ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwhf àpilẹ̀kọ 20
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ilé Bá Sú Ọmọ Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ilé Bá Sú Ọmọ Mi?
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun táwọn òbí kan ti kíyè sí
  • Kí lo wá lè ṣe tí ilé bá ń sú àwọn ọmọ rẹ?
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Nǹkan Bá Tojú Sú Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ǹjẹ́ Ìwàláàyè Títí Láé Nínú Párádísè Máa Súni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àǹfààní Tó Wà Nínú Eré Táá Mú Kí Ọmọdé Ronú
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
    Jí!—2012
Àwọn Míì
Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
ijwhf àpilẹ̀kọ 20
Ìyá kan ń wo ọmọ ẹ̀ tí ilé sú bí ọmọ náà ṣe ń wòta nídìí tábìlì tó dá jókòó sí.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ilé Bá Sú Ọmọ Mi?

Ọmọ rẹ ò jáde kúrò nílé látàárọ̀, kò sì rí nǹkan ṣe. Ló bá sọ fún ẹ pé “ilé ti sú mi jàre.” Kó o tó sọ fún un pé kó lọ wo tẹlifíṣọ̀n tàbí kó lọ gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà tó fẹ́ràn, àwọn nǹkan kan wà tó yẹ kó o mọ̀.

Ohun táwọn òbí kan ti kíyè sí

  • Irú eré ìnàjú àti iye àkókò tó ń lò nídìí ẹ̀ lè jẹ́ kílé sú ọmọ rẹ. Bàbá kan tó ń jẹ́ Robert sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé tẹlifíṣọ̀n làwọn ọmọ kan máa ń wò ṣáá tàbí kó jẹ́ géèmù orí kọ̀ǹpútà ni wọ́n máa ń gbá ní gbogbo ìgbà, ilé á máa sú irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ torí ohun kan náà ni wọ́n ń ṣe ṣáá.”

    Ìyàwó ẹ̀ tó ń jẹ́ Barbara gbà pẹ̀lú ohun tọ́kọ ẹ̀ sọ. Ó ní: “Ó gba ìrònú àti ìsapá gan-an kẹ́nì kan tó lè gbádùn ara ẹ̀, kì í sì í tètè yé èèyàn pé ohun tó dáa ni òun ń ṣe. Èyí kì í rọrùn fáwọn ọmọ tó máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí tẹlifíṣọ̀n tàbí géèmù.”

  • Wọ́n máa ń rẹ̀wẹ̀sì tí wọ́n bá ń wo àwọn ohun táwọn kan gbé sórí ìkànnì. Ilé sábà máa ń sú wọn tí wọ́n bá ń wo àwọn fọ́tò tàbí fídíò táwọn ọ̀rẹ́ wọn ń gbé sórí ìkànnì àjọlò. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Beth sọ pé: “Ó máa ń rọrùn láti ronú pé, ‘Gbogbo èèyàn ló ń gbádùn ara wọn yìí, èmi kàn jókòó sílé níbí.’”

    Tẹ́nì kan bá lo ọ̀pọ̀ àkókò lórí ìkànnì àjọlò, ìyẹn ò sọ pé kí inú irú ẹni bẹ́ẹ̀ dùn, ṣe ló máa ń jẹ́ kí nǹkan túbọ̀ sú wọn. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Chris sọ pé: “Ìkànnì àjọlò lè jẹ́ kọ́wọ́ ẹnì kan dí lóòótọ́ àmọ́ béèyàn bá ṣe ń gbé fóònù sílẹ̀ báyìí, á wá rí i pé ṣe ni òun kàn fi àkókò ṣòfò lásán.”

  • Ó lè jẹ́ kí wọ́n ronú nǹkan tuntun. Ìyá kan tó ń jẹ́ Katherine sọ pé tí ilé bá sú àwọn ọmọ, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n ronú àrà tuntun tí wọ́n lè dá kínú wọn lè dùn. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Wọ́n lè mú bébà, kí wọ́n sì fi ṣe mọ́tò tàbí ọkọ̀ ojú omi tàbí ọkọ̀ òfúrufú pàápàá. Wọ́n lè da aṣọ ìbora bo orí àwọn àga ìjókòó lọ́nà táá jẹ́ kó dà bíi yàrá tí wọ́n á ti máa ṣeré.”

    Sherry Turkle tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá sọ pé tí nǹkan bá ń sú ẹnì kan, “ṣe ló ń fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti ronú nǹkan tuntun.”a Torí náà, a ò lè sọ pé ó burú tí nǹkan bá tojú sú ẹ. Kódà, ìwé Disconnected sọ pé: “Ó dáa kí nǹkan máa tojú súni torí ó wúlò fún ọpọlọ wa bí eré ìmárale ṣe wúlò fún àwọn iṣan ara wa.”

Òótọ́ ibẹ̀: Mọ̀ pé kì í ṣe ìṣòro tí nǹkan bá ń sú àwọn ọmọ ẹ àmọ́ ó jẹ́ àǹfààní láti ronú oríṣiríṣi nǹkan tuntun tí wọ́n lè ṣe.

Kí lo wá lè ṣe tí ilé bá ń sú àwọn ọmọ rẹ?

  • Tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ káwọn ọmọ ẹ lọ ṣeré níta. Barbara, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tún sọ pé: “Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni oòrùn àti atẹ́gùn tó tura lè ṣe lára èèyàn tí nǹkan bá ti súni. Táwọn ọmọ wa bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣeré níta báyìí, ìrònú wọn yí padà nìyẹn!”

    Ìlànà Bíbélì: “Ohun gbogbo ni àkókò wà fún, . . . ìgbà rírẹ́rìn-ín àti ìgbà títa pọ́n-ún pọ́n-ún kiri.”​—Oníwàásù 3:​1, 4, àlàyé ìsàlẹ̀.

    Rò ó wò ná: Ṣé mo lè fún àwọn ọmọ mi láǹfààní láti máa ṣeré níta lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? Tí kò bá ṣeé ṣe kí wọ́n ṣeré níta, àwọn nǹkan míì wo ni wọ́n lè ṣe nínú ilé tó yàtọ̀ sáwọn ohun tí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀?

  • Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ronú láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Ìyá kan tó ń jẹ́ Lillian sọ pé: “Wọ́n lè bá àwọn àgbàlagbà roko ilé wọn, wọ́n lè bá wọn gbálẹ̀, wọ́n lè bá wọn se oúnjẹ tàbí kí wọ́n lọ kí wọn nílé. Ojúlówó ayọ̀ ni ẹni tó bá ń ran àwọn míì lọ́wọ́ máa ń ní.”

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹni tó bá lawọ́ máa láásìkí, ẹni tó bá sì ń mára tu àwọn míì, ara máa tu òun náà.”​—Òwe 11:25.

    Rò ó wò ná: Báwo lo ṣe lè jẹ́ káwọn ọmọ ẹ rí ayọ̀ tó máa ń wà nínú ríran àwọn míì lọ́wọ́?

  • Fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn. Tó o bá ń sọ bọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe ń fún ẹ láyọ̀ fáwọn ọmọ ẹ, ó máa nípa rere lórí wọn. Ìyá kan tó ń jẹ́ Sarah sọ pé: “Tá a bá ń jẹ́ kó dà bíi pé àwa náà ò gbádùn ayé wa, ńṣe ni nǹkan á túbọ̀ máa sú àwọn ọmọ wa. Àmọ́ tínú wa bá ń dùn, tá à ń láyọ̀, ohun kan náà lá máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ wa.”

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn máa ń jẹ àsè nígbà gbogbo.”​—Òwe 15:15.

    Rò ó wò ná: Kí ni mo máa ń sọ létí àwọn ọmọ mi nípa àwọn nǹkan tí mò ń ṣe lójoojúmọ́? Tí ilé bá sú èmi náà, kí làwọn ọmọ mi ń rí tí mo máa ń ṣe láti yanjú ẹ̀?

Ohun tó o lè ṣe: Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ kọ àwọn nǹkan tuntun tí wọ́n lè ṣe síbì kan. Ìyá kan tó ń jẹ́ Allison sọ pé: “A ní àpótí kan tí ìdílé wa máa ń ju àwọn àbá tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa bá ní sí.”

a Látinú ìwé Reclaiming Conversation.

“Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀”

Michael àti Tammy.

“Táwọn ọmọ bá sọ pé ilé sú àwọn, má sọ fún wọn pé kí wọ́n lọ wo tẹlifíṣọ̀n tàbí kí wọ́n lọ fi fóònù wọn ṣeré o. Ohun tí wọ́n ń fọgbọ́n sọ ni pé, mọ́mì, dádì, ó ti yá ẹ jẹ́ ká jọ sọ̀rọ̀. Àǹfààní ńlá nìyẹn sì máa ń jẹ́ láti bá wọn sọ̀rọ̀!”​—Michael àti ìyàwó ẹ̀ Tammy.

Àtúnyẹ̀wò: Kí lo lè ṣe tí ilé bá sú àwọn ọmọ rẹ?

  • Tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ lọ ṣeré níta. Tí atẹ́gùn tó tura bá fẹ́ sí àwọn ọmọ ẹ lára, ó máa jẹ́ kára tù wọ́n, wọ́n á ronú jinlẹ̀, wọ́n á sì lè ṣe àwọn nǹkan tuntun.

  • Ran àwọn ọmọ ẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ronú bí wọ́n ṣe máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Tí wọ́n bá ń ṣe ran àwọn míì lọ́wọ́, wọ́n á ní ojúlówó ayọ̀, nǹkan ò sì ní máa fi bẹ́ẹ̀ sú wọn.

  • Fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn. Tí ìwọ náà bá ń láyọ̀ lójoojúmọ́, ó ṣeé ṣe kí ayọ̀ náà ran àwọn ọmọ rẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́