Jámánì: Wọ́n pàtẹ ìwé síwájú ilé táwọn tí ogun lé kúrò nílùú dé sí
ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ
Ìròyìn—Nípa Àwọn Ará Wa
Wọ́n Wàásù fún Àwọn Tó Kó Wá Àtàwọn tí Ogun Lé Wá
Àwọn tó ń sọ oríṣiríṣi èdè ti pọ̀ gan-an lórílẹ̀-èdè Jámánì torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti kó wá síbẹ̀, ogun ló sì lé àwọn míì wá. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ètò Ọlọ́run dá àwọn àwùjọ kan àtàwọn akéde tí kò tíì di àwùjọ tí iye wọn jẹ́ igba ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [229] sílẹ̀ láàárín oṣù mẹ́sàn-án, èdè tí wọ́n ń sọ sì yàtọ̀ sí ti orílẹ̀-èdè Jámánì. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] akéde ló ń lọ sí ọgbọ̀n [30] kíláàsì tí wọ́n ti ń kọ́ èdè, àpapọ̀ èdè mẹ́tàlá [13] sì ni gbogbo wọn ń kọ́.
Àwọn ará máa ń wàásù fún àwọn tí ogun lé wá sí orílẹ̀-èdè náà láwọn ibi tí wọ́n dé sí. Ibi tó lé ní igba [200] làwọn ará pàtẹ ìwé sí, ìwé tí wọ́n sì ti fi síta tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé ogójì [640,000].
Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé káwọn ará ṣe àkànṣe ìwàásù láti ọsù May sí July ọdún 2016. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méje [700] akéde tó ń sọ èdè Lárúbáwá, tí wọ́n wá láti orílè-èdè méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló rìnrìn àjò lọ sí àgbègbè mẹ́wàá lórílẹ̀-èdè Austria àti Jámánì, kí wọ́n lè wàásù fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ń gbé níbẹ̀ tí wọ́n ń sọ èdè Lárúbáwá.
Àwọn Ẹyọ Owó Tó Wà Lójú Ọ̀nà
Ẹsẹ̀ ni àádọ́ta [50] akéde tó wà ní Ìjọ Faber’s Road Kriol lórílẹ̀-èdè Belize sábà máa ń fi rìn lọ sí ibi tí wọ́n á ti wàásù. Ọ̀pọ̀ àwọn ará yìí ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, àmọ́ wọ́n lawọ́, wọ́n sì máa ń wá bí wọ́n á ṣe ṣohun tó fi hàn bẹ́ẹ̀. Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, nígbà tí àwọn ará yìí ń wàásù láti ilé dé ilé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣa àwọn ẹyọ owó kéékèèké tó wà lójú ọ̀nà eléruku tí wọ́n ń gbà bí wọ́n ṣe ń lọ. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ látìgbà yẹn, tó bá sì ti di ìparí ọdún kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń pàdé pọ̀ kí wọ́n lè fọ àwọn ẹyọ owó náà, wọ́n á yọ ọ́ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n á sì kà á.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹyọ owó yẹn ò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí, torí igba [200] irú ẹ̀ ló máa jẹ́ owó dọ́là kan ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, síbẹ̀, lọ́dọọdún, àpapọ̀ iye tí wọ́n máa ń rí tó igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [225] owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Àwọn ará yìí máa ń pín owó náà sí ọ̀nà méjì, wọ́n á fi ìdá kan bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n á sì fi èyí tó kù ṣe ìtìlẹyìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé.
Àwọn Tó Gbọ́ Ọ Tó Mílíọ̀nù Mẹ́rin!
Ọ̀kan nínú àwọn ohun tó jẹ́ mánigbàgbé nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Bùrúńdì wáyé ní March 5, 2016, nígbà tí Arákùnrin Anthony Griffin, tó jẹ́ aṣojú oríléeṣẹ́ wá ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè náà. Wọ́n ṣe ètò kan lákànṣẹ lọ́jọ́ náà, ilé iṣẹ́ rédíò ìjọba lórílẹ̀-èdè náà sì bá wọn gbé ètò náà látìbẹ̀rẹ̀ dópin sáfẹ́fẹ́ káwọn ará nínú ìjọ lè gbọ́ ọ. Àwọn tó gbọ́ ètò náà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́rin!
Iṣẹ́ ńlá ni ètò tí wọ́n gbé sáfẹ́fẹ́ lórí rédíò yẹn ṣe, ohun tó dáa la sì gbọ́ lẹ́nu ọ̀pọ̀ èèyàn. Ọ̀kan lára àwọn amojú ẹ̀rọ tó gbé ètò náà sáfẹ́fẹ́ sọ pé, “Ẹ ní láti ṣerú ètò yìí sí i!” Òṣìṣẹ́ kan níléeṣẹ́ rédíò náà tún sọ pé: “Mo rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ máa [ṣe irú àwọn ètò yìí], torí ó dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa gbà là.” Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn bọ́ọ̀sì àti takisí tó ń gbérò ló yí rédíò wọn síbi tí wọ́n ti ń ṣe ètò náà.
Wọ́n Dáwọ́ Orin Dúró
Lọ́dún 2016, lọ́jọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, àwọn ará ní àwùjọ kékeré kan tó wà ní àdádó lórílẹ̀-èdè Nepal gbọ́ pé àwọn olórin kan fẹ́ ṣe àríyá ńlá nínú iléèwé tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbọ̀ngàn tí wọ́n gbà fún Ìrántí Ikú Kristi. Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú bá àwọn ará.
Ariwo máa ń pọ̀ gan-an nírú àwọn àríyá yìí. Láàárọ́ ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi, àwọn ará ń tún ibi tí wọ́n fẹ́ lò ṣe lọ́wọ́ ni ẹni tó dá àríyá náà sílẹ̀ bá wá bá wọn, ó ní, “Orin wa ò lè jẹ́ kẹ́ ẹ gbọ́ nǹkan kan níbí.”
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ àríyá náà lọ́sàn-án, bí wọ́n sì ṣe rò ó náà ló rí, ṣe lariwo gba afẹ́fẹ́ kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará lọ yá ẹ̀rọ gbohùngbohùn tó tóbi ju èyí tí wọ́n fẹ́ lò tẹ́lẹ̀, wọn ò gbọ́ nǹkan kan nígbà tí wọ́n dán makirofóònù wò bóyá ó ń ṣiṣẹ́. Inú wọn ò dùn rárá, síbẹ̀ wọ́n gbàdúrà gan-an lórí ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tó ku bí ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ Ìràntí Ikú Kristi, tí ọ̀pọ̀ àwọn ará sì ti ń dé, ni àwọn tó wà níbi àríyá náà bá dédé dáwọ́ orin dúró. Àṣé àwọn kan tó ti mutí níbẹ̀ ló ń bára wọn jà, ni àwọn ọlọ́pàá bá fòpin sí àríyá náà. Àwọn ará wá ṣe Ìrántí Ikú Kristi láìsí ariwo kankan, gbogbo nǹkan lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀, ìyẹn sì buyì kún ìpàdé náà gan-an.
Wọ́n Yin Ìkànnì jw.org
Aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni Giuseppe lórílẹ̀-èdè Ítálì. Iléeṣẹ́ kan táwọn èèyàn máa ń kàn sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tí tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́ ló ń bá ṣiṣẹ́, àmọ́ àtilé ló ti ń ṣiṣẹ́. Lóṣù May ọdún tó kọjá, òun àti àwọn bí àádọ́rin [70] tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ lọ síbi ìpàdé kan tí iléeṣẹ́ wọn pè, kí wọ́n lè jọ sọ̀rọ̀ nípa àwon àbá tuntun tó máa mú kí iṣẹ́ wọn dáa sí i. Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà ló bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, ó sọ pé àwọn ìkànnì kan wà tó dáa gan-an, ó sì máa wu àwọn kí ìkànnì iléeṣẹ́ àwọn rí bẹ́ẹ̀. Ó wá fi àpẹẹrẹ ìkànnì kan han àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ lójú tẹlifíṣọ̀n, ló bá di ìkànnì jw.org. Ó ya Giuseppe lẹ́nu gan-an nígbà tó rí abala ìbẹ̀rẹ̀ ìkànnì jw.org lójú tẹlifíṣọ̀n. Ọ̀gá iléeṣẹ́ náà sọ pé, “Ìkànnì tó dáa jù láyé rèé!” Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ìkànnì jw.org. Ó sọ pé òun fẹ́ràn bí àwọn ìlujá orí ìkànnì náà ò ṣe ṣòroó rí àti bí àwọn àwòrán orí ẹ̀ ṣe máa ń fani mọ́ra.
Giuseppe sọ pé, “Ó ya àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lẹ́nu nígbà tí wọ́n gbọ́ iye èdè tó wà lórí ìkànnì yìí. Nígbà tí ọ̀gá iléeṣẹ́ náà sọ̀rọ̀ tán, ọ̀gá tí mò ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ rẹ̀ sọ fún òun àti gbogbo àwọn tó wá sípàdé náà pé: ‘Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Giuseppe.’ Ni ọ̀gá iléeṣẹ́ bá sọ fún mi pé: ‘Iṣẹ́ ni ètò ẹ̀yin ajẹ́rìí ń ṣe o. Kò sí iléeṣẹ́ tàbí àjọ náà láyé yìí tí ìkànnì tẹ́ ẹ ṣe yìí ò ní máa wù. Wo adúrú iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe kí wọ́n lè máa gbé ìsọfúnni tuntun sórí ẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ kó máa rọrùn lò fáwọn èèyàn. Tún wo bí wọ́n á ṣe máa wo gbogbo ohun tó wà níbẹ̀ fínnífínní kó má bàa sí àṣìṣe.’ ” Giuseppe wá sọ pé, “Ojú tì mí díẹ̀, torí èmi kọ́ ni mo ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń yìn mí fún. Àmọ́ inú mi dùn gan-an pé ọ̀pọ̀ àwọn tí ò mọ nǹkan kan nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wá mọ̀ wá. Báyìí, mo ti ń bá àwọn kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ sọ̀rọ̀ Bíbélì déédéé, mo tiẹ̀ ti ń kọ́ mẹ́ta nínú wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Bí iléeṣẹ́ tí Giuseppe ń bá ṣiṣẹ́ ṣe ń lọ sórí jw.org láti wo bí ìkànnì náà ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni Giuseppe náà ń bá àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sọ̀rọ̀ Bíbélì.
Ó Ní Òun Ò Gbá Bọ́ọ̀lù Mọ́
Ajẹntínà: Jorge àtàwọn ará jọ ń gbá bọ́ọ̀lù
Ọ̀dọ́ ni Jorge tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà. Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2010 ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ ọmọ kíláàsì rẹ̀ ti kọ́kọ́ wàásù fún un. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jorge máa ń gbá bọ́ọ̀lù ní gbogbo àkókò yẹn. Ó mọ bọ́ọ̀lù gbá gan-an débi pé ó di ọ̀kan lára àwọn tó ń gbá bọ́ọ̀lù fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan tó lórúkọ. Ní April 2014, wọ́n fún un láǹfààní pé kó di ara ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan lórílẹ̀-èdè Jámánì. Inú ẹ̀ dùn gan-an pé òun máa to di èèyàn pàtàkì nídìí iṣẹ́ bọ́ọ̀lù gbígbá, ó sì gbà pé òun máa ṣe é. Nígbà tó ku ọjọ́ díẹ̀ tí Jorge máa rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù fún iṣẹ́ yìí, kóòṣì rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣebí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, àbí? Má ba ayé ara ẹ jẹ́ pẹ̀lú ìrìn àjò tó o fẹ́ lo yìí. Ṣó o rí i, nígbà tí mo ṣì kéré, Ẹlẹ́rìí Jèhófà lèmi náà. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan nílẹ̀ Éṣíà ní kí n wá di ara wọn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ṣèlérí pé wọ́n máa fún mi, gbogbo ẹ̀ ló sì wọ̀ mí lójú. Ni èmi àti ìdílé mi bá jọ rìnrìn àjò lọ síbẹ̀, àmọ́ bá a ṣe rò ó kọ́ ló rí, ṣe la pa dà wálé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.” Jorge sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tí kóòṣì sọ yìí wọ̀ mí lára gan-an, ni mo bá sọ pé mi ò lọ sílẹ̀ Yúróòpù mọ́. Lọ́dún 2015, mo di akéde Ìjọba Ọlọ́run, mo sì ṣèrìbọmi.”
Ó Rí Ìbùkún Gidi Gbà Lọ́fẹ̀ẹ́
Ní September 2015, wọ́n ṣe Àpéjọ Àgbègbè “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù!” ní ìlú Kampala, lórílẹ̀-èdè Uganda. Inú àwọn tó wá síbi àpéjọ náà dùn gan-an nígbà tí Mark Sanderson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Luganda.
Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan sọ pé: “Bíbélì tó rẹwà tí mo rí gbà yìí múnú mi dùn gan-an! Lásìkò tá a fẹ́ ṣe àpéjọ yẹn, póòpù ń bọ̀ wá sí orílẹ̀-èdè Uganda, àwọn èèyàn sì ń múra sílẹ̀ dè é. Kí àwọn kan lè fi àbẹ̀wò yẹn pawó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ta ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà tí wọ́n sọ pé Ọlọ́run ti fi ìbùkún sí, ọgbọ̀n [30] owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni wọ́n sì ń tà á. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ gbàbùkún, síbẹ̀ wọn ò lówó lọ́wọ́. Àmọ́ èmi rí ìbùkún gidi gbà lọ́fẹ̀ẹ́ ní tèmi. Gbogbo àwọn tó wá sí àpéjọ náà ni Jèhófà fún ní ìbùkún yẹn, ó wá kù sọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan láti fi ohun tó bá wù ú látọkàn wá ṣe ọrẹ. Lójoojúmọ́, tí mo bá ti ń ka ọ̀rọ̀ Jèhófà lédè àbínibí mi, tí mo sì ń túbọ̀ mọ Jèhófà, mo máa ń rọ́wọ́ rẹ̀ láyé mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún mi ní Bíbélì.”
Ṣé Ibi Táwọn Ẹ̀dá Abẹ̀mí Ń Gbé Ni Wọ́n Ti Ń Tẹ̀wẹ́ Lóòótọ́?
Lórílẹ̀-èdè Kóńgò (Kinshasa), àwọn pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì lágbègbè kan gbìyànjú láti fẹnu ba ìkànnì wa, ìyẹn www.jw.org jẹ́, wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn pé ibi táwọn ẹ̀dá abẹ̀mí ń gbé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń tẹ àwọn ìwé wọn. Kí wọ́n lè rí nǹkan ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn, wọ́n sọ pé lẹ́tà “www” tó wà lára ìkànnì wa bá nọ́ńbà 666 tó wà nínú ìwé Ìṣípayá mu. (Ìṣí. 13:18) Torí èyí, àwọn kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀ sọ pé àwọn ò kẹ́kọ̀ọ́ mọ́.
Tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fi ọ̀rọ̀ yìí sádùúrà, wọ́n wá pe àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ọkọ tàbí ìyàwó wọn pé kí wọ́n wá sí ilé àwọn. Tọkọtaya mẹ́ta sì wá. Wọ́n kọ́kọ́ jọ jẹun, lẹ́yìn oúnjẹ, tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà fi fídíò Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—A Ṣètò Wa Láti Wàásù Ìhìn Rere hàn wọ́n. Ohun tí wọ́n rí nínú fídíò yẹn jẹ́ kí wọ́n rí i pé irọ́ lásánlàsàn ni gbogbo ohun tí wọ́n gbọ́ nípa ibi tá a ti ń tẹ àwọn ìwé wa. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ọkọ obìnrin kan lára àwọn tí tọkọtaya náà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ fún wọn ní ọgọ́rùn-ún [100] owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ó ní òun fi ṣe ọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé, ó sì ní kí wọ́n bá òun fi jíṣẹ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Bí Wọ́n Ṣe Ń Kọ́ Orin Tuntun
Ó máa ń wu àwọn ará ní ibì kan tó wà ládàádó lórílẹ̀-èdè Papua New Guinea láti kọ́ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run tuntun, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí Íńtánẹ́ẹ̀tì níbẹ̀. Torí náà, ṣe ni Ìjọ Mundip máa ń rán arákùnrin kan lọ sí ìlú tó sún mọ́ wọn jù. Ìrìn wákàtí méjì ló máa ń rìn kó tó rí bọ́ọ̀sì wọ̀, bọ́ọ̀sì ọ̀hún sì máa rin ìrìn wákàtí méjì kó tó débi tó ń lọ. Tó bá wá débẹ̀, á lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, á sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ orin tuntun náà sínú ìwé kan. Tó bá ti wá pa dà sílé, á kọ ọ́ sójú pátákó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kí gbogbo èèyàn lè rí i. Àwọn ará ìjọ máa wá dà á kọ kí wọ́n lè máa lò ó nípàdé. Inú wọn ń dùn gan-an pé àwọn àtàwọn ará wọn kárí ayé jọ ń jọ́sìn Jèhófà bí wọ́n ṣe jọ ń kọrin nípàdé.