Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ohun Táwọn Ẹlẹ́sìn Ń Ṣe Nípa Ogun Tó Ń Jà Nílẹ̀ Ukraine—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn olórí ẹ̀sìn táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún ń ṣe nípa ogun tó ń jà ní Ukraine:
“Àlùfáà Kirill tó jẹ́ aṣáájú ẹ̀sìn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ilẹ̀ Rọ́ṣíà kò tíì sọ bóyá bí Rọ́ṣíà ṣe gbógun ja ilẹ̀ Ukraine tọ́ tàbí kò tọ́. . . . Àmọ́ ọjọ́ pẹ́ tí Ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ ti ń tan ìròyìn èké kálẹ̀ nípa ilẹ̀ Ukraine, àwọn ìròyìn yẹn sì wà lára ohun tí Putin fi ń dá ogun tó ń jà láre.”—EUobserver, March 7, 2022.
“Àwọn ohun tí Àlùfáà Kirill ń ṣe . . . fi hàn pé ó fara mọ́ bí ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe gbógun wọ ilẹ̀ Ukraine. Ó ka ogun náà sí ọ̀nà kan láti gbógun ti ẹ̀ṣẹ̀.”—AP News, March 8, 2022.
“Ní ọjọ́ Monday, Àlùfáà Epiphanius Kìíní ti ìlú Kyiv tó jẹ́ aṣáájú ẹ̀sìn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ilẹ̀ Ukraine sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé káwọn náà ‘gbógun ti àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà’ . . . Ó tún sọ pé wọn ò dẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n bá pa àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà.”—Jerusalem Post, March 16, 2022.
“Àwa [ìyẹn Àjọ Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Àtàwọn Ètò Ẹ̀sìn Míì ti Ilẹ̀ Ukraine (UCCRO)] wà lẹ́yìn Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ilẹ̀ Ukraine àtàwọn alátìlẹyìn wọn. A fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe ń gbèjà ilẹ̀ Ukraine lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, a sì ń gbàdúrà fún wọn.”—UCCROa Statement, February 24, 2022.
Kí lèrò ẹ? Ṣé ó yẹ káwọn ẹlẹ́sìn tó pé ara wọn ní ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi máa gba àwọn ọmọ ìjọ wọn níyànjú pé kí wọ́n lọ jagun? Kí ni Bíbélì sọ?
Ọjọ́ pẹ́ táwọn ẹlẹ́sìn ti ń lọ́wọ́ sí ogun
Tipẹ́tipẹ́ làwọn ẹlẹ́sìn ti gbà pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa jagun, kódà wọ́n máa ń ṣètìlẹyìn fáwọn tó ń lọ sójú ogun. Lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n máa ń díbọ́n bíi pé wọ́n ń wá àlàáfíà. Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kéde fáyé pé ẹlẹ́tàn làwọn onísìn yìí. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀ nínú àwọn ìwé wa.
Àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ogun Ìsìn—‘Ẹ̀tàn Ọlọ́rọ̀ Ìbànújẹ́’” jẹ́ ká mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti lọ́wọ́ sí ìpakúpa àwọn èèyàn lórúkọ Ọlọ́run àti Kristi.
Àpilẹ̀kọ náà “The Catholic Church in Africa” sọ nípa bí àwọn ẹlẹ́sìn ò ṣe dá ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìpakúpa tó wáyé dúró.
Àwọn àpilẹ̀kọ náà “Is Religion to Blame?,” “Religion’s Role in Man’s Wars,” àti “Religion Takes Sides” jẹ́ ká mọ bí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì míì ṣe ti ẹgbẹ́ méjèèjì tó ja ọ̀pọ̀ ogun lẹ́yìn.
Ṣé ó yẹ káwọn Kristẹni máa lọ́wọ́ sí ogun?
Ohun tí Jésù fi kọ́ni: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) “Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín.”—Mátíù 5:44-47.
Rò ó wò ná: Ṣé ó yẹ káwọn ẹ̀sìn tó sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tún máa rọ àwọn ọmọ ìjọ wọn pé kí wọ́n máa pààyàn lójú ogun? Tó o bá fẹ́ mọ ìdáhùn ìbéèrè yìí, ka àwọn àpilẹ̀kọ náà “Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọ̀tá Ẹni?” àti “True Christians and War.”
Ohun tí Jésù fi kọ́ni: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Ká ní Ìjọba mi jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ì bá ti jà kí wọ́n má bàa fà mí lé àwọn [ọ̀tá] lọ́wọ́.” (Jòhánù 18:36) “Gbogbo àwọn tó bá yọ idà máa ṣègbé nípasẹ̀ idà.”—Mátíù 26:47-52.
Rò ó wò ná: Tó bá jẹ́ pé àwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ jà láti gbèjà Jésù, ṣé ó wá yẹ kí wọ́n jà torí àwọn ìdí míì? Ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Jagun?” kó o lè rí bí àwọn Kristẹni ìgbàanì ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ Jésù délẹ̀délẹ̀.
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ìsìn tó ń ṣètìlẹyìn fún ogun?
Bíbélì fi kọ́ni pé Ọlọ́run ò ní tẹ́wọ́ gba àwọn ìsìn tó sọ pé Jésù làwọn ń ṣojú fún, àmọ́ tí wọn ò fi àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílò.—Mátíù 7:21-23; Títù 1:16.
Ìwé Ìfihàn jẹ́ ká mọ̀ pé lójú Ọlọ́run, ọrùn àwọn ẹlẹ́sìn ni ẹ̀jẹ̀ “gbogbo àwọn tí wọ́n pa ní ayé” wà. (Ìfihàn 18:21, 24) Ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Bábílónì Ńlá?” kó o lè mọ ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀.
Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo àwọn ìsìn tí Ọlọ́run ò tẹ́wọ́ gbà máa pa run, bí ìgbà tá a gé igi tó ti jẹra tó ń mú èso tí kò ní láárí jáde ‘lulẹ̀, tí a sì jù ú sínú iná.’ (Mátíù 7:15-20) Ka àpilẹ̀kọ náà “Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!” kó o lè mọ bí èyí ṣe máa ṣẹlẹ̀.
Ibi tá a ti gba àwọn fọ́tò yìí, apá òsì sí apá ọ̀tún: Photo by Sefa Karacan/Anadolu Agency/Getty Images; Maxym Marusenko/NurPhoto via Getty Images
a Lára àwọn tó para pọ̀ di Àjọ Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Àtàwọn Ètò Ẹ̀sìn Míì ti Ilẹ̀ Ukraine, ìyẹn UCCRO ni àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tó jẹ́ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, Kátólíìkì, Pùròtẹ́sítáǹtì àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Ajíhìnrere títí kan àwọn Júù àti Mùsùlùmí.