ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwhf àpilẹ̀kọ 1
  • Bó o Ṣe Lè Kápá Ìbínú Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó o Ṣe Lè Kápá Ìbínú Rẹ
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbínú?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Tí Èdèkòyédè Bá Wáyé Láàárín Tọkọtaya
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Máà Jẹ́ Kí Ìbínú Mú Ọ Kọsẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • “Ìjìnlẹ̀ Òye Tí Ènìyàn Ní Máa Ń Dẹwọ́ Ìbínú Rẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
ijwhf àpilẹ̀kọ 1
Ìyàwó kan ń bínú torí pé ọkọ rẹ̀ ń wo tẹlifíṣọ̀n nígbà tí òun ń fọ abọ́

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Bó o Ṣe Lè Kápá Ìbínú Rẹ

Ká sọ pé ọkọ tàbí ìyàwó rẹ sọ̀rọ̀ kan tàbí ṣe ohun kan tó múnú bí ẹ, o wá gbìyànjú láti pa ìbínú yẹn mọ́ra, nígbà tí ẹnì kejì rẹ kíyè sí pé inú ń bí ẹ, ó tún wá ń bi ẹ ní ìbéèrè, ìyẹn wá múnú bí ẹ sí i. Báwo lo ṣe lè kápá ìbínú rẹ̀ tí irú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀?

  • Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  • Ohun tó o lè ṣe

Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  • Ìbínú lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ. Ìwádìí ti fi hàn pé ó máa rọrùn fún ẹni tí kì í kápá ìbínú rẹ láti ní àrùn ọkàn, ìsoríkọ́, ẹ̀jẹ̀ ríru àti àwọn àìsàn tí kì í jẹ́ kí oúnjẹ dà bó ṣe yẹ. Ìbínú tún máa ń fa àìsàn tí kì í jẹ́ kí èèyàn rí oorun sùn, ó máa ń fa àníyàn, ó lè fa àìsàn sí àwọ̀ ara tàbí àrùn rọpárọsẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú” torí ìpalára ló máa ń yọrí sí.​—Sáàmù 37:8.

  • Kò dáa kí èèyàn máa di ìbínú sínú. Tó o bá ń fi ìbínú rẹ pamọ́, ṣe ló máa dà bí ìgbà tí àrùn kan ń ba ẹ jà láti inú wá. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ kó o máa ṣe àríwísí àwọn míì. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kó ṣòro fún àwọn èèyàn láti bá ẹ gbé torí pé, àjọgbé yín kò ní wọ̀, ó sì lè ba ìgbéyàwó rẹ jẹ́.

Ohun tó o lè ṣe

  • Àwọn ìwà dáadáa rẹ̀ ni kó o máa wò. Kọ àwọn nǹkan mẹ́ta tó o fẹ́ràn nípa ẹnì kejì rẹ sílẹ̀. Nígbà míì tó bá ṣe nǹkan tó múnú bí ẹ, ronú nípa àwọn ìwà dáadáa tó o kọ sílẹ̀ lọ́jọ́sí. Èyí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kápá ìbínú rẹ.

    Ìlànà Bíbélì: ‘Ẹ fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.’​—Kólósè 3:15.

    Ìyàwó ilé kan tó ń ṣiṣẹ́ ń ronú nípa bí ọkọ rẹ̀ ṣe máa ń bá a ṣe iṣẹ́ ilé, tó máa ń tẹ́tí sí i, tó sì máa ń tọ́jú rẹ̀ nígbà tó bá rẹ̀ ẹ́
  • Kọ́ bó o ṣe lè máa dárí jini. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, fi ojú tí ẹnì kejì rẹ fi ń wo nǹkan wò ó. Èyí máa jẹ́ kó o mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, ìyẹn ni Bíbélì pè ní “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì.” (1 Pétérù 3:8) Lẹ́yìn náà, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ohun tó ṣe burú tó bẹ́ẹ̀ ti mi ò fi lè dárí jì í?’

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹwà ni ó jẹ́ ... láti gbójú fo ìrélànàkọjá.”​—Òwe 19:11.

  • Fi sùúrù àti ọgbọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ. Máa lo ọ̀rọ̀ náà “Mo” tó o bá ń sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wà á fi sọ pé, “O ò kì í ń ro ti ẹlòmíì mọ́ tìẹ rárá, oò pè mí kí n lè mọ ibi tó o wà,” o lè sọ pé, “Ọkàn mi kì í balẹ̀ tí mi ò bá mọ ibi tó o wà, pàápàá tí ilẹ̀ bá ti ṣú, mi ò mọ̀ bóyá àlááfíà lo wà.” Tó o bá ń fi sùúrù sọ̀rọ̀, ìyẹn máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kápá ìbínú rẹ.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.”​—Kólósè 4:6.

  • Fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ, fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tí ẹnì kejì rẹ fẹ́ sọ, kó o má sì dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu. Tó bá ti sọ̀rọ̀ tán, tún àwọn kókó tó wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ, kó o bàa lè rí i dájú pé ọ̀rọ̀ tó sọ yé ẹ dáadáa. Tó o bá ń ṣe báyìí, ó máa rọrùn fún ẹ láti kápá ìbínú rẹ.

    Ìlànà Bíbélì: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”—Jákọ́bù 1:19.

Tim àti Jennifer

“Tó o bá ń di ìbínú sínú, ìṣòro yẹn ò ní tán nílẹ̀, ọjọ́ kan sì ń bọ̀ tí wà á gbaná jẹ. Ohun tó dáa jù lọ ni pé kẹ́ ẹ jọ fara balẹ̀ yanjú ìṣòro náà. Lẹ́yìn tí èmi àti ọkọ mi bá ti yanjú ọ̀rọ̀ kan, àwa méjèèjì máa ń sọ pé, ‘Jẹ́ ká pa dà ṣe ara wa lọ́kan.’”​—Jennifer, àti ọkọ rẹ̀, Tim.

Jade àti Corey

“Ohun kan tí mo fẹ́ràn tí ọkọ mi máa ń ṣe ni pé, ó máa ń tẹ́tí sí mi, ó sì máa ń ka ọ̀rọ̀ mi sí. Kódà bí kò bá tiẹ̀ fara mọ́ èrò mi, ó ṣì máa ń gbọ́ tèmi. Tí mo bá sọ èrò mi, kì í jẹ́ kí n wo ara mi bí ẹni tí kò gbọ́n.”​—Jade, àti ọkọ rẹ̀, Corey.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́