ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 121
  • Ta Lo Lè Fọkàn Tán?—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Lo Lè Fọkàn Tán?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹni tó o lè fọkàn tán
  • Fífọkàntánni Ló Ń Mú Kí Ìgbésí Ayé Èèyàn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àwọn Èèyàn Ò Fọkàn Tán Àwọn Olóṣèlú Mọ́—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Jésù Máa Fòpin sí Ipò Òṣì
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Fọkàn Tán Àwọn Arákùnrin Àtàwọn Arábìnrin Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 121
Àwòrán: Àwọn tọ́pọ̀ èèyàn gbà pé ó ṣeé fọkàn tán: 1. Àwọn olóṣèlú. 2. Àwọn aṣáájú ìsìn. 3. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì.

Òsì: Olena Yefremkina/stock.adobe.com; àárín: lunamarina/stock.adobe.com; ọ̀tún: Rido/stock.adobe.com

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ta Lo Lè Fọkàn Tán?—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Ó máa ń dun àwọn èèyàn gan-an tí ẹni tí wọ́n fọkàn tán bá já wọn kulẹ̀. Ọ̀pọ̀ ò fọkàn tán . . .

  • àwọn olóṣèlú tó jẹ́ pé àpò ara wọn ni wọ́n ń dù.

  • àwọn oníròyìn tí kì í sọ òótọ́ délẹ̀délẹ̀ tí wọ́n sì máa ń gbè sápá kan.

  • àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí kì í ro táwọn èèyàn.

  • àwọn aṣáájú ìsìn tó ń gbé àwọn olóṣèlú lárugẹ dípò kí wọ́n máa ṣojú fún Ọlọ́run.

Ó yẹ kéèyàn ṣọ́ra kó tó fọkàn tán ẹnì kan. Bíbélì kìlọ̀ pé:

  • “Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè; eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn.”—Orin Dafidi 146:3, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

Ẹni tó o lè fọkàn tán

 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tá a lè fọkàn tán, ìyẹn Jésù Kristi. Kì í ṣe pé Jésù kàn jẹ́ èèyàn dáadáa tó gbé láyé àtijọ́ nìkan ni, àmọ́ Ọlọ́run ti fi í “jẹ Ọba . . . , Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.” (Lúùkù 1:32, 33) Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, Ìjọba yìí sì ti ń ṣàkóso lọ́run báyìí.—Mátíù 6:10.

  • Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tó o fi lè fọkàn tán Jésù, ka àwọn àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run?” àti “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?”

Ìwé tó o lè fọkàn tán

Bíbélì sọ púpọ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù àtàwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì míì. Àwọn ìsọfúnni pàtàkì tó o lè fọkàn tán ló wà nínú ìwé yìí. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Bíbélì, a rọ̀ ẹ́ pé kó o kọ̀rọ̀ sí fọ́ọ̀mù téèyàn fi lè béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. A máa fún ẹ láwọn ìwé tó o fi máa kẹ́kọ̀ọ́, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan á sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè lóye ẹ̀kọ́ náà. Ọ̀pọ̀ nǹkan lo máa kọ́, lára ẹ̀ ni irú ẹni tí Jésù jẹ́, ohun tó ti ṣe, ohun tó ń ṣe lọ́wọ́ àtohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.

Gbìyànjú Ẹ̀ Wò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́