ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 10/15 ojú ìwé 4-7
  • Má Gbàgbé Ọ̀la

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Gbàgbé Ọ̀la
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Dẹ́kun Ṣíṣàníyàn”
  • Baba Yín Mọ Ohun Tẹ́ Ẹ Nílò
  • ‘Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Wíwá Ìjọba Ọlọ́run Lákọ̀ọ́kọ́’
  • “Kí Ìjọba Rẹ Dé”
  • Ẹ To Ìṣúra Jọ Pa Mọ́ ní Ọ̀run
  • Kí Ló Yẹ Kó O Ṣe?
  • Mátíù 6:34​—‘Ẹ Má Ṣàníyàn Nípa Ọ̀la’
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Má Ṣe Máa Ṣàníyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Àníyàn?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àníyàn
    Jí!—2016
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 10/15 ojú ìwé 4-7

Má Gbàgbé Ọ̀la

NÍGBÀ tí Jésù Kristi ń ṣe ìwàásù pàtàkì kan lẹ́bàá òkè ní Gálílì, ó sọ̀rọ̀ kan. Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe kà nínú Bibeli Mimọ ni pé: “Ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ọla; ọla ni yio ṣe aniyan ohun ara rẹ̀.”—Mátíù 6:34.

Kí lo rò pé gbólóhùn náà ‘ọ̀la ni yóò ṣe àníyàn ohun ara rẹ̀’ túmọ̀ sí? Ṣé ohun tó ń sọ ni pé kó o máa jayé òní nìkan kó o sì gbàgbé nípa ọ̀la? Ṣé irú èrò bẹ́ẹ̀ bá ohun tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gbà gbọ́ mu?

“Ẹ Dẹ́kun Ṣíṣàníyàn”

Ka ọ̀rọ̀ Jésù yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú Mátíù 6:25-32. Lára ohun tó sọ ni pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀. . . . Ẹ fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí wọn kì í fún irúgbìn tàbí ká irúgbìn tàbí kó jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́; síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. . . . Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀? Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní ti ọ̀ràn ti aṣọ, èé ṣe tí ẹ fi ń ṣàníyàn? Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n lára àwọn òdòdó lílì pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú . . . Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.”

Jésù wá fi ìmọ̀ràn méjì kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ìmọ̀ràn àkọ́kọ́ ni: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba [Ọlọ́run] àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” Èkejì ni: “Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.”—Mátíù 6:33, 34.

Baba Yín Mọ Ohun Tẹ́ Ẹ Nílò

Ǹjẹ́ o rò pé ńṣe ni Jésù ń sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, títí kan àwọn tó jẹ́ àgbẹ̀, pé kí wọ́n má wulẹ̀ ṣèyọnu pé àwọn ń ‘fún irúgbìn tàbí ká irúgbìn tàbí kó irúgbìn jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́’ ni? Ṣé ó ní kí wọ́n má wulẹ̀ “ṣe làálàá” mọ́ láti máa “rànwú” láti fi rán aṣọ tí wọ́n máa wọ̀ ni? (Òwe 21:5; 24:30-34; Oníwàásù 11:4) Rárá o. Bí wọn ò bá ṣiṣẹ́ mọ́, àfàìmọ̀ ni wọn ò ní dẹni tó ń “tọrọ ní àkókò ìkárúgbìn,” torí pé wọn ò ní lóúnjẹ tí wọ́n máa jẹ, wọn ò sì ní ráṣọ wọ̀.—Òwe 20:4.

Àníyàn ṣíṣe wá ńkọ́? Ṣé ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé àwọn tó ń gbọ́rọ̀ òun lè bọ́ lọ́wọ́ àníyàn ṣíṣe pátápátá? Rárá o. Tó bá jẹ́ pé ohun tó ń sọ nìyẹn, á jẹ́ pé ńṣe ló gbé wọn gẹṣin aáyán. Kódà, ìnira bá Jésù fúnra rẹ̀ dé góńgó, ó sì ṣàníyàn gan-an lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú un tí wọ́n sì pa á lọ́jọ́ kejì.—Lúùkù 22:44.

Ohun tó jóòótọ́ pọ́ńbélé ni Jésù kàn sọ nínú ìwàásù rẹ̀ yẹn. Tó o bá ń ṣàníyàn jù nípa ìṣòro rẹ, ìyẹn ò ní kí ìṣòro ọ̀hún yanjú. Bí àpẹẹrẹ, o ò lè tipa àníyàn ṣíṣe mú kí ẹ̀mí rẹ gùn sí i. Jésù sọ pé àníyàn ṣíṣe kò ní “fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè” rẹ. (Mátíù 6:27) Ká sòótọ́, téèyàn bá ṣàníyàn gan-an fúngbà pípẹ́, ó lè máà jẹ́ kẹ́mìí onítọ̀hún gùn.

Ìmọ̀ràn Jésù wúlò gan-an ni. Ọ̀pọ̀ nǹkan tá a máa ń torí ẹ̀ dààmú ni kì í ṣẹlẹ̀ rárá. Bó ṣe rí fún àgbà òṣèlú, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, tó ń jẹ́ Winston Churchill nìyẹn lásìkò tí Ogun Àgbáyé Kejì ṣì gbóná janjan. Ó sọ nípa díẹ̀ lára àníyàn rẹ̀ lásìkò náà pé: “Nígbà tí mo ronú lórí gbogbo àníyàn mi wọ̀nyẹn, ṣe ni mo rántí ìtàn bàbá arúgbó kan tó sọ nígbà tó kù díẹ̀ tó máa kú pé àwọn ohun tó ti kó ìdààmú bá òun nígbèésí ayé pọ̀ gan-an, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ jù lọ nǹkan wọ̀nyẹn kò tíì ṣẹlẹ̀.” Ní tòdodo, ohun tó bọ́gbọ́n mu, pàápàá lásìkò yìí tí kòókòó jàn-ánjàn-án àti ìṣòro ìgbésí ayé lè tètè kó àníyàn bá wa, ni pé ìṣòro ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni ká máa bójú tó, ká má máa da ara wa láàmú nípa ti ọjọ́ tí ò tíì dé.

‘Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Wíwá Ìjọba Ọlọ́run Lákọ̀ọ́kọ́’

Ibi tí Jésù ń bọ́rọ̀ lọ tiẹ̀ wá ju ọ̀rọ̀ nípa bí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ ìdààmú ọkàn àti ìnira lọ. Jésù mọ̀ pé tá a bá ń ṣàníyàn nípa bí ọwọ́ wa ṣe máa tẹ àwọn ohun kòṣeémánìí, tá a sì jẹ́ kí ìfẹ́ ọrọ̀ àti adùn ayé gbà wá lọ́kàn, a ò ní ráyè fáwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù. (Fílípì 1:10) Àmọ́ o lè máa rò ó pé, ‘Kí ló tún wá lè ṣe pàtàkì ju pé kọ́wọ́ èèyàn tẹ àwọn ohun kòṣeémánìí láyé?’ Ohun náà ni àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa sí Ọlọ́run. Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tó yẹ kó gbawájú nígbèésí ayé wa ni pé ‘ká máa bá a nìṣó ní wíwá ìjọba Ọlọ́run àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.’—Mátíù 6:33.

Nígbà ayé Jésù, nǹkan ìní tara ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń lépa lójú méjèèjì. Bí wọ́n ṣe máa kó ọrọ̀ jọ ló gbawájú láyé wọn. Ṣùgbọ́n Jésù rọ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí tiwọn rí bẹ́ẹ̀. Níwọ̀n bí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, “gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe” wọn ni pé kí wọ́n “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí [wọ́n] sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—Oníwàásù 12:13.

Tí ìlépa nǹkan tara, ìyẹn “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀,” bá lọ gba àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ yẹn lọ́kàn, wọn ò ní lè fọkàn sí ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. (Mátíù 13:22) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.” (1 Tímótì 6:9) Kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù má bàa kó sínú ìdẹkùn yẹn, Jésù rán wọn létí pé Baba wọn tí ń bẹ lọ́run mọ̀ pé wọ́n nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ó ní Ọlọ́run yóò pèsè fún wọn bó ṣe ń pèsè fún “àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.” (Mátíù 6:26, 32) Dípò tí wọ́n á fi jẹ́ kí àníyàn gbígbọ́ bùkátà gbà wọ́n lọ́kàn, ńṣe ni kí wọ́n sa gbogbo ipá wọn, kí wọ́n wá fi èyí tó kù sọ́wọ́ Jèhófà.—Fílípì 4:6, 7.

Nígbà tí Jésù sọ pé ‘ọ̀la ni yóò ṣe àníyàn ara rẹ̀,’ ohun tó ń sọ ni pé ká má ṣe jẹ́ kí àníyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́la dá kún àwọn ìṣòro tòní tá a ṣì ń bá yí. Bí Bíbélì mìíràn ṣe túmọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù yìí ni pé: “Ẹ má ṣe àníyàn nípa nǹkan ti ọ̀la; nitori ọ̀la ni nǹkan ti ọ̀la wà fún; wahala ti òní nìkan ti tó fún òní láìfi ti ọ̀la kún un.”—Mátíù 6:34, Ìròhìn Ayọ̀.

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”

Àmọ́ ṣá o, ọ̀tọ̀ ni pé ká má ṣe da ara wa láàmú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́la, ọ̀tọ̀ sì ni pé ká kúkú ṣàìbìkítà nípa ọ̀la. Jésù ò ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣàìbìkítà nípa ọ̀la o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa ronú gidigidi nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Ó tọ́, ó sì yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà nípa ohun tí wọ́n nílò ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ìyẹn oúnjẹ òòjọ́ wọn. Àmọ́ wọ́n ní láti kọ́kọ́ máa gbàdúrà nípa àwọn ohun kan tó jẹ́ pé ọjọ́ iwájú ni wọ́n máa wáyé, ìyẹn ni pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, àti pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe ní ayé.—Mátíù 6:9-11.

A ò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn èèyàn ìgbà ayé Nóà o. Ọwọ́ wọ́n dí gan-an ni. “Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, [wọ́n] sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó” débi pé ‘wọn kò fiyè sí’ ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn. Ibo lọ̀rọ̀ wọn wá já sí? Bíbélì ní: ‘Ìkún omi dé, ó sì gbá gbogbo wọn lọ.’ (Mátíù 24:36-42) Àpọ́sítélì Pétérù náà lo ìtàn ìgbà Nóà yìí láti fi rán wa létí pé ká má gbàgbé nípa ọ̀la. Ó wá sọ pé: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!”—2 Pétérù 3:5-7, 11, 12.

Ẹ To Ìṣúra Jọ Pa Mọ́ ní Ọ̀run

Ẹ jẹ́ ká fi ọjọ́ Jèhófà “sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí” o. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò nípa lórí bá a ṣe ń lo àkókò wa, agbára wa, ẹ̀bùn tá a ní, nǹkan ìní wa àti òye wa. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìlépa nǹkan tara, ì báà jẹ́ àwọn nǹkan tó jẹ́ kòṣeémánìí tàbí adùn ayé, gbà wá lọ́kàn débi tá ò fi ní ráyè tó fáwọn nǹkan tó jẹ mọ́ “iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” Tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tá a ó máa fi gbádùn ara wa lónìí nìkan là ń lépa, ọwọ́ wa lè tẹ̀ wọ́n o, àmọ́ kì í tọ́jọ́. Bí Jésù ṣe wí, ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé ká “to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara [wa] ní ọ̀run,” dípò ká máa tò ó sí ayé.—Mátíù 6:19, 20.

Jésù mú kókó yìí ṣe kedere nínú àkàwé rẹ̀ nípa ọkùnrin kan tó ń ṣètò bóun yóò ṣe fẹlá kóun sì máa jayé orí òun lọ́jọ́ iwájú àmọ́ kò ro ti Ọlọ́run mọ́ gbogbo ètò tó ṣe. Ó ṣẹlẹ̀ pé ilẹ̀ ọkùnrin yìí méso jáde gan-an. Ló bá wó àwọn àká rẹ̀ ó sì kọ́ àwọn míì tó tóbi gan-an, torí kó lè máa ṣe fàájì, kó máa jẹ, kó máa mu, kó sì máa gbádùn ẹ̀mí ẹ̀. Kí laburú tí ìyẹn wá yọrí sí? Òun ni pé ọkùnrin náà kú láìtọ́ wò rárá nínú gbogbo ohun tó ṣe. Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù ni pé kò ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run. Jésù wá parí ọ̀rọ̀ náà pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Lúùkù 12:15-21; Òwe 19:21.

Kí Ló Yẹ Kó O Ṣe?

Má ṣe irú àṣìṣe tí ọkùnrin tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ṣe o. Ṣe ni kó o wọ́nà láti mọ ohun tí Ọlọ́run pinnu láti ṣe lọ́jọ́ iwájú, kó o sì fìyẹn sípò iwájú nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe. Ọlọ́run kò fohun tó fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú bò fáwa èèyàn. Wòlíì kan láyé àtijọ́, tó ń jẹ́ Ámósì, sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.” (Ámósì 3:7) O lè rí ohun tí Jèhófà tipasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ ṣí payá fún wa kà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí.—2 Tímótì 3:16, 17.

Ara nǹkan tí Bíbélì ṣí payá ni ohun tó máa wáyé láìpẹ́, tó sì máa kan gbogbo ayé lọ́nà tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí. Jésù ní: “Ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí.” (Mátíù 24:21) Kò sí ẹ̀dá èèyàn tó lè dá ìṣẹ̀lẹ̀ yìí dúró o. Àwọn olùjọsìn tòótọ́ pàápàá ò ní fẹ́ kí ohunkóhun dá a dúró. Kí nìdí? Ìdí ni pé yóò mú gbogbo ìwà ibi kúrò láyé, tí yóò sì jẹ́ kí “ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan” bẹ̀rẹ̀, ìyẹn ìjọba tuntun kan látọ̀runwá àti àwùjọ èèyàn tuntun kan lórí ilẹ̀ ayé. Nínú ayé tuntun ọ̀hún, Ọlọ́run “yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [àwọn èèyàn], ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:1-4.

Ǹjẹ́ kò wá bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn wáyè láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bí èyí ṣe máa ṣẹlẹ̀? Ǹjẹ́ ò ń fẹ́ kẹ́nì kan wá kọ́ ẹ nípa rẹ̀? Ní káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́. O sì lè kọ̀wé sáwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí. Lákòótán, rí i pé o ò kàn máa jayé òní nìkan. Máa rántí pé ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu kan ń bọ̀.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn . . . Ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́