Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kéèyàn Kàn Máa Jayé Òní Nìkan?
ÀWỌN èèyàn sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ní ògbóǹkangí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà Albert Einstein sọ. Ọ̀rọ̀ náà ni: “N kì í ronú nípa ọjọ́ ọ̀la. Torí ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, ọ̀la ọ̀hún ti dé.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè ní: “Má wulẹ̀ yọra ẹ lẹ́nu nípa ọjọ́ ọ̀la.” Ìwọ pàápàá lè ti gbọ́ lẹ́nu àwọn èèyàn pé: “Báyé bá ṣe gbà là ń ṣe é.” “O jẹ́ jayé orí ẹ lónìí.” Tàbí kí wọ́n ní: “Gbàgbé nípa ọ̀la.”
Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń firú ojú bẹ́ẹ̀ wo ìgbésí ayé. Ohun táwọn ọmọlẹ́yìn Epikúréì ayé ìgbàanì fi ṣe àkọmọ̀nà wọn ni: “Jẹ, kó o mu, kó o gbádùn ara ẹ. Asán ni gbogbo nǹkan yòókù.” Nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, irú ojú táwọn kan fi wo ìgbésí ayé náà nìyẹn. Wọ́n máa ń sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (1 Kọ́ríńtì 15:32) Wọ́n gbà pé ìgbà kúkúrú tá à ń lò láyé yìí nìkan la ní, pé kò sí ìrètí míì mọ́. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń sọ pé kéèyàn kúkú jayé yìí dọ́ba.
Àmọ́, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló jẹ́ pé kò sí ohun tó jẹ mọ́ à ń lépa adùn ayé lọ́rọ̀ tiwọn nítorí ipò òṣì tí wọ́n bá ara wọn. Kẹ́mìí sáà ti má bọ́ ni wọ́n kàn ń bá kiri. Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ kí wọ́n máa ronú nípa ọjọ́ ọ̀la, tó jẹ́ pé lójú wọn ìyà òun ìṣẹ́ náà ló ń dúró dè wọ́n “lọ́la” ọ̀hún?
Ṣó Yẹ Kéèyàn Múra Sílẹ̀ De Ọ̀la?
Àwọn tí nǹkan ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ le fún pàápàá máa ń gbà pé kò sí àǹfààní kankan nínú mímúra sílẹ̀ de ọ̀la. Wọ́n lè sọ pé: “Kí lo fẹ́ máa yọ ara ẹ lẹ́nu fún?” Àwọn míì lè sọ pé àwọn tó ń múra sílẹ̀ de ọ̀la máa ń rí i pé ńṣe làwọn kàn ṣe wàhálà dà nù, torí pé ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà kì í gbabẹ̀. Jóòbù babańlá ìgbàanì pàápàá sọ̀rètí nù pátápátá nígbà tó rí i pé gbogbo ìwéwèé òun di èyí tó “pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ,” tí gbogbo ohun tó rò pé òun àti ìdílé òun máa fi gbádùn ayé lẹ́yìn ọ̀la pa rẹ́ ráúráú.—Jóòbù 17:11; Oníwàásù 9:11.
Ọmọ ilẹ̀ Scotland náà, Robert Burns, tó jẹ́ òǹkọ̀wé ewì, fi wàhálà ọmọ èèyàn wé ti eku kan tí òun ṣèèṣì fi ohun ìtúlẹ̀ ba ìtẹ́ rẹ̀ jẹ́ nínú oko. Ó ní ńṣe ni eku yìí yáa sá àsálà fẹ́mìí ẹ̀ nígbà tó di pé gbogbo àgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ dòfo. Òǹkọ̀wé ewì yìí wá sọ pé, ‘Bí ìgbésí ayé ọmọ èèyàn ṣe rí náà nìyẹn, torí pé àìmọye ìgbà ni ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú máa n ba gbogbo ohun tá a ti ṣètò kalẹ̀ jẹ́.’
Ṣé ká má wá ronú mọ́ rárá nípa ọjọ́ ọ̀la ni? Ó tì o. Ká sòótọ́, àìmúrasílẹ̀ máa ń yọrí sí jàǹbá tó bùáyà nígbà tí ìjì líle tàbí àwọn ìjábá míì bá wáyé. Bí àpẹẹrẹ, òótọ́ ni pé kò sóhun tẹ́nikẹ́ni lè ṣe tó lè dá ìjì líle bí irú èyí tí wọ́n pè ní Katrina dúró. Àmọ́ ká ní wọ́n fi ìjábá tó ṣeé ṣe kó wáyé sọ́kàn nígbà tí wọ́n ń ṣètò ìlú náà látilẹ̀wá ni, ǹjẹ́ ìyẹn ò ní dín ìpalára tí ìjì náà ṣe nílùú yẹn kù?
Lójú tìrẹ, ǹjẹ́ o rò pé ó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn kàn máa jayé òní nìkan kó gbàgbé nípa ọ̀la? Wo ohun tí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí sọ nípa rẹ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
“Jẹ, kó o mu, kó o gbádùn ara ẹ. Asán ni gbogbo nǹkan yòókù”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ká ní wọ́n fi ìjábá tó ṣeé ṣe kó wáyé sọ́kàn látilẹ̀wá ni, ǹjẹ́ ìyẹn ó ní dín ìpalára tí ìjì líle tí wọ́n pè ní Katrina ṣe kù?
[Credit Line]
U.S. Coast Guard Digital