ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 47
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Jẹ́ Olóòótọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Jẹ́ Olóòótọ́?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí tí àwọn èèyàn kan kì í fi í ṣòótọ́
  • Ìdí tó fi dáa kéèyàn jẹ́ olóòótọ́
  • Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun Gbogbo
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun Gbogbo
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìṣòtítọ́ Lérè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àǹfààní Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Olóòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 47
Ọmọ kan ń jíwèé wò nígbà ìdánwò, ó ń fún ọmọ míì ní ìwé kékeré kan

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Jẹ́ Olóòótọ́?

  • Ìdí tí àwọn èèyàn kan kì í fi í ṣòótọ́

  • Ìdí tó fi dáa kéèyàn jẹ́ olóòótọ́

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Ìdí tí àwọn èèyàn kan kì í fi í ṣòótọ́

Lóde òní, ó máa ń ṣe àwọn èèyàn bíi pé òtítọ́ ò lérè. Ohun táwọn kan máa ń rò ni pé:

  • ‘Tí mi ò bá parọ́ fún àwọn òbí mi, wọ́n lè fìyà jẹ mí.’

  • ‘Tí mi ò bá jíwèé wò nígbà ìdánwò yìí, mo lè gbòdo.’

  • ‘Tí mi ò bá jí kiní yìí, màá ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fowó pa mọ́ ni kí n tó lè rà á.’

Àwọn kan lè máa rò pé, ‘Kì í ṣe nǹkan bàbàrà. Ṣebí gbogbo èèyàn ló ń ṣe irú ẹ̀?’

Bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ìdáhùn ìbéèrè yẹn. Ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́, ló gbà pé ó dáa kéèyàn jẹ́ olóòótọ́, ó sì nídìí tí wọ́n fi gbà bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé a máa jèrè ohun tá a bá ṣe, yálà rere tàbí búburú.

Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí irọ́ pípa ti ṣe fún àwọn èèyàn kan.

Ó dá mọ́mì lójú pé irọ́ ni mò ń pa. Ẹ̀ẹ̀mẹta ni mo parọ́ fún wọn lórí ọ̀rọ̀ yẹn, ó sì wá múnú bí wọn gan-an. Fún ọ̀sẹ̀ méjì, wọn ò jẹ́ kí n lo fóònù, wọn ò sì jẹ́ kí n wo tẹlifíṣọ̀n fún oṣù kan. Látìgbà yẹn, mi ò tún parọ́ fún àwọn òbí mi mọ́!”​—Anita .

Ronú nípa èyí: Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ó máa ṣe díẹ̀ kí mọ́mì Anita tó tún lè fọkàn tán an?

Bíbélì sọ pé: “Nítorí náà, nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.”​—Éfésù 4:25.

Mi ò tiẹ̀ wá rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan, torí pé irọ́ náà ni mo pa fún wọn tẹ́lẹ̀. Téèyàn bá ń sọ òótọ́ látìbẹ̀rẹ̀, irú nǹkan yẹn ò ní ṣẹlẹ̀ sí i!”​—Anthony.

Ronú nípa èyí: Kí ni Anthony ò bá ti ṣe kí ohun tó ṣe é yẹn má bàa ṣẹlẹ̀?

Bíbélì sọ pé: “Ètè èké jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n àwọn tí ń fi ìṣòtítọ́ hùwà jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.”​—Òwe 12:22.

Tó bá ń sọ̀rọ̀ báyìí, ẹnu ẹ̀ dùn gan-an, ó sì máa ń bù mọ́ ọ̀rọ̀. Mo fẹ́ràn ọ̀rẹ́ mi yìí, mi ò sì kí ń fẹ́ ro nǹkan tó bá sọ jù. Àmọ́ kò rọrùn fún mi láti fọkàn tán an tàbí gba ọ̀rọ̀ ẹ̀ gbọ́.”​—Yvonne.

Ronú nípa èyí: Ojú wo làwọn èèyàn á fi máa wo ọ̀rẹ́ Yvonne yìí torí bó ṣe máa ń bù mọ́ ọ̀rọ̀ tí kì í sì í sọ òótọ́?

Bíbélì sọ pé: “A . . . dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”​—Hébérù 13:18.

Ilé kan tí ìpìlẹ̀ rẹ̀ ti fọ́

Tí ìpìlẹ̀ ilé kan bá fọ́, ògiri ilé yẹn lè má lágbára mọ́; lọ́nà kan náà, téèyàn ò bá ṣòótọ́, ó lè ba orúkọ rere tó ní jẹ́

Ìdí tó fi dáa kéèyàn jẹ́ olóòótọ́

Wá wo ohun rere tó lè ṣẹlẹ̀ tó o bá jẹ́ olóòótọ́.

Mo bá a mú un, mo wá dá a dúró, mo sì dá owó rẹ̀ pa dà fún un. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ mi gan-an. Ó ní: ‘O mà ṣèèyàn ò. Ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní ṣe ohun tó o ṣe yìí.’ Obìnrin yẹn mọ̀ pé ohun tó dáa ni mo ṣe, inú mi sì dùn gan-an!”​—Vivian.

Ronú nípa èyí: Kí nìdí tó fi ṣeé ṣe kí ìwà rere Vivian ya obìnrin náà lẹ́nu? Àǹfààní wo ni Vivian rí torí pé ó jẹ́ olóòótọ́?

Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni . . . àwọn tí ń ṣe òdodo ní gbogbo ìgbà.”​—Sáàmù 106:3.

Nígbà míì tá a bá ń tún ọ́fíìsì kan ṣe, a lè rí owó ẹyọ nílẹ̀. Gbogbo ìgbà tá a bá ti rí owó bẹ́yẹn la máa ń fi sórí tábìlì. Ọ̀gá kan fẹ́rẹ̀ẹ́ bínú sí wa, ó rò pé tiwa ti pọ̀ jù. Ó ní, ‘ Owó ẹyọ kan péré mà ni!’ Àmọ́ ṣẹ́ ẹ rí i, obìnrin yẹn fọkàn tán wa gan-an.”​—Julia.

Ronú nípa èyí: Ìrànlọ́wọ́ wo làwọn tó mọ Julia sí olóòótọ́ lè ṣe fún un tó bá ń wá iṣẹ́ míì, tó sì nílò àwọn tó lè jẹ́rìí sí i pé èèyàn dáadáa ni?

Bíbélì sọ pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú.”​—2 Tímótì 2:​15.

Tí mo bá gbà á, owó máa pọ̀ nìyẹn, àmọ́ mi ò lè ṣe é. Mo sọ fún ọ̀gá tó ń bójú tó àkáǹtì, inú ẹ̀ sì dùn gan-an. Ilé iṣẹ́ náà lówó dáadáa, àmọ́ tí mo bá gba owó tó lé yẹn, á máa ṣe mí bíi pé mo jí i ni.”​—Bethany.

Ronú nípa èyí: Ṣé ìyàtọ̀ kankan wà nínú kéèyàn jí nǹkan ní ilé iṣé àti kéèyàn jí nǹkan ẹnì kan?

Bíbélì sọ pé: “Oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.”​—Òwe 3:32.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Tobi

TOBI

Iṣẹ́ ńlá ni àwọn èèyàn máa ń ṣe láti ṣètò bí wọ́n ṣe máa jíwèé wò nígbà ìdánwò. Tí wọ́n bá lè máa lo ìdajì àkókò tí wọ́n fi ń ṣèyẹn láti kàwé, wọ́n á yege nínú ìdánwò náà!

Austin

AUSTIN

Mo máa ń bi ara mi pé, ‘Kí ló burú jù tó lè ṣẹlẹ̀ sí mi tí mo bá sọ òótọ́ nípa nǹkan kan tó ṣẹlẹ̀?’ Màá wá fìyẹn wé ohun tó lè ṣẹlẹ̀ ká ní mo parọ́. Bí mo ṣe máa ń ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ yẹn ló máa ń jẹ́ kí n ṣòótọ́.

Heidy

HEIDY

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń parọ́ torí wọ́n rò pé ìyà máa jẹ wọ́n tí wọ́n bá sọ òótọ́. Téèyàn bá tiẹ̀ jìyà torí pé ó sọ òótọ́, ó ṣì dáa ju kí ẹ̀rí ọkàn máa dá a lẹ́bi tórí pé ó parọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́