ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 13
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn Tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 1)

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn Tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 1)
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • YEIMY
  • MATTEO
  • BRUNA
  • ANDRÉ
  • Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Báyìí?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn Tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 2)
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2013
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 3)
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 13

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn Tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 1)

Ṣé o mọ ọ̀dọ́ kan tí àìsàn tó le ń ṣe? Àbí o ní àìsàn tàbí àìlera kan tí ò jẹ́ kó o lè ṣe àwọn ohun tí àwọn ẹgbẹ́ rẹ ń ṣe?

Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, inú ẹ lè má dùn nígbà míì, kò sì sẹ́ni tírú ẹ̀ ò lè ṣe. Àmọ́ Bíbélì sọ ohun méjì tó tuni nínú.

  • Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ẹ, mọ ìṣòro tó ò ń bá fínra. Pàtàkì ibẹ̀ wá ni pé, “ó bìkítà fún [ẹ].”—1 Pétérù 5:7.

  • Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa wo gbogbo àìsàn! O lè rí i kà nínú Bíbélì, ní Aísáyà 33:24 àti Ìṣípayá 21:1-4.

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó ń ṣàìsàn tó le ló ti rí i pé ohun tó mú káwọn lè máa fara da ìṣòro náà ni pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àtàwọn ìlérí tó ṣe. Wo àpẹẹrẹ àwọn mẹ́rin.

  • YEIMY

  • MATTEO

  • BRUNA

  • ANDRÉ

YEIMY

Nígbà tí mo fi máa pé ọmọ ọdún mọ́kànlá, ó ti di dandan kí n máa lo kẹ̀kẹ́ arọ táá máa gbé mi kiri. Mi ò lè ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, bíi kí n gbé nǹkan tí kò wúwo.

Ọmọ ọdún márùn-ún ni mí tí wọ́n ti sọ pé mo ní àrùn kan tó ń ba iṣan ara jẹ́, kì í sì í jẹ́ kí n lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan. Ìgbà míì wà tí inú mi kì í dùn torí mi ò lè ṣe ohun táwọn ẹgbẹ́ mi ń ṣe. Àmọ́ àwọn òbí mi àtàwọn tó wà nínú ìjọ mi ò fi mí sílẹ̀, wọ́n ń ṣe ohun tó ń múnú mi dùn, wọ́n sì ń ràn mí lọ́wọ́ kí n lè sún mọ́ Ọlọ́run. Mo máa ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù, àwọn tá a sì jọ jẹ́ Kristẹni sábà máa ń bá mi lọ tí mo bá fẹ́ lọ bá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Jésù sọ pé búburú ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un. (Mátíù 6:34) Torí náà, mi kì í da àníyàn tòní mọ́ tọ̀la, àfojúsùn tọ́wọ́ mi sì lè tẹ̀ ni mo máa ń lé. Mò ń retí ọjọ́ tí màá ní “ìyè tòótọ́” nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, tí màá bọ́ lọ́wọ́ àìsàn burúkú yìí.—1 Tímótì 6:19.

Ronú nípa èyí: Yeimy máa ń lé ‘àfojúsùn tọ́wọ́ rẹ̀ lè tẹ̀,’ ìyẹn sì ràn án lọ́wọ́. Báwo ni ìwọ náà ṣe lè ṣe irú ẹ̀?—1 Kọ́ríńtì 9:26.

MATTEO

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́fà, ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í dùn mí, ohun táwọn dókítà sì kọ́kọ́ sọ ni pé torí mò ń dàgbà sí i ló fà á. Àmọ́ lẹ́yìn ọdún kan, wọ́n rí i pé kókó kan ti wú síbi eegun ẹ̀yìn mi.

Dókítà ṣiṣẹ́ abẹ fún mi, àmọ́ nǹkan bí ìdajì kókó yẹn ló rí yọ. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, lẹ́yìn oṣù méjì, kókó ọ̀hún tún ti hù, ó sì ti pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀! Látìgbà yẹn, oríṣiríṣi àyẹ̀wò ni mo ti ṣe, àìmọye ìtọ́jú ni mo ti gbà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni nǹkan ò sì lọ bí mo ṣe rò.

Nígbà míì, kókó ẹ̀yìn mi yẹn máa ń mú kí gbogbo ara máa ro mí, pàápàá ẹ̀yìn mi àti àyà mi, ó sì máa ń dà bíi pé wọ́n ń fi ọ̀bẹ gún mi ní lára. Àmọ́ mo máa ń gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ara mi sú mi. Mo máa ń rán ara mi létí pé àwọn ẹlòmíì náà ti fara da ìṣòro tó le gan-an, síbẹ̀ wọ́n ń láyọ̀. Ó dá mi lójú pé lọ́jọ́ kan, Jèhófà Ọlọ́run máa mú ìlérí tó ṣe pé òun máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ wá ṣẹ, ìyẹn ló sì ń ràn mí lọ́wọ́ jù tí mo fi ń láyọ̀.—Ìṣípayá 21:4.

Ronú nípa èyí: Tó o bá ń ronú nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ wá, báwo ló ṣe lè jẹ́ kó o fara da ìṣòro tó ń bá ẹ fínra bíi ti Matteo?—Aísáyà 65:17.

BRUNA

Ohun tó ń ṣe mí ò hàn lójú mi, ìyẹn sì lè mú káwọn kan máa rò pé ọ̀lẹ ni mí. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé gbogbo nǹkan ló nira fún mi láti ṣe, títí kan iṣẹ́ ilé, ìwé kíkà, kódà, àti dìde lórí bẹ́ẹ̀dì ò rọrùn.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), wọ́n sọ pé mo ní àrùn burúkú kan tó máa ń jẹ́ kí iṣan ara èèyàn le gbagidi, kì í sì í lọ. Kò jẹ́ kí n lè ṣiṣẹ́, kò sì jẹ́ kí n lè jọ́sìn Ọlọ́run bí mo ṣe fẹ́. Léraléra ni mo máa ń ka ìwé 1 Pétérù 5:7, tó sọ pé: “Ẹ . . . kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.” Tí mo bá ń rántí pé ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa jẹ Jèhófà lógún, ó máa ń mú kí n lókun. Òun ló ń jẹ́ kí n máa fara dà á títí dòní.

Ronú nípa èyí: Àǹfààní wo ló máa ṣe ẹ́ tó o bá ń kó àwọn àníyàn rẹ lé Jèhófà, bíi ti Bruna?—Sáàmù 55:22.

ANDRÉ

Ojú ọmọdé láwọn kan fi máa ń wò mí. Ẹ̀bi wọn kọ́, bí ọmọdé lèmi náà kúkú ṣe rí.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjì, wọ́n ní mo ní àrùn jẹjẹrẹ. Àrùn jẹjẹrẹ tó ń ṣe mí yìí ò wọ́pọ̀, àti inú ọ̀pá ẹ̀yìn mi ló ti ń hù lọ sínú ọpọlọ. Àwọn dókítà bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú mi, àmọ́ àwọn ìtọ́jú tí mò ń gbà kó bá mi lọ́nà míì, kò jẹ́ kí n dàgbà. Díẹ̀ ni mo fi ga ju tábìlì ìjẹun, bẹ́ẹ̀ mo ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún! Tí mo bá sọ ọjọ́ orí mi fáwọn èèyàn, irọ́ ni ọ̀pọ̀ máa ń rò pé mò ń pa!

Àmọ́ àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni máa ń fọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí. Wọn kì í mú mi ṣeré, bíi tàwọn ọmọ iléèwé mi. Mo máa ń ní in lọ́kàn pé nǹkan ṣì máa dáa. Ṣé ẹ rí i, ohun tó dáa jù téèyàn lè ní ni mo ní, mo ní Jèhófà lọ́rẹ̀ẹ́! Ohunkóhun tí ì báà ṣẹlẹ̀ sí mi, ó dá mi lójú pé Jèhófà ò ní fi mí sílẹ̀. Tí mo bá ń ronú nípa ayé tuntun rèǹtèrente tí Ọlọ́run ṣèlérí, ó máa ń múnú mi dùn, ó sì ń jẹ́ kí n nírètí pé nǹkan ṣì máa dáa.—Aísáyà 33:24.

Ronú nípa èyí: Bí André ṣe sọ, kí nìdí tó fi jẹ́ pé “ohun tó dáa jù téèyàn lè ní” ni kéèyàn ní Jèhófà lọ́rẹ̀ẹ́?—Jòhánù 17:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́