ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb13 ojú ìwé 174-177
  • Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn 1913

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn 1913
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn 1914
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Àwọn Ibi Tá a ó Ti Ṣe Àpéjọ Àgbègbè “Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!” Ti Ọdún 2007
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • A Óò Dán Ìgbàgbọ́ Kristẹni Wò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àwọn Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù—Gbogbo Ọ̀nà La Fi Ń Mú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2013
yb13 ojú ìwé 174-177
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 174, 175]

Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn 1913

ILÉ ÌṢỌ́ January 1, 1913, ti èdè Gẹ̀ẹ́sì fa ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Herbert Kaufman tó jẹ́ oníròyìn ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan yọ. Nílé lóko làwọn èèyàn ti gbọ́rọ̀ náà nígbà yẹn lọ́hùn-ún pé: “Kò sẹ́ni tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé nǹkan báyìí ò lè ṣẹlẹ̀ mọ́ . . . Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan tá a rò pé kò lè ṣẹlẹ̀ ló ti wá ń ṣẹlẹ̀ báyìí.” Nígbà tí ọdún 1913 fi máa bẹ̀rẹ̀, kò sẹ́ni tí kò gbà pé nǹkan máa ṣẹnuure lọ́jọ́ ọ̀la.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 174]

Bí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe ń dábírà lójoojúmọ́ wà lára ohun tó fi àwọn èèyàn lọ́kàn balẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ilé iṣẹ́ kan tó ń jẹ́ Ford Motor Company, tí wọ́n máa ń ṣe ọkọ̀ ṣí ilé iṣẹ́ tuntun kan sílùú Highland, ní ìpínlẹ̀ Michigan. Èyí jẹ́ kí owó ọkọ̀ já wálẹ̀ lọ́sàn-an kan òru kan, tí iye àwọn èèyàn tó sì lè rówó ra ọkọ̀ wá pọ̀ gan-an. Kí ni wọ́n ṣe tówó ọkọ̀ fi já wálẹ̀? Ilé iṣẹ́ tuntun náà ní ibi tí wọ́n ti ń to ẹ̀yà ara ọkọ̀ pọ̀. Èyí jẹ́ kí wọ́n lè máa to ọkọ̀ wọn kan táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó, ìyẹn Model T. Kì í pẹ́ rárá tí wọ́n fi máa ń tò ó, kò sì wọ́nwó.

Àwa èèyàn Jèhófà náà gbà pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa, àmọ́ ìdí tá a fi gbà bẹ́ẹ̀ yàtọ̀. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti fi ọ̀pọ̀ ọdún pòkìkí pé ọdún 1914 máa jẹ́ ọdún tó ṣàrà ọ̀tọ̀, wọ́n sì ń retí pé nǹkan àgbàyanu ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́dún yẹn. Ṣe ni ìtara wọn ń pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ bí ọdún náà ti ń sún mọ́lé.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 177]

Káàdì: Àwòrán ìrìn-àjò Pásítọ̀ Russell láti ibì kan sí ibòmíì ló wà lórí káàdì tó ṣe é firánṣẹ́ bíi lẹ́tà yìí

Ní June ọdún 1913, a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àpéjọ àgbègbè kan tẹ̀ lé òmíràn, èyí tó kọ́kọ́ wáyé ni àpéjọ ọlọ́jọ́ kan nílùú Kansas, ìpínlẹ̀ Missouri, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọ̀sẹ̀ mẹ́rin gbáko ni ọkọ̀ ojú irin kan tá a gbà fi ń kó àwọn ará tí iye wọn ju igba lọ sáwọn ìlú tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Amẹ́ríkà àti orílẹ̀-èdè Kánádà. Ní àpéjọ àgbègbè kọ̀ọ̀kan tó wáyé, wọ́n fún àwọn tó wá fúngbà àkọ́kọ́ láǹfààní láti béèrè ohun tí kò bá yé wọn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, torí náà, a bẹ̀rẹ̀ sí í kàn sáwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́.

Lọ́dún 1913, àwọn òṣìṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn sapá láti gbé “Photo-Drama of Creation,” ìyẹn Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá jáde. Wákàtí mẹ́jọ ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwòrán náà gbà, àsọyé Bíbélì wà níbẹ̀, orin wà níbẹ̀ tó ń lọ lábẹ́lẹ̀ bí àwòrán kọ̀ọ̀kan ṣe ṣe ń jáde. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà pé fíìmù yìí máa ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà yẹn iye àwọn akéde tó ń wàásù ìhìn rere ò ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọgọ́rùn-ún kan [5,100] lọ. Wọ́n sọ ohun tí wọ́n ní lọ́kàn nípa fíìmù yìí pé, a “fẹ́ polongo rẹ̀ ká gbogbo ibi tó bá lè dé lórí ilẹ̀ ayé.”

Kí ni wọ́n rétí pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914? Ṣé àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ sí fíìmù “Photo-Drama” yìí? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Àkókò Àwọn Kèfèrí bá dópin? Ara àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti wà lọ́nà láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí. Ọkàn wọn balẹ̀ pé Jèhófà ò ní fi àwọn sílẹ̀.

Ogun Àgbáyé Kìíní tó máa tó bẹ̀rẹ̀ máa mú kí ìrètí àwọn èèyàn wọmi. Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ò ní lè rí nǹkan kan ṣe sí ìṣòro tó ń dé bá àwọn èèyàn. Ọdún tó máa tẹ̀ lé e máa mú ìyípadà ńlá bá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti gbogbo ayé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́