NASA Photo
Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ṣé Ìjọba Kan Wà Tó Máa Mú Kí Àlàáfíà Wà Kárí Ayé?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Bí ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe ń yí pa dà nínú ayé lónìí ti mú kí nǹkan sú àwọn ìjọba. Kódà àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà pàápàá láwọn ìṣòro bí àìgbọ́ra-ẹni-yé tó ń wáyé láàárín àwọn olóṣèlú, báwọn ará ìlú kì í ṣe fára mọ́ èsì ìbò àti ìwọ́de táwọn ará ìlú ń ṣe.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìjọba kan wà tó máa mú kí àlàáfíà wà kárí ayé. Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ nípa ìjọba yìí rí. Ìjọba yìí ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àdúrà tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀.
“Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́. Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.’ ”—Mátíù 6:9, 10.
Kí ni Bíbélì sọ nípa ìjọba yìí?
Ìjọba tó máa mú kí àlàáfíà wà
Ọ̀run ni Ìjọba yìí á ti máa ṣàkóso.
Jésù pe ìjọba yìí ní “Ìjọba ọ̀run.” (Mátíù 4:17; 5:3, 10, 19, 20) Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.”—Jòhánù 18:36.
Ìjọba yìí ló máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn.
Bíbélì sọ pé: “Ìjọba yìí . . . máa fọ́ àwọn ìjọba [èèyàn] túútúú, ó máa fòpin sí gbogbo wọn, òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Jésù ló máa jẹ́ ọba Ìjọba yìí, Ìjọba náà kò sì ní pa run láé.
Bíbélì sọ pé: “Àkóso rẹ̀ jẹ́ àkóso tó máa wà títí láé, tí kò ní kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ ò sì ní pa run.”—Dáníẹ́lì 7:13, 14.
Ìjọba yìí máa jẹ́ kí àlàáfíà àti ààbò wà láyé.
Bíbélì sọ pé: “Kálukú wọn máa jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”—Míkà 4:4.
Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ìjọ́ba yìí
Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi àkókò àti okun ẹ̀ “wàásù ìhìn rere Ìjọba náà.” (Mátíù 9:35) Ó tún sọ tẹ́lẹ̀ pé:
“A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.”—Mátíù 24:14.
Lónìí, ó ju igba ó lé ogójì (240) ilẹ̀ tá a ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. A rọ̀ ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ìjọ́ba yìí àti bó ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní.
Jọ̀wọ́ wo fídíò yìí Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?