ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ
Bíbélì Tó Máa Lálòpẹ́
ÀWA Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ràn Bíbélì ju ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ. A máa ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ déédéé, a sì fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14) Torí náà, àwọn ará wa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti rí i dájú pé àwọn ohun tá a fi ṣe Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2013 máa jẹ́ kó dùn-ún wò, kó sì lálòpẹ́.
Nígbà tí àwọn ará tó ń ṣiṣẹ́ níbi ìtẹ̀wé wa ní ìlú Wallkill, ìpínlẹ̀ New York ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń sọ nípa bí a ṣe fẹ́ kí Bíbélì tuntun yìí rí fún ààrẹ ilé iṣẹ́ kan tó ń di ìwé pọ̀, ààrẹ náà sọ pé, “Kò tíì sí irú Bíbélì tẹ́ ẹ̀ ń sọ yẹn rí.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “Òótọ́ kan tó korò láti sọ ni pé ṣàgbẹ̀-lójú-yòyò ni ọ̀pọ̀ Bíbélì táwọn èèyàn ń ṣe. Wọ́n lè fani lójú mọ́ra lórí tábìlì tàbí níbi ìkówèésí, àmọ́ wọn kì í lálòpẹ́.”
Àwọn kan lára àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a ṣe jáde tẹ́lẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ lálòpẹ́. Torí náà, àwọn ará tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìtẹ̀wé wa nílùú Wallkill fara balẹ̀ ṣe àyẹ̀wò èèpo ẹ̀yìn àwọn ìwé, onírúurú gọ́ọ̀mù àti ọ̀kan-ò-jọ̀kan ọ̀nà téèyàn lè gbà di ìwé pọ̀ kí wọ́n lè ṣe Bíbélì tó máa lálòpẹ́ láìka ojú ọjọ́ tó yàtọ̀ síra kárí ayé sí. Lẹ́yìn tí wọ́n parí ìwádìí wọn, wọ́n ṣe Bíbélì mélòó kan jáde, wọ́n sì ní kí àwọn ará lò wọ́n wò ní onírúurú orílẹ̀-èdè tí ipò ojú ọjọ́ kò ti bára dé.
Wọ́n dá àwọn Bíbélì náà pa dà lẹ́yìn oṣù mẹ́fà. Àwọn ará wa ṣe àwọn ẹ̀dà míì tó sàn ju ti àkọ́kọ́, wọ́n sì tún fún àwọn kan láti lò ó wò. Àpapọ̀ ẹ̀dà Bíbélì tí wọ́n ṣe fún àyẹ̀wò yìí jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán dín mẹ́wàá [1,690]. Ohun àìròtẹ́lẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí àwọn kan lára àwọn Bíbélì náà. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gun orí ọ̀kan lára wọn kọjá, òjò pa òmíràn ní òru mọ́jú, àkúnya omi tó wáyé sì bo òmíràn mọ́lẹ̀.
Lọ́dún 2011, nígbà tí wọ́n ń ṣe àwọn àyẹ̀wò yìí lọ́wọ́, a ra àwọn ẹ̀rọ ìdìwépọ̀ ayára-bí-àṣá sí ilé ìtẹ̀wé wa tó wà nílùú Wallkill lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti nílùú Ebina, lórílẹ̀-èdè Japan. Láwọn ilé ìtẹ̀wé wa méjèèjì yìí, a ní láti rí i pé a tẹ Bíbélì tó pọ̀ tó láti pín nígbà tá a bá mú un jáde. A sì tún ní láti rí i dájú pé àwọn Bíbélì tá a bá tẹ̀ nílé ìtẹ̀wé méjèèjì rí bákan náà.
Èèpo Ẹ̀yìn Ìwé Tó Ń Ká Kò
Ṣe ni èèpo ẹ̀yìn àwọn Bíbélì náà kọ́kọ́ ń ká kò
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2012, a bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ẹ̀dà ti ọdún 1984, ní ilé ìtẹ̀wé méjèèjì, a sì ń lo àwọn kan lára àwọn èèpo ẹ̀yìn ìwé tuntun náà. Àmọ́ a ò tíì ṣe àyẹ̀wò gọ́ọ̀mù àti bébà tá a lẹ̀ mọ́ ara èèpo náà láti mọ bó ṣe máa rí tí wọ́n bá ń lò ó, èyí mú kí èèpo ẹ̀yìn àwọn Bíbélì náà bẹ̀rẹ̀ sí í ká kò gan-an. Torí náà, a dá iṣẹ́ dúró.
Ilé iṣẹ́ tó ṣe ọ̀kan lára àwọn ohun tá a lò sọ pé èèpo ẹ̀yìn ìwé tó ń ká kò kì í ṣe nǹkan tuntun lágbo àwọn ilé iṣẹ́ tó ń di ìwé pọ̀, torí náà kò sóhun táwọn lè ṣe sí i. Dípò kí àwọn ará wa ṣe àwọn Bíbélì náà ní ẹlẹ́yìn líle, wọ́n sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n le ṣe Bíbélì tí èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ máa rọ̀ dáadáa, tó máa lálòpẹ́, tó sì máa dùn-ún wò. Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́rin tí wọ́n ti ń ṣàyẹ̀wò nípa lílo onírúurú gọ́ọ̀mù àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n fi ń di ìwé pọ̀, wọ́n rí èyí tó mú kí wọ́n pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn Bíbélì tí èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ rọ̀ dáadáa, tí kò sì ní máa ká kò.
Ilé ìtẹ̀wé wa ní ìlú Wallkill
Ibi ìpàdé ọdọọdún ti àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania tó wáyé ní October 5, ọdún 2013 ni wọ́n ti fẹ́ mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tún ṣe náà jáde. Ọjọ́ Friday, August 9, ọdún 2013 ni àwọn ilé ìtẹ̀wé wa rí àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fẹ́ tẹ̀ náà gbà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ ẹ́ lọ́jọ́ kejì. Wọ́n tẹ ẹ̀dà àkọ́kọ́ jáde lódindi ní August 15. Jálẹ̀ ọ̀sẹ̀ méje tó tẹ̀ lé e, tọ̀sántòru làwọn ará fi ṣiṣẹ́ láwọn ilé ìtẹ̀wé wa nílùú Wallkill àti Ebina kí wọ́n lè tẹ mílíọ̀nù kan àti ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [1,600,000] Bíbélì jáde, kí wọ́n sì kó o ránṣẹ́. Iye yìí pọ̀ tó láti mú kí àwọn tó bá wá sí ìpàdé ọdọọdún rí Bíbélì náà gbà.
Bí Bíbélì yìí ṣe dùn-ún wò, tó sì lálòpẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ tó ń fúnni ní ìyè túbọ̀ fani mọ́ra. Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ́ tí arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gba ẹ̀dà Bíbélì tuntun náà, ó kọ̀wé pé, “Ní báyìí tá a ti ní ẹ̀dà Bíbélì tuntun, ó rọrùn fún mi láti lóye Bíbélì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”