ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 112
  • Ibo Là Ń Pè Ní Ọ̀run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Là Ń Pè Ní Ọ̀run?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Báwo Ni Ọ̀run Ṣe Rí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àwọn Wo Ló Wà Ní Ọ̀run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ìfihàn 21:1—“Ọ̀run Tuntun Kan àti Ayé Tuntun Kan”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?
    Jí!—2011
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 112
Òòrùn ń tàn lórí òfuurufú

Ibo Là Ń Pè Ní Ọ̀run?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ọ̀nà pàtàkì mẹ́ta ni Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà, “ọ̀run”: (1) ọ̀run tí a lè fójú rí; (2) ibi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń gbé; àti (3) ohun tó ṣàpẹẹrẹ ipò àṣẹ gíga. Àyíká ọ̀rọ̀ la fi máa ń mọ èyí tó jẹ́ nínú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.a

  1. Ọ̀run tí a lè fojú rí. “Ọ̀run” yìí ń tọ́ka sí ojú ọ̀run tá a máa ń rí láti ayé, níbi tí atẹ́gùn ti ń fẹ́, tí àwọn ẹyẹ ti ń fò, tí òfuurufú ti ń rọ̀jò àti yìnyín àti ibi tí ààrá ti máa ń sán. (Sáàmù 78:26; Òwe 25:3; Aísáyà 55:10; Lúùkù 17:24) Ó tún lè túmọ̀ sí ibi gbalasa tó yí òbíríkítí ayé ká, níbi tí “oòrùn àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀” wà.—Diutarónómì 4:19; Jẹ́nẹ́sísì 1:1.

  2. Ibi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń gbé. Ọ̀rọ̀ náà, “ọ̀run” tún lè túmọ̀ sí ọ̀run tí a kò lè fojú rí tàbí ibi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń gbé. Ó kọjá àgbáálá ayé tá a lè fojú rí. (1 Àwọn Ọba 8:27; Jòhánù 6:38) Ọ̀run yìí ni Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ “Ẹ̀mí” àtàwọn áńgẹ́lì tó dá wà. Ẹ̀dá ẹ̀mí náà láwọn áńgẹ́lì yìí. (Jòhánù 4:24; Mátíù 24:36) Láwọn ìgbà míì, “ọ̀run” máa ń dúró fún àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́, ìyẹn “ìjọ àwọn ẹni mímọ́.”​—Sáàmù 89:5-7.

    Bíbélì tún máa ń lo “ọ̀run” láti tọ́ka sí “ibi . . .  tí [Jèhófà] ń gbé” gan-an láàárín àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yòókù. (1 Àwọn Ọba 8:43, 49; Hébérù 9:24; Ìṣípayá 13:6) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n á lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run, wọn ò sì ní lè dé iwájú Jèhófà mọ́. Àmọ́, wọ́n ṣì máa jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí.​—Ìṣípayá 12:7-9, 12.

  3. Ohun tó ṣàpẹẹrẹ ipò àṣẹ gíga. Ìwé Mímọ́ tún máa ń fi “ọ̀run” ṣàpẹẹrẹ ipò tó gá, pàápàá ipò àwọn aláṣẹ. Àwọn tó máa ń wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀ ni:

    • Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀, tó jẹ́ Olódùmarè Ọba Aláṣẹ—2 Kíróníkà 32:20; Lúùkù 15:21.

    • Ìjọba Ọlọ́run, tó máa rọ́pò ìjọba àwọn èèyàn. Bíbélì pe Ìjọba yìí ní “ọ̀run tuntun”​—Aísáyà 65:17; 66:22; 2 Pétérù 3:13.b

    • Àwọn Kristẹni tó wà láyé àmọ́ tí wọ́n ń retí àtilọ sọ́run.​—Éfésù 2:6.

    • Àwọn ìjọba èèyàn tó ń ṣàkóso lé àwọn tó kù lórí.​—Aísáyà 14:12-14; Dáníẹ́lì 4:20-22; 2 Pétérù 3:7.

    • Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú tó ń ṣàkóso ayé báyìí.​—Éfésù 6:12; 1 Jòhánù 5:19

Báwo ni ọ̀run ṣe rí?

Ọwọ́ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó wà lọ́run dí gan an. Àìmọye mílíọ̀nù àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ló ń gbé lọ́run, tí wọ́n ń “pa ọ̀rọ̀ [Jèhófà] mọ́.”—Sáàmù 103:20, 21; Dáníẹ́lì 7:10.

Bíbélì sọ pé ọ̀run mọ́lẹ̀ yòò. (1 Tímótì 6:15, 16) Wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí ọ̀run tó ní “ìrísí ìtànyòò” nínú ìran, “ìṣàn iná” sì ni Dáníẹ́lì rí nínú ìran ọ̀run tó rí. (Ìsíkíẹ́lì 1:26-28; Dáníẹ́lì 7:9, 10) Ọ̀run jẹ́ mímọ́, tàbí ká sọ pé ó mọ́ tónítóní, ó sì rẹwà.​—Sáàmù 96:6; Aísáyà 63:15; Ìṣípayá 4:2, 3.

Gbogbo àlàyé tí Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ́ pé ibi ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ni ọ̀run jẹ́. (Ìsíkíẹ́lì 43:2, 3) Àmọ́, kò sí bí àwa èèyàn ṣe lè lóye bí ọ̀run ṣe rí gan an, torí òye wa ò lè gbé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run torí pé a kì í ṣe ẹ̀dá ẹ̀mí.

a Ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run” wá látinú èdè Hébérù tó túmọ̀ sí “gíga” tàbí “gíga jù lọ.” (Òwe 25:3) Wo ìwé The New Brown, Driver, and Briggs Hebrew and English Lexicon of the Old Testament, ojú ìwé 1029.

b Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tó ń jẹ́ McClintock and Strong’s Cyclopedia sọ pé ọ̀run tuntun tí Aísáyà 65:17 ń tọ́ka sí ni “ìṣàkóso tuntun, ìjọba tuntun”​—Ìdìpọ̀ Kẹrin, ojú ìwé 122.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́