ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Jèhófà Mú Ká ‘Dàgbà Níbi Tó Gbìn Wá Sí’
TÍ WỌ́N bá sọ fẹ́nì kan pé kó “máa dàgbà níbi tí wọ́n gbìn ín sí,” ó lè má kọ́kọ́ yé e. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà lohun tá a sọ yìí ṣẹlẹ̀ sí tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Mats àti Ann-Catrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Sweden. Báwo ni ìmọ̀ràn yẹn ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́? Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe ṣẹlẹ̀.
Ọdún 1979 ni Mats àti Ann-Catrin Kassholm lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àtìgbà yẹn ni ètò Ọlọ́run ti ń rán wọn lọ sáwọn orílẹ̀-èdè bí Iran, Mauritius, Myanmar, Tanzania, Uganda àti Zaire. Ìgbà tí wọ́n wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wọn tó ń jẹ́ Jack Redford gbà wọ́n nímọ̀ràn tó ràn wọ́n lọ́wọ́ ní gbogbo ibi tí ètò Ọlọ́run rán wọn lọ. Torí pé wọ́n fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, ṣe ló dà bíi pé à ń gbìn wọ́n, à ń fà wọ́n tu, a sì ń tún wọn gbìn sáwọn orílẹ̀-èdè náà. Ẹ jẹ́ ká gbọ́rọ̀ lẹ́nu wọn.
Ẹ jọ̀ọ́, báwo lẹ ṣe rí òtítọ́?
Mats: Orílẹ̀-èdè Poland là ń gbé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àmọ́ bàbá mi rí i pé oríṣiríṣi ìwàkiwà ló wà nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni bàbá mi máa ń sọ pé, “Ẹ̀sìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ wà níbì kan!” Nígbà tó yá, mo rí i pé òótọ́ ni bàbá mi ń sọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé nígbà yẹn, mo máa ń ra oríṣiríṣi ìwé àlòkù. Ọ̀kan lára ìwé tí mo rà ni ìwé aláwọ̀ búlúù kan tó ń jẹ́ Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye. Orúkọ ìwé yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, alẹ́ ọjọ́ yẹn ni mo sì kà á láti páálí dé páálí. Nígbà tó máa fi di àárọ̀ ọjọ́ kejì, mo mọ̀ pé mo ti rí òtítọ́!
Láti April 1972, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọ̀pọ̀ lára ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì ń rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè mi. Ṣe lọ̀rọ̀ mi dà bí ọkùnrin oníṣòwò tí Jésù sọ nínú àpèjúwe ẹ̀ pé ó rí péálì tó dáa, ó sì ta gbogbo ohun tó ní kó lè rà á. Ohun tí mo ṣe gan-an nìyẹn, mo pinnu pé Jèhófà ni màá fayé mi sìn dípò kí n lọ sí yunifásítì, kí n sì di dókítà. (Mát. 13:45, 46) Torí náà, mo ṣèrìbọmi ní December 10, 1972.
Kò tíì pé ọdún kan lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, àwọn òbí mi àti àbúrò mi ọkùnrin náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Nígbà tó di July 1973, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Arábìnrin kan tó rẹwà, tó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà wà lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà onítara tó wà níjọ wa, Ann-Catrin lorúkọ ẹ̀. A nífẹ̀ẹ́ ara wa, a sì ṣègbéyàwó ní 1975. Lẹ́yìn ìyẹn, a lo ọdún mẹ́rin nílùú Strömsund, lórílẹ̀-èdè Sweden, ibẹ̀ rẹwà gan-an, àwọn èèyàn ibẹ̀ sì máa ń gbọ́ ìwàásù.
Ann-Catrin: Ìgbà tó kù díẹ̀ kí bàbá mi ṣe tán ní yunifásítì nílùú Stockholm ni wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ọmọ oṣù mẹ́ta péré ni mí nígbà yẹn, síbẹ̀, bàbá mi máa ń gbé mi dání lọ sípàdé àti òde ìwàásù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èyí ò dùn mọ́ màmá mi nínú, wọn ò sì gbà pé ẹ̀sìn tòótọ́ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n yí èrò wọn pa dà, àwọn náà sì ṣèrìbọmi. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13) péré ni mí nígbà tí mo ṣèrìbọmi, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16). Mo lọ sìn nílùú Umeå, níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù sí i, Lẹ́yìn náà mo di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.
Lẹ́yìn tí èmi àti Mats ṣègbéyàwó, inú wa dùn pé a láǹfààní láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ọ̀kan lára wọn ni ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Maivor, ó fi eré ìdárayá tó máa sọ ọ́ di olókìkí sílẹ̀ kó lè túbọ̀ sin Jèhófà, òun àti àbúrò mi obìnrin sì jọ ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Wọ́n lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1984, wọ́n sì jọ ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Ecuador.
Láwọn ibi tí wọ́n rán yín lọ, báwo lẹ ṣe fi ìmọ̀ràn tí wọ́n fún yín sílò pé kẹ́ ẹ ‘máa dàgbà níbi tí wọ́n gbìn yín sí?’
Mats: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sọ pé ká kúrò níbi tá a wà, ká sì lọ síbòmíì. Ohun tó jẹ́ kára wa mọlé láwọn ibi tí wọ́n rán wa lọ ni bá a ṣe ń fara wé Jésù, tá a sì nírẹ̀lẹ̀ bíi tiẹ̀. (Kól. 2:6, 7) Bí àpẹẹrẹ, dípò ká máa retí pé káwọn ará tó wà níbẹ̀ máa ṣe nǹkan bá a ṣe fẹ́, àwa la máa ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan. A tún máa ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe láti mọ àṣà ìbílẹ̀ wọn àti ìdí tí wọ́n fi ń ṣe nǹkan tí wọ́n ń ṣe. Bá a ṣe túbọ̀ ń fara wé Jésù, bẹ́ẹ̀ là ń rí i pé a “dà bí igi tí a gbìn sétí odò” tó ń dàgbà níbi tí wọ́n gbìn ín sí.—Sm. 1:2, 3.
A máa ń rìnrìn àjò gan-an tá a bá fẹ́ lọ bẹ ìjọ wò
Ann-Catrin: Kí igi kan tó lè hù níbi tí wọ́n tún un gbìn sí, ó gba pé kí ìtànṣán oòrùn tàn sí i. Bọ́rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn, gbogbo ìgbà ni Jèhófà ti jẹ́ “oòrùn” fún wa. (Sm. 84:11) Ó fún wa láwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó nífẹ̀ẹ́ wa dénú, tára wọn sì yá mọ́ọ̀yàn. Bí àpẹẹrẹ, níjọ kékeré kan tá a wà nílùú Tehran, lórílẹ̀-èdè Iran, àwọn ará tó wà níbẹ̀ lawọ́ sí wa gan-an, ìyẹn sì rán wa létí bí wọ́n ṣe máa ń tọ́jú àlejò láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò wù wá ká kúrò ní Iran, ní July 1980, ìjọba fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè yẹn, wọ́n sì fún wa lọ́jọ́ méjì péré pé ká kúrò níbẹ̀. Torí náà, ètò Ọlọ́run ní ká lọ sí Zaire, tí wọ́n ń pè ní Kóńgò báyìí nílẹ̀ Áfíríkà.
A gbádùn iṣẹ́ wa gan-an nígbà tá a wà ní Zaire—1982
Nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ pé Áfíríkà ni wọ́n ń rán wa lọ, ṣe ni mo bú sẹ́kún. Mo gbọ́ pé ejò pọ̀ níbẹ̀, oríṣiríṣi àrùn ló sì wà níbẹ̀, ìyẹn jẹ́ kẹ́rù bà mí gan-an. Àmọ́ méjì lára àwọn ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ tó ti sìn ní Áfíríkà rí, tí wọ́n sì pẹ́ níbẹ̀ sọ fún wa pé: “Ẹ ò tíì débẹ̀ rí, ẹ tiẹ̀ ṣì débẹ̀ ná. Ẹ̀ẹ́ rí i pé ẹ máa gbádùn ẹ̀.” Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn! Àwọn ará tó wà níbẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n sì kóni mọ́ra gan-an. Kódà nígbà tá a fẹ́ kúrò ní Zaire ní ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà torí pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa, ṣe ni mò ń fi ara mi ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé àdúrà tí mò ń gbà nígbà yẹn ni pé kí Jèhófà má jẹ́ kí wọ́n gbé wa kúrò ní Áfíríkà.
Ní báyìí tẹ́ ẹ ti lo àádọ́ta (50) ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn, àwọn nǹkan wo ló ń fún yín láyọ̀?
Inú mọ́tò tá à ń sùn rèé nígbà tá a wà ní Tanzania—1988
Mats: Iṣẹ́ tá à ń ṣe ti jẹ́ ká ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ àtàtà tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì tí wọ́n sì wá láti ibi tó yàtọ̀ síra. Láwọn ibì kan, inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń kọ́ ọ̀pọ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kódà ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ń kọ́ èèyàn tó tó ogún (20) lẹ́kọ̀ọ́ nígbà míì! Yàtọ̀ síyẹn, mi ò lè gbàgbé bí àwọn ará ní Áfíríkà ṣe fìfẹ́ hàn sí wa, tí wọ́n sì ṣe wá lálejò. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń bẹ àwọn ìjọ wò ní Tanzania, inú mọ́tò wa tá a páàkì sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wọn la máa ń sùn, àmọ́ àwọn ará tó wà níbẹ̀ máa ń tọ́jú wa gan-an, kódà wọ́n máa ń ṣe “kọjá agbára wọn.” (2 Kọ́r. 8:3) Nǹkan míì tá a máa ń gbádùn ni àkókò témi àtìyàwó mi fi jọ máa ń sọ̀rọ̀ lálaalẹ́. Tá a bá ti délé, àwa méjèèjì á jọ jókòó, àá sọ gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà, àá sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí àwọn nǹkan tó ṣe fún wa.
Ann-Catrin: Ní tèmi, inú mi dùn gan-an pé mo gbé láàárín àwọn ará níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kárí ayé. A kọ́ àṣà wọn, a sì tún kọ́ àwọn èdè míì bíi Farsi, Faransé, Luganda àti Swahili. A dá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́, a láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà, a sì ṣiṣẹ́ “ní ìṣọ̀kan” pẹ̀lú wọn nínú ìjọsìn Jèhófà.—Sef. 3:9.
A tún rí onírúurú iṣẹ́ àrà Jèhófà láwọn ibi tá a lọ. Gbogbo ìgbà tá a bá gba iṣẹ́ tuntun nínú ètò Jèhófà ló máa ń dà bíi pé àwa àti Jèhófà jọ ń rìnrìn àjò, ó sì ń fi wá mọ̀nà. Jèhófà ti kọ́ wa láwọn nǹkan tá ò lè mọ̀ fúnra wa láé.
A wàásù níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Tanzania
Àwọn ìṣòro wo lẹ ti ní, kí ló sì ràn yín lọ́wọ́ láti fara dà á?
Mats: Àwọn ìgbà míì wà tá a máa ń ṣàìsàn irú bí àìsàn ibà. Àwọn ìgbà kan sì wà tí wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ abẹ fún ìyàwó mi ní pàjáwìrì. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń ṣàníyàn nípa àwọn òbí wa tó ti dàgbà, àmọ́ inú wa dùn pé àwọn àbúrò wa máa ń tọ́jú wọn dáadáa. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń tọ́jú wọn, wọ́n ní sùúrù, wọ́n fayọ̀ ṣe é, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ wọn. (1 Tím. 5:4) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò sí lọ́dọ̀ wọn, à ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe láti tọ́jú wọn, àárò wọn máa ń sọ wá nígbà míì, ó sì máa ń ṣe wá bíi pé káwa náà wà níbẹ̀ ká lè túbọ̀ tọ́jú wọn.
Ann-Catrin: Nígbà tá a wà ní Zaire lọ́dún 1983, àìsàn kọ́lẹ́rà ṣe mí. Dókítà sọ fún ọkọ mi pé, “Rí i pé o gbé e kúrò lórílẹ̀-èdè yìí lónìí!” Lọ́jọ́ kejì, èmi àtọkọ mi wọkọ̀ òfúrufú tí wọ́n fi ń kẹ́rù lọ sí Sweden torí ọkọ̀ yẹn nìkan ló ń lọ sórílẹ̀-èdè náà.
Mats: A sunkún gan-an torí a rò pé a ò ní lè ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì mọ́. Àmọ́ ara ìyàwó mi yá bó tiẹ̀ jẹ́ pé dókítà rò pé ara ẹ̀ ò ní yá. Ọdún kan lẹ́yìn náà, a pa dà sí Zaire, àmọ́ ìjọ kékeré kan tó ń sọ èdè Swahili nílùú Lubumbashi ni ètò Ọlọ́run ní ká lọ.
Ann-Catrin: Nígbà tá a wà ní Lubumbashi, oyún bà jẹ́ lára mi. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò fẹ́ bímọ, ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bà wá lọ́kàn jẹ́ gan-an. Lásìkò tí ìbànújẹ́ dorí wa kodò yẹn, Jèhófà bù kún wa lọ́nà tá ò retí. Ó jẹ́ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kò pé ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn, iye akéde ìjọ wa tó jẹ́ márùndínlógójì (35) di àádọ́rin (70). Bákan náà, iye àwọn tó ń wá sípàdé tó jẹ́ ogójì (40) tẹ́lẹ̀ di igba ó lé ogún (220). A túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, Jèhófà bù kún wa gan-an, ìyẹn sì tù mí nínú. Síbẹ̀, a ṣì máa ń rántí ọmọ wa, a máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, a sì ń retí ìgbà tí Jèhófà máa mú gbogbo ẹ̀dùn ọkàn wa kúrò.
Mats: Ìgbà kan wà tí àìsàn kan máa ń mú kó rẹ ìyàwó mi gan-an. Ìgbà yẹn náà làwọn dókítà sọ fún mi pé mo lárùn jẹjẹrẹ tó le gan-an, wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ abẹ fún mi. Àmọ́ ní báyìí, ara mi ti le, ìyàwó mi náà sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà.
A ti wá rí i pé àwa nìkan kọ́ la níṣòro. Lẹ́yìn ogun tí wọ́n fẹ́ fi pa ẹ̀yà kan run lórílẹ̀-èdè Rwanda lọ́dún 1994, a lọ kí àwọn ará ní àgọ́ àwọn tí ogun lé kúrò nílùú. Nígbà tá a rí bí ìgbàgbọ́ wọn ṣe lágbára àti bí wọ́n ṣe ń fara dà á bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún wọn rárá, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà lágbára láti bójú tó àwọn èèyàn ẹ̀ nínú ipò yòówù kí wọ́n wà.—Sm. 55:22.
Ann-Catrin: Nígbà tá a lọ síbi tí wọ́n ti ya ẹ̀ka ọ́fíìsì wa sí mímọ́ ní Uganda lọ́dún 2007, nǹkan míì ṣẹlẹ̀ tó bà wá nínú jẹ́. Lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, àwa àtàwọn míṣọ́nnárì pẹ̀lú àwọn ará Bẹ́tẹ́lì tó tó mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) rìnrìn àjò lọ sílùú Nairobi, lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Ká tó dé ààlà orílẹ̀-èdè náà, ọkọ̀ akẹ́rù kan yà wá bá wa, ó sì kọlù wá. Awakọ̀ ọkọ̀ yẹn àtàwọn márùn-ún lára àwọn ọ̀rẹ́ wa ló kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, arábìnrin kan sì kú lẹ́yìn tí wọ́n dé ilé ìwòsàn. À ń retí ìgbà tá a tún máa rí àwọn ọ̀rẹ́ wa yẹn!—Jóòbù 14:13-15.
Èmi náà fara pa, àmọ́ nígbà tó yá, àwọn egbò yẹn jinná. Ṣùgbọ́n, èmi, Mats àtàwọn ará kan tá a jọ wà nínú ọkọ̀ náà máa ń ní ìdààmú ọkàn torí jàǹbá tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Òru ni ìdààmú máa ń bá mi, ó máa ń jí mi kalẹ̀, ó sì máa ń ṣe mí bíi pé ọkàn mi fẹ́ dáṣẹ́ dúró. Kí n sòótọ́, ẹ̀rù máa ń bà wá gan-an tó bá ti ṣẹlẹ̀. Àmọ́ àdúrà tá à ń gbà déédéé àti bá a ṣe máa ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a fẹ́ràn tù wá nínú gan-an, ó sì jẹ́ ká fara dà á. A tún lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà tó mọ̀ nípa nǹkan tó ń ṣe wá, ìyẹn náà sì ràn wá lọ́wọ́. Ní báyìí, ìdààmú ọkàn náà ti lọlẹ̀ gan-an, àmọ́ a máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká lè ran àwọn míì tó nírú ìdààmú ọkàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́.
Nígbà tẹ́ ẹ̀ ń sọ nípa bí Jèhófà ṣe ràn yín lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro tẹ́ ẹ ní, ẹ sọ pé Jèhófà gbé yín “bí ẹyin tútù.” Kí lẹ ní lọ́kàn?
Mats: Àwọn Swahili máa ń pòwe kan pé “Tumebebwa kama mayai mabichi,” ìtumọ̀ ẹ̀ ni pé “Wọ́n gbé wa bí ẹyin tútù.” Bí ẹnì kan ṣe rọra máa ń gbé ẹyin tútù kó má bàa fọ́, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́, tó sì ń tì wá lẹ́yìn ní gbogbo ibi tí wọ́n rán wa lọ. Gbogbo ìgbà la máa ń ní ohun tá a nílò, kódà a máa ń ní kọjá ohun tá a nílò nígbà míì. Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà ràn wá lọ́wọ́ ni bó ṣe lo Ìgbìmọ̀ Olùdarí láti bójú tó wa.
Ann-Catrin: Ẹ jẹ́ kí n sọ ọ̀kan lára ìgbà tí Jèhófà fìfẹ́ bójú tó wa. Lọ́jọ́ kan, wọ́n pè wá láti orílẹ̀-èdè Sweden pé ara bàbá mi ò yá, wọ́n sì ti wà nílé ìwòsàn. Ara Mats ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yá díẹ̀díẹ̀ ni torí àìsàn ibà tó ṣe é, a ò sì lówó tá a fi máa wọkọ̀ òfúrufú lọ síbẹ̀. Torí náà, a pinnu pé ká ta mọ́tò wa. Lẹ́yìn náà, àwọn méjì kan pè wá. Tọkọtaya kan tó gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ ló kọ́kọ́ pè, wọ́n ní àwọn máa sanwó ẹnì kan. Ẹnì kejì tó pè wá ni arábìnrin àgbàlagbà kan. Wọ́n máa ń tọ́jú owó sínú àpótí kan, wọ́n sì pinnu pé ẹni tó bá nílò ìrànlọ́wọ́ làwọn máa fún. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, Jèhófà ti ṣọ̀nà àbáyọ fún wa!—Héb. 13:6.
Ó ti tó àádọ́ta (50) ọdún tẹ́ ẹ ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún báyìí, kí lẹ ti kọ́?
Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Myanmar la ti ń sìn báyìí
Ann-Catrin: Mo ti wá rí i pé a ‘máa lágbára tá a bá fara balẹ̀, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.’ Tá a bá fọkàn tán Jèhófà, ó máa jà fún wa, kò sì ní fi wá sílẹ̀. (Àìsá. 30:15; 2 Kíró. 20:15, 17) Bá a ṣe fi gbogbo okun wa sin Jèhófà láwọn ibi tí wọ́n rán wa lọ ti jẹ́ kí Jèhófà bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀, kódà kò síṣẹ́ míì tá a lè fayé wa ṣe tá a máa rí irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ gbà.
Mats: Ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù tí mo kọ́ ni pé kí n máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nínú gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe, kí n sì rí bó ṣe máa gbé ìgbésẹ̀ nítorí mi. (Sm. 37:5) Gbogbo ìgbà ló máa ń mú ìlérí yẹn ṣẹ, kò já mi kulẹ̀ rí. Kódà títí di ìsinsìnyí, Jèhófà ṣì ń mú ìlérí yẹn ṣẹ ní Bẹ́tẹ́lì tá a wà báyìí lórílẹ̀-èdè Myanmar.
Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó fi hàn sí wa hàn sí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Tí wọ́n bá jẹ́ kí Jèhófà lò wọ́n, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa jẹ́ kí wọ́n dàgbà níbi tó bá gbìn wọ́n sí, á sì bù kún iṣẹ́ ìsìn wọn.