lágbára.” (2 Kọ́r. 4:17) Bákan náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Ronú nípa ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí, tí wọn ò sì mọ àwọn nǹkan rere tí Jèhófà máa ṣe fún wọn lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀rọ̀ ṣókí tó o bá sọ lè jẹ́ kó wù wọ́n láti mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fáráyé lọ́jọ́ iwájú.

Arákùnrin àgbàlagbà yẹn tún jókòó sínú ilé ẹ̀ nígbà ẹ̀rùn, ó sì ń ronú nípa àwòrán Párádísè tó wà lórí tablet ẹ̀. Kẹ̀kẹ́ tó ní táyà táwọn àgbàlagbà fi máa ń rìn wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ àtàwọn ike oògùn tó pọ̀.

Máa ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú (Wo ìpínrọ̀ 17)d


18. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán Jèhófà pé ó máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ?

18 Lẹ́yìn tí Jóòbù borí àwọn àdánwò ẹ̀, ó sọ fún Jèhófà pé: “Mo ti wá mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo àti pé kò sí ohun tó wà lọ́kàn rẹ tí kò ní ṣeé ṣe fún ọ.” (Jóòbù 42:2) Jóòbù mọ̀ pé kò sóhun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ kó má mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Ohun tá a mọ̀ yìí ń jẹ́ káwa náà lè máa fara dà á nìṣó. Wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé obìnrin kan ń ṣàìsàn tó le gan-an, nǹkan ti tojú sú u torí pé oríṣiríṣi dókítà ló ti tọ́jú ẹ̀, síbẹ̀ wọn ò lè wò ó sàn. Àmọ́ nígbà tó yá, ó rí dókítà kan tó mọṣẹ́ dáadáa, tó mọ àìsàn tó ń ṣe é, tó sì ṣàlàyé bóun ṣe máa tọ́jú ẹ̀, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì máa gba àkókò díẹ̀ kára ẹ̀ tó yá. Ohun tí dókítà yẹn sọ máa jẹ́ kó lè fara da àìsàn náà torí ó mọ̀ pé ara òun máa yá. Lọ́nà kan náà, à ń fara da ìṣòro wa torí a mọ̀ pé Párádísè máa dé.

19. Kí ló máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa?

19 A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fara da ìṣòro wa. Àwọn nǹkan tó fi ń ràn wá lọ́wọ́ ni: Àdúrà, Bíbélì, àwọn ará àti Ìjọba Ọlọ́run tá à ń retí. Torí náà, tá a bá ń gbàdúrà, tá à ń ka Bíbélì, tá a sún mọ́ àwọn ará, tá a sì ń retí Ìjọba Ọlọ́run, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á títí dìgbà tí ayé tí Sátánì ń darí yìí ò ní sí mọ́, tí ìyà sì máa dópin.—Fílí. 4:13.

BÁWO LÀWỌN NǸKAN YÌÍ ṢE Ń JẸ́ KÁ FARA DA ÌṢÒRO WA?

  • àdúrà àti Bíbélì

  • àwọn ará

  • àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣèlérí

ORIN 33 Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin àgbàlagbà kan ti ń sin Jèhófà tipẹ́, ó sì ti fara da ọ̀pọ̀ nǹkan.

c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin àgbàlagbà kan ti ń sin Jèhófà tipẹ́, ó sì ti fara da ọ̀pọ̀ nǹkan.

d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin àgbàlagbà kan ti ń sin Jèhófà tipẹ́, ó sì ti fara da ọ̀pọ̀ nǹkan.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́