ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 43
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lóye Àwọn Òbí Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lóye Àwọn Òbí Mi?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè nípa èdèkòyédè
  • Ìdí tí èdèkòyédè fi máa ń wáyé
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Kí Ni Kí N Ṣe Báwọn Òbí Mi Bá Ń Jà?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Mọ Àwọn Òbí Mi?
    Jí!—2010
  • Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù!
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Bí O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Láìsí Àríyànjiyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 43
Àwọn ọmọ máa ń fẹ́ bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n bá jọ ṣeré jáde

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lóye Àwọn Òbí Mi?

  • Ìbéèrè nípa èdèkòyédè

  • Ìdí tí èdèkòyédè fi máa ń wáyé

  • Ohun tó o lè ṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Ìbéèrè nípa èdèkòyédè

  • Èwo nínú àwọn òbí rẹ lẹ jọ sábà máa ń ni èdèkòyédè?

    • Bàbá

    • Ìyá

  • Báwo ni èdèkòyédè ṣe máa ń wáyé láàárín yín sí?

    • Kì í sábà wáyé

    • Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan

    • Ní gbogbo ìgbà

  • Báwo ni èdèkòyédè náà ṣe máa ń le tó?

    • A tètè máa ń yanjú ẹ̀ tí àlááfíà sì máa jọba.

    • A máa yanjú ẹ̀ àmọ́ á jẹ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àríyànjiyàn.

    • Bá a ti ẹ̀ jiyàn pàápàá ìyẹn ò ní kó yanjú.

Tí o kò bá kí ń lóye àwọn òbí rẹ, o lè máa rò ó pé ó yẹ kí wọ́n wá nǹkan ṣe sí i kí àyípadà lè wà. Bí wàá ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá rí àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti dín èdèkòyédè náà kù. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wo . . .

Ìdí tí èdèkòyédè fi máa ń wáyé

  • Bó o ṣe ń ronú. Bó o ṣe ń dàgbà, wà á máa ronú lórí àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe nígbà tó o ṣì wà lọ́mọdé. Èyí á mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí ní ronú lórí àwọn nǹkan tó o rò pé ó yẹ kó o ṣe, àmọ́ tó ṣeéṣe kó ta ko ohun táwọn òbí rẹ fẹ́. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ pé: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.”​—Ẹ́kísódù 20:12.

    Òótọ́ ọ̀rọ̀: Kéèyàn tó lè yẹra fún ìbínú ó gba pé kónítọ̀hún gbọ́n kó sì tún dàgbà dénú.

  • Òmìnira. Bó o ṣe ń dàgbà, ó ṣeé ṣe káwọn òbí rẹ fún ẹ lómìnira sí i. Àmọ́ ìṣòro ibẹ̀ ni pé, ó lè má pọ̀ tó bó o ṣe fẹ́ àbí kó má tètè yá bó o ṣe rò, ìyẹn sì lè yọrí sí èdèkòyédè. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí.”​—Éfésù 6:1.

    Òótọ́ ọ̀rọ̀: Lọ́pọ̀ ìgbà, ọwọ́ tó o fi ń mú òmìnira táwọn òbí rẹ ń fún ọ, ló máa sọ bí wọ́n á ṣe máa fún ọ lómìnira sí i.

Ohun tó o lè ṣe

  • Gbájú mọ́ ojúṣe rẹ. Kàkà tí wàá fi máa dá àwọn òbí rẹ lẹ́bi, àbí kó o máa bá wọn jà, o ò ṣe kúkú wo ohun tó o lè ṣe tí wàá fi wá àlááfíà. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jeffrey sọ pé, “Kì í ṣe ohun táwọn òbí bá sọ ló sábà máa ń fa ìjà, bí èèyàn bá ṣe fèsì ló máa ń fà á, ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀ ni.”

    Bíbélì sọ pé: “Níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà.”​—Róòmù 12:18.

  • Tẹ́tí sílẹ̀. Samantha ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé, “Kò rọrùn fún mi láti máa fetí sílẹ̀, àmọ́ táwọn òbí bá rí i pé ò ń tẹ́tí sí wọn, ó ṣeé ṣe kí àwọn náà fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.”

    Bíbélì sọ pé: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”​—Jákọ́bù 1:19.

    1. Agbada tí wọ́n fi ń dín nǹkan gbaná lórí iná; 2. Apá ò sì ká iná náà mọ́

    Bí iná ni aáwọ̀ rí, béèyàn kò bá tètè wá nǹkan ṣe sí i ó máa di nǹkan ńlá

  • Ẹ máa ronú pa pọ̀. Ìwọ àti àwọn òbí rẹ lè jọ yanjú aáwọ̀ àárín yín. Ṣe ni kó o gba ohun tí àwọn òbí rẹ bá ń sọ torí ire rẹ ni wọ́n ń wá. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Adam sọ pẹ́, “Tí òbí bá ń bá ọmọ wí lórí nǹkan kan, ohun tó máa ṣe ọmọ náà láǹfààní ni òbí máa ń rò, àwọn ọmọ náà á sì máa rò ohun tó dára jù fún àwọn, torí náà, èrò àwọn méjèèjì bára mu.”

    Bíbélì sọ pé: “Kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà.”​—Róòmù 14:19.

  • Máa fòye báni lò. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah sọ pé: “O máa ń ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá rántí pé bí mo ṣe ní ìṣòro tèmi làwọn òbí mi náà ní tiwọn.” Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Carla náà sọ pé, “Mo máa ń fi ọ̀rọ̀ àwọn òbí mi ro ara mi wò, mo màá ń rò ó pé, báwo ló ṣe máa rí tó bá jẹ́ èmi ni mò ń tọ́jú àwọn ọmọ, tí mo sì tún ní ìṣòro tèmi náà? Ṣe ire àwọn ọmọ mi ló máa jẹ mí lógún?”

    Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”​—Fílípì 2:4.

  • Jẹ́ onígbọràn. Lákòótán, ohun tí Bíbélì fẹ́ kó o ṣe nìyẹn. (Kólósè 3:​20) Tó o bá sì fara mọ́ ọ, nǹkan á rọrùn fún ọ. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Karen sọ pé: “Ọ̀kan mi máa ń balẹ̀ tí mo bá ti ṣe ohun tí àwọn òbí mi fẹ́, wọ́n ti ṣe wàhálà gan-an nítorí mi, ó sì yẹ kí n san án pa dà fún wọn.” Tá a bá jẹ́ onígbọràn, kò ní sí wàhálà láàárín àwa àti àwọn òbí wa!

    Bíbélì sọ pé: “Níbi tí igi kò bá sí, iná a kú.”​—Òwe 26:20.

Ìmọ̀ràn kan rèé. Tó bá jẹ́ pé o ò kì i fẹ́ bá èèyàn sọ̀rọ̀, o ò ṣe máa kọ èrò rẹ sílẹ̀, tàbí kó o tẹ àtẹ̀jíṣẹ́. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Alyssa sọ pé, “Ohun tí mo máa ń ṣe nìyẹn nígbà tí mi ò bá lè sọ nǹkan tó wà lọ́kàn mi síta, ó sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni, torí màá lè sọ ohun tó wà lọ́kàn mi láì pariwo, mi ò sì ní sọ ohun tí màá kábàámọ̀ rẹ̀ tó bá yá.”

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

Marilyn

“Tó bá tí rẹ èèyàn, ńṣe ni èèyàn á kàn máa kanra. Àmọ́ ohun tó dáa jù nígbà míì ni pé kéèyàn dákẹ́, kó sì lọ sùn. Tó bá máa fi di àárọ̀ ọjọ́ kejì nǹkan á ti yàtọ̀.”​—Marilyn.

Devin

“Sùúrù ló máa jẹ́ kó o lè borí ìṣòro èyíkéyìí tó o bá ní. Tí aáwọ̀ bá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀, sinmẹ̀dọ̀ kó o sì ronú jinlẹ̀. Tá a bá sọ̀rọ̀ lákòókò tínú ń bí wa lọ́wọ́, ìgbà yẹn ni ìṣòro náà máa ń le sí i.”​—Devin.

Mackenzie

“Mi ò fẹ́ kó di ọjọ́ iwájú kí n wá máa kábàámọ̀ pé mi ò ṣe ohun tó yẹ fún àwọn òbí mi. Èyí ló máa ń jẹ́ kí n fetí sílẹ̀ tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, tí mi ò sì kì í tètè gbaná jẹ.”​—Mackenzie.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́