ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 60
  • Báwo Lo Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù Ikú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Lo Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù Ikú?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • ‘Òtítọ́ Yóò Sọ Yín Di Òmìnira’—Lọ́nà Wo?
    Jí!—2012
  • Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Jèhófà Wà Ní Ọkàn Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Kíkọ́ Láti Rí Ìgbádùn Nínú Ìbẹ̀rù Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ẹ Bẹru Jehofa Ki Ẹ Sì Fi Ogo Fun Orukọ Mímọ́ rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 60

Báwo Lo Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù Ikú?

Ohun tí Bíbélì sọ

A máa ń bẹ̀rù ikú lóòótọ́ torí ọ̀tá wa ni, a sì máa n sa gbogbo ipá wa ká lè dáàbò bo ẹ̀mí wa. (1 Kọ́ríńtì 15:26) Àmọ́, ìbẹ̀rù ikú tí kò bọ́gbọ́n mu nítorí ìtàn èké tàbí ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán ti fi àwọn èèyàn “sábẹ́ ìsìnrú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn.” (Hébérù 2:15) Tó o bá ń bẹ̀rù ikú ju bó ṣe yẹ lọ, o kò ní gbádùn ìgbésí ayé rẹ, àmọ́ tó o bá mọ òtítọ́, wàá bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú.​—Jòhánù 8:32.

Òtítọ́ nípa ohun tí ikú jẹ́

  • Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan. (Sáàmù 146:4) Má ṣe máa bẹ̀rù pé wàá jìyà tàbí joró lẹ́yìn tó o bá kú, torí pé Bíbélì fi ikú wé oorun.​—Sáàmù 13:3; Jòhánù 11:11-​14.

  • Àwọn òkú kò lè pa wá lára. Kódà, àwọn oníjàgídíjàgan tó jẹ́ ọ̀tá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tí di “aláìlè-ta-pútú nínú ikú.” (Òwe 21:16) Bíbélì sọ pé: “ìkórìíra wọn àti owú wọn ti ṣègbé.”​—Oníwàásù 9:6.

  • Ikú kì í ṣe òpin ìrìn àjò ẹ̀dá láyé. Ọlọ́run yóò jí àwọn èèyàn tó ti ku dìde nípasẹ̀ àjíǹde.​—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.

  • Ọlọ́run ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ‘ikú kì yóò sí mọ́.’ (Ìṣípayá 21:4) Nígbà yẹn, àwọn èèyàn á ti bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú èyíkéyìí. Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”​—Sáàmù 37:29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́