ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 18
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí I Pé Kí Ọkùnrin Fẹ́ Ju Ìyàwó Kan Lọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí I Pé Kí Ọkùnrin Fẹ́ Ju Ìyàwó Kan Lọ?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ṣé Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Ìkóbìnrinjọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Ní Ayọ̀?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Bíbélì Dáhùn Ìbéèrè Mẹ́wàá Nípa Ìbálòpọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 18
Ọwọ́ ọkọ àti ìyàwó

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí I Pé KÍ Ọkùnrin Fẹ́ Ju Ìyàwó Kan Lọ?

Ohun tí Bíbélì sọ

Láwọn ìgbà kan, Ọlọ́run fàyè gba ọkùnrin kan láti ní ju ìyàwó kan lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 4:19; 16:1-4; 29:18–29) Àmọ́ Ọlọ́run kọ́ ló dá àṣà kí ọkùnrin máa fẹ́ ju ìyàwó kan lọ sílẹ̀. Ìyàwó kan ṣoṣo ló fún Ádámù.

Ọlọ́run ní kí Jésù Kristi fìdí ohun tí òun ní lọ́kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ múlẹ̀ pa dà, ohun náà ni pé kí ọkùnrin fẹ́ ìyàwó kan ṣoṣo. (Jòhánù 8:28) Nígbà táwọn èèyàn béèrè ọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó lọ́wọ́ Jésù, ó ní: “Ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’”—Mátíù 19:4, 5.

Nígbà tó yá, Ọlọ́run mí sí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láti sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkùnrin ní aya tirẹ̀, kí olúkúlùkù obìnrin sì ní ọkọ tirẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:2) Bíbélì tún sọ pé, Kristẹni ọkùnrin èyíkéyìí tó ti gbéyàwó tí wọ́n bá fún ní iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú ìjọ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ “ọkọ aya kan.”—1 Tímótì 3:2, 12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́