BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ
A Ṣètò Ìrànwọ́ Lásìkò ‘Ogun, àti Ìròyìn Nípa Àwọn Ogun’
MAY 27, 2022
Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, kò sí àní-àní pé àá máa gbọ́ ‘nípa àwọn ogun, àti ìròyìn nípa àwọn ogun.’ (Mátíù 24:6) Síbẹ̀, tí ogun bá ṣẹlẹ̀ ní agbègbè táwọn ará wa ń gbé, a máa ń pèsè ohun tí wọ́n nílò. Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí Ti Ọdún 2022 #3 sọ àwọn nǹkan tó ń mórí ẹni wú nípa bá a ṣe ń ṣètò ìrànwọ́ fáwọn ará wa tó ń jìyà nítorí ogun tó ń jà ní Ukraine. Kí làwọn ará wa ṣe kí wọ́n lè ṣètò ìrànwọ́ láìka ogun tó ń jà yìí sí? Àǹfààní wo ni ètò ìrànwọ́ yìí ti ṣe fún àwọn ará wa ní orílẹ̀-èdè Ukraine?
Bá A Ṣe Mọ Ohun Tí Wọ́n Nílò àti Bá A Ṣe Fi Ránṣẹ́
Lọ́jọ́ náà gan-an tí ogun yẹn bẹ̀rẹ̀ ní February 24, 2022, Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí fọwọ́ sí ètò ìnáwó láti ran àwọn ará tó wà ní Ukraine lọ́wọ́. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì Ukraine bẹ̀rẹ̀ sí í ra ohun táwọn ará nílò. Lẹ́yìn náà, wọ́n dá ìgbìmọ̀ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) tá a máa ṣètò ìrànwọ́ (ìyẹn DRC) sílẹ̀. Wọ́n sì ní káwọn ìgbìmọ̀ DRC yìí máa pín àwọn nǹkan tí wọ́n rà fáwọn ará.
Láfikún sí ètò tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Ukraine ń ṣe, àwọn tó wà ní Oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà bẹ̀rẹ̀ sí í ronú ọ̀nà tó dáa jù lọ tí wọ́n lè gbà ṣèrànwọ́. Torí náà, Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí àti Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ fún Ẹ̀ka Tó Ń Rajà Kárí Ayé pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Ukraine àti ti Poland kí wọ́n lè bójú tó ohun táwọn ará wa nílò. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ojoojúmọ́ ni àwọn ará tó wà ní Ẹ̀ka Tó Ń Rajà, Ẹ̀ka Tó Ń Kó Ẹrù Ránṣẹ́ àti Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Òfin láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì méjèèjì máa ń ṣèpàdé pọ̀ pẹ̀lú ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Ukraine àtàwọn tó wà ní Ẹ̀ka Tó Ń Rajà Kárí Ayé.
Ohun tó wà nínú ẹrù tí wọ́n fi ránṣẹ́ ni oúnjẹ, ohun èlò ìmọ́tótó, oògùn àti ọ̀rọ̀ ìṣírí tí wọ́n kọ sínú bébà kékeré
Ẹ gbọ́ ohun tí Arákùnrin Jay Swinney tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Rajà Kárí Ayé sọ. Ó ní: “Ohun tá a kọ́kọ́ máa ń ṣe ni pé ká mọ ohun táwọn ará wa nílò. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń ṣètò oúnjẹ àtàwọn nǹkan tí wọ́n lè fi ṣe ìmọ́tótó. Àmọ́ o, ohun kan ni pé ká mọ ohun táwọn ará wa nílò ká sì kó wọn jọ. Nǹkan ọ̀tọ̀ gbàá ni bá a ṣe máa fi àwọn nǹkan náà ránṣẹ́ sáwọn ará tó wà níbi tógun ti ń jà ní Ukraine. A sì fẹ́ káwọn nǹkan náà tètè dé ọ̀dọ̀ wọn, ká má sì fi ẹ̀mí ẹnikẹ́ni sínú ewu.”
Nígbà tó fi máa di March 9, 2022, àwọn arákùnrin yìí ti mọ nǹkan tí àwọn ará wa nílò. Lára ohun tí wọ́n kó sínú páálí tí wọ́n máa kó ránṣẹ́ ni àwọn oúnjẹ alágolo àtàwọn oúnjẹ míì bí ẹ̀wà, ìrẹsì pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìmọ́tótó bí ọṣẹ àti bébà ìnùdí. Wọ́n fojú bù ú nígbà yẹn pé ó máa ná wọn tó dọ́là márùndínláàádọ́rin (65) láti ra oúnjẹ ọ̀sẹ̀ mẹ́rin fún ẹnì kan ṣoṣo. Torí pé àwọn ará wa tó nílò àwọn nǹkan yìí máa pọ̀ gan-an, Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí fọwọ́ sí i pé ká ṣètò owó tó jọjú fáwọn nǹkan yìí. Àmọ́, báwo la ṣe máa kó àwọn nǹkan yìí ránṣẹ́ láìfi ẹ̀mí àwọn ará sínú ewu?
Ní March 13, àwọn arákùnrin méjì láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Poland rìnrìn àjò lọ sí Lviv, lórílẹ̀-èdè Ukraine láti mọ bó ṣe máa rọrùn tó láti kó àwọn nǹkan ìrànwọ́ tó kù lọ. Ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó gbéra, àwọn kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Poland àti Ukraine múra àwọn arákùnrin méjì yìí sílẹ̀ fún ìrìn àjò náà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì bá wọn ṣe ìwé ìrìnnà àtàwọn ohun míì tí wọ́n nílò fún ìrìn àjò wọn. Bákan náà, wọ́n kọ àkọlé gàdàgbà kan sára ọkọ̀ wọn láti fi hàn pé ètò ìrànwọ́ ni wọ́n wá fún, wọ́n sì ń bá àwọn arákùnrin tó wà ní Ukraine ṣiṣẹ́ pọ̀ kí wọ́n lè mọ ọ̀nà tó máa yá láti gbà tí wọ́n bá ti wọ Ukraine. Jèhófà bù kún gbogbo ètò tá a ṣe torí pé àwọn ẹrù náà dé ọ̀dọ̀ àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù láàárín ọjọ́ kan tí wọ́n kó o wọ ìlú Lviv, àwọn arákùnrin méjì náà sì pa dà sí Poland láyọ̀.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìrìn àjò àkọ́kọ́ yọrí sí rere, ẹrù ìrànwọ́ tí àwọn arákùnrin náà kó lọ kò tó tọ́ọ̀nù kan. A fojú bù ú pé ohun tí wọ́n nílò ṣì máa tó igba ó lé ogún (220) tọ́ọ̀nù! Báwo la ṣe máa kó ẹrù tó pọ̀ tó báyìí tá a sì máa tètè pín in fún àwọn ará?
“Àwọn Èèyàn Rẹ Máa Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú”
Lẹ́yìn tá a gbé ìròyìn nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Ukraine sórí ìkànnì jw.org, àwọn ará kárí ayé bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n á ṣe ṣèrànwọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà lọ́nà jíjìn fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé torí wọ́n mọ̀ pé ọ̀nà tó dáa jù lọ ni wọ́n máa gbà lo owó yìí. Àmọ́, àwọn ará tí wọ́n ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó sún mọ́ Ukraine lo àkókò wọn, okun wọn àtàwọn ohun ìní wọn láti ṣèrànwọ́. Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé.
Lórílẹ̀-èdè Poland, àwọn ará tó yọ̀ǹda ara wọn fi ọ̀pọ̀ nǹkan ránṣẹ́, àwọn ọmọdé náà ya àwòrán sórí káàdì, wọ́n sì fi ránṣẹ́. Arákùnrin Bartosz Kościelniak tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Rajà lórílẹ̀-èdè Poland sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti ka ohun tó wà nínú Sáàmù 110:3 tó sọ pé ‘àwọn èèyàn Jèhófà máa yọ̀ǹda ara wọn tinútinú.’ Àmọ́ nígbà tí mo fojú ara mi rí bí àwọn èèyàn ṣe múra tán láti yọ̀ǹda ara wọn tinútinú, tó sì ń ṣe wọ́n bíi pé kí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ìyẹn jẹ́ kó dá mi lójú pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yẹn.”
Ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ní iléeṣẹ́ akẹ́rù ńlá kan yọ̀ǹda àwọn ọkọ̀ akẹ́rù rẹ̀, ó sì tún ra epo tí wọ́n nílò sínú àwọn ọkọ̀ náà. Arákùnrin náà sọ pé: “Àǹfààní ńlá ni mo kà á sí láti fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará. Inú mi sì dùn gan-an pé mo yọ̀ǹda ohun tí mo ní.” Ohun tó ju ẹgbẹ̀rún méje àti ọgọ́rùn-ún méje (7,700) lítà epo làwọn ará fi tọrẹ, wọ́n sì tún lo àkókò àti okun wọn láti rìnrìn àjò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó kìlómítà méjìdínláàádọ́ta (48,000) kí wọ́n lè kó gbogbo ẹrù náà!
Iṣẹ́ ńlá làwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó yọ̀ǹda ara wọn ṣe torí pé lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) péré tí wọ́n fi ẹrù àkọ́kọ́ ránṣẹ́, ìyẹn ní March 28, wọ́n tún fi àádọ́fà (110) tọ́ọ̀nù àwọn nǹkan bí oúnjẹ, ohun èlò ìmọ́tótó àti oògùn ránṣẹ́ sí Ukraine. Bí àwọn ará wa àtàwọn míì ṣe fi àwọn ohun ìní wọn tọrẹ lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ ti jẹ́ kí owó tá a fẹ́ ná dín kù gan-an. Títí di báyìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fi ẹrù tó lé ní igba ó lé mẹ́sàn-án (209) tọ́ọ̀nù ránṣẹ́ sí Ukraine, ìyẹn sì máa fẹ́rẹ̀ẹ́ kún ọkọ̀ akẹ́rù ńlá méje. Báwo làwọn nǹkan tá a fi ránṣẹ́ yìí ṣe rí lára àwọn ará wa?
‘A Rí Bí Ìfẹ́ Tẹ́ Ẹ Ní sí Wa Ṣe Pọ̀ Tó!’
Nígbà táwọn ẹrù tá a fi ránṣẹ́ dé Lviv, àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ní Ukraine bẹ̀rẹ̀ sí í pín in fáwọn tó nílò ẹ̀ ní ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lára àwọn ìlú tá a kó ẹrù náà lọ fi ohun tó ju ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (1,300) kìlómítà jìnnà sí ìlú Lviv. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará yẹn fara ṣe iṣẹ́ náà, ó ṣì gba ọ̀pọ̀ àkókò kí wọ́n tó kó àwọn ẹrù náà dé ọ̀dọ̀ àwọn tó nílò ẹ̀.a
Arákùnrin Markus Reinhardt tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Ukraine sọ pé: “Lákòókò rògbòdìyàn yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ti rí bí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ hàn sí wọn, wọ́n sì tún rí bó ti ṣe pàtàkí tó láti máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run bá fún wa, kódà kí wàhálà tó ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ní káwọn ará tọ́jú oúnjẹ àti omi tí wọ́n máa nílò fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan sílé. Arákùnrin Anton tó jẹ́ alàgbà ní ìjọ kan ní ìlú Kyiv sọ bí ìtọ́ni tí wọ́n fún wọn ṣe wúlò tó, ó ní: ‘Ètò Ọlọ́run ti múra wa sílẹ̀ fún àwọn àsìkò tó nira yìí, ìtọ́ni tí wọ́n fún wa pé ká ní oúnjẹ, omi àti rédíò sílé ló gba ẹ̀mí wa là. A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà.’ Inu wa dùn pé àwọn ará tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn, torí ohun táwọn ará ní sílé yẹn ni wọ́n fi ń gbéra títí ẹ̀ka ọ́fíìsì fi láǹfààní láti fi àwọn nǹkan tí wọ́n nílò ránṣẹ́ sí wọn.”
Báwo lọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn ará tí wọ́n fi ẹrù ránṣẹ́ sí? Mykola àti Zinaida tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kharkiv sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wọn, wọ́n sọ pé: “Ẹ ṣeun gan-an fún oúnjẹ àti oògùn tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́. Ìfẹ́ yìí jọ wá lójú gan-an, ó dá wa lójú pé Jèhófà ló rán yín sí wa.” Valentyna tí òun náà ń gbé lágbègbè yẹn sọ pé: “Látìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀ ni èrò ti máa ń pọ̀ rẹpẹtẹ láwọn ibi tá a ti ń ra nǹkan. Ọ̀pọ̀ ìgbà la kì í rí àwọn ohun tá a nílò rà. Àmọ́ Jèhófà rí ohun tá à ń bá yí. Ó sì lo àwọn ará láti pín ẹrù tí ètò Ọlọ́run fi ránṣẹ́ dé ilé wa. Ó yà mí lẹ́nu pé ohun tá a nílò gẹ́lẹ́ ló wà nínú àwọn ẹrù náà! Láwọn àkókò tí nǹkan nira, tó sì dà bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ yìí, Jèhófà àti ètò ẹ̀ ti fi ìfẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ hàn sí wa. . . . Inú wa dùn gan-an pé Jèhófà ń pèsè ohun tá a nílò lásìkò tá a nílò ẹ̀ gẹ́lẹ́.”
Yevhen, Iryna, àti Mykyta tí wọ́n sá kúrò níbi tógun ti ń jà ní ìlú Mariupol sọ pé: “A mọrírì ìrànlọ́wọ́ yín àti ìfẹ́ tẹ́ ẹ fi hàn sí ìdílé wa lásìkò wàhálà yìí. Ká sòótọ́, ó bọ́ sákòókò gan-an. Nígbà tá a gba àwọn ẹrù tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́, a rò pé àwọn ẹ̀bùn nìkan ló wa níbẹ̀, àmọ́ nígbà tá a tú àwọn ẹrù náà, a tún rí bí ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní sí wa ṣe pọ̀ tó!”
Ó dájú pé ẹ̀mí Jèhófà àti ìtọ́ni látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run ló jẹ́ kó ṣeé ṣe láti pín àwọn ẹrù tí ètò Ọlọ́run kó ránṣẹ́ láti fi ṣèrànwọ́ lásìkò ‘ogun, àti ìròyìn nípa àwọn ogun.’ Àwọn ọrẹ tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́ fún iṣẹ́ kárí ayé ló jẹ́ ká lè pèsè ìrànwọ́ yìí fún àwọn ará wa. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọrẹ bẹ́ẹ̀ lẹ sì fi ń ránṣẹ́ látorí ìkànnì donate.jw.org. Ẹ ṣeun gan-an, a mọrírì ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín.
A Pèsè Ìrànwọ́ Láìjáfara, A sì Ṣe Bẹ́ẹ̀ Láìtẹ Òfin Ààbò Lójú
February 24, 2022: Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí fọwọ́ sí owó tí wọ́n máa ná láti fi ra nǹkan táwọn ará nílò, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ni Ukraine sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò ìrànwọ́
February 24–March 8, 2022: Ẹ̀ka ọ́fíìsì Ukraine bẹ̀rẹ̀ sí í ra ohun táwọn ará nílò. Lẹ́yìn náà, wọ́n ní kí àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù (DRC) bẹ̀rẹ̀ sí í pín àwọn nǹkan tí wọ́n rà. Ètò míì tí ẹ̀ka ọ́fíìsì tún ṣe ni bí wọ́n ṣe máa gba ẹrù tí wọ́n gbé wá láti orílẹ̀-èdè Poland, kí wọ́n sì pín in
March 9, 2022: Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí fọwọ́ sí i pé kí wọ́n fi ohun táwọn tó wà ní Ukraine nílò ránṣẹ́ sí wọn
March 10–12, 2022: Wọ́n ṣètò láti kó àwọn ohun èlò ìrànwọ́ láti Poland lọ sí Lviv, lórílẹ̀-èdè Ukraine, kí wọ́n lè mọ bí ìrìn àjò náà ṣe máa rọrùn tó
March 13, 2022: Wọ́n kó àwọn ohun èlò ìrànwọ́ láti Poland lọ sí Lviv, lórílẹ̀-èdè Ukraine
March 14–16, 2022: Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ ṣètò àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti kó àwọn ẹrù tí ètò Ọlọ́run fi ránṣẹ́ jọ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan nítòsí Poznan, lórílẹ̀-èdè Poland
March 17, 2022: Ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn tí wọ́n kó ẹrù àkọ́kọ́ lọ, wọ́n tún kó ẹrù tó wúwo tó tọ́ọ̀nù mẹ́tàlá (13) lọ sí ibodè Ukraine
March 21–27, 2022: Ọ̀nà tá a gbà kó ẹrù tá a fi ránṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ náà la gbà kó àwọn tó kù. Wọ́n á kọ́kọ́ kó ẹrù náà jọ ní Poland, wọ́n á sì kó o lọ sí Ukraine. Lẹ́yìn náà, wọ́n á fi ránṣẹ́ sáwọn agbègbè tí wọ́n ti nílò ẹ̀ láàárín ọjọ́ kan
March 28, 2022: Láàárín ogún (20) ọjọ́ lẹ́yìn tí wọ́n fọ́wọ́ sí i, wọ́n fi ẹrù tó wúwo tó àádọ́fà (110) tọ́ọ̀nù oúnjẹ, ohun èlò ìmọ́tótó àti oògùn ránṣẹ́ sí Ukraine
Títí di báyìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fi ẹrù tó lé ní igba àti mẹ́sàn-án (209) tọ́ọ̀nù ránṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè Ukraine, ìyẹn sì máa fẹ́rẹ̀ẹ́ kún ọkọ̀ akẹ́rù ńlá méje.
a Tó o bá fẹ̀ mọ̀ sí i nípa bá a ṣe fi àwọn ẹrù náà ránṣẹ́, ka àpilẹ̀kọ náà “Brothers Courageously Deliver Aid, Rescue Others in Ukrainian War Zone” lédè Gẹ̀ẹ́sì.