ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbv àpilẹ̀kọ 4
  • Mátíù 6:34​—‘Ẹ Má Ṣàníyàn Nípa Ọ̀la’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mátíù 6:34​—‘Ẹ Má Ṣàníyàn Nípa Ọ̀la’
  • Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtumọ̀ Mátíù 6:34
  • Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Mátíù 6:34
  • Má Gbàgbé Ọ̀la
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Má Ṣe Máa Ṣàníyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Àníyàn?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dẹ́kun Dídààmú Kọjá Ààlà?
    Jí!—2001
Àwọn Míì
Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
ijwbv àpilẹ̀kọ 4

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Mátíù 6:34—‘Ẹ Má Ṣàníyàn Nípa Ọ̀la’

“Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.”​—Mátíù 6:​34, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

“Ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ọla, ọla ni yio ṣe aniyan ara rẹ̀. Buburu ti ojọ tó fún u.”​—Mátíù 6:34, Bíbélì Mímọ́.

Ìtumọ̀ Mátíù 6:34

Jésù fi ọ̀rọ̀ yìí dá àwọn tó ń tẹ́tí sí i lójú pé wọn ò ní láti ṣàníyàn jù nípa àwọn ìṣòro tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́la. Kàkà bẹ́ẹ̀, á ṣe wọ́n láǹfààní tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn ìṣòro ìgbésí ayé bí wọ́n ṣe ń yọjú lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.

Jésù ò ní ká má ronú nípa ọ̀la tàbí ká má ṣe ètò kankan fún ọjọ́ iwájú wa. (Òwe 21:⁠5) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé ká yẹra fún àníyàn àṣejù tàbí ìrònú àròjù nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Irú àwọn àníyàn yìí lè mú ká pàdánù ayọ̀ wa, tá ò sì ní lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó yẹ ká ṣe mọ́. Tá a bá ń ṣàníyàn lónìí, ìyẹn ò ní káwọn ìṣòro ọjọ́ iwájú yanjú. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ohun tá à ń ṣàníyàn nípa wọn kì í sábà ṣẹlẹ̀, ó sì lè má burú tó bá a ṣe rò.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Mátíù 6:34

Ara Ìwàásù Jésù Lórí Òkè tó wà ní Mátíù orí 5 sí 7 ni ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ yìí. Nínú ìwàásù yẹn, Jésù ṣàlàyé pé táa bá ń ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ, ìyẹn kò lè mú kí ìgbésí ayé wa dáa sí i tàbí kó mú kí ẹ̀mí wa gùn sí i. (Mátíù 6:27) Ó tún sọ pé tí a bá fi Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wa, kò ní sí ìdí fún wa láti ṣàníyàn àṣejù nípa ọjọ́ ọ̀la. Ọlọ́run ń bójú tó àwọn ewéko àti ẹranko, ó sì dájú pé á bójú tó àìní àwọn tó ń sìn ín náà.​—Mátíù 6:​25, 26, 28-33.

Ka Mátíù orí 6 pẹ̀lú àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, àwọn atọ́ka etí ìwé àti àwọn àwòrán.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́