ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 170-175
  • Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn 1914

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn 1914
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nǹkan Túbọ̀ Burú Sí I Láyé
  • Wọ́n Tẹnu Mọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù Láwọn Àpéjọ
  • Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Wá Wo “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò”
  • Àwọn Apínwèé-Ìsìn-Kiri Àtàwọn Tó Yọ̀ǹda Ara Wọn Ṣe Iṣẹ́ Ìwàásù
  • Àkókò Àwọn Kèfèrí Dópin
  • “Iṣẹ́ Àgbàyanu Kan”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • A Óò Dán Ìgbàgbọ́ Kristẹni Wò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àwọn Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù—Gbogbo Ọ̀nà La Fi Ń Mú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn 1913
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2013
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 170-175

Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn 1914

ILÉ ÌṢỌ́ January 1, 1914 sọ pé: “A nígbàgbọ́ pé a ó túbọ̀ lè ṣe iṣẹ́ ìsìn fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ ní Ọdún 1914 ju àwọn ọdún míì lọ ní Àsìkò Ìkórè yìí.” Ọdún tí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń retí tipẹ́ ti dé, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ kárakára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Lọ́dún yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbọ́ nípa àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì torí iṣẹ́ àṣekára tí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́ ohun tí àwọn èèyàn fún láfiyèsí lásìkò yẹn yàtọ̀ pátápátá.

Nǹkan Túbọ̀ Burú Sí I Láyé

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1914, ọ̀kan lára ìyanṣẹ́lódì tó gbóná janjan jù lọ nínú ìtàn àwọn òṣìṣẹ́ nílẹ̀ Amẹ́ríkà gbẹ̀mí àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin títí kan àwọn ọmọdé. Ilé iṣẹ́ ìwakùsà lé àwọn òṣìṣẹ́ tó yan iṣẹ́ lódì àtàwọn ìdílé wọn kúrò nínú ilé tí wọ́n fi wọ́n sí, àwọn awakùsà náà sì wá lọ ń gbé inú àgọ́. Ní April 20 ọdún náà, ìró ìbọn bẹ̀rẹ̀ sí í dún kíkankíkan nítòsí ìlú Ludlow, ní ìpínlẹ̀ Colorado, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn kan dáná sun àgọ́ àwọn awakùsà náà. Inú bí àwọn awakùsà tó wà ní àgbègbè náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn ẹ̀ṣọ́ ilé iṣẹ́ náà. Àwọn sójà ló wá pẹ̀rọ̀ sí ìjà ọ̀hún.

Nǹkan tún burú jáì ju ìyẹn lọ nílẹ̀ Yúróòpù. Ní June 28, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Gavrilo Princip, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Serbia tó ń gbé ní Bosnia yìnbọn pa Ọmọọba Francis Ferdinand ti ilẹ̀ Austria, èyí ló fi dáná ìjàngbọ̀n tó yọrí sí Ogun Àgbáyé Kìíní. Nígbà tí ọdún yẹn fi máa parí, Ogun Àgbáyé Kìíní, tí wọ́n ń pè ní Ogun Ńlá nígbà yẹn, ti gba gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù kan.

Wọ́n Tẹnu Mọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù Láwọn Àpéjọ

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé rúkèrúdò ń pọ̀ sí i láyé, Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń gba ara wọn níyànjú láti túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù. Ọjọ́ kẹwàá oṣù April ni wọ́n ṣe àpéjọ àgbègbè àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè South Africa. Àwọn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] ló pésẹ̀ síbẹ̀. Arákùnrin William W. Johnston sọ́ pe: “Agbo kékeré ni wá lóòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdajì àwọn [tó wá sí àpéjọ náà] ló ṣèrìbọmi. . . . Arábìnrin mẹ́jọ àti arákùnrin mẹ́jọ ló ya ara wọn sí mímọ́ lọ́nà tí Olúwa ní ká máa gbà ṣe é.” Ní ọjọ́ tó kẹ́yìn àpéjọ náà, àwọn tó pé jọ síbẹ̀ jíròrò ọ̀nà tó dára jù tí wọ́n lè gbà mú kí iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ fìdí múlẹ̀ lórílẹ̀-èdè South Africa. Lónìí, àwọn akéde tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn-ún [90,000] lórílẹ̀-èdè náà jẹ́ ẹ̀rí pé ‘agbo kékeré’ yẹn ti ṣàṣeyọrí.

Ní June 28, 1914, ìyẹn ọjọ́ tí wọ́n yìnbọn pa Ọmọọba Ferdinand, Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ṣe àpéjọ kan lọ́wọ́ ní ìlú Clinton, ìpínlẹ̀ Iowa, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ní June 30, nígbà tí àpéjọ náà ń lọ lọ́wọ́, Arákùnrin A. H. MacMillan sọ pé: “Tá a bá fẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ èrè náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run sú wa, ká máa lọ sóde ẹ̀rí ní gbogbo ìgbà tó bá ṣeé ṣe, ká máa kópa nínú iṣẹ́ ìkórè náà.”

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Wá Wo “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò”

Ìlú New York City la ti kọ́kọ́ fi àwòrán Photo-Drama of Creation [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] han àwọn èèyàn ní January 11, 1914. Àsọyé Bíbélì àti orin tó bá àwọn àwòrán tó ń jáde mu wà nínú sinimá aláwọ̀ mèremère yìí. Ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] làwọn tó wo sinimá náà lọ́jọ́ tá a kọ́kọ́ fi han àwọn èèyàn, ọ̀pọ̀ ló sì pa dà sílé torí pé ibẹ̀ ti kún fọ́fọ́.

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ pé ọdún méjì gbáko la fi ṣe sinimá “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá,” àmọ́ iṣẹ́ ṣì pọ̀ tó yẹ ká ṣe lórí rẹ̀ ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í fi han àwọn èèyàn lóṣù January. Ní oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ lọ́dún 1914, àwọn ará ṣe ọ̀pọ̀ àtúnṣe sí sinimá náà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fi apá kan tó ní ọ̀rọ̀ Arákùnrin Charles Taze Russell kún un ní ìbẹ̀rẹ̀, èyí jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn tó ṣe sinimá náà.

Ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa sinimá yìí ni pé ó tó ọgọ́rin [80] ìlú tí àwọn èèyàn ti wò ó ní àkókò kan náà. Nígbà tó fi máa di oṣù July 1914, àwọn èèyàn ti wò ó ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, inú ilé kún fọ́fọ́ níbi tí wọ́n ti wò ó ní ìlú Glasgow àti London. Nígbà tó fi máa di oṣù September, a lọ fi han àwọn èèyàn ní orílẹ̀-èdè Denmark, Finland, Jámánì, Sweden àti Switzerland. Lóṣù October, sinimá náà dé orílẹ̀-èdè Ọsirélíà àti New Zealand. Lápapọ̀, àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ló wo sinimá náà lọ́dún tá a kọ́kọ́ gbé e jáde.

Ẹ̀dà sinimá yìí kọ̀ọ̀kan ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún gíláàsì tí wọ́n ya àwòrán sí, àwọn bébà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tá a ṣe àwòrán sinimá sí àtàwọn ohùn tá a ti gbà sílẹ̀. Owó gọbọi la fi ṣe àwọn ẹ̀dà sinimá náà, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó sì mọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa ló ń fi hàn. Torí náà, àwọn ìlú ńlá nìkan làwọn èèyàn ti wo sinimá náà látòkèdélẹ̀. Àmọ́ káwọn tó wà láwọn ìgbèríko pẹ̀lú lè rí i wò, Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe oríṣi ẹ̀dà rẹ̀ mẹ́ta tí kò gùn púpọ̀. Wọ́n pe ẹ̀dà méjì lára rẹ̀ ní “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Eureka.” Ọ̀kan lára rẹ̀ ní àwọn gíláàsì mèremère tí wọ́n fi ń gbé sinimá jáde, orin àti àsọyé Bíbélì. Oríṣi kejì àti ìkẹta jẹ́ ohùn nìkan, kò ní àwòrán tàbí sinimá. Wọ́n pe ẹ̀dà kẹta ní “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Eureka Fún Ìdílé,” kò gùn rárá. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin [70,000] ló ti wo, ó kéré tán, ẹ̀dà kan lára àwọn ẹ̀dà sinimá yìí nígbà tí ọdún 1914 fi máa parí. Kò sì tíì pé oṣù mẹ́rin tá a gbé sinimá náà jáde tí gbogbo èyí fi ṣẹlẹ̀.

Àwọn Apínwèé-Ìsìn-Kiri Àtàwọn Tó Yọ̀ǹda Ara Wọn Ṣe Iṣẹ́ Ìwàásù

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì pẹ́ tí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò” táwọn èèyàn gbádùn gan-an yìí, wọ́n tún rí i pé ó yẹ káwọn tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù láwọn ọ̀nà míì ju èyí lọ. Nínú lẹ́tà kan tí Arákùnrin Charles Taze Russell kọ ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn tó ń pín ìwé ìsìn kiri, ìyẹn àwọn tí à ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà báyìí, ó sọ pé: “Kò sí ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn míì tó ń mú èso rẹpẹtẹ jáde lákòókò Ìkórè yìí. Torí náà, a ò fẹ́ kí àwọn tó ń pín ìwé ìsìn kiri tún máa ṣe iṣẹ́ Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò . . . Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin míì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Olúwa . . . lè máa bá iṣẹ́ Àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ.”

Ní January ọdún 1914, iye àwọn tó ń pín ìwé ìsìn kiri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rin [850]. Jálẹ̀ ọdún yẹn, àwọn ajíhìnrere onítara yìí pín ohun tó lé ní ọ̀kẹ́ márùndínlógójì [700,000] ẹ̀dà ìwé Studies in the Scriptures. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ “ọ̀rọ̀ tó wúni lórí” nípa àwọn tó ń pín ìwé ìsìn kiri, ó sì rọ àwọn tó ń kà á pé kí wọ́n máa “fún wọn ní ìṣírí torí pé àwọn pẹ̀lú ní àwọn ìṣòro tó ń bá wọn fínra.”

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yòókù pín àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè. Lọ́dún 1914, iye ìwé àṣàrò kúkúrú The Bible Students Monthly àtàwọn àṣàrò kúkúrú míì tí wọ́n fi sóde lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàdínláàádọ́ta [47,000,000]!

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kíyè sí àwọn ohun táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ṣe. Wọ́n máa ń wàásù fún gbogbo èèyàn, ọ̀fẹ́ sì ni àwọn ìpàdé wọn. Ọ̀kan lára àwọn olórí ìsìn Ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé: “Tó bá yá, ojú ọ̀bàyéjẹ́ làwọn èèyàn á máa fi wo ẹ̀sìn tó bá ń gba owó lọ́wọ́ wọn, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà yẹn? Ṣe ni Pásítọ̀ Russell fẹ́ dójú tì wá.”

Àkókò Àwọn Kèfèrí Dópin

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà gbọ́ pé àkókò àwọn kèfèrí tí Lúùkù 21:24 (Bíbélì Mímọ́) sọ máa wá sí òpin ní October 1, 1914. Èyí mú kí wọ́n túbọ̀ máa fojú sọ́nà bí oṣù October ṣe ń sún mọ́lé. Àwọn kan lára wọn tiẹ̀ ní káàdì tí wọ́n fi ń ka ọjọ́, wọ́n sì ń sàmì sí i bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Ọ̀pọ̀ ló rò pé ọjọ́ yẹn làwọn máa wọnú ibi mímọ́ tàbí ọ̀run.

Ní òwúrọ̀ Friday, October 2, 1914, Arákùnrin Russell wọ yàrá ìjẹun tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ó sì fi tayọ̀tayọ̀ kéde pé: “Àkókò Àwọn Kèfèrí ti dópin; àwọn ọba wọn ti lo ìgbà wọn kọjá.” Ó ṣeé ṣe káwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà rántí ọ̀rọ̀ yẹn, bó ṣe wà nínú orin kọkànléláàádọ́sàn [171] nínú ìwé orin Hymns of the Millennial Dawn. Láti ọdún 1879 ni Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń kọ ọ́ lórin pé “Àkókò àwọn kèfèrí ń parí lọ,” àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́, torí pé ká sòótọ́, Àkókò Àwọn Kèfèrí tàbí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” ti parí. (Lúùkù 21:24) Nígbà tó yá, òye tuntun tó ṣe pàtàkì yìí fara hàn nínú àwọn ìwé orin wa.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 175]

Káàdì yìí làwọn kan fi ń ka ọjọ́ nígbà yẹn kí wọ́n lè jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú

Nígbà tí ọdún náà fi máa parí, Ọlọ́run ti fìdí Ìjọba Mèsáyà múlẹ̀ gbọin ní ọ̀run, torí náà àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rò pé àwọn pẹ̀lú ti parí iṣẹ́ tiwọn. Wọn kò mọ̀ pé àkókò ìdánwò àti ìyọ́mọ́ ló ń wọlé bọ̀. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 1915 ni “Ẹyin ha lè mu nínú ago tí èmi ó mu?” Wọ́n gbé e ka Mátíù 20:22 nínú Bíbélì Mímọ́. Àwọn àdánwò tí Jésù máa fojú winá rẹ̀ títí dójú ikú ló pè ní “ago.” Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í fojú winá àdánwò láàárín ara wọn àti látọ̀dọ̀ àwọn ará ìta. Ohun tí wọ́n bá ṣe nígbà àdánwò náà máa fi hàn bóyá lóòótọ́ ni wọ́n dúró ṣinṣin sí Jèhófà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́