ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 81
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Nǹkan Bá Tojú Sú Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Nǹkan Bá Tojú Sú Mi?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ilé Bá Sú Ọmọ Mi?
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ǹjẹ́ Ìwàláàyè Títí Láé Nínú Párádísè Máa Súni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
    Jí!—2012
  • Ǹjẹ́ Ó Wù Ọ́ Láti Wà Láàyè Títí Láé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 81
Ọ̀dọ́kùnrin kan ní oríṣiríṣi ẹ̀rọ ìgbàlódé, àmọ́ ṣe ló dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀, tó ń ka àjà

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Nǹkan Bá Tojú Sú Mi?

Àwọn kan gbà pé kò sóhun tó ń súni tó kí òjò ká èèyàn mọ́lé lọ́sàn-án ọjọ́ kan, kó má lè jáde nílé, kó má sì rí nǹkan kan ṣe. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Robert sọ pé, “Nírú àkókò yẹn, ṣe ni màá kàn jókòó sójú kan, tí mi ò ní mohun tí màá ṣe.”

Ṣó ti ṣe ẹ́ rí? Tírú ẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́!

  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  • Ohun tó o lè ṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  • Lílo ẹ̀rọ ìgbàlódé lè má ṣèrànwọ́.

    O lè lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lóòótọ́ kí ọjọ́ lè tètè lọ, àmọ́ ó lè má jẹ́ kó o ronú dáadáa, á sì jẹ́ kí nǹkan túbọ̀ sú ẹ. Jeremy tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21) sọ pé, “Wàá rí i pé ṣe lo kàn ranjú mọ́ fóònù tàbí kọ̀ǹpútà ẹ lásán ni, o ò ní lè dánú rò.”

    Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Elena gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Ó ní, “Ó níbi táwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé lè ṣèrànwọ́ dé. Kì í jẹ́ kéèyàn ronú nípa àwọn nǹkan gidi tó ń lọ láyìíká ẹni, torí ẹ̀ ló fi jẹ́ pé tó o bá ṣe ń gbé fóònù ẹ sílẹ̀ báyìí, ṣe ni gbogbo ẹ̀ á túbọ̀ sú ẹ!”

  • Ojú tó o bá fi wò ó ṣe pàtàkì.

    Ṣé ti pé èèyàn ní nǹkan púpọ̀ láti ṣe túmọ̀ sí pé nǹkan ò lè sú onítọ̀hún? Ó sinmi lórí bó o bá ṣe fẹ́ràn ohun tó ò ń ṣe tó. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń Karen rántí pé: “Iléèwé máa ń sú mi gan-an, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àtàárọ̀ dalẹ́ ni mo máa ń ríṣẹ́ ṣe. Tó ò bá fẹ́ kí nǹkan sú ẹ, àfi kí ọkàn ẹ wà níbi ohun tó ò ń ṣe.”

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé . . . Tó ò bá rí nǹkan ṣe, kì í ṣe ìṣòro, àǹfààní ló jẹ́ láti ronú oríṣiríṣi nǹkan gidi tó o lè ṣe.

Ewéko tó dà bíi pé guitar, gègé àti bébà, àti irinṣẹ́ ayàwòrán ń hù jáde lára rẹ̀

Ṣe ni àkókò tó o ní dà bí ilẹ̀ tó lọ́ràá, tó o bá lò ó bó ṣe yẹ, wàá rí àwọn nǹkan tuntun fi ṣe

Ohun tó o lè ṣe

Nífẹ̀ẹ́ sí oríṣiríṣi nǹkan. O lè lọ́rẹ̀ẹ́ tuntun tàbí kó o bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ nǹkan tuntun. Ṣèwádìí lórí àwọn nǹkan kan tó ò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Nǹkan kì í sábà sú àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n bá tiẹ̀ dá wà, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ àwọn míì!

Ìlànà Bíbélì: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é.”​—Oníwàásù 9:​10.

“Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Mandarin Chinese, bí mo sì ṣe ń fi kọ́ra lójoojúmọ́ ti jẹ́ kí n rí i pé ọjọ́ pẹ́ tí mo ti ṣerú ẹ̀ gbẹ̀yìn. Ó máa ń wù mí kí n ní iṣẹ́ kan tí mò ń ṣe. Ó máa ń jẹ́ kí n pọkàn pọ̀, ó sì máa ń jẹ́ kí n fi àkókò mi ṣe nǹkan gidi.”​—Melinda.

Mọ ìdí tó o fi ń ṣe nǹkan kan. Tó o bá mọ ìdí tó o fi ń ṣe nǹkan kan, á túbọ̀ wù ẹ́ láti máa ṣe é. Kódà, iṣẹ́ iléèwé ẹ là má fi bẹ́ẹ̀ sú ẹ tó o bá mọ ìdí tó o fi ń ṣe é.

Ìlànà Bíbélì: “Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó . . . jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.”​—Oníwàásù 2:​24.

“Nígbà tó kù díẹ̀ kí n parí iléèwé, wákàtí mẹ́jọ ni mo fi ń kàwé lóòjọ́ torí pé mo ti jẹ gbèsè àwọn ìwé kan to yẹ kí n ti kà sílẹ̀. Àbẹ́ ẹ rò pó máa sú mi? Kò tiẹ̀ sú mi rárá torí mo mọ ohun tí mò ń lé. Ohun tó máa jẹ́ àbájáde ẹ̀ ni mo gbájú mọ́, ìyẹn ọjọ́ tí mo máa kẹ́kọ̀ọ́ yege, òun ló sì ṣí mi lórí tí mo fi tẹra mọ́ ìwé kíkà.”​—Hannah.

Gba kámú àwọn nǹkan kan tó ò lè yí pa dà. Àwọn iṣẹ́ kan tó máa ń gbádùn mọ́ni pàápàá máa ń gba pé kó o ṣe àwọn nǹkan kan léraléra. Ìgbà míì sì wà táwọn ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ ẹ gan-an máa yẹ àdéhùn, tí wọ́n á já ẹ sí kolobo. Dípò kó o wá jẹ́ kíyẹn kó ìbànújẹ́ bá ẹ, gbìyànjú láti fi ojú tó tọ́ wò ó.

Ìlànà Bíbélì: “Ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ yá gágá a máa jẹ àsè nígbà gbogbo.”​—Òwe 15:15.

“Ọ̀rẹ́ mi kan sọ fún mi pé kí n máa gbádùn àsìkò tí mo bá dá wà. Ó ní gbogbo wa ló ṣe pàtàkì ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà lèèyàn á máa wà láàárín àwọn míì, ìgbà míì máa wà téèyàn máa dá wà. Kì í ṣe torí òní nìkan, torí ọ̀la ni.”​—Ivy.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Hannah

“Tẹ́lẹ̀, mo máa ń jowú àwọn tó dà bíi pé wọ́n ń gbádùn ìgbésí ayé wọn. Ìgbà tó yá ni mo wá rí i pé èèyàn bíi tèmi làwọn náà, ohun tí wọ́n kàn fi àkókò wọn ṣe ló yàtọ̀. Èmi náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi àkókò mi ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn nǹkan tuntun, mo sì ṣèwádìí lórí àwọn nǹkan kan tó gbádùn mọ́ mi. Tí ìmọ̀ tó o ní nípa ayé yìí bá ṣe pọ̀ tó ni wàá túbọ̀ máa gbádùn ẹ̀, tí wàá sì fẹ́ máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Kò wá ní sí ohun tó ń jẹ́ pé nǹkan ń sú ẹ.”​—Hannah.

Caleb

“Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, ṣe ni mo máa ń gbá géèmù tí nǹkan bá ti tojú sú mi. Àmọ́ bí mo ṣe ń dàgbà ni mo rí i pé ṣe lẹni tó bá ń fi gbogbo àkókò gbá géèmù ń fàkókò ẹ̀ ṣòfò. Tó o bá ń gbá a lọ́wọ́, wàá rò pé ò ń ṣe nǹkan gidi kan ni, àmọ́ tó o bá gbá a tán, wàá rí i pé o ò rí nǹkan kan gbé ṣe. Nígbà tó yá, mo rí àwọn nǹkan gidi míì fàkókò mi ṣe.”​—Caleb.

Micaela

“Lójú mi, ó máa ń dà bíi pé ojoojúmọ́ ni ọjọ́ ń fà bí ìgbín, tí nǹkan sì ń sú mi, àmọ́ nígbà tó yá, mo rí i pé tí mo bá fẹ́ káwọn èèyàn sún mọ́ mi, àfi kémi náà sún mọ́ wọn. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì ṣèrànwọ́ gan-an. Ní báyìí, ṣe ni mo máa ń dúpẹ́ fún àwọn ìgbà tí mo bá dá wà, torí ó ṣọ̀wọ́n kí ń dá wà báyìí!”​—Micaela.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́