ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 79
  • Ṣé Mo Ti Tó Ẹni Tó Ń Kúrò Nílé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Mo Ti Tó Ẹni Tó Ń Kúrò Nílé?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣàyẹ̀wò ìdí tó o fi fẹ́ ṣe é
  • Rò ó dáadáa
  • Ṣé Ó Ti Yẹ Kí N Kúrò Lọ́dọ̀ Àwọn Òbí Mi?
    Jí!—2010
  • Ṣé Mo Ti Tó Ẹni Tó Lè Lọ Dá Gbé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Ìgbà Tó Yẹ Kó O Pa Dà Sọ́dọ̀ Àwọn Òbí Rẹ
    Jí!—2015
  • Ìfẹ́sọ́nà—Apá Kìíní: Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 79
Ọ̀dọ́kùnrin kan ń di ẹrù rẹ̀, ó sì ń múra láti kúrò nílé

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Mo Ti Tó Ẹni Tó Ń Kúrò Nílé?

Téèyàn bá fẹ́ kó kúrò nílé, ó máa ń dùn mọ́ọ̀yàn, ó sì tún máa ń dáyà jáni. Báwo lo ṣe máa mọ̀ bóyá o ti tó ẹni tó ń dá gbé láyè ara ẹ̀?

  • Ṣàyẹ̀wò ìdí tó o fi fẹ́ ṣe é

  • Rò ó dáadáa

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Ṣàyẹ̀wò ìdí tó o fi fẹ́ ṣe é

Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó o fi lè pinnu pé o fẹ́ kúrò nílé, àmọ́ àwọn ìdí kan wà tí kò fi bẹ́ẹ̀ bọ́gbọ́n mu. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Mario gbà bẹ́ẹ̀, ó ní, “Torí pé mo fẹ́ sá fáwọn ojúṣe mi nínú ilé ni mo ṣe fẹ́ kó kúrò ńlé.”

Ṣó o fẹ́ gbọ́, ó ṣeé ṣe kí òmìnira tó o ní dín kù tó o bá kúrò nílé. Onya tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) sọ pé, “Tó o bá ti kúrò ńlé, ìwọ ni wàá máa tọ́jú ilé ẹ fúnra ẹ, ìwọ ni wàá máa dáná fúnra ẹ, tí wàá sì máa sanwó tibí sanwó tọ̀hún. Kò ní sí pé àwọn òbí ẹ ń bá ẹ fọwọ́ kún un!”

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ó yẹ kó o mọ ìdí tó o fi fẹ́ kúrò nílé kó o lè mọ̀ bóyá o ti tó ẹni tó ń kúrò nílé.

Rò ó dáadáa

Jésù sọ pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” (Lúùkù 14:28) Báwo lo ṣe lè “gbéṣirò lé ìnáwó náà” tó bá dọ̀rọ̀ kíkó kúrò ńlé? Yẹ ara ẹ wò lórí àwọn kókó yìí.

ṢÉ ỌMỌLÚÀBÍ NI Ẹ́ TÓ BÁ DỌ̀RỌ̀ KÁ NÁWÓ?

Bíbélì sọ pé: “Owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò.”​​—Oníwàásù 7:​12.

  • Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti fowó pa mọ́?

  • Ṣé yànfùyànfù lo máa ń náwó?

  • Ṣé o sábà máa ń yáwó lọ́wọ́ àwọn míì?

Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni lo dáhùn sí ìkankan nínú àwọn ìbéèrè yìí, a jẹ́ pé tó o bá lọ ń dá gbé, bóyá ni àbámọ̀ ò ní gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ ẹ!

“Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) ni ẹ̀gbọ́n mi nígbà tí wọ́n kúrò ńlé. Láàárín ọdún kan, wọ́n ti ná gbogbo owó tí wọ́n ń tọ́jú tán, báǹkì gbẹ́sẹ̀ lé mọ́tò wọn, wọn ò yá wọn lówó mọ́ torí wọ́n ti ba orúkọ ara wọn jẹ́; wọ́n wá ń bẹ̀ wá pé ká jẹ́ káwọn má pa dà bọ̀ nílé.”​​—Danielle.

Ohun tó o lè ṣe báyìí: Bi àwọn òbí ẹ léèrè iye tí wọ́n sábà máa ń ná lóṣù kan. Àwọn nǹkan wo ni wọ́n máa ń sanwó fún, báwo sì ni wọ́n ṣe ń ṣètò iye tó ń wọlé fún wọn kí wọ́n lè kájú ìnáwó wọn? Báwo ni wọ́n ṣe ń fowó pa mọ́?

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá kọ́ bó o ṣe lè náwó ní báyìí tó o ṣì wà nílé, ó máa jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe máa forí rọ́ ìṣòro ìnáwó tó o bá ti ń dá gbé.

ṢÉ O MÁA Ń KÓRA Ẹ NÍJÀÁNU?

Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.”​—Gálátíà 6:5.

  • Ṣé o máa ń fòní dónìí fọ̀la dọ́la?

  • Ṣé ó dìgbà táwọn òbí ẹ bá tó rán ẹ létí iṣẹ́ tó yẹ kó o ṣe kó o tó ṣe é?

  • Tó o bá jáde, ṣé o máa ń kọjá aago tí àwọn òbí ẹ bá dá fún ẹ pé kó o délé?

Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni lo dáhùn sí ìkankan nínú àwọn ìbéèrè yìí, ó ṣeé ṣe kó túbọ̀ nira fún ẹ láti máa hùwà ọmọlúàbí tó o bá ti ń dá gbé.

“Tó o bá ti dá wà, àwọn nǹkan kan wà tó jẹ́ pé kì í ṣe pó máa ń wù ẹ́ ṣe, àmọ́ o gbọ́dọ̀ wáyè fún un. Kò sẹ́ni tó máa sọ fún ẹ pé kó o ṣe àwọn nǹkan yẹn, àfi kó o ní in lọ́kàn pé o gbọ́dọ̀ ṣe é, kó o sì ṣètò bí wàá ṣe máa ṣe é déédéé.”​—Jessica.

Ohun tó o lè ṣe báyìí: Fún odindi oṣù kan, gbìyànjú láti rí i pé o ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ nínú ilé yín, bó bá ṣe lè pọ̀ tó. Bí àpẹẹrẹ, tọ́jú inú ilé fúnra ẹ, ìwọ ni kó o fọ aṣọ ẹ, lọ sọ́jà, máa dáná lálaalẹ́, kó o sì fọ abọ́ tẹ́ ẹ bá jẹun tán. Èyí máa jẹ́ kó o rí bí nǹkan ṣe máa rí tó o bá ti ń dá gbé.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá fẹ́ máa dá gbé láyè ara ẹ, ó ṣe pàtàkì kó o máa kóra ẹ níjàánu.

Ọ̀dọ́kùnrin kan ti fò jáde látinú ọkọ̀ òfuurufú kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá fẹ́ lo ohun tí wọ́n fi ń fò

Téèyàn bá kó kúrò ńlé láìmúra sílẹ̀, ṣe ló dà bí ẹni bẹ́ jáde látinú ọkọ̀ òfuurufú láìkọ́kọ́ kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ohun tí wọ́n fi ń fò lójú òfuurufú

ṢÉ O MÁA Ń LÈ KÁPÁ ÌMỌ̀LÁRA Ẹ?

Bíbélì sọ pé: “Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú . . . kúrò.”​—Kólósè 3:8.

  • Ṣé ó máa ń nira fún ẹ láti bá àwọn míì da nǹkan pọ̀?

  • Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti kápá ìbínú ẹ?

  • Ṣé ohun tí ìwọ bá ṣáà ti fẹ́ lo máa ń fẹ́ káwọn míì ṣe ṣáá?

Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni lo dáhùn sí ìkankan nínú àwọn ìbéèrè yìí, ó ṣeé ṣe kó o níṣòro tó o bá ń bá ọ̀rẹ́ rẹ míì gbé, ohun kan náà ló sì máa ṣẹlẹ̀ tó bá yá tó o bá ṣègbéyàwó.

“Ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn míì gbé ni kùdìẹ̀kudiẹ mi fara hàn. Mo rí i pé kò yẹ kí n máa retí kí àwọn míì ní àmúmọ́ra témi bá ń kanra torí pé ó ti rẹ̀ mí. Àfi kí n wá ọgbọ́n míì dá sí i tí mi ò fi ní pa àwọn míì lára.”​—Helena.

Ohun tó o lè ṣe báyìí: Kọ́ bí ìwọ àtàwọn òbí ẹ pẹ̀lú àwọn àbúrò àti ẹ̀gbọ́n ẹ á ṣe máa gbọ́ra yín yé. Ó ṣe tán, bó o bá ṣe ṣe sáwọn tẹ́ ẹ jọ ń gbé báyìí tí wọ́n bá ṣàṣìṣe máa pinnu bó o ṣe máa ṣe sí ẹnikẹ́ni tẹ́ ẹ bá jọ gbé lọ́jọ́ iwájú.

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Dídágbé láyè ara ẹni kì í ṣe ohun téèyàn lè fi kẹ́wọ́ torí pé ó ń sá fún ojúṣe, ohun tó gba kéèyàn múra sílẹ̀ ni. O ò ṣe bá àwọn tó ti ṣe irú ẹ̀ yọrí sọ̀rọ̀? Bi wọ́n pé, ká sọ pé wọ́n láǹfààní ẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, kí làwọn ohun tí wọn ì bá ṣe tàbí kí wọ́n má ṣe, tàbí kí lohun tó wù wọ́n kí wọ́n mọ̀ nígbà yẹn tí wọn ò mọ̀, àmọ́ tí wọ́n ti mọ̀ báyìí? Ó dáa kéèyàn gbé irú ìgbésẹ̀ yẹn tó bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì èyíkéyìí!

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Dapo

“Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló máa ń fojú kéré bó ṣe máa ń nira tó láti máa dá gbọ́ bùkátà ara wọn. Kì í ṣohun tó rọrùn láti rí ilé tówó ẹ̀ mọ níwọ̀n! Torí pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni ò mọ̀yẹn, ṣe ni wọ́n máa ń kánjú kúrò nílé lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn, . . . tó bá sì yá, ilé ọ̀hún náà ni wọ́n á pa dà sí.”​—Dapo.

Ashley

“Tí ọ̀dọ́ kan bá ń gbé ilé lọ́dọ̀ àwọn òbí ẹ̀, ó máa láǹfààní láti máa gba ojúṣe kún ojúṣe díẹ̀díẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi kún iṣẹ́ ilé tí wọ́n ń ṣe, kí wọ́n máa san lára owó táwọn òbí wọn fi ń gbọ́ bùkátà tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa dáná fún ìdílé wọn. Ṣe ni àwọn ìgbésẹ̀ kéékèèké yìí máa jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe máa ṣe tó o bá ti ń dá gbé.”​—Ashley.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́