ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 29
  • Bó O Ṣe Lè Borí Àníyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Borí Àníyàn
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn àbá tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣàníyàn jù
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dẹ́kun Dídààmú Kọjá Ààlà?
    Jí!—2001
  • Má Ṣe Máa Ṣàníyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Mátíù 6:34​—‘Ẹ Má Ṣàníyàn Nípa Ọ̀la’
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • 2 Ó Ń Jẹ́ Ká Borí Ìṣòro
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 29
Àgbàlagbà tó ní ìdààmú ọkàn.

Bó O Ṣe Lè Borí Àníyàn

Tí àníyàn bá ti pọ̀ jù, ó lè ṣe àkóbá fún ìlera rẹ, ó sì lè fa ìdààmú ọkàn. Kódà, ó tún lè dá ìṣòro mìíràn sílẹ̀, tó máa le ju ìṣòro àkọ́kọ́ tó fa ìrònú fún ẹ.

Àwọn àbá tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣàníyàn jù

  • Ojú ẹni tí inú ẹ̀ ò dùn.

    Má ṣe máa fetí sí ìròyìn burúkú ní gbogbo ìgbà. O ò nílò láti mọ gbogbo ìsọfúnni nípa àwọn wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀. Tí o bá ń fetí sí ìròyìn burúkú ní gbogbo ìgbà, ó lè mú kí ẹ̀rù máa bà ọ́, kó o sì sọ ìrètí nù.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ̀mí tí ìdààmú bá máa ń tánni lókun.”​—Òwe 17:22.

    “Ó rọrùn láti sọ gbígbọ́ àwọn ìròyìn tuntun dàṣà, àmọ́ kì í ṣe àṣà tó dáa. Tí mo bá dín ìròyìn tí mò ń gbọ́ kù, àníyàn mi náà máa ń dín kù.”​—John.

    Ronú nípa rẹ̀: Ṣé dandan ni kó o gbọ́ gbogbo ìròyìn tuntun?

  • Aago.

    Ṣètò àsìkò rẹ, kí o sì tẹ̀ lé e. Gbìyànjú láti ní àsìkò kan pàtó tí wàá máa jí, jẹun, ṣe iṣẹ́ ilé, tí wàá sì máa sùn. Tó o bá ní ètò fún àwọn ohun tó ò ń ṣe, ó máa mú kí ìgbé ayé rẹ wà létòlétò, èyí sì máa dín àníyàn rẹ kù.

    Ìlànà Bíbélì: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.”​—Òwe 21:5.

    “Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 bẹ̀rẹ̀, mi ò tẹ̀ lé ètò tí mo ṣe mọ́, èyí wá mú kí n máa lo àsìkò tó pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ nídìí eré ìnàjú. Mo fẹ́ lo àsìkò mi lọ́nà tó dáa, nítorí èyí, mo ṣètò bí màá ṣe máa ṣe àwọn ojúṣe mi ojoojúmọ́.”​—Joseph.

    Ronú nípa rẹ̀: Ṣé o ti ṣètò àsìkò rẹ lọ́nà tó máa mú kó o lè ṣe àwọn nǹkan pàtàkì ní ojoojúmọ́?

  • Ojú ẹni tó láyọ̀.

    Ní èrò rere. Tó o bá ń ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan tí ò tíì ṣẹlẹ̀ tàbí nǹkan burúkú tó lè ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú, ọkàn rẹ ò ní balẹ̀. O ò ṣe ronú nípa nǹkan méjì sí mẹ́ta tó o lè dúpẹ́ fún?

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa dúpẹ́.”​—Kólósè 3:15.

    “Kíka Bíbélì máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti yẹra fún ìròyìn búburú, ó sì máa ń jẹ́ kí n máa ronú ohun rere. Ó lè dà bí ohun tí ò tó nǹkan, àmọ́ ó máa ń wúlò gan-an!”​—Lisa.

    Ronú nípa rẹ̀: Ṣé o sábà máa ń darí gbogbo àfiyèsí rẹ sórí àwọn nǹkan tí kò dáa tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ, tí wàá sì gbàgbé àwọn nǹkan dáadáa?

  • Ẹ̀bùn.

    Ronú nípa àwọn ẹlòmíì. Tí àníyàn bá ti gbà ẹ́ lọ́kàn, o lè fẹ́ dá wà, dípò kó o jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ronú nípa bó o ṣe lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.

    Ìlànà Bíbélì: “Bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.”​—Fílípì 2:4.

    “Inú mi máa ń dùn tí mo bá ṣe nǹkan dáadáa fún àwọn ẹlòmíì. Tí mo bá ń ṣe àwọn nǹkan tó máa mú inú àwọn ẹlòmíì dùn, àníyàn tèmi náà máa ń dín kù. Kódà, mi ò tiẹ̀ ní ráyè ṣàníyàn mọ́.”​—Maria.

    Ronú nípa rẹ̀: Ṣé o mọ àwọn èèyàn tí wọ́n lè nílò àfikún ìrànlọ́wọ́, ọ̀nà wo lo lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́?

  • Ọkàn.

    Ní ìlera tó dáa. Máa ṣe eré ìmárale tí ó tó, kí o sì máa sinmi. Jẹ oúnjẹ aṣaralóore. Tí o bá ń bójú tó ìlera rẹ, o ò ní máa fìgbà gbogbo ronú lórí àwọn ìṣòro, wàá sì gbà pé nǹkan ṣì máa dáa.

    Ìlànà Bíbélì: “Àǹfààní . . . wà nínú eré ìmárale.”​—1 Tímótì 4:8.

    “Èmi àti ọmọ mi ò lè rìn síbí rìn sọ́hùn-ún bí a ṣe fẹ́ níta. Nítorí èyí, a ṣètò láti máa ṣe eré ìmárale nínú ilé wa. Èyí mú kí inú wa dùn sí i, àjọṣe wa sì ti dára sí i.”​—Catherine.

    Ronú nípa rẹ̀: Ǹjẹ́ o nílò láti jẹ oúnjẹ aṣaralóore sí i, kí o sì túbọ̀ máa ṣe eré ìmárale, kí ìlera rẹ lè sunwọ̀n sí i?

Ní àfikún sí fífi àwọn àbá yìí sílò, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ti jàǹfààní nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlérí tó ṣeé gbára lé tó wà nínú Bíbélì nípa ọjọ́ ọ̀la tó dára. Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?”

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá ń ṣàníyàn

Sáàmù 55:22: “Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró.”a

Ohun tó túmọ̀ sí: A lè ju ẹrù wa sí Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà. Lára àwọn ẹrù yẹn sì ni àwọn àníyàn wa. Tí a bá ń gbàdúrà, ṣe ni à ń bá Ẹlẹ́dàá wa sọ̀rọ̀ ní ti gidi. Ẹni tó ń gbé wa ró, tó sì ń “tù wá nínú nínú gbogbo àdánwò wa.”​—2 Kọ́ríńtì 1:​3, 4.

Òwe 12:25: “Àníyàn inú ọkàn [èèyàn] máa ń mú kó rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ ọ̀rọ̀ rere máa ń mú kó túra ká.”

Ohun tó túmọ̀ sí: A ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n lè fún wá níṣìírí, kí wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún wọn.

Mátíù 6:27: “Èwo nínú yín ló lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwàláàyè rẹ̀, tó bá ń ṣàníyàn?”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ṣíṣe àníyàn kò wúlò. Kò lè ràn wá lọ́wọ́, kò sì lè yanjú ìṣòro, ṣe ló tún máa ń fi kún ìṣòro wa.

Mátíù 6:​31, 32: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ wá sọ pé, ‘Kí la máa jẹ?’ tàbí, ‘Kí la máa mu?’ tàbí, ‘Kí la máa wọ̀?’ . . . Baba yín ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan yìí.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Jèhófà Ọlọ́run mọ àwọn ohun tá a nílò bí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé, kí àwa fúnra wa tó mọ̀ pé a nílò rẹ̀.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.​—Sáàmù 83:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́