Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2014
“Kí Ìjọba Rẹ Dé.” Mátíù 6:10
Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, Jèhófà fi Jésù jẹ Ọba ní ọ̀run. Látìgbà yẹn ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti ń fi ìtara sọ àwọn ìbùkún tí Ìjọba Kristi máa mú wá. Fojú inú wò ó ná! Nígbà ìṣàkóso tí Jésù máa fìfẹ́ ṣe, ayé máa di Párádísè, àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn ló sì máa wà níbẹ̀. Kò ní sí ìwà ọ̀daràn, ìjà, àìsàn, ìyà àti ikú mọ́!
Àwọn ìbùkún yìí kò ní pẹ́ tẹ̀ wá lọ́wọ́. Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe àlá lásán, ó máa dé, ó sì máa ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́. Máa gbàdúrà pé kí Ìjọba náà dé, máa sọ fún àwọn míì nípa rẹ̀, kí o sì jẹ́ kí gbogbo ohun tí Ìjọba náà fẹ́ ṣe máa wà lọ́kàn rẹ.