ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 73
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Mi Látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Mi Látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Ọmọ Mi?
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Mi Níléèwé?
    Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
  • Jíja Àjàbọ́ Lọ́wọ́ Ìfòòró Ẹni
    Jí!—2003
  • Fífòòró Ẹni—Díẹ̀ Lára Ohun Tó Ń Fà Á Àtàwọn Ohun Tó Ń Yọrí Sí
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 73
Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ̀dọ́kùnrin kan lẹ́yìn tí wọ́n halẹ̀ mọ́ ọn látorí íńtánẹ́ẹ̀tì

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Mi Látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  • Ohun tó o lè ṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Ohun tó yẹ kó o mọ̀

Íńtánẹ́ẹ̀tì ti mú kó rọrùn fáwọn èèyàn láti máa halẹ̀ mọ́ àwọn míì. Ìwé CyberSafe sọ pé “torí pé èèyàn ò lè rójú ẹni tó ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i lórí íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn ti jẹ́ kí àwọn tó jẹ́ ọmọlúàbí pàápàá máa ṣàìdaa sí àwọn míì lórí íńtánẹ́ẹ̀tì.”

Àwọn kan wà tó ṣeé ṣe kí wọ́n dájú sọ. Lára wọn ni àwọn tó máa ń ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, àwọn tó dà bíi pé ìṣesí tàbí ìrísí wọn yàtọ̀ sí tàwọn tó kù, tàbí àwọn tó máa ń fojú kéré ara wọn láwùjọ.

Tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ ẹnì kan látorí íńtánẹ́ẹ̀tì, ó lè ṣèpalára fún un gan-an. Ó lè mú kí ẹni náà máa dá wà, kó sì máa sorí kọ́. Ó tiẹ̀ ti mú káwọn kan gbẹ̀mí ara wọn.

Ohun tó o lè ṣe

Kọ́kọ́ bi ara rẹ pé, ‘Ṣé lóòótọ́ ni ẹni yìí ń halẹ̀ mọ́ mi?’ Ìgbà míì wà tí ẹlòmíì á sọ̀rọ̀ tó dùn wá, àmọ́ tí òun ò kà á sí ní tiẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, a lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí Bíbélì fún wa, pé:

“Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya, nítorí pé fífara ya sinmi ní oókan àyà àwọn arìndìn.”​—Oníwàásù 7:9.

Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ṣe lẹnì kan ń mọ̀ọ́mọ̀ yọ ẹ́ lẹ́nu, tó ń dójú tì ẹ́ tàbí tó ń fòòró ẹ̀mí ẹ, ó ń halẹ̀ mọ́ ẹ nìyẹn.

Tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ ẹ látorí íńtánẹ́ẹ̀tì, máa fi sọ́kàn pé: Bó o bá ṣe hùwà pa dà lè mú kí ìṣòro náà dín kù tàbí kó le sí i. Gbìyànjú ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn àbá yìí.

Má ṣe dá ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ẹ lóhùn. Bíbélì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀, ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.”​—Òwe 17:27.

Ìdí kan tí ìmọ̀ràn yẹn fi gbéṣẹ́ rèé: Nínú ìwé Cyberbullying and Cyberthreats tí Nancy Willard kọ, ó sọ pé: “Ohun táwọn tó máa ń halẹ̀ mọ́ àwọn míì máa ń fẹ́ ṣe gan-an ni pé wọ́n fẹ́ kí ẹni náà fara ya. Tí wọ́n bá ti lè rí i pé ẹni náà ti bínú, agbára tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ nìyẹn.”

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Nígbà míì, ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn má dá wọn lóhùn rárá.

Tó bá tiẹ̀ ń ṣe ẹ́ bíi kó o gbẹ̀san, má gbẹ̀san. Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ má ṣe máa fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe tàbí ìkẹ́gàn san ìkẹ́gàn.”​—1 Pétérù 3:9.

Ìdí kan tí ìmọ̀ràn yẹn fi gbéṣẹ́ rèé: Ìwé Cyber-Safe Kids, Cyber-Savvy Teens sọ pé, “Téèyàn bá fìbínú hàn sí àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ ọn, ṣe ló ń fi ibi tó kù sí hàn wọ́n, ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ ọn.” Tó o bá sì gbẹ̀san lára wọn, ó lè lọ dà bíi pé ìwọ náà ń wá wàhálà.

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Má ṣe dá kún wàhálà tí wọ́n ń bá ẹ fà.

Múra sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ.” (Róòmù 12:21) Nǹkan wà tó o lè ṣe tí wọn ò fi ní halẹ̀ mọ́ ẹ mọ́, láìní dá kún ìṣòro náà.

Bí àpẹẹrẹ:

  • Tẹ bọ́tìnì tí ẹni náà ò fi ní lè fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹ mọ́ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Ìwé Mean Behind the Screen sọ pé, “Téèyàn bá tó ka ọ̀rọ̀ kan ló máa mọ̀ bóyá ó dun òun àbí kò dun òun.”

  • Tó ò bá tiẹ̀ ka ọ̀rọ̀ tẹ́ni náà fi ránṣẹ́, máa tọ́jú gbogbo ẹ̀ pa mọ́. Wàá lè fi gbèjà ara ẹ. Èyí kan àwọn ọ̀rọ̀ ìbínú tó fi ránṣẹ́, àwọn àtẹ̀jíṣẹ́, e-mail, àwọn ohun tó gbé sórí ìkànnì àjọlò, ohùn tó gbà sílẹ̀ tó wá fi ránṣẹ́ sí ẹ tàbí ohunkóhun míì tó fi ránṣẹ́.

  • Sọ fún ẹni náà pé kó jáwọ́. Fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i, jẹ́ kó mọ̀ pé kì í ṣọ̀rọ̀ eré, síbẹ̀ má jẹ́ kí ìbínú hàn nínú ọ̀rọ̀ ẹ. Àpẹẹrẹ ohun tó o lè kọ nìyí:

    • “Má fi ọ̀rọ̀ kankan ránṣẹ́ mọ́.”

    • “Yọ ohun tó o gbé sórí ìkànnì yìí kúrò.”

    • “Tírú nǹkan yìí bá ṣì ń ṣẹlẹ̀, màá gbé àwọn ìgbésẹ̀ míì kí n lè rí i pé irú ẹ̀ ò wáyé mọ́.”

  • Má fojú kéré ara ẹ. Dípò tí wàá fi máa wo ibi tó o kù sí, ibi tó o dáa sí ni kó o máa wò. (2 Kọ́ríńtì 11:6) Bíi tàwọn tó máa ń halẹ̀ mọ́ni lójúkojú, àwọn tó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ látorí íńtánẹ́ẹ̀tì náà máa ń ṣọ́ àwọn tí wọ́n bá rí i pé wọ́n dùn ún mú.

  • Sọ̀rọ̀ náà fún àgbàlagbà. Kọ́kọ́ sọ fáwọn òbí ẹ. O tún lè fẹjọ́ sun àjọ tó ń bójú tó ìkànnì ti ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ẹ ń lò. Tọ́rọ̀ bá dójú ẹ̀ pátápátá, kí ìwọ àtàwọn òbí ẹ lọ fẹjọ́ sun àwọn aláṣẹ iléèwé ẹ tàbí kẹ́ ẹ fẹjọ́ sun àwọn ọlọ́pàá. Ẹ tiẹ̀ lè ki ẹsẹ̀ òfin bọ̀ ọ́.

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Nǹkan wà tó o lè ṣe tí wọn ò fi ní halẹ̀ mọ́ ẹ mọ́ tàbí tí ohun tí wọ́n ń ṣe sí ẹ ò fi ní pa ẹ́ lára jù.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Natalie

“Tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ ẹ látorí íńtánẹ́ẹ̀tì, bi ara ẹ pé: ‘Ṣó tiẹ̀ yẹ kí n máa lo ìkànnì tí wọ́n ti ń halẹ̀ mọ́ mi yìí ni? Ṣé kì í ṣe pé ìpalára tó ń ṣe fún mi pọ̀ ju àǹfààní tó ń ṣe mí lọ? Ṣé mo lè ṣe é tí ẹni náà ò fi ní lè fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí mi mọ́? Lọ́pọ̀ ìgbà, nǹkan kan máa ń wà tó o lè ṣe tí wàá fi yọra ẹ kúrò nínú ìṣòro náà.”—Natalie.

Darius

“Tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ ẹ látorí íńtánẹ́ẹ̀tì, sọ fún ẹnì kan tó dàgbà. Má bẹ̀rù pé àwọn èèyàn á máa sọ pé ‘o ò lè’ àbí pé wọ́n á máa pè ẹ́ ní ‘ọ̀dẹ̀.’ Kì í ṣe irú ẹni tó o jẹ́ nìyẹn. Ìwọ gan-an lo ṣakin, torí ẹni tó bá dákẹ́, tara ẹ̀ á bá a dákẹ́.”​—Darius.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́