Àwọn ohun pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún tó kọjá
Jèhófà Ọlọ́run mí sí wòlíì Aísáyà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Dípò bàbà, èmi yóò mú wúrà wá, àti dípò irin, èmi yóò mú fàdákà wá, àti dípò igi, bàbà, àti dípò àwọn òkúta, irin.” (Aísá. 60:17) Ní ọdún tó kọjá, a rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣì ń ní ìmúṣẹ. Bó ṣe jẹ́ pé nǹkan túbọ̀ máa ń sunwọ̀n sí i téèyàn bá fi ohun èèlò tó túbọ̀ jẹ́ ojúlówó pààrọ̀ ti tẹ́lẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé àwọn àtúnṣe tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run ń mú kí àwọn nǹkan sunwọ̀n sí i.—Mát. 24:3.