ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb15 ojú ìwé 166-ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 3
  • Aditi To Koko Kekoo Otito

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Aditi To Koko Kekoo Otito
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Jèhófà Ti Mú Kí Ojú Rẹ̀ Tàn sí Wọn Lára’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Wà Lójúfò Láti Wá Àwọn Adití Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Yín Rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Jèhófà Fi Èrè sí Iṣẹ́ Mi
    Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Jèhófà Kò Gbàgbé Àwọn Adití
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
yb15 ojú ìwé 166-ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 3

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Adití Tó Kọ́kọ́ Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́

José Pérez

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1960

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1982

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó mọ èdè àwọn adití nínú ìjọ tí José lọ nígbà tó wà ní kékeré, báwọn ará ṣe fi hàn pé àwọn fẹ́ràn rẹ̀ mú kó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 166

NÍGBÀ tí mo wà ní kékeré, etí mi ò gbọ́rọ̀ dáadáa mọ́, torí náà mo lọ sílé ìwé àwọn adití láti kọ́ èdè adití. Ìgbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlá ni mo kọ́kọ́ mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́ nígbà tí ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tá a jọ wà ládùúgbò pè mí wá sí ìpàdé ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ ò yé mi, wọ́n fi ọ̀yàyà kí mi, mo sì pinnu pé màá máa lọ síbẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ará tó wà nínú ìjọ náà máa ń pè mí wá jẹun nílé wọn, wọ́n sì tún máa ń pè mí sáwọn nǹkan míì tí wọ́n bá ń ṣe.

Ọdún 1982 ni mo di akéde, mo sì ṣèrìbọmi kí ọdún yẹn tó parí. Ní ọdún 1984, mo fẹ́ Eva tóun náà jẹ́ adití. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan jinlẹ̀, ìfẹ́ tá a rí láàárín àwọn ará jẹ́ ká mọ̀ pé ètò Jèhófà nìyí, inú wa sì máa ń dùn pé a wà nínú ìjọ.—Jòh. 13:35.

Ní ọdún 1992, ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò láti kọ́ àwọn ará mélòó kan ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà. Kò pẹ́ rárá tí àwọn ará yìí fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn adití kàn, tí wọ́n sì ń wàásù ìhìn rere fún wọn. Ìtẹ̀síwájú túbọ̀ bá ìwàásù fún àwọn adití lọ́dún 1994 nígbà tí wọ́n ní kí tọkọtaya kan láti erékùṣù Puerto Rico wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Orílẹ̀-èdè Dominican kí wọ́n lè wá kọ́ àwọn ará mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní èdè àwọn adití.

Kí ọdún 1994 tó parí, èmi àti Eva bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwùjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ tó ń lo èdè àwọn adití. Ìgbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé tí wọ́n ti ń lo èdè àwọn adití la ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Irú èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú bí Sátánì ṣe gbéjà ko ẹ̀tọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run àti ipa tí Ìjọba Mèsáyà ń kó láti mú ètè Ọlọ́run ṣẹ.

Ní December 1, ọdún 1995, wọ́n dá ìjọ tó ń lo Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà sílẹ̀ nílùú Santo Domingo àti Santiago. Nígbà tó fi máa di oṣù August ọdún 2014, iye ìjọ tó ń lo èdè àwọn adití ti di mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26], iye àwùjọ tó ń lo èdè náà sì ti di méjìdínlógún [18].

Èmi àti Eva fi èdè àwọn adití kọ́ àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, òun la sì fi ṣe èdè àbínibí wọn. Ibi tí wọ́n ti ń túmọ̀ èdè àwọn adití ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni Éber, tó jẹ́ àkọ́bí wa lọ́kùnrin ti ń ṣiṣẹ́. Mo ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ, Eva sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Bí ìjọ tó ń lo Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà ṣe pọ̀ sí i láti ọdún 1995 sí 2014

  • 1995

    Ìjọ 2

    Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 167
  • 2014

    Ìjọ 26, àwùjọ 18

    Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 167
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́