ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 76
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí ni wọ́n máa ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?
  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o lọ?
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ibi Ìjọsìn Wa Rèé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Bá A Ṣe Ṣètò Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 76
Ọ̀dọ́kùnrin kan ń wo àwọn tó ń wọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàdé ní ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ní ilé ìjọsìn tí wọ́n máa ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kí ni wọ́n ń ṣe níbẹ̀, àǹfààní wo lo sì máa rí tó o bá lọ síbẹ̀?

  • Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?

  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o lọ?

  • Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Kí ni wọ́n máa ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?

Gbọ̀ngàn Ìjọba la ti máa ń kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó lè ṣe wá láǹfààní. Àwọn ìpàdé tá à ń ṣe níbẹ̀ máa jẹ́ kó o:

  • mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run.

  • mọ ìdí tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀ láyé.

  • máa hùwà rere.

  • rí àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa.

Ǹjẹ́ O Mọ̀? Ìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń pe ibi ìpàdé wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ni pé ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run là ń sọ níbẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.​​—Mátíù 6:​9, 10; 24:14; Lúùkù 4:43.

Kí nìdí tó fi yẹ kó o lọ?

Àwọn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àwọn ìlànà Bíbélì tá à ń kọ́ ní ibi ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa jẹ́ kó o “ní ọgbọ́n.” (Òwe 4:5) Ìyẹn ni pé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ ní ìgbésí ayé rẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa jẹ́ kó o rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì ní ìgbésí ayé, irú bíi:

  • Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa?

  • Ṣé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé?

  • Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú?

Díè rèé lára àwọn àsọyé Bíbélì tá a máa ń gbọ́ ní òpin ọ̀sẹ̀ láwọn ìpàdé wa:

  • Kí nìdí Tó Fi Yẹ Kí Bíbélì Jẹ́ Amọ̀nà Rẹ?

  • Ọ̀dọ̀ Ta Lo Ti Lè Rí Ìrànlọ́wọ́ Lákòókò Wàhálà?

  • Ohun tí Ìjọba Ọlọ́run Ń Ṣe Fún Wa Nísinsìnyí.

“Ọmọ kíláàsì mi kan wá sí ìpàdé. Ó jókòó pẹ̀lú ìdílé wa, a sì fún un ní ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, ó sọ fún mi pé òun fẹ́ràn báwọn èèyàn ṣe ń dáhùn nígbà tí wọ́n ń béèrè ìbéèrè. Ó tún sọ pé àwọn ò ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì àwọn bíi tiwa.”​​—Brenda.

Ǹjẹ́ O Mọ̀? Ọ̀fẹ́ ni àyè ìjókòó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, a kì í sì gbé igbá owó.

Wàá rí ìṣírí gbà. Bíbélì sọ pé ọ̀kan lára ìdí táwa Kristẹni fi ń péjọ pọ̀ ni láti “fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì.” (Hébérù 10:​24, 25) Nínú ayé táwọn èèyàn ò ti mọ̀ ju tara wọn lọ yìí, ó dájú pé ó máa dára gan-an téèyàn bá ń péjọ pẹ̀lú àwọn tó máa ń fi Ọlọ́run ṣáájú, tọ́rọ̀ àwọn míì sì jẹ lógún.

“Mo lè ti ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ kan kó sì ti rẹ̀ mí gan-an, àmọ́ tí mo bá dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn èèyàn máa ń mú kí ara tù mí. Tí mo bá ń pa dà sílé lẹ́yìn tá a bá parí ìpàdé, inú mi máa ń dùn, ara mi sì máa ń yá gágá láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọjọ́ lọ́jọ́ kejì.”​​—Elisa.

Ǹjẹ́ O Mọ̀? Ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà kárí ayé, láwọn ibi tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà [60,000]. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àtàbọ̀ [1,500] Gbọ̀ngàn Ìjọba là ń kọ́ lọ́dọọdún nítorí àwọn ẹni tuntun tó ń wá sí ìpàdé wa.a

Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Jessica

“Nígbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama, ọmọ kíláàsì mi kan tẹ̀lé mi lọ sí ìpàdé, inú rẹ̀ sì dùn gan-an bó ṣe rí tí àwọn ọmọdé àtàgbà ṣe jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ pọ̀. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀gá mi wá sí ìpàdé, ohun tó sì múnú rẹ̀ dùn ni bá a ṣe ń lo Bíbélì lóòrèkóòrè. Èmi náà túbọ̀ mọyì ìpàdé wa bí ọ̀gá mi ṣe ń sọ pé òun mọrírì ìpàdé wa!”​—Jessica.

Timothy

“Àwọn ìpàdé wa máa ń mára tù mí, ó sì máa ń jẹ́ kí ń bọ́ lọ́wọ́ àníyàn. Ibẹ̀ la ti máa ń kọ́ bá a ṣe lè gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀, bá a ṣe lè máa hùwà rere àtàwọn nǹkan míì. Gbogbo ìgbà tí mo bá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba ni mo máa ń rí ìṣírí gbà tí ara sì máa ń tù mí.”​—Timothy.

Jacob

“Ọkùnrin kan tí mo pè wá sí ìpàdé sọ pé: ‘Ìdí tí mo fi wá sí ìpàdé ni pé mo fẹ́ rí àwọn nǹkan tí màá fi mọ̀ pé irọ́ ni àwọn ohun tẹ́ ẹ gbà gbọ́. Àmọ́ mo wá rí i pé ohun tí mo gbà gbọ́ gan-an ni kì í ṣe òótọ́!’ Ohun míì tó tún wú u lórí ni báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ṣọ̀yàyà sí i. Ó ní: ‘Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ yín ni, bẹ́ẹ ṣe ń ṣe sí mi mú kó dà bíi pé a ti mọra tipẹ́!’”​—Jacob.

Madison

“Àwọn ìgbà kan wà tí mo rò pé, ‘Mi ò ní dúró tí ìpàdé bá ti parí, ṣe ni màá tètè máa lọ sílé.’ Àmọ́ tí ìpàdé bá ti ń lọ lọ́wọ́, èrò yẹn máa ń kúrò lọ́kàn mi. Ńṣe lèmi àtàwọn èèyàn á máa sọ̀rọ̀ tá a bá ti parí ìpàdé, mì ò sì ní mọ ìdí tí mo fi ní irú èrò yẹn kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀. Tí kì í bá ṣe àwọn ìpàdé wa ni, mi ò bá má ní àwọn ọ̀rẹ́ dáadáa tí mo ní báyìí.”​—Madison.

a Tó o bá fẹ́ mọ ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà, lọ sí ìkànnì jw.org ní abala “Ìpàdé Ìjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà,” kó o sì tẹ “Wá Ibi Tó Sún Mọ́ Ẹ.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́